ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 10/15 ojú ìwé 3-7
  • Máa Lépa Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Kó O Lè Ṣe Ara Rẹ Láǹfààní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Lépa Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Kó O Lè Ṣe Ara Rẹ Láǹfààní
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà Tí Nǹkan Tẹ̀mí Gbà Dára Ju Nǹkan Tara Lọ
  • Àwọn Ìlànà Tó Dára Jù Lọ Ni Bíbélì Ń Gbé Lárugẹ
  • Èrè Pọ̀ Nínú Lílépa Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí
  • Ǹjẹ́ Àǹfààní Tiẹ̀ Wà Nínú Kéèyàn Máa Lépa Ọrọ̀ Tẹ̀mí?
  • Máa Lépa Ọrọ̀ Tẹ̀mí Tí Kì Í Tán
  • Àwọn Ìwà Rere Tó Ń Mú Káyé Ẹni Dára
    Jí!—2014
  • Ọrọ̀ Ha Lè Mú Ọ Láyọ̀ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìlànà Ìwà Rere Tó Wà Títí Ayé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ojúlówó Aásìkí Ń Bọ̀ Nínú Ayé Tuntun ti Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 10/15 ojú ìwé 3-7

Máa Lépa Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Kó O Lè Ṣe Ara Rẹ Láǹfààní

“Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.”—Oníwàásù 5:10.

TÍ KÒÓKÒÓ-JÀN-ÁNJÀN-ÁN ẹní bá ti pọ̀ jù, ó lè kóni lọ́kàn sókè, èyí sì lè fa àìsàn, ó tiẹ̀ lè ṣekú pani nígbà míì pàápàá. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ìdílé kan ti dà rú nítorí pé ọkọ àti aya ti kọ ara wọn sílẹ̀. Àníyàn àṣejù nípa àwọn nǹkan ìní tara lohun tó sì sábà ń fa ìṣòro yìí. Tó bá sì jẹ́ pé àwọn nǹkan ìní tara ló jẹ ẹnì kan lógún jù, dípò tí onítọ̀hún yóò máa fi gbádùn àwọn nǹkan tó ní, bó ṣe máa ní púpọ̀ sí i ni yóò máa wá kiri láìka àkóbá tí èyí lè ṣe fún un sí. Ìwé kan sọ pé: “Gbogbo ayé ló fẹ́ di ọlọ́rọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tójú àwọn ọlọ́rọ̀ ń rí kúrò ní kèrémí.”

Téèyàn bá ń lépa nǹkan tara ṣáá ní gbogbo ìgbà, kò ní lè láyọ̀ tó yẹ kó ní. Nítorí pé ẹ̀dá èèyàn níṣòro yìí, nǹkan kan tó lágbára máa ń darí wọn, nǹkan náà sì ni ìpolówó ọjà! Àìmọye nǹkan ni wọ́n ń polówó lórí tẹlifíṣọ̀n àti lórí rédíò, wọ́n fẹ́ kó o ra àwọn nǹkan tó ò nílò àtàwọn nǹkan tágbára rẹ ò ká pàápàá. Kékeré sì kọ́ ni àkóbá tó lè tìdí àwọn nǹkan wọ̀nyí jáde.

Téèyàn bá lọ kẹ́ ara rẹ̀ bà jẹ́, èyí lè ní ipa téèyàn ò ní tètè fura sí lórí ẹni, ó sì lè ṣàkóbá fúnni. Bí àpẹẹrẹ, Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” (Òwe 14:30) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kòókòó-jàn-ánjàn-án, àníyàn àti wàhálà àtikó-ọrọ̀-jọ lè fa àìsàn síni lára ó sì lè ba ayọ̀ èèyàn jẹ́. Àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn ò ní lọ déédéé mọ́ tó bá jẹ́ pé bá a ṣe máa ní àwọn ohun ìní tara ló ń gbà wá lọ́kàn. Tí ìdílé ẹnì kan àti ìgbésí ayé rẹ̀ láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà bá sì ń jó àjórẹ̀yìn, ìgbésí ayé rẹ̀ látòkèdélẹ̀ yóò dojú rú.

