ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 6/1 ojú ìwé 3-4
  • Kí ní Fa Gbogbo Ṣíṣe Nǹkan ní Bòókẹ́lẹ́ Yìí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí ní Fa Gbogbo Ṣíṣe Nǹkan ní Bòókẹ́lẹ́ Yìí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nígbà Tí Ṣíṣe Nǹkan Ní Bòókẹ́lẹ́ Bá Ń Fi Hàn Pé Ewu Ń Bọ̀
  • Èwo Ni Wọ́n Ń Dán Wò Báyìí?
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
    Jí!—2018
  • Àṣírí Kan Tó O Lè Sọ fún Ẹlòmíì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Inú Wa Dùn Láti Mọ Àṣírí Kan
    Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Àṣírí Tí Àwọn Kristẹni Kò Jẹ́ Pa mọ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 6/1 ojú ìwé 3-4

Kí ní Fa Gbogbo Ṣíṣe Nǹkan ní Bòókẹ́lẹ́ Yìí?

“KÒ SÍ ohun tí ó kó ìnira báni tó ọ̀rọ̀ àṣírí.” Ó ṣe tán, ohun tí òwe ilẹ̀ Faransé kan sọ nìyẹn. Èyí ha lè ṣàlàyé ìdí tí a fi máa ń láyọ̀ nígbà tí a bá mọ àṣírí kan, ṣùgbọ́n, tí agara máa ń dá wa nígbà tí a kò bá lè sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Síbẹ̀, fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fi ọ̀yàyà tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ àṣírí, ní dídára pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀, bí wọ́n ti ń lépa góńgó kan náà.

Lára àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ni àwọn ẹgbẹ́ awo tí ó wà ní Íjíbítì, Gíríìsì, àti Róòmù. Nígbà tí ó yá, díẹ̀ lára àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí yà bàrá kúrò nínú ète wọn ní ti ìsìn, wọ́n sì gbé ọ̀ràn ìṣèlú, ọrọ̀ ajé, tàbí ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà rù. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí a dá ẹgbẹ́ àwọn oníṣòwò sílẹ̀ ní Europe ti sànmánì agbedeméjì, àwọn mẹ́ńbà wọn ń ṣe nǹkan ní bòókẹ́lẹ́ kí wọ́n baà lè dáàbò bo ara wọn ní ti ọrọ̀ ajé.

Lọ́pọ̀ ìgbà, a ti dá ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ sílẹ̀ lóde òní fún àwọn ète rere, bóyá fún “àwọn ète ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ti afẹ́dàáfẹ́re,” gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica ti sọ, àti “láti darí ètò afẹ́nifẹ́re àti ti ìmọ̀ ẹ̀kọ́.” Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ìyá, ẹgbẹ́ èwe, ẹgbẹ́ àjùmọ̀ṣe, àti àwọn ẹgbẹ́ mìíràn pẹ̀lú máa ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan ní bòókẹ́lẹ́, tàbí ó kéré tán, wọ́n máa ń ṣe àwọn nǹkan díẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́. Ní gbogbogbòò, àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí kì í ní ète àtipani lára, àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ wulẹ̀ ń láyọ̀ láti máa ṣe nǹkan ní bòókẹ́lẹ́ ni. Ààtò bòókẹ́lẹ́ ìmúwẹgbẹ́ ń fani mọ́ra gan-an, ó sì ń fún ìdè jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àti ẹ̀mí ìṣọ̀kan lókun. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ máa ń nímọ̀lára pé àwọn jẹ́ apá kan rẹ̀, wọ́n sì ń nímọ̀lára lílépa ète kan. Àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ bí irú èyí kì í wu àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà wọn léwu. Kò sí ewu kankan fún àwọn tí kì í ṣe mẹ́ńbà fún ṣíṣàìmọ àṣírí wọn.

