Ta Ló Yẹ Kó Pinnu Bí Ìdílé Yóò Ṣe Tóbi Tó?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRAZIL
NÍ ỌMỌ ọjọ́ mẹ́ta péré, wọ́n gbé ọmọkùnrin náà jù sílẹ̀ nínú àpò láílọ́ọ̀nù kan ní ibùdókọ̀ abẹ́lẹ̀ kan. Àmọ́, ìwé agbéròyìnjáde kan ní Brazil sọ pé àwọn ìdílé bíi mélòó kan yọ̀ọ̀da láti gba ọmọ jòjòló náà ṣọmọ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn gangan kò wọ́pọ̀, iye àwọn ọmọ tí a kò fẹ́ àti àwọn tí a ń gbé jù síbì kan ń pọ̀ sí i jákèjádò ayé. Mímọ ẹrù iṣẹ́ níṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òbí kì í sábà sí lọ́pọ̀ ìgbà. Ìlànà málòóyún ha ni ojútùú rẹ̀ bí? Yóò ha ṣàìtọ́ láti wéwèé bí ìdílé ẹni yóò ṣe tóbi tó?
Gẹ́gẹ́ bí Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé ti sọ, nǹkan bí ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún oyún tí àwọn ènìyàn ń ní lágbàáyé ni wọn kò wéwèé rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe pé wọn kò wéwèé oyún nìkan ni ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ ẹ pẹ̀lú.
Àwọn púpọ̀ wá ọ̀nà láti má ṣe lóyún, bóyá nítorí ìṣòro ìlera, ilé gbígbé, tàbí ti iṣẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ìlànà málòóyún, bí àwọn hóró egbòogi ìfètòsọ́mọbíbí tàbí kọ́ńdọ̀mù, wọ́pọ̀. Ìṣẹ́yún àti ìṣodi-aláìlèbímọ ni a tún máa ń lò bí ìlànà ìfètòsọ́mọbíbí. Nípa ìṣẹ́yún ní Brazil, ìwé agbéròyìnjáde O Estado de S. Paulo ròyìn pé: “Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú díwọ̀n pé lọ́dọọdún, mílíọ̀nù 5 lára mílíọ̀nù 13 àwọn obìnrin tí ń lóyún ní Brazil máa ń ṣẹ́ oyún náà ní bòókẹ́lẹ́.” Bákan náà, ìwé ìròyìn Time sọ pé ìpín 71 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn obìnrin Brazil tí wọ́n ṣì lè bímọ, tí n gbé pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin, ní ń ṣàkóso ìbímọ. Lára wọn, ìpín 41 nínú ọgọ́rùn-ún ní ń lo hóró egbòogi, tí a sì ti sọ ìpín 44 nínú ọgọ́rùn-ún di aláìlèbímọ.
Ìwádìí kan fi hàn pé ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ará Brazil lérò pé ó pọn dandan láti fètò sí iye ọmọ. Àwọn mìíràn kọ ìfètòsọ́mọbíbí nítorí èrò ìgbàgbọ́ nínú kádàrá tàbí nítorí ríronú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí ìdílé ní ‘ọmọ púpọ̀ gan-an bí Ọlọ́run bá ṣe fún wọn tó.’ Ta ló yẹ kó pinnu bí ìdílé yóò ṣe tóbi tó—ire àǹfààní àwọn tọkọtaya tàbí ti orílẹ̀-èdè tàbí ti ìsìn ni bí?
Ìṣàkóso Ìbímọ—Èrèdí Àríyànjiyàn Nípa Rẹ̀?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì, ìsìn tí ó tóbi jù lọ ní Brazil, fàyè gba ìlànà ṣíṣàìní ìbálòpọ̀ nígbà ìmẹ́yinjáde, wọ́n ta ko àwọn ìlànà málòóyún, yálà ó mú ìṣẹ́yún lọ́wọ́ tàbí kò mú ìṣẹ́yún lọ́wọ́. Póòpù Paul Kẹfà sọ pé: “Gbogbo ìbálòpọ̀ láàárín tọkọtaya [ní láti] fàyè gba títàtaré ìwàláàyè.” Póòpù John Paul Kejì sọ pé: “Bí a bá fojú gidi wo ìlànà málòóyún, kò bófin mu rárá débi pé, fún ìdí èyíkéyìí, a kò lè dá a láre.” Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Kátólíìkì lọ́ra láti ṣàkóso bí ìdílé wọ́n ṣe tóbi tó, ní wíwo ìlànà málòóyún gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìwé àtìgbàdégbà ìṣègùn náà Lancet polongo pé: “Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn yóò lo ìgbésí ayé láìní ìmọ̀ ẹ̀kọ́, láìríṣẹ́ṣe, láìrí ilé gidi gbé àti láìlè jàǹfààní ìṣètò ìlera, ìfẹ́dàáfẹ́re àti ìmọ́tótó kíkéré jù lọ, lájorí okùnfà gbogbo rẹ̀ sì ni ìlọsókè iye araàlú tí a kò ṣàkóso rẹ̀.” Nípa bẹ́ẹ̀, ní bíbẹ̀rù àkúnya ènìyàn àti ipò òṣì, àwọn ìjọba kan ń fún ìfètòsọ́mọbíbí níṣìírí, bí ṣọ́ọ̀ṣì tilẹ̀ lòdì sí i. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè, Paul Ehrlich, sọ pé, fún àpẹẹrẹ, “Costa Rica dín ìpíndọ́gba iye ọmọ tí a ń bí [ní ìdílé kọ̀ọ̀kan] kù láti 7 sí 3.”
