ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/06 ojú ìwé 8-9
  • Béèyàn Ṣe Lè Pinnu Ìwọ̀n Táá Máa Wò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Béèyàn Ṣe Lè Pinnu Ìwọ̀n Táá Máa Wò
  • Jí!—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílo Tẹlifíṣọ̀n Tìṣọ́ratìṣọ́ra
    Jí!—2000
  • Ṣé Tẹlifíṣọ̀n Ń Jani Lólè Àkókò Lóòótọ́?
    Jí!—2006
  • Tẹlifíṣọ̀n “Olùkọ́ Tó Ń kọ́ Wa Láìmọ̀”
    Jí!—2006
Jí!—2006
g 10/06 ojú ìwé 8-9

Béèyàn Ṣe Lè Pinnu Ìwọ̀n Táá Máa Wò

CLAUDINE sọ pé: “Tá a bá ti tan tẹlifíṣọ̀n báyìí, gbogbo ohun tí wọ́n bá ti ń ṣe lórí ẹ̀ la máa ń wò, ṣe la ó máa ti orí ètò kan dé orí òmíràn. A ò ní pa á títí dìgbà tá a bá fẹ́ lọ sùn.” Àwọn kan máa ń sọ pé: “Mi ò tiẹ̀ lè gbójú kúrò lára ẹ̀,” àwọn míì sì máa ń sọ pé, “Kò wù mí kí n máa wo tẹlifíṣọ̀n tó bí mo ṣe ń wò ó yẹn, ṣùgbọ́n mi ò rọ́gbọ́n dá sí i ni.” Ṣó ò tíì máa wo tẹlifíṣọ̀n jù? Ṣò ó ń ṣàníyàn lórí ipa tí tẹlifíṣọ̀n lè máa ní lórí ìdílé rẹ? Àwọn àbá díẹ̀ tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ rèé tí wàá fi lè máa pinnu bó o ṣe fẹ́ máa wo tẹlifíṣọ̀n tó.

1. KÍYÈ SÍ BÍ OHUN TÓ Ò Ń WÒ ṢE PỌ̀ TÓ. Òwe 14:15: sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Ìwà ọgbọ́n ni pé kó o ṣàyẹ̀wò bó o ṣe ń wo tẹlifíṣọ̀n tó kó o lè mọ̀ bó o bá ní láti dín àkókò náà kù. Fi bí ọ̀sẹ̀ kan ṣàkọsílẹ̀ iye àkókò tó o fi ń wo tẹlifíṣọ̀n. O tún lè kọ àwọn ètò tó o wò sílẹ̀, àwọn ohun tó o rí kọ́ nínú ẹ̀ àti bó o ṣe gbádùn àwọn ètò yẹn tó. Pàtàkì ibẹ̀ ṣáà ni pé kó o ṣírò iye àkókò tó o fi ń jókòó sídìí tẹlifíṣọ̀n. Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti rí bí àkókò tó ò ń lò ṣe pọ̀ tó. Tó o bá rí bí àkókò tó o fi ń wo tẹlifíṣọ̀n ṣe pọ̀ tó nínú ọjọ́ ayé ẹ, ìyẹn nìkan ti tóó mú kó o wá nǹkan ṣe sí i.

2. DÍN IYE ÀKÓKÒ TÓ Ò Ń LÒ NÍDÌÍ Ẹ̀ KÙ. Gbìyànjú kó o má wo tẹlifíṣọ̀n lọ́jọ́ kan, lọ́sẹ̀ kan tàbí lóṣù kan. Ẹ̀wẹ̀, o tún lè fi gbèdéke lé iye àkókò tí wàá fi máa wo tẹlifíṣọ̀n lójúmọ́. Tó o bá dín ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kúrò lára àkókò tó o fi ń wo tẹlifíṣọ̀n lójoojúmọ́, wàá ní wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lóṣooṣù tó o lè lò fún nǹkan míì. Fi àkókò yẹn ṣe nǹkan míì tó nítumọ̀, bíi ṣíṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, kíka ìwé tó dáa tàbí lílo àkókò yẹn pẹ̀lú ẹbí àtọ̀rẹ́. Ìwádìí fi hàn pé àwọn tó ń wo tẹlifíṣọ̀n níwọ̀nba ló máa ń gbádùn ẹ̀ ju àwọn tó ń wò ó láwòjù.

