ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yc ẹ̀kọ́ 1 ojú ìwé 4-5
  • Inú Wa Dùn Láti Mọ Àṣírí Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Inú Wa Dùn Láti Mọ Àṣírí Kan
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣírí Kan Tó O Lè Sọ fún Ẹlòmíì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìròyìn Yìí
    Jí!—2018
  • Àṣírí Tí Àwọn Kristẹni Kò Jẹ́ Pa mọ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • “Ọgbọ́n Ọlọ́run Nínú Àṣírí Mímọ́” Kan
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Kọ́ Ọmọ Rẹ
yc ẹ̀kọ́ 1 ojú ìwé 4-5
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ẹ̀kọ́ 1

Inú Wa Dùn Láti Mọ Àṣírí Kan

Ǹjẹ́ ẹnì kan ti sọ ọ̀rọ̀ àṣírí fún ẹ rí?—a Bíbélì sọ àṣírí pàtàkì kan. Ó pè é ní “àṣírí ọlọ́wọ̀,” nítorí pé Ọlọ́run ló ni àṣírí yẹn, àwọn èèyàn kò sì mọ̀ nípa rẹ̀. Kódà, ó wu àwọn áńgẹ́lì kí wọ́n mọ àṣírí náà. Ṣé ìwọ náà fẹ́ mọ àṣírí yìí?—

Kí lo rò pé àwọn áńgẹ́lì yìí fẹ́ mọ̀?

Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Ádámù àti Éfà ni orúkọ wọn. Ọlọ́run fi wọ́n sínú ọgbà kan tó rẹwà, tó ń jẹ́ ọgbà Édẹ́nì. Ká ní Ádámù àti Éfà ti ṣègbọràn ni, àwọn àti àwọn ọmọ wọn ò bá ti sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè, bíi ti ọgbà tí Ọlọ́run fi wọ́n sí tẹ́lẹ̀. Wọ́n ò bá sì máa gbé títí láé nínú Párádísè. Àmọ́, ǹjẹ́ o rántí ohun tí Ádámù àti Éfà ṣe?—

Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tí àwa èèyàn kò fi sí nínú Párádísè lónìí. Àmọ́, Ọlọ́run sọ pé òun máa mú kí gbogbo ayé yìí rẹwà, inú gbogbo èèyàn á dùn, wọ́n á sì máa gbé títí láé. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ṣe é? Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn èèyàn kò mọ bó ṣe fẹ́ ṣe é, torí pé àṣírí ni.

Nígbà tí Jésù wá sáyé, ó sọ fún àwọn èèyàn nípa àṣírí yìí. Ó sọ pé Ìjọba Ọlọ́run ni àṣírí náà. Jésù sọ pé ká máa gbàdúrà pé kí Ìjọba yìí dé. Torí tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, ó máa jẹ́ kí ilẹ̀ ayé di Párádísè tó rẹwà.

Ṣé inú ẹ dùn láti mọ àṣírí yìí?— Rántí pé, àwọn tó bá ṣègbọràn sí Jèhófà nìkan ló máa gbé nínú Párádísè. Bíbélì sọ ìtàn tó pọ̀ fún wa nípa àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí wọ́n gbọ́rọ̀ sí Jèhófà lẹ́nu. Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ wọ́n?— Ó dáa, jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ nínú wọn, àti bí a ṣe lè fara wé wọn.

KÀ Á NÍNÚ BÍBÉLÌ RẸ

  • Máàkù 4:11

  • 1 Pétérù 1:12

  • Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:8, 9; 3:6, 23

  • Mátíù 6:9, 10

  • Sáàmù 37:11, 29

a Nínú gbogbo ìtàn tó wà nínú ìwé yìí, wàá rí àmì dáàṣì (—) lẹ́yìn àwọn ìbéèrè kan. Á dáa kó o dánu dúró níbi tó o bá ti rí i, kí o jẹ́ kí ọmọ rẹ dáhùn ìbéèrè náà.

ÌBÉÈRÈ:

  • Kí nìdí tí ilẹ̀ ayé kò fi jẹ́ Párádísè lónìí?

  • Àṣírí pàtàkì wo ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

  • Kí ni Jésù sọ fún àwọn èèyàn nípa àṣírí yìí?

  • Tó o bá fẹ́ máa gbé nínú Párádísè, kí lo gbọ́dọ̀ ṣe?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́