Tẹlifíṣọ̀n “Olùkọ́ Tó Ń kọ́ Wa Láìmọ̀”
Ọ̀PỌ̀ ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ ni tẹlifíṣọ̀n ń kọ́ wa. Òun ló ń jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn ilẹ̀ àtàwọn èèyàn tá ò bá tí mọ̀ nípa wọn. Ó dà bíi pé ó máa ń mú wa rìnrìn-àjò lọ sáwọn igbó kìjikìji, orí àwọn òkìtì yìnyín, àwọn téńté orí òkè, ó sì tún máa ń mú wa dé ìsàlẹ̀ ibú. Ó ń mú ká mọ̀ nípa àwọn nǹkan pípabanbarì bí àwọn nǹkan akéréjojú àtàwọn ìràwọ̀. Ojú ẹsẹ̀ táwọn nǹkan ń ṣẹlẹ̀ láti apá ibi tó jìnnà jù lọ láyé là ń gbọ́ nípa wọn. Ó ń jẹ́ ká mọ ohun tó ń lọ lágbo òṣèlú, à ń mọ ìtàn, àwọn ọ̀rọ̀ tó ń lọ láwùjọ àti àṣà. Tẹlifíṣọ̀n ń sọ̀rọ̀ lórí tibi-tire tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn. Ó ń dá wa lára yá, ó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ń ru wá sókè.
Àmọ́ ọ̀pọ̀ ètò orí tẹlifíṣọ̀n ò bójú mu kò sì ní ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn tó ń bẹnu àtẹ́ lu àpọ̀jù ìwà ipá àti ìbálòpọ̀ tí wọ́n ń gbé jáde kedere lórí tẹlifíṣọ̀n ni wọ́n pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń ta ko tẹlifíṣọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Amẹ́ríkà fi hàn pé méjì nínú mẹ́ta lára ètò tí wọ́n bá ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n ló máa ń ní àwọn ìran ibi tí wọ́n ti hùwà ipá, èyí ló sì jẹ́ kó pọ̀ tó ìwà ipá mẹ́fà tí wọ́n máa ń fi hàn láàárín wákàtí kan. Nígbà tí ọ̀dọ́ kan bá fi máa dàgbà, á ti wo ẹgbẹẹgbẹ̀rún eré tí wọ́n ti hùwà ipá tí wọ́n sì pa èèyàn nínú ẹ̀. Ìṣekúṣe pàápàá á ti pàpọ̀jù. Ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n ló ní ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ nínú, ìdá márùndínlógójì nínú ìdá ọgọ́rùn-ún ló ń fi ìwà ìṣekúṣe hàn, ṣe ni wọ́n sì máa ń fi í hàn bí ohun tí kò léwu kankan tó sì jẹ́ láàárín àwọn méjì tí kì í ṣe tọkọtaya.a
Jákèjádò ayé làwọn ètò tó ń gbé ìwà ipá àti ìbálòpọ̀ jáde ti ń gbayì. Àwọn fíìmù ilẹ̀ Amẹ́ríkà, tí wọ́n fi ìwà ipá àti ọ̀ràn ìbálòpọ̀ dárà sínú ẹ̀, tí wọ́n sì ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n máa ń tètè dé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Kò pọn dandan káwọn tó kópa nínú ẹ̀ ṣe é dáadáa tàbí kí wọ́n kọ ìtàn náà tìṣọ́ratìṣọ́ra, kò ṣòro láti yé àwọn tó ń wò ó. Kó bàa lè di àrímáleèlọ fáwọn òǹwòran, wọ́n máa ń rí i pé ìjà, ìpànìyàn, ìró àti ohùn lóríṣiríṣi àti ìbálòpọ̀ pọ̀ nínú ẹ̀ dáadáa. Àmọ́, bí wọ́n bá fẹ́ káwọn èèyàn máa jókòó ti tẹlifíṣọ̀n fún àkókò pípẹ́, wọ́n ní láti máa yíwọ́ padà. Tó bá jẹ́ pé ohun kan náà làwọn òǹwòran ń rí ṣáá, á tètè máa sú wọn; ohun tó ń jọ wọ́n lójú tẹ́lẹ̀ á di ohun tó ti sú wọn. Kó má bàa wá di pé ó sú wọn, àwọn tó ń ṣe fíìmù máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti rí i pé eré náà ṣẹ̀rù bà wọ́n ó sì dùn mọ́ wọn nípa jíjẹ́ kí ìwà ipá inú fíìmù pọ̀ sí i, káwọn òṣèré máa bara wọn ṣèṣekúṣe fàlàlà, kí ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀ sì máa ṣàn.
