ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/22 ojú ìwé 12-14
  • “Ètò Ayé Tuntun”—Ó Bẹ̀rẹ̀ Lọ́nà Àìfararọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ètò Ayé Tuntun”—Ó Bẹ̀rẹ̀ Lọ́nà Àìfararọ
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ogun Tí Ó Pẹ́ Títí Pẹ̀lú Ìrora Ọkàn
  • Ní Bèbè Ìwọko Gbèsè
  • Ìsìn, Ipá Tí Ń Fa Ìfẹsẹ̀múlẹ̀ Ni Bí?
  • Àwọn Àyájọ́ Pàtàkì Tí Kò Ní Púpọ̀ Láti Ṣayẹyẹ
  • Bí Ètò Ayé Tuntun Náà Kò Ṣe Gbéṣẹ́,  Ìṣàkóso Tòótọ́ ti Ọlọ́run Ń Gbilẹ̀!
  • Awọn Ìwéwèé Eniyan Fun Ailewu Jakejado Awọn Orilẹ-ede
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ninu Iwakiri fun Ètò Aye Titun Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ṣíṣe Nǹkan Ní Bòókẹ́lẹ́ ní Orúkọ Olúwa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ayé Kan Láìsí Ogun Ha Ṣeé Ṣe Bí?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 7/22 ojú ìwé 12-14

“Ètò Ayé Tuntun”—Ó Bẹ̀rẹ̀ Lọ́nà Àìfararọ

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ GERMANY

BÍ 1991 ṣe bẹ̀rẹ̀, àwọn ènìyàn ní ìfojúsọ́nà fún ire. Ogun Tútù náà ti dópin. Lóòótọ́, ìṣòro ti Kuwait wà níbẹ̀, tí Iraq ti kógun tì ní oṣù August tí ó lọ. Àmọ́, Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti fi agbára rẹ̀ hàn, ó sì ti pàṣẹ fún Iraq láti palẹ̀ mọ́ kúrò ní January 15. Ìparapọ̀ ológun tí a yára ṣètò láti ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè 28 lára àjọ UN, tí ó sì múra tán láti fipá mú Iraq láti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún ohun tí a béèrè fún náà. Ìfojúsọ́nà pọ̀ gan-an débi pé ìdúró fífìdí múlẹ̀ tí àwùjọ àgbáyé mú sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ sànmánì tuntun kan.

Ààrẹ United States nígbà náà, George Bush, sọ̀rọ̀ nípa “ìṣeéṣe, fún àwa fúnra wa àti àwọn ìrandíran tí ń bọ̀, láti ṣàgbékalẹ̀ ètò ayé tuntun kan, ayé kan níbi tí ìṣàkóso òfin, láìṣe òfin ìfigagbága àfẹ̀míṣe, ń ṣàkóso ìhùwà jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè.”

Lẹ́yìn náà ni Iraq kọtí ikún sí déètì January 15 tí wọ́n fún un, ó sì yọrí sí ìkọlù láti ojú òfuurufú àti ìrọ̀jò ọta sórí ibùdó ológun ilẹ̀ Iraq. Ní kedere, àwùjọ àgbáyé ní ohun tí ń sọ lọ́kàn. Kò tó oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, ní April 11, àjọ UN kéde pé Ogun Gulf ti dópin. Ó jọ pé ìlérí ètò ayé tuntun alálàáfíà, tí ipò ìṣúnná owó àti ètò ìṣèlú rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ fẹ́ẹ́ di òótọ́.

