Ṣíṣe Nǹkan Ní Bòókẹ́lẹ́ ní Orúkọ Olúwa
ÌBÚJÁDE gáàsì olóró ní ọ̀nà abẹ́lẹ̀ ní Tokyo, Japan, ní March 1995, pa ènìyàn 12, ó kó àìsàn bá ẹgbẹẹgbẹ̀rún púpọ̀ sí i, ó sì ṣèrànwọ́ láti túdìí àṣírí kan. Ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ kan tí a mọ̀ sí Aum Shinrikyo (Òtítọ́ Gíga Jù Lọ) ti kó àwọn gáàsì olóró jọ ní bòókẹ́lẹ́, láti lò fún lílépa àwọn góńgó abàmì.
Oṣù kan lẹ́yìn náà, bọ́ǹbù kan tí ó bú gbàù fọ́ ilé ìjọba àpapọ̀ tí ó wà ní Ìlú Oklahoma, U.S.A. túútúú, ó sì gbẹ̀mí 167 ènìyàn. Ó jọ pé ẹ̀rí fi hàn pé, ìkọlù náà ní í ṣe pẹ̀lú ìforígbárí tí ìjọba ní pẹ̀lú ẹgbẹ́ awo ìsìn Branch Davidian ní Waco, Texas, ní ọdún méjì géérégé ṣáájú. Nígbà yẹn, àwọn bí 80 tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ awo náà kú. Ìbúgbàù bọ́ńbù náà tún ṣí àṣírí kan tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kò mọ̀ payá: Àìmọye ẹgbẹ́ ológun àsúrépèjagun ń bẹ lẹ́nu iṣẹ́ ní United States nísinsìnyí, a sì fura sí díẹ̀ lára wọn pé wọ́n ń wéwèé ní bòókẹ́lẹ́ láti gbégbèésẹ̀ lòdì sí ìjọba.
Bí ọdún 1995 ti ń kógbá sílé, a rí àjókù òkú àwọn ènìyàn 16 nínú igbó kan lẹ́bàá Grenoble, ní ilẹ̀ Faransé. Wọ́n ti jẹ́ mẹ́ńbà Order of the Solar Temple, ẹgbẹ́ awo ìsìn kékeré kan, tí ìròyìn ní Switzerland àti Kánádà gbé jáde ní October 1994, nígbà tí 53 nínú mẹ́ńbà rẹ̀ ṣekú pa ara wọn tàbí tí a ṣekú pa wọ́n. Ṣùgbọ́n, ẹgbẹ́ awo náà kò tú ká, àní lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí pàápàá. Ohun tí ó jẹ́ ète àti góńgó ẹgbẹ́ yìí kò tí ì hàn sójú táyé títí di òní olónìí.
Ewu Ìsìn Tí Ń Ṣe Nǹkan Ní Bòókẹ́lẹ́
Lójú ìwòye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí irú wọ̀nyí, ó ha yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń fura sí àwọn àwùjọ ìsìn bí? Dájúdájú, kò sí ẹni tí ó fẹ́ ṣètìlẹ́yìn fún àjọ ìmùlẹ̀ kan—yálà ó jẹ́ ti ìsìn tàbí kì í ṣe ti ìsìn—tí yóò ṣi ìgbẹ́kẹ̀lé tí ẹni náà ní nínú rẹ̀ lò, tí yóò sì mú kí ó máa lépa àwọn góńgó tí òun kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n, kí ni àwọn ènìyàn lè ṣe láti má ṣe kó sínú páńpẹ́ dídi mẹ́ńbà àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ tí ète wọn ṣeé gbé ìbéèrè dìde sí?
Dájúdájú, yóò bọ́gbọ́n mu kí ẹnikẹ́ni tí ń gbèrò àtidi mẹ́ńbà ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ kan wádìí àwọn ète ẹgbẹ́ náà gan-an. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ojúlùmọ̀ fipá mú wa wẹgbẹ́, a sì gbọ́dọ̀ gbé ìpinnu wa karí òkodoro òtítọ́, kì í ṣe kárí ìmọ̀lára lásàn. Rántí pé, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ẹni náà fúnra rẹ̀—kì í ṣe àwọn ẹlòmíràn—ni a óò ké sí láti fojú gbiná ohun yòó wù tí ó lè tìdí rẹ̀ jáde.
Títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì ni ọ̀nà tí ó dájú jù lọ láti yẹra pátápátá fún àwọn ẹgbẹ́ eléwu, tí ète wọn kò sunwọ̀n. (Aísáyà 30:21) Èyí kan wíwà láìdásí tọ̀tún tòsì ní ti ìṣèlú, fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn, títí kan àwọn ọ̀tá wa pẹ̀lú, yíyẹra fún ‘àwọn iṣẹ́ ti ara,’ àti mímú àwọn èso ẹ̀mí Ọlọ́run dàgbà. Ní pàtàkì jù lọ, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ayé, gẹ́gẹ́ bí Jésù pàápàá kì í ti í ṣe apá kan rẹ̀, ipa ọ̀nà yí sì fagi lé jíjẹ́ mẹ́ńbà ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ ayé.—Gálátíà 5:19-23; Jòhánù 17:14, 16; 18:36; Róòmù 12:17-21; Jákọ́bù 4:4.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ aláápọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n fi ọwọ́ pàtàkì mú ìgbàgbọ́ wọn, tí wọ́n sì ń gbìyànjù ní gbangba láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Kárí ayé, a mọ̀ wọ́n bí ẹní mowó sí ẹgbẹ́ ìsìn tí ‘ń wá àlàáfíà, tí ó sì ń lépa rẹ̀.’ (Pétérù Kíní 3:11) Ìwé wọn, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, sọ lọ́nà tí ó tọ́ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ lọ́nàkọnà. A ṣàlàyé àwọn ìgbàgbọ́ wọn tí a gbé karí Bíbélì lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ sínú àwọn ìtẹ̀jáde wọn, tí ó wà fún ẹnikẹ́ni láti kà. Ní àfikún sí i, wọ́n ń ṣe àkànṣe ìsapá láti ké sí gbogbo ènìyàn wá sí àwọn ìpàdé wọn, láti fojú ara wọn rí, kí wọ́n sì fetí ara wọn gbọ́ àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.”
Ìsìn tòótọ́ kì í sọ ṣíṣe nǹkan ní bòókẹ́lẹ́ dàṣà rárá. A ti fún àwọn olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ nítọ̀ọ́ni láti má ṣe fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ bò tàbí kí wọ́n fi ète wọn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà rúni lójú. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìjímìjí fi ẹ̀kọ́ wọn kún Jerúsálẹ́mù. Gbogbo ìgbàgbọ́ àti ìgbòkègbodò wọ́n hàn sí gbogbo ènìyàn. Bákan náà ní ọ̀ràn rí pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí. Lọ́nà tí ó ṣeé lóye, nígbà tí àwọn ìjọba bóo fẹ́ bóo kọ̀ bá dí òmìnira ìjọsìn lọ́wọ́ láìyẹ, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa fi ìṣọ́ra àti ìfẹ́ bá ìgbòkègbodò wọn lọ, ní ṣíṣègbọràn sí “Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn,” ipò kan tí a gbé kà wọ́n lórí nítorí tí wọ́n ń jẹ́rìí ní gbangba láìṣojo.—Ìṣe 5:27-29; 8:1; 12:1-14; Mátíù 10:16, 26, 27.
Bí ó bá wá sọ́kàn rẹ rí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè jẹ́ ẹgbẹ́ awo tàbí ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀, ìyẹn jẹ́ nítorí pé o kò mọ̀ wọ́n dáradára. Bí ipò nǹkan ti gbọ́dọ̀ rí nìyẹn fún ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ọ̀rúndún kìíní.
Ìṣe orí 28 sọ fún wa nípa ìpàdé kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe ní Róòmù pẹ̀lú ‘sàràkí-sàràkí lára àwọn Júù.’ Wọ́n sọ fún un pé: “Àwa ronú pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu láti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ohun tí àwọn ìrònú rẹ jẹ́, nítorí pé ní òótọ́ ní ti ẹ̀ya ìsìn yí a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” (Ìṣe 28:16-22) Ní ìdáhùnpadà, Pọ́ọ̀lù “ṣàlàyé ọ̀ràn náà fún wọn nípa jíjẹ́rìí kúnnákúnná nípa ìjọba Ọlọ́run . . . àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbà . . . gbọ́.” (Ìṣe 28:23, 24) Dájúdájú mímọ òkodoro òtítọ́ nípa ẹ̀sìn Kristẹni jẹ́ fún ire wọn pípẹ́ títí.
Bí wọ́n tilẹ̀ ti fi ara wọn jìn fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, tí wọ́n ń ṣe lójú táyé, tí wọn kì í sì í fi bò, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò láyọ̀ láti ṣí òtítọ́ ṣíṣe kedere nípa ìgbòkègbodò àti ìgbàgbọ́ wọn payá fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ mọ òtítọ́. Èé ṣe tí o kò fi ṣèwádìí fúnra rẹ, kí o baà lè wà ní ìpo láti mọ̀ dáradára nípa ìgbàgbọ́ wọn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dùn láti ṣí irú ẹni tí wọ́n jẹ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣe payá