Ọgọ́rùn-ún Ọdún Rèé Tá A Ti Ń Polongo Ìjọba Ọlọ́run!
1. Kí la rọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà pé kí wọ́n ṣe ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn?
1 “Ẹ wò ó, Ọba náà ti ń ṣàkóso! Ẹ̀yin ni aṣojú tí ń polongo rẹ̀. Torí náà, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere, ẹ fọn rere Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Arákùnrin Rutherford ló sọ ọ̀rọ̀ tó ń tani jí yìí ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn. Ńṣe ló rọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà pé kí wọ́n polongo Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn níbi gbogbo. Ohun tí a sì ń ṣe gan-an nìyẹn! Bíi tàwọn tó kọ́kọ́ di Kristẹni, a ti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kól. 1:23) Kí la ti ṣe láti polongo Ìjọba Ọlọ́run ní ọgọ́rùn-ún ọdún kan tó ń pé lọ yìí? Báwo la ṣe lè túbọ̀ polongo Ìjọba Ọlọ́run bí a ṣe ń sún mọ́ ọgọ́rùn-ún ọdún tí Ọlọ́run gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ ní ọ̀run?
2. Báwo ni àwọn ìtẹ̀jáde wa ṣe ń gbé Ìjọba Ọlọ́run lárugẹ?
2 Ohun Tá A Ti Ṣe: Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn ìtẹ̀jáde wa ti ń gbé Ìjọba Ọlọ́run lárugẹ. Láti ọdún 1939 ni olórí ìwé ìròyìn wa ti ní àkọlé náà: Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà. Ìwé ìròyìn yìí máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tí yóò ṣe. Ìwé ìròyìn Jí! náà máa ń tẹnu mọ́ ọn pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìṣòro aráyé. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì yìí ni ìwé ìròyìn tí wọ́n túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ, tí wọ́n sì pín káàkiri jù lọ láyé!—Ìṣí. 14:6.
3. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a ti gbà polongo Ìjọba náà?
3 Àwa èèyàn Jèhófà ti lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti polongo Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, a lo àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí wọ́n so ẹ̀rọ gbohùngbohùn mọ́, àwọn ètò orí rédíò àti ẹ̀rọ giramafóònù tó ṣeé gbé rìn. Àwọn ọ̀nà tá a mẹ́nu kàn yìí ti jẹ́ ká lè tan ìhìn rere náà kálẹ̀ dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn nígbà tí àwọn tó ń pòkìkí Ìjọba náà kéré jọjọ. (Sm. 19:4) Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, onírúurú ìsọfúnni la ti gbé sórí ìkànnì jw.org, èyí tó ń jẹ́ ká lè polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àìmọye èèyàn, títí kan àwọn tó ń gbé ní àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa.
4. Àwọn ọ̀nà àkànṣe wo la ti gbà wàásù?
4 Àwa èèyàn Jèhófà tún ti lo àwọn ọ̀nà àkànṣe ká lè tan ìhìn rere náà káàkiri. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún 1995, a bẹ̀rẹ̀ sí í mú kí ọ̀nà tá a gbà ń wàásù gbòòrò sí i. Láfikún sí iṣẹ́ ìwàásù láti ilé délé, à ń wàásù níbi ìgbafẹ́, ibi ìgbọ́kọ̀sí àti láwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣòwò. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ṣètò àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí káàkiri ayé. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìjọ ti ń wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ wọn, wọ́n á to àwọn ìwé wa sórí tábìlì àtàwọn ohun tó ṣeé gbé kiri láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí. Síbẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé ṣì ni ọ̀nà kan pàtàkì lára àwọn ọ̀nà tá a gbà ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run.—Ìṣe 20:20.
5. Àwọn àǹfààní wo ni ọ̀pọ̀ lára wa máa ní lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tuntun tó ń bọ̀ yìí?
5 Ohun Tá A Fẹ́ Ṣe: Ọ̀pọ̀ máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní oṣù September tó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn tuntun. Ṣé ìwọ náà á fẹ́ di aṣáájú-ọ̀nà déédéé? Ǹjẹ́ o lè máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ látìgbàdégbà tí o kò bá lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé? Bóyá o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà tàbí o kò lè ṣe é, ó dájú pé Jèhófà yóò bù kún ọ fún gbogbo ohun tó o ṣe torí kó o lè kópa nínú iṣẹ́ pípolongo Ìjọba náà.—Mál. 3:10.
6. Kí nìdí tí oṣù October ọdún 2014 fi máa ṣàrà ọ̀tọ̀?
6 Oṣù October ọdún 2014 ló máa pé ọgọ́rùn-ún ọdún tí Ọlọ́run gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ ní ọ̀run. Ó bá a mu wẹ́kú bí ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí à ń fi sóde lóṣù October ṣe dá lórí Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti pín ìwé ìròyìn yìí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Bá a ṣe ń retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ǹjẹ́ kí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa bá a lọ ní “pípolongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run” fún gbogbo àwọn tó bá fetí sílẹ̀.—Ìṣe 8:12.