Àwọn Ogun Tí Ó Pẹ́ Títí Pẹ̀lú Ìrora Ọkàn

Ní agbedeméjì 1991, àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira méjì, Slovenia àti Croatia, kéde òmìnira kúrò lára Yugoslavia àkókò yẹn, tí èyí sí bẹ̀rẹ̀ ogun abẹ́lé tí ó wá ṣamọ̀nà sí ṣíṣẹ̀dá àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan tí wọ́n dá dúró. Kò tó ọdún kan lẹ́yìn náà, olùṣàyẹ̀wo kúlẹ̀kúlẹ̀ Pierre Hassner sọ pé: “Bíi ti Europe ní 1914, ètò ayé tuntun ti George Bush forí ṣánpọ́n ní Sarajevo.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìfojúsọ́nà fún àlàáfíà ń dára sí i nígbà tí àpérò bẹ̀rẹ̀ ní Dayton, Ohio, U.S.A., ní November 1995, wọ́n sì fọwọ́ síwèé àdéhùn àlàáfíà ní Paris ní December 14. Bí 1995 ti ń parí lọ, wọ́n tún mú kí ìrètí gbérí pé bóyá ètò ayé tuntun náà kò forí ṣánpọ́n síbẹ̀síbẹ̀.

Àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira ilẹ̀ Union of Soviet Socialist Republics ń pínyà díẹ̀díẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ ara wọn. Ní 1991, Lithuania, Estonia, àti Latvia ni wọ́n kọ́kọ́ lọ, tí àwọn mìíràn sì tẹ̀ lé wọn láìpẹ́. Wọ́n dá ẹgbẹ́ kan tí a kò fọwọ́ dan-indan-in ṣàkóso, tí a mọ̀ sí Àjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Òlómìnira Alájọṣe sílẹ̀ ní December, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n wà lára Soviet Union tẹ́lẹ̀ rí kọ̀ láti dara pọ̀. Lẹ́yìn náà, ní December 25, Gorbachev kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ kúrò ní ipò ààrẹ Soviet.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn orílẹ̀-èdè olómìnira tí wọ́n dá wà pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí í yọ kúrò. Fún àpẹẹrẹ, Chechnya, ibi àkámọ́ kékeré kan tí ó jẹ́ ilẹ̀ Mùsùlùmí ní àríwá agbègbè Caucasus ní Rọ́ṣíà, ń tiraka fún òmìnira. Ìgbìyànjú rẹ̀ láti dá dúró lópin ọdún 1994 tanná ran ìkọlù, láti ọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Rọ́ṣíà, tí ó fa àríyànjiyàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan bí 30,000 ẹ̀mí ló ti ṣòfò láti ìgbà tí yánpọnyánrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, ogun náà ṣì ń bá a lọ títí di ọdún yìí.

Títí di October 1995, nǹkan bí ogun 27 sí 46—ó sinmi lórí ìsọ̀rí tí a pín wọn sí—ń lọ jákèjádò ayé.

Ní Bèbè Ìwọko Gbèsè

Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, ó hàn pé ẹsẹ̀ ètò ayé tuntun náà ń mì ní ti ìṣèlú àti ọrọ̀ ajé pẹ̀lú.

Ní 1991, Nicaragua dín agbára owó rẹ̀ kù, àmọ́, síbẹ̀síbẹ̀, mílíọ̀nù 25 cordobas dọ́gba pẹ̀lú dọ́là United States kan ṣoṣo. Láàárín àkókò náà, Zaire ń nírìírí ìwọ̀n ọ̀wọ́n gógó ọjà tí ó ga ní ìpín 850 nínú ọgọ́rùn-ún, tí èyí sì ń fipá mú àwọn aráàlú láti forí ti ọ̀kan lára ipò ìdẹ̀ra ìgbésí ayé rírẹlẹ̀ jù lọ lágbàáyé. Ipò ọrọ̀ ajé Rọ́ṣíà ń ní ìṣòro pẹ̀lú. Ìwọ̀n ọ̀wọ́n gógó ọjà ga ní ìpín 2,200 nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dún ní 1992, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ owó di aláìníyelórí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan wá sunwọ̀n sí i lẹ́yìn náà, ní 1995, ó dájú pé àwọn ìṣòro ọrọ̀ ajé kò tí ì kásẹ̀ nílẹ̀.