Ọ̀nà Tí Nǹkan Tẹ̀mí Gbà Dára Ju Nǹkan Tara Lọ

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ ìyànjú yìí pé: “Ẹ . . . jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” (Róòmù 12:2) Ayé fẹ́ràn àwọn tó bá ń ṣe nǹkan lọ́nà tí ayé gbà ń ṣe nǹkan. (Jòhánù 15:19) Ayé fẹ́ ṣe ohun tó máa wù ọ́ láti rí, tó máa wù ọ́ láti fọwọ́ kàn, tó máa wù ọ́ láti tọ́ wò, tó máa wù ọ́ láti gbóòórùn tó sì máa wù ọ́ láti gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni o, ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì nìkan ni wọ́n fẹ́ kó o máa lé. Àwọn nǹkan tó jẹ́ “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” nìkan layé ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kí ìwọ àtàwọn mìíràn bàa lè máa lépa nǹkan ìní tara.—1 Jòhánù 2:15-17.

Àmọ́ ṣá o, àwọn ohun kan wà tó ṣe pàtàkì gan-an ju owó, òkìkí, àti ọrọ̀ lọ. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, kò sóhun tó wà láyé yìí tí Sólómọ́nì Ọba ò ní tán. Ó ní ilé lóríṣiríṣi, àìmọye ọgbà, ohun ọ̀gbìn, ìránṣẹ́, ẹran ọ̀sìn, àwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó sì tún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà àti fàdákà. Sólómọ́nì ní ohun ìní ju gbogbo àwọn tó gbáyé ṣáájú rẹ̀ lọ. Ọlà rẹ̀ pọ̀ jaburata. Gbogbo nǹkan tọ́kàn èèyàn lè fà sí ni Sólómọ́nì fẹ́rẹ̀ẹ́ ní tán. Síbẹ̀, nígbà tó wo gbogbo nǹkan tó gbéṣe láyé, ó ní: “Asán ni gbogbo rẹ̀ àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 2:1-11.

Ọgbọ́n tó ju ọgbọ́n lọ tí Jèhófà fún Sólómọ́nì mú kí ó mọ̀ pé ìgbà téèyàn bá lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí ló máa tó ní ìtẹ́lọ́rùn. Ó kọ ọ́ pé: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníwàásù 12:13.

Ìṣúra tó wà nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeyebíye ju wúrà tàbí fàdákà lọ. (Òwe 16:16) Bí a ti máa ń ṣàwárí àwọn ohun iyebíye, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn òtítọ́ gidi wà nínú Bíbélì tó o lè ṣàwárí wọn. Ṣé wàá wá inú Bíbélì bí ìgbà téèyàn ń walẹ̀ kó o lè rí àwọn nǹkan wọ̀nyí? (Òwe 2:1-6) Ohun tí Ẹlẹ́dàá, Ẹni tí àwọn ohun ṣíṣeyebíye wọ̀nyí ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá rọ̀ ọ́ pé kó o ṣe nìyẹn, òun yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Àmọ́, báwo ni yóò ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́?

Jèhófà jẹ́ ká mọ òtítọ́ tó ṣeyebíye nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀. (Sáàmù 1:1-3; Aísáyà 48:17, 18; Mátíù 24:45-47; 1 Kọ́ríńtì 2:10) Tó o bá ń ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun ṣíṣeyebíye wọ̀nyí, yóò jẹ́ kó o lè fi làákàyè rẹ yan ọ̀nà tó dára tó sì ń ṣeni láǹfààní jù lọ. Kò sì ní ṣòro fún wa láti ṣe ìyẹn nítorí pé Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa, mọ ohun tá a nílò ká lè láyọ̀ ní ti tòótọ́.

Àwọn Ìlànà Tó Dára Jù Lọ Ni Bíbélì Ń Gbé Lárugẹ

Ìbáwí tàbí ìmọ̀ràn tó yè kooro tó wà nínú Bíbélì ṣeé tẹ̀ lé, kò sì láfiwé. Kò sóhun tó dára tó ọ̀nà tó sọ pé kéèyàn máa gbà hùwà. Ìmọ̀ràn Bíbélì ò sì kùtà rí. Gbogbo ìgbà táwọn èèyàn fi í sílò ló ń wúlò. Àwọn kan lára àwọn ìmọ̀ràn tó yè kooro tí Bíbélì fúnni rèé: ó ní ká tẹpá mọṣẹ́, ká má ṣàbòsí, ká má ṣe máa ná owó nínàákúnàá, ká má sì ṣọ̀lẹ.—Òwe 6:6-8; 20:23; 31:16.

