Ìlànà Ìwà Híhù Ò Dúró Sójú Kan
ÌTÀN àtayébáyé kan sọ pé ọ̀mọ̀ràn kan tó ń jẹ́ Diogenes tó ń gbé nílùú Áténì ní ọ̀rúndún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni ń wá ẹni tó jẹ́ oníwà mímọ́. Wọ́n lọ́rọ̀ náà ká a lára débi pé ó tanná sí àtùpà ó ń káàkiri lọ́sàn-án gangan, síbẹ̀ kò rí.
Bóyá ìtàn yìí rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ o, a ò lè sọ torí a ò rí ẹ̀rí kankan nípa rẹ̀. Àmọ́, ká ní ayé òde òní ni Diogenes ń wá ẹni tó jẹ́ oníwà mímọ́ ni, ìlọ́po ìlọ́po wàhálà yẹn ni yóò ṣe kó tó lè rí. Ńṣe ló dà bíi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ọ sétí rárá pé ó yẹ kí gbogbo èèyàn máa tẹ̀ lé ìlànà ìwà híhù kan pàtó. Ìgbà gbogbo làwọn oníròyìn máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà ìbàjẹ́ táwọn èèyàn ń hù, yálà lọ́ọ̀dẹ̀ ilé wọn, lágbo àwọn tó ń ṣèjọba, nídìí iṣẹ́ ẹni, níbi ìdíje, láàárín àwọn oníṣòwò, àtàwọn ibòmíì gbogbo. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ọmọlúwàbí tó ti wà látayébáyé làwọn èèyàn ò kà sí mọ́. Kódà, wọ́n ń tún àwọn ìlànà ìwà híhù táwọn èèyàn ti mọ̀ tipẹ́tipẹ́ gbé yẹ̀ wò, wọ́n á ní kò bóde mu mọ́. Àwọn ẹlòmíì sì gbà pé àwọn ìlànà ìwà rere kan dáa, àmọ́ wọn kì í tẹ̀ lé e.
Ọ̀gbẹ́ni Alan Wolfe tó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀sìn láwùjọ ẹ̀dá sọ pé: “Ayé ìgbà tí ìmọ̀ àwọn èèyàn ṣọ̀kan nípa irú ìwà tó bójú mu ti kọjá.” Ó tún sọ pé: “Kò tíì ṣẹlẹ̀ báyìí rí pé káwọn èèyàn ní gbogbo gbòò gbà pé àwọn ìlànà àti ètò àbáláyé ò ṣeé gbára lé fún ìtọ́sọ́nà.” Nígbà tí ìwé ìròyìn Los Angeles Times ń sọ̀rọ̀ nípa ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ó tọ́ka sí ọ̀rọ̀ kan tí onímọ̀ èrò orí náà Jonathan Glover sọ, pé ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó jẹ́ kí ìwà ipá gbòde kan lóde òní ni àìtẹ̀lé òfin ìwà híhù nínú ẹ̀sìn àti láwùjọ.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò fohùn ṣọ̀kan nípa irú ìwà tó yẹ ọmọlúwàbí láwùjọ, àwọn kan ṣì ń wá bí wọ́n á ṣe rí ìlànà nípa irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù. Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, Federico Mayor tó fìgbà kan jẹ́ olùdarí àgbà fún Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lórí Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀, sọ pé: “Ní báyìí, ọ̀nà àtimọ àwọn ìwà tó yẹ ọmọlúwàbí ló jẹ aráyé lógún jù.” Àmọ́ ṣá o, pípa táráyé pa ìwà ọmọlúwàbí tì kò fi hàn pé kò sí ìlànà ìwà híhù tó dáa tó yẹ kéèyàn máa tẹ̀ lé.
Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ gbogbo èèyàn máa lè fìmọ̀ ṣọ̀kan nípa ìlànà ìwà híhù tó yẹ káráyé máa tẹ̀ lé? Rárá o. Bí ò bá wá sí ìlànà ìwà híhù kan pàtó tí gbogbo èèyàn fohùn ṣọ̀kan lé lórí láti máa tẹ̀ lé, ta ló máa lè sọ pé ìwà kan ló dáa tàbí pé ọ̀kan ni ò dáa? Abájọ tí ẹ̀mí kóníkálukú máa ṣe ohun tó tọ́ lójú ẹ̀ fi gbòde lónìí. Àmọ́, ó hàn gbangba pé ńṣe ni irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ ń mú káwọn èèyàn sọ ìwà ọmọlúwàbí nù dípò kí ìwà wọn dáa sí i.
Ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà Paul Johnson tó jẹ́ òpìtàn sọ pé ẹ̀mí kóníkálukú máa ṣe ohun tó tọ́ lójú ẹ̀ yìí ti “ṣàkóbá fún . . . ẹ̀mí dáadáa táráyé ní nípa ìwà tó yẹ ọmọlúwàbí àti ìlànà ìwà híhù tó dára,” tó jọ pé ó wà láyé ṣáájú ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún.
Ǹjẹ́ ó wá ṣeé ṣe kéèyàn rí “ìlànà ìwà híhù tó dára” tàbí kí “òfin ìwà híhù láwùjọ” wà téèyàn á máa tẹ̀ lé? Ǹjẹ́ ibì kan wà tá a ti lè rí ìlànà ìwà híhù tó wúlò títí ayé táá mú kí ayé wa tòrò mini táá sì jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dáa? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.