Ọ̀nà kan téèyàn lè gbà dín àkókò tó ń lò nídìí tẹlifíṣọ̀n kù ni pé kó gbé e kúrò ní yàrá. Àwọn ọmọ tí tẹlifíṣọ̀n wà ní yàrá wọn máa ń fi ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wákàtí kan ààbọ̀ wo tẹlifíṣọ̀n ju àwọn ọmọ tí kò sí tẹlifíṣọ̀n ní yàrá wọn lọ. Yàtọ̀ síyẹn, tí tẹlifíṣọ̀n bá wà ní yàrá ọmọ kan, òbí ò ní mọ ohun tọ́mọ náà ń wò. Táwọn òbí àtàwọn tọkọtaya náà bá gbé tẹlifíṣọ̀n tó wà ní yàrà tí wọ́n ń sùn kúrò, wọ́n á rí i pé àwọn á tún rí ààyè fún ara wọn sí i. Àwọn kan ti pinnu pé ní tàwọn ò, àwọn ò ní ní tẹlifíṣọ̀n nílé rárá.

3. ṢÈTÒ OHUN TÍ WÀÁ MÁA WÒ. A mọ̀ pé àwọn ètò tó dáa pọ̀ téèyàn lè máa wò lórí tẹlifíṣọ̀n o. Àmọ́, dípò tí wàá fi máa ti ìkànnì kan dé òmíràn, tàbí tí wàá fi máa wo gbogbo ohun tí wọ́n bá ti ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n, wo ibi tí wọ́n máa ń kọ ètò tí wọ́n máa ṣe sí kó tó dìgbà tí wọ́n máa ṣe é kó o bàa lè yan èyí tó o fẹ́ wò. Ìgbà tí ètò tó o fẹ́ wò bá bẹ̀rẹ̀ ni kó o tó tan tẹlifíṣọ̀n kó o sì pa á ní gbàrà tí ètò náà bá parí. Tàbí kẹ̀, dípò tí wàá fi máa wo ètò kan ní àkókò tí wọ́n bá gbé e sórí afẹ́fẹ́, o lè fẹ́ ká a sínú kásẹ́ẹ̀tì kó o lè wò ó nígbà mìíràn. Ìyẹn á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti wò ó nígbà míì tó bá rọrùn fún ẹ kó o sì lè yọ ìpolówó ọjà kúrò nínú ohun tí wàá wò.

4. ṢÀṢÀYÀN. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé lákòókò wa yìí, àwọn èèyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, [àti] olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” Ó ṣeé ṣe kó o gbà pé bí ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré orí tẹlifíṣọ̀n ṣe rí nìyẹn. Bíbélì gbani nímọ̀ràn pé “yà kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí.” (2 Tímótì 3:1-5) Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ fún wa pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 15:33.

Ẹni tó bá máa lè ṣàṣàyàn á jẹ́ ẹni tó lè kó ara ẹ̀ níjàánu. Ṣó ti ṣe ẹ́ rí pé kó o wo apá ìbẹ̀rẹ̀ eré tàbí fíìmù kan tó o sì rí i pé eré tàbí fíìmù tó ò ń wò yẹn kò bójú mu, síbẹ̀ tó o wo fíìmù náà tán porogodo, torí pé o fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé ohun tó ò ń wò? Ó ti ṣe ọ̀pọ̀ bẹ́ẹ̀ rí. Àmọ́, tó o bá lè jàjà pa tẹlifíṣọ̀n náà kó o fi lè ráàyè ṣe nǹkan míì, ó ṣeé ṣe kó o rí i pé ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ wù ẹ́.

Kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe tẹlifíṣọ̀n, onísáàmù náà sọ pé: “Èmi kì yóò gbé ohun tí kò dára fún ohunkóhun ka iwájú mi.” (Sáàmù 101:3) Ì bá mà dáa o tá a bá fìyẹn ṣe àkọmọ̀nà wa tá a máa fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ yan ohun tá a máa wò! Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ṣe bíi ti Claudine, tó jẹ́ pé wọ́n pinnu láti palẹ̀ tẹlifíṣọ̀n wọn mọ́. Obìnrin yẹn sọ pé: “Mi ò mọ̀ pé tẹlifíṣọ̀n ti jẹ́ kí ojú mi dá tó bẹ́ẹ̀. Bí mo bá láǹfààní láti wo tẹlifíṣọ̀n báyìí, ńṣe làwọn ohun tí kì í ṣe mí ní nǹkan kan tẹ́lẹ̀ wá ń pá mi láyà. Ohun tí mo máa ń rò tẹ́lẹ̀ ni pé mò ń ṣọ́ra lórí ohun tí mò ń wò, àmọ́ mo ti wá mọ̀ báyìí pé kò rí bẹ́ẹ̀. Tí mo bá wá wo nǹkan tó dáa, mo túbọ̀ máa ń gbádùn ẹ̀.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ṣàkọsílẹ̀ iye àkókò tó ò ń lò níbi tó o ti ń wo tẹlifíṣọ̀n

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Fàwọn nǹkan tó túbọ̀ nítumọ̀ rọ́pò wíwo tẹlifíṣọ̀n

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Má rora láti pa tẹlifíṣọ̀n yẹn!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́