Ẹ̀gàn lílókìkí jù lọ ní ti ìṣúnná owó, tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún yìí wáyé ní 1991, nígbà tí Bank of Credit & Commerce International forí ṣánpọ́n, látàri jìbìtì àti àwọn ìwà ọ̀daràn. Àwọn olùfowópamọ́ ní ilẹ̀ 62 jìyà àdánù tí ó tó ọ̀gọ̀ọ̀rọ bílíọ̀nù dọ́là United States.

Kì í ṣe àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò lọ́rọ̀ nìkan ni ẹsẹ̀ wọn ń mì; ohun tí ìsopọ̀ṣọ̀kan ná Germany alágbára ni ín lára. Àìríṣẹ́ṣe ga sókè bí àwọn òṣìṣẹ́ ti ń béèrè fún ìsìnmi gígùn sí i àti àbójútó ìlera dídára jù. Ìwọ̀n ìpaṣẹ́jẹ gíga àti àṣìlò ìlànà ètò ìfẹ́dàáfẹ́re gbé ìkìmọ́lẹ̀ púpọ̀ sí i dìde lórí ọrọ̀ ajé rẹ̀.

Ní United States, ọ̀wọ́ ìjàm̀bá líle koko kan fa ìbàjẹ́ láàárín àwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò, tí wọn kò lè san owó ìbánigbófò nítorí pé wọ́n wà nínú ìṣòro ìṣúnná owó. Ní 1993, ìwé náà, Bankruptcy 1995: The Coming Collapse of America and How to Stop It, kìlọ̀ nípa ewu gbèsè gíga fíofío tí ìjọba àpapọ̀ jẹ àti gbèsè ìwéwèé ìnáwó. Kódà, a ṣiyè méjì nípa ìfìdímúlẹ̀ ilé iṣẹ́ abánigbófò ilẹ̀ Britain náà, Lloyd’s of London. Nítorí pé àdánù ṣe é bátabàta, a fipá mú un láti ronú nípa ohun tí kò ṣeé máa rò—tí ó lè jẹ́ ìwọko gbèsè.

Ìsìn, Ipá Tí Ń Fa Ìfẹsẹ̀múlẹ̀ Ni Bí?

Ní 1991, ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Germany náà, Frankfurter Allgemeine Zeitung, sọ pé: “Ìran ètò ayé tuntun yìí ní ìpìlẹ̀ nínú ojú ìwòye ọlọ́jọ́ pípẹ́ ilẹ̀ America nípa àgbáyé tí gbogbo rẹ̀ ní apá pàtàkì ti ìsìn nínú, a sì ti ṣàlàyé wọn lọ́nà ti Kristẹni.”

Ẹnì kan lè ronú pé ó yẹ kí ìpìlẹ̀ onísìn tí ètò ayé tuntun yìí ní lè mú kí ó túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ sí i. Àmọ́, ní ti gidi, àìráragbaǹkansí ìsìn àti gbọ́nmisi-omi-òto ṣamọ̀nà sí àìfẹsẹ̀múlẹ̀ títàn káàkiri. Algeria àti Íjíbítì jẹ́ méjì péré lára àwọn ìjọba bíi mélòó kan tí kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn Mùsùlùmí onígbàgbọ́ ìpìlẹ̀. Ìjì ìpániláyà tí ìsìn ṣokùnfà kọ lu orílẹ̀-èdè méjèèjì. Rògbòdìyàn ìsìn ní India kan ìwà ipá ọlọ́jọ́ méje kan nítorí ẹ̀yà ìsìn ní Bombay, láàárín 1993, tí ó gba ẹ̀mí tí ó lé ní 550.

Àìṣọ̀kan ìsìn fawọ́ ìtẹ̀síwájú ìsopọ̀ṣọ̀kan ìsìn Kristẹni àgbáyé sẹ́yìn ní 1994 nígbà tí Ṣọ́ọ̀ṣì Anglikan fi àwọn obìnrin 32 joyè àlùfáà. Póòpù John Paul Kejì pe èyí ní “ìdènà ńlá fún gbogbo ìrètí ìmúpadàṣọ̀kan láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti àwùjọ Anglikan.”

