Ninu Iwakiri fun Ètò Aye Titun Kan
“KO SI aworan ilẹ kankan lati ṣamọna wa si ibi ti a nlọ, si aye titun atọwọda tiwa funraawa yii. Bi aye ti bojuwo ẹhin wo ẹwadun mẹsan an ti ogun, rogbodiyan, ifura, ẹ jẹ ki a tun wo iwaju—si ọrundun titun kan, ati ẹgbẹrundun titun kan, ti alaafia, ominira ati aasiki.”
Aarẹ George Bush ti U.S. sọ awọn ọrọ wọnni ni January 1, 1990. Ninu ihin-iṣẹ kan ti o farajọra, aarẹ Mikhail Gorbachev ti Soviet pète ifọwọsowọpọ ninu awọn ọdun 1990 lati dá ‘aye silẹ kuro lọwọ awọn ibẹru ati ainigbẹkẹle, ti awọn ohun ija ogun ti ko pọndandan, awọn ilana oṣelu ti ko bodemu ati awọn ẹkọ igbagbọ ologun, ati awọn ohun ìdínà atọwọda laaarin awọn eniyan ati ijọba.’ Bẹẹ ni, Mainichi Daily News Japan ti January 3, 1990, ti rohin.
Lọna ti o ṣekedere, ireti tubọ nga sii. Bẹẹ si ni wọn ṣì wa ní ọdun kan lẹhin naa. Ninu ọrọ aarẹ ni ibẹrẹ ijooko Igbimọ Aṣofin ni January 29, 1991, aarẹ Bush pàṣamọ̀ mọ́ ija ogun ni Persian Gulf o si wipe: “Ohun ti o wa ninu ewu ju orilẹ-ede kekere kan [Kuwait] lọ, o jẹ iwewee pataki kan—ètò aye titun kan nibi ti awọn orilẹ-ede ọlọkankojọkan ti wa ni iṣọkan ninu ilepa kan naa lati jere ohun ti araye ńyánhànhàn fun kari aye: alaafia ati ailewu, ominira ati ipo tí ofin ti gbilẹ.”
Kii ṣe Ilepa Ti O Bọ́ Lọwọ Idaamu
Ọpọlọpọ awọn iṣoro dí eniyan lọwọ ninu ilepa rẹ fun ètò aye titun kan. Dajudaju awọn iforigbari ologun ṣediwọ. Ni titọka si awọn ogun ti nlọ lọwọ nigba naa ni Iraq ati Kuwait, iwe irohin Time ti January 28, 1991, wipe: “Gẹgẹ bi awọn bọmbu ti nbọ silẹ ti awọn àfọ̀njá olóró si nfo, awọn ireti fun ètò aye titun ni rudurudu ti a mọ daadaa gbapo rẹ.” Iwe irohin naa fikun pe: “Ko si ẹnikẹni ti o nilati wà labẹ ẹtan eyikeyi pe ètò aye titun ti a fọ́nnu rẹ̀ pupọpupọ ti wa ni ipo bayii tabi tilẹ sunmọle paapaa.”
Ifọwọsowọpọ jakejado orilẹ-ede ni ọwọ ko tii tẹ̀ rí, eyi si dí awọn isapa eniyan lati fidi ètò aye titun kan mulẹ lọna. Ninu irohin ti o farahan ninu itẹjade naa The World & I (January 1991), awọn ọmọwe ṣayẹwo “ètò ti njẹ jade ti awọn alagbara ògbóǹtarìgì ti o niiṣe pẹlu awọn orilẹ-ede miiran ati ipa ti o ṣeeṣe ki o ni lori ètò aye titun naa.” Olóòtú iwe naa pari ọrọ pe: “Itan mu un wa sọkan pe ààlà ti o wa laaarin ogun ati alaafia jẹ ẹlẹgé pupọ ni akoko ti o rọgbọ julọ. Ifọwọsowọpọ jakejado orilẹ-ede, ni pataki laaarin awọn alagbara jàǹkànjàǹkàn, ṣe pataki fun iyipada alaṣeyọri si rere lati inu Ogun Tutu si ètò aye titun kan.”
Awọn iṣoro ayika tun ṣe idena fun ètò aye titun naa ti ọpọlọpọ finúrò. Ninu State of the World 1991 (irohin Worldwatch Institute kan), Lester R. Brown wi pe: “Ko si ẹni ti o le sọ pẹlu idaniloju bi ètò titun naa yoo ti ri. Ṣugbọn bi awa yoo ba gbe ọjọ iwaju onireti kan kalẹ fun iran ti nbọ, nigba naa isapa ńláǹlà ti o beere fun lati ṣe iyipada ibajẹ ayika planẹti yii yoo bori ninu awọn alaamọri aye fun ọpọlọpọ ẹwadun ti nbọ.” Irohin naa ṣakiyesi pe biba afẹfẹ jẹ́ ti “dé iwọn ti nhalẹ mọ ilera ninu ọgọrọọrun ilu ati iwọn ti nba irugbin jẹ ninu ọpọlọpọ orilẹ-ede.” O fikun un pe: “Bi iye awọn eniyan ti ngbe planẹti naa ti npọ sii, ni iye awọn ẹya eweko ati ẹranko nlọ silẹ sii. Iparun ibugbe awọn ohun alaaye ati ayika ẹlẹgbin nmu ọkankojọkan ẹda ẹlẹmii ati eweko dinku sii. Iwọn imooru ti nga sii ati ìpòórá ibori afẹfẹ ozone le fikun ipadanu naa.”
Ni kedere, nigba naa, iwakiri eniyan fun ètò aye titun kan ni o kun fun awọn iṣoro. Ilepa naa ha le ṣaṣeyọrisi rere bi? A ha le sọ pe aye titun kan ti sunmọle bi? Bi o ba ri bẹẹ, bawo ni a ṣe le mu un wa?