Bákan náà ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ràn rere kan, ó ní: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè.”—Mátíù 6:19, 20.

Bí ọ̀rọ̀ ìyànjú yẹn ṣe wúlò ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà ló wúlò lóde òní. Dípò tí a óò fi jẹ́ kí kíkó ọrọ̀ jọ gbà wá lọ́kàn, á ṣe wá láǹfààní nísinsìnyí tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ. Ohun tó máa jẹ́ kó lè ṣeé ṣe ni pé ká máa to ìṣúra tẹ̀mí jọ, èyí tó máa jẹ́ ká lè ní ayọ̀ tòótọ́ àti ìtẹ́lọ́rùn nígbèésí ayé wa. Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Nípa kíka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti fífi ohun tá à ń kọ́ ṣèwà hù ni.

Èrè Pọ̀ Nínú Lílépa Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí

Àwọn ìlànà tẹ̀mí máa ń ṣeni láǹfààní nípa tara àti nípa tẹ̀mí tá a bá lò ó bó ṣe yẹ. Gẹ́gẹ́ bí agbòjò ṣe máa ń dáàbò boni nígbà òjò, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìlànà tó yè kooro ṣe máa ń dáàbò bò wá ní ti pé ó ń jẹ́ ká mọ àkóbá tí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lè ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé: “Àmọ́ ṣá o, àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:9, 10.

Ìfẹ́ ọrọ̀ táwọn èèyàn ní ló ń fẹjú mọ́ wọ́n tí wọ́n fi ń lépa ọrọ̀, ipò àti agbára púpọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé nípa èrú àti ìwà àìṣòótọ́ lọ́wọ́ wọn fi ń tẹ ohun tí wọ́n ń lé. Lílépa àwọn nǹkan tara máa ń jẹ́ kéèyàn fi àkókò ṣòfò, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn lo okun, àti agbára rẹ̀ dà nù. Ó tiẹ̀ lè máà jẹ́ kéèyàn sùn lóru pàápàá. (Oníwàásù 5:12) Téèyàn bá fẹ́ máa kó ọrọ̀ jọ ṣáá, kì í jẹ́ kéèyàn tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Jésù Kristi, ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ náà tó tíì gbé ayé rí sọ ọ̀nà tó dára jù lọ, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Ó mọ̀ pé ọrọ̀ tẹ̀mí máa ń jẹ́ kéèyàn ní èrè tí kì í tán àti pé ó ṣe pàtàkì gan-an ju àwọn nǹkan tara tó máa ń wà fúngbà díẹ̀.—Lúùkù 12:13-31.

Ǹjẹ́ Àǹfààní Tiẹ̀ Wà Nínú Kéèyàn Máa Lépa Ọrọ̀ Tẹ̀mí?

Greg rántí ohun kan tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àwọn òbí mi sapá gidigidi, wọ́n fẹ́ mú mi gbà pé àwọn nǹkan tẹ̀mí kì í ṣe nǹkan téèyàn lè máa lépa. Àmọ́, lílé tí mò ń lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ torí pé mi ò kó ara mi lọ́kàn sókè pé mo fẹ́ dọlọ́rọ̀.”

Àwọn nǹkan tẹ̀mí tún máa ń mú kí àjọṣe tó wà láàárín ẹni àtàwọn ẹlòmíràn túbọ̀ dára sí i. Irú ẹni tó o jẹ́ ló mú káwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ fẹ́ràn ẹ̀ kì í ṣe nítorí ohun tó o ní. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.” (Òwe 13:20) Yàtọ̀ síyẹn, ọgbọ́n àti ìfẹ́ ló ń mú kí ìdílé ṣàṣeyọrí, kì í ṣe àwọn nǹkan ìní tara.—Éfésù 5:22–6:4.

Kò sẹ́ni tí wọ́n bí ìlànà nípa àwọn ohun tó dára mọ́. Ńṣe la máa ń kọ́ àwọn ìlànà wọ̀nyí, yálà lára àwọn ojúgbà wa tàbí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ẹ̀kọ́ tá a bá kọ́ látinú Bíbélì lè yí èrò tá a ní nípa àwọn nǹkan tara padà. Don tó ń ṣiṣẹ́ ní báńkì nígbà kan rí sọ pé: “Àwọn ìlànà náà ràn mí lọ́wọ́ láti tún inú rò, àwọn nǹkan kòṣeémáàní tí mo ní sì ti wá tẹ́ mi lọ́rùn.”