Ní April 19, 1993, pákáǹleke láàárín ìjọba United States àti àwọn mẹ́ḿbà ìsìn ẹgbẹ́ awo kan, Branch Davidian—tí ó ti yọrí sí ìdótì àgbàlá ẹgbẹ́ awo náà ní Waco, Texas, àti pípa àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ mẹ́rin—gba ẹ̀mi, ó kéré tán, 75 lára àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ awo náà. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, wọ́n ṣì ń wádìí lórí ìṣeéṣe náà pé jíju bọ́m̀bù àwọn olùpániláyà tí ó pa 168 ènìyàn ní ilé ìjọba àpapọ̀ ní Oklahoma City lè jẹ́ láti gbẹ̀san ìkọlù tí ó ṣẹlẹ̀ ní Waco.

Ayé ta gìrì ní ìbẹ̀rẹ̀ 1995 láti gbọ́ nípa ìkọlù gáàsì olóró olùpániláyà níbi ìgbékalẹ̀ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ Tokyo. Ènìyàn mẹ́wàá ló kú, ẹgbẹẹgbẹ̀rún sì fara pa. Ayé túbọ̀ ta gìrì nígbà tí a di ẹrù ẹ̀bi rẹ̀ ru ẹ̀ya ìsìn oníṣìípayá tí ń jẹ́ Aum Shinrikyo, tàbí Òtítọ́ Gíga Jù Lọ Aum.

Àwọn Àyájọ́ Pàtàkì Tí Kò Ní Púpọ̀ Láti Ṣayẹyẹ

Ní 1492, Colombus ṣèèṣì dé Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé. Àríyànjiyàn yí ayẹyẹ àyájọ́ 500 ọdún àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní 1992 ká. Nǹkan bíi mílíọ̀nù 40 àtìrandíran àwọn Amerind hùwà jàgídíjàgan sí ọ̀rọ̀ tí ń dábàá pé ará Europe kan ló “ṣàwárí” ilẹ̀ tí àwọn baba ńlá wọn gbé, tí wọ́n sì gbilẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó bí òun fúnra rẹ̀. Àwọn kan pé olùyẹ̀wòkiri náà ní “àmì àkọ́kọ́ ìkóninífà àti ìṣẹ́gun.” Lótìítọ́, dídé tí Columbus dé sí Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì Ayé jẹ́ àgbákò ju ìbùkún lọ fún àwọn ọmọ onílẹ̀ tí ń gbé ibẹ̀. Àwọn tí a pè ní aṣẹ́gun Kristẹni olùṣẹ́gun jà wọ́n lólè ilẹ̀, ipò àṣẹ àkóso, iyì, àti ìgbésí ayé wọn.

Ní September 1995, Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ olóṣù 16 kan láti ṣèrántí àyájọ́ ayẹyẹ 3,000 ọdún tí Ọba Dáfídì ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ìbànújẹ́ ló bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ náà nígbà tí ọta òṣìkàpànìyàn kan mú Olórí Ìjọba Yitzhak Rabin balẹ̀ ní November 4 ní ìṣẹ̀jú díẹ̀ lẹ́yìn tí ó bá àwùjọ àwọn olùwọ́de àlàáfíà kan sọ̀rọ̀ tán. Èyí gbé ìbànújẹ́ karí ìgbésẹ̀ àlàáfíà ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, ní fífi hàn pé kì í ṣe pé àwọn ìyàtọ̀ ìsìn lílágbára wà láàárín àwọn Júù àti àwọn ará Palẹ́stìnì nìkan ni ṣùgbọ́n láàárín àwọn Júù fúnra wọn pàápàá.

