ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 6/15 ojú ìwé 4-7
  • Ìlànà Ìwà Rere Tó Wà Títí Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìlànà Ìwà Rere Tó Wà Títí Ayé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ni Orísun Àwọn Ànímọ́ Bẹ́ẹ̀?
  • Ibi Tá A Ti Lè Rí Ìlànà Ìwà Híhù Tó Ṣeé Gbára Lé
  • Ṣé Wàá Fẹ́ Jàǹfààní Rẹ̀?
  • Àwọn Ìwà Rere Tó Ń Mú Káyé Ẹni Dára
    Jí!—2014
  • Ìdí Tí Ìwà Ọmọlúwàbí Fi Ṣe Pàtàkì
    Jí!—2019
  • Ìlànà Ìwà Híhù Ò Dúró Sójú Kan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Máa Lépa Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Kó O Lè Ṣe Ara Rẹ Láǹfààní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 6/15 ojú ìwé 4-7

Ìlànà Ìwà Rere Tó Wà Títí Ayé

KÒ SÍ àwùjọ èèyàn tí kò láwọn òfin àti ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé nípa ohun tó jẹ́ ìwà ọmọlúwàbí. Ǹjẹ́ ìwọ alára ò gbà pé kárí ayé làwọn èèyàn ń fojú pàtàkì wo àwọn ànímọ́ bí ìṣòtítọ́, inúure, ìyọ́nú àti ẹ̀mí ìfẹ́nifẹ́re?

Ta Ni Orísun Àwọn Ànímọ́ Bẹ́ẹ̀?

Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù gbé láàárín oríṣi ẹ̀yà mẹ́ta tí kálukú wọn ní ìlànà ìwà híhù ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Àwọn ẹ̀yà náà ni Júù, àwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù. Sọ́ọ̀lù rí i pé yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òfin àti àṣà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀yà yẹn sọ pé káwọn èèyàn máa tẹ̀ lé, olúkúlùkù èèyàn ló ní ohun àdámọ́ni kan tó jẹ́ atọ́nà rẹ̀ nínú ìwà híhù, ìyẹn ẹ̀rí ọkàn. Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù di Kristẹni tí wọ́n wá ń pè é ní àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó kọ̀wé pé: “Nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tí kò ní òfin bá ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá [ìyẹn “níbàámu pẹ̀lú ọgbọ́n inú ẹ̀dá,” Bíbélì The New Testament in Modern Speech], àwọn ènìyàn wọ̀nyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní òfin, jẹ́ òfin fún ara wọn. Àwọn gan-an ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀ràn òfin hàn gbangba pé a kọ ọ́ sínú ọkàn-àyà wọn, nígbà tí ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí.”—Róòmù 2:14, 15.

Àmọ́ ṣé “ọgbọ́n inú ẹ̀dá” nìkan tó láti máa fi mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́? Ìwọ alára lè ti rí i látinú ìtàn ẹ̀dá èèyàn pé, ìkùnà ọmọ èèyàn, yálà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kò lóǹkà. Èyí ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn rí i pé a nílò ìtọ́sọ́nà láti orísun tó ga ju tọmọ èèyàn lọ ká tó lè ní ìlànà ìwà híhù àtàtà tá a ó máa tẹ̀ lé nígbèésí ayé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò sì gbà pé Ẹlẹ́dàá aráyé gan-an lẹni tó tọ́ kó fún wa nírú àwọn ìlànà tó wúlò títí ayé bẹ́ẹ̀. Dókítà kan tó ń jẹ́ Carl Jung sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Ohun Téèyàn Ò Mọ̀ Nípa Ara Rẹ̀ (Gẹ̀ẹ́sì), pé: “Ẹni tí kò bá gbára lé Ọlọ́run kò ní lè dènà onírúurú ìdẹwò inú ayé yìí.”

Ohun tí ọ̀gbẹ́ni yìí sọ bá ohun tí wòlíì ìgbàanì kan sọ mu, ó ní: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ẹlẹ́dàá wa sọ pé: ‘Èmi ni Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.’—Aísáyà 48:17.

