Lílo Tẹlifíṣọ̀n Tìṣọ́ratìṣọ́ra
ÌRÒYÌN tí àwùjọ kan tó ń kíyè sí ilé iṣẹ́ ìròyìn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kó jọ, tí wọ́n pè ní Not in the Public Interest—Local TV News in America, sọ pé, tẹlifíṣọ̀n ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí “òpìtàn pàtàkì, adámọjókòó àti olùyí èrò ará ìlú padà. Tẹlifíṣọ̀n wà káàkiri . . . Bí èéfín sìgá ló ṣe wà káàkiri.” Bí fífa èéfín sìgá símú sì ṣe léwu ni lílo ọ̀pọ̀ wákàtí nídìí wíwo tẹlifíṣọ̀n ṣe lè ṣe ìpalára fún èèyàn, pàápàá jù lọ fún àwọn ọmọdé.
Táa bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá orí tẹlifíṣọ̀n, ìròyìn kan náà tún sọ pé, “ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwádìí ló ti fi hàn pé wíwo ìran oníwà ipá lórí tẹlifíṣọ̀n máa ń nípa òdì lórí bí àwọn ọmọ ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, ó ń sọ wọ́n di òfínràn, àti aláìlójú àánú.” Ẹgbẹ́ Àwọn Oníṣègùn Amẹ́ríkà sọ ní ọdún 1992 pé, “ìwà ipá orí tẹlifíṣọ̀n jẹ́ ewu pàtàkì tó ń halẹ̀ mọ́ ìlera àwọn ọ̀dọ́.”
Báwo lo ṣe lè ṣeé kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n má ṣèpalára fún àwọn ọmọ rẹ? Ìròyìn náà pèsè àwọn ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, èyí tí wọ́n fà yọ láti inú àwọn àbá tí díẹ̀ lára àwọn àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ará ìlú mú wá, nípa bí a ṣe lè túbọ̀ lo tẹlifíṣọ̀n tìṣọ́ratìṣọ́ra. Díẹ̀ lára àwọn àbá náà nìyí.
◼ Fètò sí bóo ṣe ń wo tẹlifíṣọ̀n kóo sì jẹ́ kó mọ níwọ̀n. Fi ààlà sí ìgbà tí àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ wò ó mọ. Má ṣe gbé tẹlifíṣọ̀n sí iyàrá àwọn ọmọ.
◼ Gbé àwòrán àgbáyé sẹ́gbẹ̀ẹ́ tẹlifíṣọ̀n kí àwọn ọmọ bàa lè máa wo àwọn ibi tí wọ́n ń rí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lára rẹ̀.
◼ Wo tẹlifíṣọ̀n pẹ̀lú àwọn ọmọ kí o bàa lè ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó jẹ́ ìtànjẹ lásán àti ohun tó jẹ́ òótọ́ fún wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí kò tíì pé ọdún mẹ́wàá ni kì í mọ̀yàtọ̀ nínú wọn.
◼ Gbé tẹlifíṣọ̀n kúrò níbi tí ọwọ́ tí lè tó o fàlàlà nínú ilé. Gbé e síbi tóo ti lè tilẹ̀kùn mọ́ ọn. Ìyẹn á mú kó ṣòro díẹ̀ fún wọn láti tàn án, kí wọ́n sì máa yí i láti ìkànnì kan sí òmíràn.