Onírúurú ayẹyẹ àyájọ́ 50 ọdún ni a ṣe láàárín 1991 sí 1995 ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ogun Àgbáyé Kejì—ìkọlù ní Pearl Harbor, tí ó jẹ́ kí United States kó wọnú ogun náà; kíkó tí àwọn Alájùmọ̀ṣepọ̀ kógun ti Europe; ìtúsílẹ̀ àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ẹgbẹ́ Nazi; ìṣẹ́gun àwọn Alájùmọ̀ṣepọ̀ ní Europe; àti jíju bọ́m̀bù átọ́míìkì àkọ́kọ́ sóri Japan. Lójú ẹ̀jẹ̀ àti omijé tí ó bá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí rìn, àwọn ènìyàn kan béèrè bí ó bá yẹ kí a ṣayẹyẹ wọn ní tòótọ́.

Èyí ṣamọ̀nà sí àyájọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì míràn, ìdásílẹ̀ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní October 1945. Nígbà yẹn, ìrètí ga sí i pé níkẹyìn, a ti rí kọ́kọ́rọ́ sí ṣíṣàṣeparí àlàáfíà àgbáyé.

Gẹ́gẹ́ bí Boutros Boutros-Ghali, akọ̀wé àgbà Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti sọ láìpẹ́ yìí ní gbígbèjà rẹ̀, ó ti ní ọ̀pọ̀ ìjagunmólú. Àmọ́, kò tí ì ṣàṣeyọrí ní mímú ìlépa àkọsílẹ̀ ète rẹ̀ ṣẹ, ìyẹn ni “láti mú kí àlàáfíà àti àìléwu fẹsẹ̀ múlẹ̀ jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè.” Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ti gbìyànjú láti mú kí àlàáfíà fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní àwọn ibi tí kò ti sí àlàáfíà kankan tí a óò fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀. Títí di 1995, ó ti kùnà láti mú kí ètò ayé tuntun tí kò fara rọ náà gbéṣẹ́.

Bí Ètò Ayé Tuntun Náà Kò Ṣe Gbéṣẹ́,  Ìṣàkóso Tòótọ́ ti Ọlọ́run Ń Gbilẹ̀!

Lójú àìdúró sójú kan ètò ìṣèlú, ọrọ̀ ajé, àti ìsìn tí ó ṣokùnfa kí ìrètí wọn nípa ètò ayé tuntun kan máa rà mọ́lẹ̀ lójú wọn, àwọn ènìyàn kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ nípa ayé onídàrúdàpọ̀ tuntun kan. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí ẹ̀rí síwájú sí i pé ayé tuntun tí Ọlọ́run yóò mú wá nìkan ni yóò gbádùn ìfẹsẹ̀múlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ àwùjọ ènìyàn.

Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, òpin Ogun Tútù náà túmọ̀ sí òmìnira ńláǹlà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní jíjẹ́ kí wọ́n lè ṣe àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ṣíṣàrà ọ̀tọ̀ ní Budapest, Kiev, Moscow, Prague, St. Petersburg, Warsaw, àti ní àwọn ibòmíràn. Èyí fún ìṣètò ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri àgbáyé lókun, ó sì ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù wọn yára. Nípa bẹ́ẹ̀, kò yani lẹ́nu pé iye àwọn Ẹlẹ́rìí agbékánkánṣiṣẹ́ ní ibì kan péré lára àwọn agbègbè wọ̀nyí lọ sókè láti 49,171 ní 1991 sí 153,361 ní 1995. Láàárín ọdún mẹ́rin kan náà, iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbogbo àgbáyé lọ sókè láti 4,278,820 sí 5,199,895. Ìṣàkóso tòótọ́ ti Ọlọ́run ń gbilẹ̀ lọ́nà tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí!

Bẹ́ẹ̀ ni, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń gbé ìrètí wọn nípa ọjọ iwájú karí ìlérí Jèhófà Ọlọ́run nípa “àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun kan” nínú èyí tí “òdodo yoo . . . máa gbé.” (Pétérù Kejì 3:10, 13) Ẹ wo bí ó ti lọ́gbọ́n nínú tó ju yíyíjú sí ètò ayé tuntun ènìyàn lọ, èyí tí, ó bẹ̀rẹ̀ lọ́nà àìfararọ, tí a óò fà tu kúrò láyé láìpẹ́!—Dáníẹ́lì 2:44.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́