Ibi Tá A Ti Lè Rí Ìlànà Ìwà Híhù Tó Ṣeé Gbára Lé

Inú Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ìwé akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ìwà rere táwọn èèyàn ní lọ́wọ́ jù lọ láyé, la ti mú òótọ́ ọ̀rọ̀ méjì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ fà yọ yìí. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jákèjádò ayé, títí kan àwọn tí kì í ṣe Kristẹni àtàwọn tí ò ṣẹ̀sìn kankan, ló ti ka Ìwé Mímọ́ láti lè ní ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ òye. Akéwì ọmọ ilẹ̀ Jámánì kan tó ń jẹ́ Johann Wolfgang von Goethe sọ pé: “Ní tèmi, mo fẹ́ràn Bíbélì mo sì bọ̀wọ̀ fún un gan-an, torí òun ló jẹ́ kí n mọ èyí tó pọ̀ jù nínú ìwà dáadáa tí mò ń hù.” A rí i kà pé aṣáájú ẹ̀sìn Híńdù kan tó ń jẹ́ Mohandas Gandhi sọ pé: “Ẹ rí i dájú pé ẹ mọ ẹ̀kọ́ inú Ìwàásù Lórí Òkè [tó jẹ́ ara ẹ̀kọ́ tí Jésù Kristi kọ́ni nínú Bíbélì] ní àmọ̀dunjú . . . Torí pé gbogbo wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan lẹ̀kọ́ yẹn wà fún.”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan, sọ ipa pàtàkì tí Ìwé Mímọ́ ń kó nínú pípèsè àwọn ìlànà tó ṣeé gbára lé, ó ní: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni.” (2 Tímótì 3:16) Ṣé bẹ́ẹ̀ ni lóòótọ́?

Ìwọ fúnra rẹ̀ ò ṣe yẹ̀ ẹ́ wò? Wo àwọn ìlànà tá a tò sí ojú ewé tó tẹ̀ lé èyí. Ṣàkíyèsí ìwà dáadáa tí wọ́n ń gbìn síni lọ́kàn. Ṣàṣàrò lórí bí àwọn ìwà tí wọ́n ń kọ́ni ṣe lè mú káyé rẹ àti àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn èèyàn túbọ̀ dáa sí i.

Ṣé Wàá Fẹ́ Jàǹfààní Rẹ̀?

Ńṣe làwọn ọ̀rọ̀ tá a fà yọ yìí wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ díẹ̀ lára ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn wíwúlò tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí, onírúurú ìkìlọ̀ ló tún wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa èròkerò, ọ̀rọ̀ tí ò dáa àti ìwà ìbàjẹ́ tó máa ń bayé ẹni jẹ́.—Òwe 6:16-19.

Ká sòótọ́, àwọn ohun tó ti sọ nù mọ́ aráyé lápapọ̀ lọ́wọ́ lẹ̀kọ́ Bíbélì ń kọ́ni, ìyẹn ìmọ̀ràn tó ń jẹ́ káwọn èèyàn lè dẹni tó ń tẹ̀ lé ìlànà ìwà híhù tó dára jù lọ. Àyípadà sí rere máa ń bá àwọn tí wọ́n bá gba àwọn ohun tí Bíbélì ń kọ́ni yìí tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé e. Ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ronú máa ń dára sí i. (Éfésù 4:23, 24) Ẹ̀mí tó ń mú wọn ṣe nǹkan máa ń sunwọ̀n sí i. Mímọ̀ tí ọ̀pọ̀ mọ ìlànà ìwà híhù tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nínú Bíbélì ti mú kí wọ́n pa ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ẹ̀tanú àti ìkórìíra rẹ́ lọ́kàn wọn. (Hébérù 4:12) Ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ àti ìwà rere tó ń gbìn síni lọ́kàn ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn jáwọ́ nínú ìwà ipá àti ìwà burúkú gbogbo kí wọ́n sì di ọmọlúwàbí èèyàn.

Bẹ́ẹ̀ ni o, ìlànà ìwà híhù inú Bíbélì ti jẹ́ kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn borí àwọn ìwà àti ìṣe burúkú tó ti wọ̀ wọ́n lẹ́wù, èyí tó jẹ́ pé ó ti sọ ayé ẹlòmíì dìdàkudà. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Kì í ṣe ìwà wọn nìkan ni ẹ̀kọ́ Bíbélì ti yí padà, ó tún yí ọkàn wọn, irú àwọn nǹkan tí wọ́n ń retí, àti ìdílé wọn pàápàá padà. Bó ti wù káyé bà jẹ́ tó, a ṣì ń rí àwọn èèyàn jákèjádò ayé tó ń yí padà dẹni rere. Irú àyípadà bẹ́ẹ̀ kò sì ní yéé wáyé. Bíbélì ní: “Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Aísáyà 40:8.