Máa Lépa Ọrọ̀ Tẹ̀mí Tí Kì Í Tán

Èrè tó wà pẹ́ títí léèyàn máa ní tó bá ń lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí, kì í ṣe èrè tó máa wà fúngbà díẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé: “Àwọn ohun tí a ń rí [ìyẹn àwọn nǹkan tara] jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ohun tí a kò rí [ìyẹn àwọn nǹkan tẹ̀mí] jẹ́ fún àìnípẹ̀kun.” (2 Kọ́ríńtì 4:18) Òótọ́ ni pé àwọn nǹkan tara lè mú ká gbádùn àwọn nǹkan tí ọkàn wa fẹ́ lójú ẹsẹ̀, àmọ́ ìwọra ò lè ṣeni láǹfààní títí lọ. Títí ayé làwọn nǹkan tẹ̀mí sì máa fi wà.—Òwe 11:4; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

Bíbélì sọ pé ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tó gbòde kan láyé ìsinyìí kò dára. Ó tún kọ́ wa pé kí á yẹra fún ojúkòkòrò nípa jíjẹ́ kí ojú wa mú ọ̀nà kan, kí ó máa wo àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn ọrọ̀ tẹ̀mí. (Fílípì 1:10) Ó jẹ́ ká mọ ohun tí ìwọra jẹ́ gan-an, pé ó jẹ́ sísọ ara ẹni di òrìṣà. Bá a ṣe ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù, ńṣe layọ̀ wa ń pọ̀ sí i. Bí a óò ṣe máa fún àwọn ẹlòmíràn ní nǹkan la ó máa rò kì í ṣe bá a ṣe máa rí nǹkan gbà lọ́wọ́ wọn. Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ yìí lágbára gan-an tó fi mú ká fi àwọn nǹkan tẹ̀mí rọ́pò ayé jíjẹ!

Òótọ́ ni pé owó máa ń dáàbò boni dé ìwọ̀n àyè kan. (Oníwàásù 7:12) Àmọ́, Bíbélì sọ ní kedere pé: “Owó tó o ní lè lọ ní ìṣẹ́jú akàn, bíi pé ó hu ìyẹ́ tá sì wá fò lọ bí idì.” (Òwe 23:5, TEV) Nítorí àtiní ọrọ̀ púpọ̀ sí i, àwọn èèyàn ti sọ àwọn ohun pàtàkì nù, àwọn nǹkan bí ìlera ara, ìdílé wọn, àní ẹ̀rí ọkàn rere pàápàá tí èyí sì wá yọrí sí àgbákò. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí ń fún wa làwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù téèyàn ń fẹ́, ìyẹn ìfẹ́, ìgbésí ayé tó nítumọ̀, àti ìjọsìn Jèhófà, Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́. Ó tún fi ẹsẹ̀ wa lé ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun nígbà tí ìran èèyàn yóò di pípé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé—ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún wa nìyẹn.

Láìpẹ́, gbogbo nǹkan táráyé ń retí yóò dé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. (Sáàmù 145:16) Nígbà yẹn, gbogbo ayé yóò “kún fún ìmọ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 11:9) Nǹkan tẹ̀mí yóò wá gbilẹ̀. A ò ní gbúròó ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti gbogbo wàhálà tó ti dá sílẹ̀ mọ́ láé. (2 Pétérù 3:13) Nígbà náà, àwọn nǹkan tó mú kí ayé dùn ún gbé, ìyẹn ìlera pípé, iṣẹ́ tó tẹ́ni lọ́rùn, ìgbádùn tó yẹ ọmọlúwàbí, àjọṣe ìdílé tó dán mọ́rán, àti àjọṣe tó wà pẹ́ títí pẹ̀lú Ọlọ́run, yóò máa múnú aráyé dùn títí láé.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Má Ṣe Ná Owó Ẹ Nínàákúnàá O!

Mọ Ohun Tó O Nílò. Jésù kọ́ wa láti máa gbàdúrà pé: “Fún wa ní oúnjẹ wa fún òòjọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí òòjọ́ ń béèrè.” (Lúùkù 11:3) Má rò pé gbogbo nǹkan tí ọkàn rẹ bá fẹ́ lo gbọ́dọ̀ ní o. Má gbà gbé pé àwọn ohun tó o ní kọ́ ló máa fún ọ ní ìwàláàyè.—Lúùkù 12:16-21.