Àríyànjiyàn Lórí Ọṣẹ́ Tí Tẹlifíṣọ̀n Ń Ṣe
Táwọn èèyàn bá ń wo ìwà ipá àti ìbálòpọ̀ lemọ́lemọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n kí ló lè ṣe fún wọn? Àwọn lámèyítọ́ sọ pé ìwà ipá orí tẹlifíṣọ̀n ń mú káwọn èèyàn máa hùwà jàgídíjàgan ó sì ń mú kójú wọn dá nígbà tí wọ́n bá rí ẹni tí wọ́n hùwà ipá sí lójúkojú. Wọ́n tún sọ pé bí wọ́n ṣe ń gbé ìbálòpọ̀ jáde ń mú káwọn èèyàn túbọ̀ máa ṣèṣekúṣe, ó sì ń mú káwọn èèyàn pa ìwà ọmọlúwàbí tì.
Ṣé lóòótọ́ ni wíwo tẹlifíṣọ̀n ń fa gbogbo ohun tí wọ́n ló ń fà yìí? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún làwọn tó ń jiyàn lórí ọ̀ràn yìí ti ń fà á mọ́ ara wọn lọ́wọ́; ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwádìí tó fi mọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé àti àpilẹ̀kọ ni wọ́n ti kọ lórí ọ̀ràn yìí. Ọ̀kan lára kókó tó ń fa arukutu jù ni bó ṣe ṣòro láti mú ẹ̀rí wá pé ohun kan ń fa òmíràn. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ń wá ẹ̀rí láti fi tì í nídìí pé bí ọmọdé bá ń ti kùtùkùtù ayé ẹ̀ jókòó sídìí tẹlifíṣọ̀n tó ń wo ìwà ipá, á máa ṣèjàngbọ̀n tó bá dàgbà tán. Nígbà míì, ó máa ń ṣòro láti fẹ̀rí hàn pé tẹlifíṣọ̀n wíwò ń fa ìwà jàgídíjàgan. Bí àpẹẹrẹ: Ká ní o lo oògùn kan fúngbà àkọ́kọ́ tó sì wá ṣẹlẹ̀ pé kòkòrò sú sí gbogbo ara ẹ láàárín wákàtí mélòó kan sígbà tó o lo oògùn náà. Nínú irú ipò yẹn, ó rọrùn láti sọ pé oògùn náà ló fa ohun tó sú sí ẹ lára. Àmọ́ nígbà míì, díẹ̀díẹ̀ ni nǹkan ọ̀hún á bẹ̀rẹ̀. Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ó lè ṣòro láti sọ pé oògùn kan téèyàn lò ló fà á, torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kí nǹkan ṣeni yàtọ̀ sírú oògùn téèyàn bá lò.
Bákan náà, ó ti ṣòro láti fẹ̀rí ẹ̀ hàn pé ìwà ipá tí wọ́n ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n ń ṣokùnfà ìwà ọ̀daràn àti ìwà míì tí kò yẹ láwùjọ. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìwádìí tí wọ́n ṣe fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀. Bákan náà, àwọn ọ̀daràn kan ti sọ pé ohun táwọn rí lórí tẹlifíṣọ̀n ló mú káwọn máa ṣe báwọn ṣe ń ṣe. Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ti fojú rí nínú ìgbésí ayé wọn. Àwọn eré oníwà ipá táwọn èèyàn ń wò lórí kọ̀ǹpútà, ìkọ́kúkọ̀ọ́ tí wọ́n ń kọ́ látọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ àti ará àti inú ipò tí wọ́n ti ń gbé ìgbésí ayé wọn lè wà lára àwọn ohun tó ń mú kí wọ́n hùwà jàgídíjàgan.