Nígbà Tí Ṣíṣe Nǹkan Ní Bòókẹ́lẹ́ Bá Ń Fi Hàn Pé Ewu Ń Bọ̀

Kì í ṣe gbogbo ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ ni ó ń ṣe nǹkan ní bòókẹ́lẹ́ dé ìwọ̀n kan náà. Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n ní “àṣírí nínú àṣírí,” lọ́nà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica gbà pè é, léwu gidigidi. Ó ṣàlàyé pé, “nípa lílo àwọn orúkọ ìnagijẹ, ìmùlẹ̀ tàbí ìṣípayá,” àwọn tí wọ́n ti gòkè àgbà nínú ẹgbẹ́ ń dọ́gbọ́n “ya ara wọn sọ́tọ̀,” tí wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ru “àwọn ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ ọmọ ẹgbẹ́” sókè “láti sapá tí ó yẹ, kí àwọn náà lè gòkè àgbà.” Ewu tí ń bẹ nínú irú àwọn ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣe kedere. Àwọn ọ̀jẹ̀wẹ́wẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ lè ṣàìmọ àwọn ète àjọ náà gan-an, nítorí tí wọn kò tí ì gòkè àgbà débi tí wọn yóò ti rí ìṣípayá náà. Ó rọrùn láti wọnú ẹgbẹ́ kan tí àwọn ìlépa rẹ̀ àti àwọn ọ̀nà tí ọwọ́ rẹ̀ yóò gbà fi tẹ̀ wọ́n kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere sí ọ, bóyá ẹgbẹ́ náà kò tí ì ṣàlàyé àwọn góńgó rẹ̀ fún ọ tán pàápàá. Ṣùgbọ́n, ó lè ṣòro gidigidi fún ẹni tí a ti mú wọnú irú ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀ láti jàjàbọ́; a ti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ìmùlẹ̀ dè é tọwọ́ tẹsẹ̀, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, ṣíṣe nǹkan ní bòókẹ́lẹ́ máa ń fi hàn pé ewu ńláǹlà ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ pàápàá nígbà tí ẹgbẹ́ kan bá ń lépa àwọn góńgó tí kò bófin mu tàbí ti oníwà ọ̀daràn, tí ó sì ń gbìyànjú láti fi wíwà rẹ̀ pa mọ́. Bí wíwà rẹ̀ àti àwọn ète rẹ̀ bá sì hàn sójú táyé, ó lè gbìyànjú láti pa àwọn tí ó jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀ àti àwọn ìwéèwé rẹ̀ fún ìgbà kúkurú mọ́ láṣìírí. Bí ọ̀ràn ṣe rí gan-an nìyẹn nípa àwọn ẹgbẹ́ akópayàbáni, tí wọ́n máa ń fi ìkọluni akópayàbáni wọn kó jìnnìjìnnì bá aráyé láti ìgbàdégbà.

Bẹ́ẹ̀ ni, ṣíṣe nǹkan ní bòókẹ́lẹ́ lè léwu, fún ẹnìkọ̀ọ̀kan àti fún àwùjọ lápapọ̀. Ronú nípa àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ asòpàǹpá ti àwọn ọ̀dọ́langba, tí wọ́n máa ń hùwà jàgídíjàgan sí àwọn tí ń lọ jẹ́jẹ́ tiwọn, àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn bíi ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ Máfíà, àwọn ẹgbẹ́ ìran aláwọ̀-funfun-lọ̀gá, irú bíi Ku Klux Klan,a kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ dárúkọ ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ akópayàbáni kárí ayé, tí wọ́n ń báa lọ láti sojú ìsapá láti mú kí àlàáfíà àti ààbò jọba kárí ayé dé.

Èwo Ni Wọ́n Ń Dán Wò Báyìí?

Ní àwọn ọdún 1950, gẹ́gẹ́ bí àbájáde Ogun Tútù, a ṣètò àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ sí àwọn ilẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn kan ní Europe láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ agbéjàkoni, bí àwọn ará Soviet bá gbìyànjú pẹ́rẹ́n láti gbógun ti Ìwọ̀ Oòrùn Europe. Fún àpẹẹrẹ, gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Germany náà, Focus, ti sọ, a gbé “àwọn ilé 79 ti ìkó-ohun-ìjà-sí” kalẹ̀ sí Austria ní àkókò yẹn. Kì í ṣe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní Europe ni ó tilẹ̀ mọ̀ nípa àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí. Láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ìwé ìròyìn kan sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990 pé: “A kò mọ iye irú àwọn àjọ bì ìwọ̀nyí tí ń bẹ lónìí, àti ohun tí wọn yóò dán wò láìpẹ́.”

Bẹ́ẹ̀ ni, ní tòótọ́. Ta ní lè mọ iye ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ tí ó lè máa wu èyíkéyìí nínú wa léwu lọ́nà tí ó ju èyí tí a lè finú rò lọ?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ẹgbẹ́ tí ń bẹ ní United States yìí ṣì pa díẹ̀ lára àwọn ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn ti àwọn ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ ìjímìjí mọ́, nípa lílo àgbélébùú tí iná ń jó lórí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì ìdánimọ̀ rẹ̀. Ní ìgbà àtijọ́, ẹgbẹ́ náà máa ń gbé sùnmọ̀mí lóròòru, tí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ máa ń lọ́ aṣọ funfun mọ́ra, tí wọ́n sì máa ń fi ìbínú wọn hàn sí àwọn aláwọ̀ dúdú, àwọn Kátólíìkì, àwọn Júù, àwọn àjèjì, àti àjọ àwọn òṣìṣẹ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́