Ṣètò Bó O Ṣe Máa Náwó Ẹ. Má ṣe ra ohun tó ò ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ pé o fẹ́ rà. Bíbélì sọ pé “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Jésù gba àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n kọ́kọ́ ṣírò iye tó máa ná wọn kí wọ́n tó dáwọ́ lé ìnáwó èyíkéyìí.—Lúùkù 14:28-30.

Má Tọrùn Bọ Gbèsè. Tó bá ṣeé ṣe, máa tọ́jú owó pa mọ́ tó o máa fi ra nǹkan dípò tí wàá fi máa ra nǹkan àwìn. Ìwé Òwe sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí pé: “Ayá-nǹkan . . . ni ìránṣẹ́ awínni.” (Òwe 22:7) Tó o bá ń kó ara rẹ níjàánu, tó ò sì náwó kọjá iye tó ń wọlé fún ọ, wàá lè ra nǹkan tó jọjú lọ́jọ́ iwájú.

Má Ṣe Fi Nǹkan Ṣòfò. Máa tọ́jú àwọn nǹkan ìní rẹ dáadáa kó má bàa tètè bà jẹ́, tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ o ò ní máa fi nǹkan ṣòfò. Ọ̀nà tí Jésù gbà lo àwọn nǹkan fi hàn pé ó mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́ nǹkan lò.—Jòhánù 6:10-13.

Mọ Ohun Tó Yẹ Kó O Kọ́kọ́ Ṣe. Ńṣe ni ọlọ́gbọ́n èèyàn máa ń ‘ra àkókò padà’ kó lè gbájú mọ́ àwọn nǹkan tó túbọ̀ ṣe pàtàkì.—Éfésù 5:15, 16.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọ̀nà Kan Wà Tó Dára Ju Kéèyàn Fi Ọ̀rọ̀ Ara Rẹ̀ Kọ́gbọ́n Lọ

Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ síni rí, yálà èyí tó dára àbí èyí tí kò dára, lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gidi. Àmọ́ ṣé òótọ́ lọ̀rọ̀ táwọn èèyàn máa ń sọ pé ‘bí ò ṣeni a kì í gbọ́n?’ Rárá o, ibì kan wà tá a ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dára gan-an gbà. Onísáàmù sọ ọ́ nígbà tó gbàdúrà pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.”—Sáàmù 119:105.

Kí nìdí tí kíkẹ́kọ̀ọ́ látinú ìtọ́ni Ọlọ́run fi sàn ju kíkẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó bá ṣẹlẹ̀ síni lọ? Ìdí kan ni pé, tó bá jẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ síni nìkan lèèyàn fi ń kọ́gbọ́n, ó máa ń kóni sí yọ́ọ́yọ́ọ́ ó sì máa ń fa ọ̀pọ̀ ìrora. Àti pé, kò pọn dandan kéèyàn jìyà kó tó gbọ́n. Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—Aísáyà 48:18.

Ohun kan tó mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ta gbogbo orísun ìmọ̀ràn tó kù yọ ni pé, inú rẹ̀ ni àkọsílẹ̀ tó tíì pẹ́ jù lọ tó sì pé pérépéré jù lọ nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọmọ èèyàn wà. O ò ní ṣàìgbà pé ó sàn kéèyàn kọ́gbọ́n lára àwọn tó ṣe dáadáa àtàwọn tó ṣàṣìṣe ju pé kí àwa fúnra wa ṣe irú àṣìṣe tí wọ́n ṣe. (1 Kọ́ríńtì 10:6-11) Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, nínú Bíbélì, Ọlọ́run fún wa láwọn òfin àtàwọn ìlànà tó dára gan-an tó sì ṣeé gbára lé pátápátá. “Òfin Jèhófà pé . . . Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.” (Sáàmù 19:7) Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n pé, kíkẹ́kọ̀ọ́ látinú ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti kẹ́kọ̀ọ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì nìkan ni ayé fẹ́ kó o máa lé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìṣúra tó ṣeyebíye ju wúrà àti fàdákà lọ ló wà nínú Bíbélì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́