Abájọ tó fi jẹ́ pé èrò àwọn èèyàn takora wọn lórí ọ̀ràn náà. Ọ̀gbẹ́ni afìṣemọ̀rònú kan lórílẹ̀-èdè Kánádà kọ̀wé pé: “Ẹ̀rí tá a rí nínú ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ò fi hàn pé wíwo ìwà ipá máa ń mú káwọn èèyàn hùwà ipá tàbí kó mú kí ìwà ipá má jọ wọ́n lójú mọ́.” Àmọ́, ìgbìmọ̀ táwọn afìṣemọ̀rònú nílẹ̀ Amẹ́ríkà gbé kalẹ̀ lórí ọ̀ràn ohun tó ń jáde lórí afẹ́fẹ́, ìyẹn American Psychological Association Committee on Media and Society, sọ pé: “Ó dájú ṣáká pé àwọn tó ń wo ìwà ipá láwòjù lórí tẹlifíṣọ̀n kì í fi bẹ́ẹ̀ róhun tó burú nínú ìwà ipá àti ìwà jàgídíjàgan.”
Wo Bí Tẹlifíṣọ̀n Ṣe Ń Nípa Lórí Ìrònú Rẹ
Rántí o, ohun táwọn amòye ń jiyàn lé lórí ni ẹ̀rí. Wọ́n fẹ́ mọ̀ bóyá wọ́n lè fẹ̀rí tì í nídìí pé wíwo tẹlifíṣọ̀n lè mú kéèyàn di oníjàgídíjàgan. Ṣàṣà èèyàn láá jiyàn pé tẹlifíṣọ̀n ò lè nípa lórí bá a ṣe ń ronú àti bá a ṣe ń hùwà. Rò ó wò ná. Tá a bá wo fọ́tò kan ṣoṣo, ó lè mú kí inú bí wa, ká yọ omijé lójú tàbí kó múnú wa dùn. Orin pẹ̀lú máa ń ru wá lọ́kàn sókè gan-an ni. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá tẹ̀ sórí ìwé gan-an lè mú ká ronú tàbí ká ní ìmọ̀lára tàbí ká tiẹ̀ ṣe nǹkan kan. Ẹ wá wo bí ipa tó máa ní lórí wa ṣe máa pọ̀ tó bí wọ́n bá wá fọgbọ́n pa àwòrán, orin àti ọ̀rọ̀ pọ̀! Abájọ tí tẹlifíṣọ̀n fi máa ń rí èèyàn mú mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀! Ó sì wá wà káàkiri. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Látìgbà tí ẹ̀dá ti mọ bó ṣe yẹ kó máa kọ èrò ẹ̀ sílẹ̀, . . . kò tíì sí nǹkan ìgbàlódé táwọn èèyàn fi lè gbé èrò wọn jáde tó lágbára bíi tẹlifíṣọ̀n.”
Àwọn olókòwò máa ń ná ẹgbàágbèje owó sórí ìpolówó ọjà lọ́dọọdún torí wọ́n mọ̀ pé ohun táwọn tó ń wo tẹlifíṣọ̀n bá rí àtohun tí wọ́n bá gbọ́ á nípa lórí wọn. Kì í ṣe pé wọ́n rò pé ìpolówó ọjà á mú kí ọjà àwọn tà ni wọ́n ṣe ń ná adúrú owó yẹn; kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ìpolówó ọjà á mú kí ọjà àwọn tà wẹ̀rẹ̀wẹ̀rẹ̀. Lọ́dún 2004, ilé iṣẹ́ Coca-Cola ná bílíọ̀nù méjì àti igba mílíọ̀nù dọ́là lórí ìpolówó ọjà wọn jákèjádò ayé nípa pípolówó ẹ̀ nínú ìwé, lórí rédíò àti lórí tẹlifíṣọ̀n. Ǹjẹ́ wọ́n ríbi tó dáa náwó wọn sí báyìí? Ilé iṣẹ́ yẹn jèrè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù méjìlélógún dọ́là lọ́dún yẹn. Àwọn tó ń polówó ọjà mọ̀ pé pípolówó ọjà lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ò lè ṣí àwọn oníbàárà nídìí láti wá rajà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ ni pé tó bá ti tó ọ̀pọ̀ ọdún táwọn ti ń nu ẹnu mọ́ àǹfààní tó wà nínú ríra ọjà náà, àwọn èèyàn á rà á.