Ǹjẹ́ ìwọ alára á fẹ́ jàǹfààní látinú “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa”? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti jẹ́ kó o mọ àwọn ìlànà Bíbélì àti bó o ṣe máa lò wọ́n lọ́nà tó máa ṣe ọ́ láǹfààní. Bó o bá ń gbé ìgbé ayé rẹ níbàámu pẹ̀lú irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ wàá rí ojú rere Ọlọ́run nísinsìnyí, wàá sì tún ní ìyè àìnípẹ̀kun, níbi tí wàá ti máa lo ìlànà ìwà híhù tí Ọlọ́run fi lélẹ̀, èyí tó wúlò títí ayé.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

ÀWỌN ÌLÀNÀ ÌWÀ RERE TÓ WÀ TÍTÍ AYÉ

Òfin Pàtàkì. “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn; ní tòótọ́, èyí ni ohun tí Òfin àti àwọn Wòlíì túmọ̀ sí.”—Mátíù 7:12.

Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ. “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) “Ìfẹ́ kì í ṣiṣẹ́ ibi sí aládùúgbò ẹni; nítorí náà, ìfẹ́ ni ìmúṣẹ òfin.”—Róòmù 13:10.

Bu ọ̀wọ̀ àti iyì fún ọmọnìkejì rẹ. “Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.”—Róòmù 12:10.

Máa wá àláàfíà. “Ẹ . . . pa àlàáfíà mọ́ láàárín ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Máàkù 9:50) “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) “Ẹ jẹ́ kí a máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà.”—Róòmù 14:19.

Lẹ́mìí ìdáríjì. “Kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.” (Mátíù 6:12) “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà.”—Éfésù 4:32.

Jẹ́ adúróṣinṣin, olóòótọ́. “Jẹ́ olóòótọ́ sí aya rẹ, òun nìkan ni kó sì jẹ́ olólùfẹ́ rẹ. . . . Jẹ́ kí aya rẹ máa múnú ẹ dùn, kó o sì máa gbádùn ọmọbìnrin tó o fẹ́ . . . Jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ máa fún ọ láyọ̀; kí ìfẹ́ rẹ̀ máa ràdọ̀ bò ọ́. . . . Kínní ṣe tí wàá tún fi máa wá fa ojú obìnrin mìíràn mọ́ra? Kí wá nìdí tí wàá fi jẹ́ kí aya aláya máa wọ̀ ọ́ lójú?” (Òwe 5:15-20, Bíbélì Today’s English Version) “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” (Lúùkù 16:10) “Ohun tí a ń retí nínú àwọn ìríjú ni pé kí a rí ènìyàn ní olùṣòtítọ́.”—1 Kọ́ríńtì 4:2.

Má ṣàbósì. “Mo ha lè mọ́ níwà pẹ̀lú àwọn òṣùwọ̀n burúkú àti pẹ̀lú àpò tí ó kún fún òkúta àfiwọn-ìwúwo tí a fi ń tanni jẹ?” (Míkà 6:11) “Àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé a ní ẹ̀rí-ọkàn aláìlábòsí, gẹ́gẹ́ bí a ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.

Máa ṣòótọ́, má ṣojúsàájú. “Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere, kí ẹ sì fún ìdájọ́ òdodo láyè ní ẹnubodè.” (Ámósì 5:15) “Ẹ bá ara yín sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì. Ẹ fi òtítọ́ àti ìdájọ́ àlàáfíà ṣe ìdájọ́ yín ní ẹnubodè yín.” (Sekaráyà 8:16) “Nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.”—Éfésù 4:25.

Jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, má ya ọ̀lẹ. “Ìwọ ha ti rí ọkùnrin tí ó jáfáfá nínú iṣẹ́ rẹ̀? Iwájú àwọn ọba ni ibi tí yóò dúró sí.” (Òwe 22:29) “Ẹ má ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ àmójútó yín.” (Róòmù 12:11) “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.”—Kólósè 3:23.

Jẹ́ oníwà tútù, oníyọ̀ọ́nú, onínúure. “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.”—Kólósè 3:12.

Máa fi ire ṣẹ́gun ibi. “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:44) “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.”—Róòmù 12:21.

Fi gbogbo agbára rẹ sin Ọlọ́run. “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní.”—Mátíù 22:37, 38.

[Àwọn àwòrán]

Títẹ̀lé ìlànà ìwà híhù tí Bíbélì ń kọ́ni máa ń jẹ́ kí àárín tọkọtaya dùn, kí ayọ̀ wà nínú ìdílé ẹni, kéèyàn sì láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́