Àwọn Èèyàn Ò Yéé Lépa Nǹkan Ìní Tara
“Tó bá jẹ́ pé kò-tó-kò-tó là ń pariwo, á jẹ́ pé kò sóhun tá a lè ní tó máa tó wa.”—Ìròyìn Àjọ Worldwatch Institute.
“KÍ LÀ ń fẹ́? Gbogbo nǹkan là ń fẹ́. Ìgbà wo la fẹ́ ní wọn? À ń fẹ́ wọn lójú ẹsẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tá a sábà máa ń gbọ́ lẹ́nu àwọn ọmọ kọ́lẹ́ẹ̀jì láwọn ọdún 1960 nìyẹn. A lè máà gbọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn mọ́ lóde òní, àmọ́ èrò yẹn ò tíì yí padà. Ká sòótọ́, ó dà bíi pé ẹ̀mí káwọn èèyàn máa lépa nǹkan ìní tara ṣáá ló gbòde kan láyé ìsinyìí.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa kó ọrọ̀ àtàwọn nǹkan ìní jọ ló jẹ wọ́n lógún jù lọ nígbèésí ayé wọn. Nígbà kan, Jimmy Carter, ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tẹ́lẹ̀ rí sọ pé: “Kì í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn lá fi ń mọ irú ẹni tó jẹ́ mọ́ báyìí o, bí kò ṣe àwọn nǹkan tó ní.” Ǹjẹ́ àwọn nǹkan míì wà tó ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan ìní tara lọ? Tó bá wà, kí ni àwọn nǹkan ọ̀hún, àwọn àǹfààní wo lèèyàn sì máa rí níbẹ̀?