Bí ìpolówó ọjà tí wọ́n fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú péré ṣe bá lè nípa lórí ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn, ó dájú pé tí wọ́n bá fi wákàtí gbọọrọ wo tẹlifíṣọ̀n, á nípa lórí wọn. Òǹkọ̀wé tó pìtàn nípa tẹlifíṣọ̀n, Television—An International History, sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣe kedere fáyé rí, tẹlifíṣọ̀n ti di olùkọ́ tó ń kọ́ wa láìmọ̀ látàrí bó ṣe máa ń dáni lára yá wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tàbí bó ṣe máa ń ṣé e lemọ́lemọ́.” Ìwé náà, A Pictorial History of Television sọ pé: “Tẹlifíṣọ̀n ń yí ọ̀nà tá à ń gbà ronú padà.” Ìbéèrè tó yẹ ká bi ara wa nìyí, ‘Ṣé ohun tí mò ń wò yìí ń nípa lórí ìrònú mi lọ́nà tí mo fẹ́ kó gbà nípa lórí ẹ̀?’
Ìbéèrè yẹn nítumọ̀ pàtàkì fáwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ohun tó ń jáde lórí tẹlifíṣọ̀n ló ta ko ìlànà Ọlọ́run tí kò gba gbẹ̀rẹ́ àti ọ̀nà ìwà híhù tó wà nínú Bíbélì. Ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ìwé Mímọ́ sọ pé kò dáa ni wọ́n ń gbé jáde bí èyí tó ṣètẹ́wọ́gbà, tó dáa tó sì bóde mu pàápàá. Bákan náà, wọn kì í sábà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó wà fáwọn Kristẹni lórí tẹlifíṣọ̀n, ṣe ni wọ́n máa ń bẹnu àtẹ́ lu irú ìlànà bẹ́ẹ̀ tàbí àwọn tó ń fi wọ́n sílò, tí wọ́n á sì fi wọ́n ṣẹlẹ́yà. Òǹkọ̀wé kan sọ ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ pé: “Kì í ṣe pé tẹlifíṣọ̀n wulẹ̀ ń sọ ìwà ìbàjẹ́ di ohun tó tọ́ nìkan ni. Àmọ́, ó ti sọ ohun tó tọ́ di ìwà ìbàjẹ́ lójú àwọn èèyàn.” Lemọ́lemọ́ ṣáá ni “olùkọ́ tó ń kọ́ wa láìmọ̀” yìí ń sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ pé: “Ohun tí ó dára burú àti pé ohun tí ó burú dára.”—Aísáyà 5:20.
Ó yẹ ká kíyè sí ohun tá à ń wò o, torí pé ó máa nípa lórí ìrònú wa. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń jẹ́ Adam Clarke sọ pé: “Láti bá ẹnì kan rìn túmọ̀ sí nínífẹ̀ẹ́ ẹni náà àti rírọ̀ mọ́ ọn; kò sì sí bá ò ṣe ní í fara wé àwọn tá a nífẹ̀ẹ́. Ìdí nìyí tá a fi máa ń sọ pé ‘Fi ọ̀rẹ́ rẹ hàn mí kí n lè sọ irú èèyàn tó o jẹ́.’ Jẹ́ kí n mọ àwọn tó ò ń bá rìn, kíá ni màá sọ irú ìwà tó ò ń hù.” Gẹ́gẹ́ bá a ti ṣe rí i, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lo àkókò tó pọ̀ gan-an níwájú àwọn òṣèré orí tẹlifíṣọ̀n tí ò lọ́gbọ́n kankan lórí, àwọn tó jẹ́ pé Kristẹni tòótọ́ ò tiẹ̀ ní ronú àtipè wá sínú ilé ẹ̀.
Tí dókítà rẹ bá ní kó o lo oògùn kan tó lágbára, àfàìmọ̀ lo ò ní fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò àǹfààní àti ewu tó wà nínú lílo oògùn náà dáadáa. Ìdí ni pé tó o bá lo oògùn tí kò yẹ kó o lò tàbí tó o tiẹ̀ lo àpọ̀jù oògùn tó yẹ kó o lò pàápàá, ó lè pa ẹ́ lára. Bákan náà lọ̀rọ̀ wíwo tẹlifíṣọ̀n. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a máa wò.
Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó jẹ́ òótọ́, tó ní ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, tó jẹ́ òdodo, tó jẹ́ mímọ́ níwà, tó dára ní fífẹ́, tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ohun tó jẹ́ oníwà funfun àti ohun tó yẹ fún ìyìn. (Fílípì 4:6-8) Ṣé wàá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yẹn? Tó o bá tẹ̀ lé e, wàá láyọ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àbọ̀ ìwádìí tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Amẹ́ríkà yìí jọ èyí tí wọ́n ṣe láwọn ibòmíì, torí pé kárí ayé ni wọ́n ti ń wo àwọn ètò tí wọ́n ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n nílẹ̀ Amẹ́ríkà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
“Tẹlifíṣọ̀n jẹ́ ohun táwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ gbé wá táá jẹ́ kó o lè gba àwọn èèyàn tó ò fẹ́ nílé ẹ láàyè láti wá máa dá ẹ lára yá nínú ilé ẹ níbẹ̀.”—David Frost, agbóhùnsáfẹ́fẹ́ kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ọ̀RỌ̀ NÍPA ÌBÁLÒPỌ̀ ÀTI ÌWÀ IPÁ TÍ WỌ́N KỌ SÍNÚ BÍBÉLÌ ŃKỌ́?
Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìwà ipá àti ìbálòpọ̀ tí wọ́n ń fi hàn lórí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn tí Bíbélì mẹ́nu kàn? Láwọn ibi tí Bíbélì ti mẹ́nu kan ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá, ṣe ló mẹ́nu bà á láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kì í ṣe láti dáni lára yá. (Róòmù 15:4) Òtítọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn ọ̀ràn ká lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn.
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti máa ń polówó ọjà lórí tẹlifíṣọ̀n, ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá tí wọ́n ń fi hàn kì í ṣe láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, torí owó ni. Àwọn tó ń polówó ọjà ń wá ọ̀nà láti fa àwọn èrò tó pọ̀ lójú mọ́ra ni, ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá sì máa ń mú káwọn èèyàn kàndí mọ́lẹ̀ níwájú tẹlifíṣọ̀n. Ìyẹn á wá mú kí wọ́n wo ìpolówó ọjà náà, kí wọ́n sì ra ohun tí wọ́n ń polówó. Ìlànà táwọn oníròyìn máa ń tẹ̀ lé ni: “Tí jàǹbá bá pọ̀ nínú ìròyìn, á ṣeé kà kún ìròyìn pàtàkì.” Ohun tí wọ́n ń fìyẹn sọ ni pé àwọn ìròyìn tó dá lórí ìwà ipá, àjálù àti ogun ló máa ń lókìkí ju àwọn ìròyìn tí kò láwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkọsílẹ̀ ìwà ipá wà nínú Bíbélì, ó rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa gbé ìgbé ayé alálàáfíà, kí wọ́n má máa gbẹ̀san, àmọ́ kí wọ́n máa yanjú ọ̀ràn ní ìtùnbí-ìnùbí. Gbọnmọgbọnmọ ló ń kìlọ̀ lòdì sí ìṣekúṣe. Àwọn ohun tí Bíbélì ń sọ yìí kọ́ ni ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n ń sọ.—Aísáyà 2:2-4; 1 Kọ́ríńtì 13:4-8; Éfésù 4:32.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
OHUN TÍ TẸLIFÍṢỌ̀N Ń ṢE FÁWỌN ÈWE
“Látàrí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwádìí tí wọ́n ti ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ àtàwọn elétò ìlera gbogbo gbòò ti rí ẹ̀rí tó mú kí wọ́n gbà pátápátá pé wíwo ìwà ipá lórí tẹlifíṣọ̀n lè wu àwọn ọmọdé léwu.”—Ilé Iṣẹ́ Henry J. Kaiser Family Foundation.
“[A gbà pẹ̀lú] àjọ kan tó ń rí sí ìdàgbàsókè àwọn ọmọdé nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ìyẹn American Academy of Pediatrics, lórí bí wọ́n ṣe sọ pé ‘kí àwọn ọmọdé láti ọmọ ọdún méjì sísàlẹ̀ má máa wo tẹlifíṣọ̀n.’ Ṣe ni ọpọlọ àwọn ọmọdé wọ̀nyí ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà, ó sì yẹ kí wọ́n máa ṣeré tí wọ́n á máa lọ́wọ́ nínú ẹ̀ kí wọ́n sì máa bá àwọn èèyàn gidi ṣeré torí pé ìyẹn ló máa mú kí wọ́n dẹni tó bá àwùjọ mu.” —Ilé iṣẹ́ The National Institute on Media and the Family.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
Ṣé ohun tí mò ń wò yìí ń darí ìrònú síbi tí mo fẹ́ máa ronú gbà?