Ṣé Tẹlifíṣọ̀n Ń Jani Lólè Àkókò Lóòótọ́?
BẸ́NÌ kan bá ní òun á fún ọ ní mílíọ̀nù kan dọ́là tó o bá ti lè gbà láti má wo tẹlifíṣọ̀n mọ́ títí ayé ẹ, ṣé wàá gbà? Ní nǹkan bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n wádìí èyí lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà mélòó kan, ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn tí wọ́n bi léèrè ló sọ pé àwọn ò lè má wo tẹlifíṣọ̀n. Wọ́n ṣe ìwádìí láti mọ ohun táwọn ọkùnrin fẹ́ jù lọ. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn sọ pé àwọn fẹ́ àlàáfíà àti ayọ̀. Ṣùgbọ́n ohun kejì tó ṣe pàtàkì sí wọn nìyẹn ṣá. Ohun tó jẹ wọ́n lógún jù lọ nígbèésí ayé wọn ni tẹlifíṣọ̀n abógiridọ́gba!
Jákèjádò ayé ni wọ́n ti mọ tẹlifíṣọ̀n bí ẹní mowó. Lọ́dún 1931, nígbà tí tẹlifíṣọ̀n kọ́kọ́ dé, alága ilé iṣẹ́ rédíò ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ìyẹn Radio Corporation of America, sọ pé: “Nígbà tí tẹlifíṣọ̀n bá gbajúgbajà tán, ibi téèyàn ò bá sí lágbàáyé nìkan ni wọn ò ti ní máa wò ó.” Ọ̀rọ̀ náà lè dà bí àsọdùn nígbà tó kọ́kọ́ sọ ọ́, àmọ́ ní báyìí ó ti di òdodo ọ̀rọ̀. Wọ́n fojú bù ú pé iye tẹlifíṣọ̀n tó wà jákèjádò ayé á tó nǹkan bíi bílíọ̀nù kan ààbọ̀, àwọn tó sì ń wo tẹlifíṣọ̀n pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ fíìfíì. Báwọn èèyàn fẹ́, bí wọ́n kọ̀, ipa kékeré kọ́ ni tẹlifíṣọ̀n ń kó nínú ìgbésí ayé wọn.
Tẹ́ ẹ bá gbọ́ iye àkókò táwọn èèyàn fi ń wo tẹlifíṣọ̀n, ẹnu á yà yín. Láìpẹ́ yìí, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe kárí ayé fi hàn pé àkókò táwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fi ń wo tẹlifíṣọ̀n lójúmọ́ lé díẹ̀ ní wákàtí mẹ́ta. Àwọn ará Amẹ́ríkà Àríwá máa ń lò tó wákàtí mẹ́rin àtààbọ̀ lójúmọ́ nídìí tẹlifíṣọ̀n. Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Japan tí wọ́n máa ń pẹ́ jù nídìí ẹ̀, máa ń lò tó wákàtí márùn-ún lójúmọ́. Tá a bá ro gbogbo àkókò yẹn pọ̀, a ó rí i pé ó ti pọ̀ jù. Tá a bá ń fi wákàtí mẹ́rin wo tẹlifíṣọ̀n lójúmọ́, tá a bá fi máa lo ọgọ́ta ọdún láyé, a ó ti lò tó àpapọ̀ ọdún mẹ́wàá nídìí tẹlifíṣọ̀n. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, kò sẹ́ni táá fẹ́ kí wọ́n kọ ọ́ sí ojú oórì òun lẹ́yìn tóun bá kú pé: “Èyí ni sàréè ẹni wa àtàtà; ìdá mẹ́fà ọjọ́ ayé ẹ̀ ló fi wo tẹlifíṣọ̀n.”
Ṣé torí pé àwọn èèyàn ń gbádùn wíwo tẹlifíṣọ̀n ni wọ́n ṣe ń wò ó? Ó lè rí bẹ́ẹ̀ nígbà míì, ó sì lè máà rí bẹ́ẹ̀ nígbà míì. Ọ̀pọ̀ ló mọ̀ pé àkókò táwọn ń lò nídìí tẹlifíṣọ̀n ti pọ̀ jù, tí ọkàn wọn sì máa ń dá wọn lẹ́bi pé àwọn ń fàkókò àwọn ṣòfò. Àwọn kan sọ pé tẹlifíṣọ̀n wíwò ti di bárakú fáwọn. Lóòótọ́, tẹlifíṣọ̀n wíwò kì í di bárakú fún èèyàn bíi ti oògùn olóró, àmọ́ àwọn méjèèjì fàwọn nǹkan kan jọra. Àwọn tó ń lo oògùn olóró máa ń lo àkókò tó pọ̀ nídìí irú oògùn bẹ́ẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fẹ́ máa lo àkókò tó bẹ́ẹ̀ nídìí ẹ̀ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fẹ́ fi í sílẹ̀, kì í ṣeé ṣe fún wọn. Torí oògùn tí wọ́n ń lò, wọ́n yááfì àwọn nǹkan tó da àwọn àtàwọn ẹlòmíì pọ̀, tó fi mọ́ ìdílé wọn, tí wọ́n bá sì ṣíwọ́ oògùn lílò, ará wọn kì í yá. Gbogbo nǹkan tó ń ṣe ẹni tó ń lo oògùn olóró yìí ló lè ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó ń wo tẹlifíṣọ̀n láwòjù.
Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba sọ pé: “Jíjẹ oyin ní àjẹjù kò dára.” (Òwe 25:27) Ìlànà yìí kan náà kan ọ̀rọ̀ wíwo tẹlifíṣọ̀n. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan dáadáa lèèyàn lè rí wò nínú tẹlifíṣọ̀n, àmọ́ wíwo tẹlifíṣọ̀n láwòjù lè gba àkókò tó yẹ kéèyàn lò pẹ̀lú ìdílé ẹ̀, kó ṣàkóbá fún ìwé kíkà, kó mú káwọn ọmọ máa jó àjórẹ̀yìn nínú ẹ̀kọ́ wọn, kó sì tún fa sísanra jọ̀kọ̀tọ̀. Tó o bá máa ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wo tẹlifíṣọ̀n, ó bọ́gbọ́n mu fún ẹ láti ronú lórí èrè tó ò ń rí nídìí ẹ̀. Àkókò wa ṣe pàtàkì ju ohun tó yẹ ká máa fi ṣòfò lọ. Bákan náà, ó mọ́gbọ́n dání fún wa láti ronú lórí irú ètò orí tẹlifíṣọ̀n tá à ń wò. A óò jíròrò kókó yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn báyìí.