Ọdún 1914 sí Ọdún 2014 Ọgọ́rùn-ún Ọdún tí Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Ní ọdún 1922, Arákùnrin J.F. Rutherford kéde pé: “Ẹ wò ó, Ọba náà ti ń ṣàkóso! . . . Ẹ fọn rere Ọba náà àti ìjọba rẹ̀.” Ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Rutherford sọ nígbà yẹn ṣì ń mórí wa yá gágá ní báyìí tó ti pé ọgọ́rùn-ún ọdún kan tí Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso. Ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti mú kí oṣù August yìí jẹ́ oṣù mánigbàgbé nípa lílo Ìkànnì wa láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run!