Ìtẹ̀jáde àjọ UN náà Facts for Life—A Communication Challenge sọ pé: “Lẹ́yìn tí obìnrin kan bá ti bímọ mẹ́rin, oyún mìíràn máa ń fa ewu púpọ̀ jù fún ìwàláàyè àti ìlera tìyátọmọ. Pàápàá jù lọ bí obìnrin kì í bá fi àlàfo tí ó ju ọdún méjì lọ sáàárín àwọn ọmọ tó ti bí ṣáájú, níní oyún, bíbímọ, fífọ́mọlọ́mú, àti títọ́jú àwọn ọmọ kéékèèké léraléra lè mú kí ara obìnrin tètè gbó.”
Ìdílé títóbi ṣì wọ́pọ̀ níbi tí ikú ọmọ jòjòló ti pọ̀, pàápàá jù lọ ní àwọn agbègbè ìgbèríkó Áfíríkà, Éṣíà, àti Latin America. Kí ló fà á? Púpọ̀ lára wọn ni kò mọ̀ nípa àwọn ìlànà málòóyún. Gẹ́gẹ́ bí aṣòfin kan ṣe sọ, ohun kan tí ó jẹ́ okùnfà rẹ̀ ní àwọn agbègbè kan lè jẹ́ pé, “kí ọkùnrin kan máa ka ara rẹ̀ sí ẹni tí ara rẹ̀ pé kìkì bí ìyàwó rẹ̀ bá ń lóyún lọ́dọọdún.” Ìwé agbéròyìnjáde Jornal da Tarde mẹ́nu kan ohun mìíràn tí ó lè jẹ́ okùnfà rẹ̀, pàápàá jù lọ ní ojú ìwòye ti obìnrin náà pé: “Àwọn ọmọ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orísun ìdùnnú ṣíṣọ̀wọ́n, ó sì ń fún wọn ní ìmọ̀lára àṣeyọrí ara ẹni.” Bákan náà, Paulo Nogueira Neto, akọ̀wé àná fún ẹ̀ka ìgbòkègbodò àyíká ẹ̀dá ní Brazil, sọ pé: “Ọmọ lalátìlẹyìn ẹni tó bá dọjọ́ alẹ́.”
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, fi í sílẹ̀ fún ọkọ àti ìyàwó láti pinnu bí ìdílé yóò ṣe tóbi tó? Ó tún fi hàn pé ìgbéyàwó tọ́, yálà fún mímú irú ọmọ jáde tàbí fún fífi ìfẹ́ni hàn nípasẹ̀ níní ìbálòpọ̀ takọtabo tí ó lọ́lá.—Kọ́ríńtì Kìíní 7:3-5; Hébérù 13:4.
Àmọ́, Ọlọ́run kò ha wí fún Ádámù àti Éfà nínú Párádísè pé kí wọ́n ‘máa bí sí i, kí wọ́n sì máa rẹ̀, kí wọ́n sì gbilẹ̀’ bí? (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Bẹ́ẹ̀ ni, síbẹ̀ kò sí ohun kan nínú Bíbélì tí ó fi hàn pé a wà lábẹ́ àṣẹ kan náà yẹn lónìí. Òǹkọ̀wé Ricardo Lezcano tọ́ka sí i pé: “Ó fẹ́ẹ́ jọ pé àìbáramu bákan ṣáá wà nínú lílo ìlànà kan náà tí a lò nínú ọ̀ràn àwọn méjì péré tí wọ́n jẹ́ olùgbé pílánẹ́ẹ̀tì yìí àti nínú ọ̀ràn [ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù] ẹ̀dá ènìyàn.” Kódà, bí ìpinnu náà bá jẹ́ láti má ṣe bímọ rárá, yíyàn ara ẹni tí a ní láti bọ̀wọ̀ fún ni.
Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé ojú ìwòye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ èyí tí a gbé karí Bíbélì. Ó wí pé: “Yàtọ̀ sí ìṣàkóso ìbímọ, tí wọ́n fi sílẹ̀ fún tọkọtaya láti pinnu, ìwà rere wọn ní ti ipò ìgbéyàwó àti ìbálòpọ̀ takọtabo le koko gan-an.” Ó fi kún un pé: “Wọ́n ka Bíbélì sí orísun kan ṣoṣo fún èrò ìgbàgbọ́ àti ìlànà ìhùwà wọn.”
Ǹjẹ́ gbogbo ọ̀nà tí a ń gbà díwọ̀n bí ìdílé yóò ṣe tóbi tó ló tọ́? Rárá. Níwọ̀n bí ìwàláàyè ti jẹ́ ohun ṣíṣeyebíye, Òfin Ọlọ́run sí Ísírẹ́lì pàṣẹ pé kí a wo ẹnikẹ́ni tí ó bá fa ìṣẹ́yún bí apànìyàn. (Ẹ́kísódù 20:13; 21:22, 23) Ní ti ọ̀ràn ìsọdi-aláìlèbímọ, irú bí nípa iṣẹ́ abẹ yíyọ ẹ̀yà ìbímọ, ìpinnu náà jẹ́ ti àdáṣe ẹ̀rí ọkàn ẹni, níwọ̀n bí a kò ti mẹ́nu kan èyí ní tààrà nínú Bíbélì. “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5)a Bí ó sì ti jẹ́ pé onírúurú ìlànà ìṣàkóso ìbímọ ló wà, ìtọ́sọ́nà ìṣègùn lè ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ láti pinnu bóyá wọ́n dàníyàn láti lo irú kan pàtó tàbí wọn kò fẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ṣe Àwọn Ìpinnu Tí Apá Rẹ Yóò Ká
Gbogbo ohun tí ó wà nínú ìgbésí ayé kọ́ ni a lè wéwèé. Àmọ́, ìwọ yóò ha ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí ilé kan láifèrò gidi sí ohun tí yóò ná ọ? A lè tún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí ilé tà, àmọ́ a kò lè dá àwọn ọmọ padà. Nígbà náà, tí a bá ń wéwèé àtilóyún, kò ha yẹ kí a ronú nípa agbára ọkọ àti ìyàwó láti pèsè àwọn kòṣeémánìí ìgbésí ayé?
Dájúdájú, a kò ní fẹ́ kí ìdílé wa má jẹunre kánú, bẹ́ẹ̀ ni a kò níí fẹ́ láti jẹ́ ẹrù ìnira fún àwọn ẹlòmíràn. (Tímótì Kìíní 5:8) Nígbà kan náà, yàtọ̀ sí oúnjẹ àti ibùgbé, àwọn ọmọ nílò ẹ̀kọ́ ìwé, ìlànà ìwà rere, àti ìfẹ́.
Ní àfikún sí ṣíṣírò ohun tí yóò gbà ní ti iṣẹ́, owó, àti sùúrù, ó tún yẹ kí a ronú nípa ìlera ìyàwó náà. Fífọgbọ́n wéwèé bí àkókò ìlóyún yóò ti jìnnà síra tó máa ń dáàbò bo ìwàláàyè, ó sì máa ń ṣètìlẹ́yìn fún ìlera tí ó sàn jù. Ìwé Facts for Life sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ jù lọ láti dín àwọn ewu ìlóyún àti ìbímọ kù fún ìyá àti ọmọ jẹ́ láti wéwèé àlàfo àkókò láàárín àwọn ọmọ tí a óò bí. Ewu ìbímọ máa ń pọ̀ jù nígbà tí aboyún náà kò bá ì pé ọdún 18 tàbí tí ó ti lé ní ọdún 35, tàbí tí ó ti ní oyún lẹ́ẹ̀mẹrin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tẹ́lẹ̀, tàbí tí ó bá jẹ́ àlàfo tí kò tó ọdún méjì ló wà láàárín ọmọ kan sí àtẹ̀lé rẹ̀.”
Ó yẹ kí àwọn tọkọtaya tí ń ronú nípa bíbímọ ronú pé, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀, ayé tí ó kún fún ìwà ipá, ìyàn, ogun, àti àìdánilójú ní ti ètò ọrọ̀ ajé ló yí wa ká. (Mátíù 24:3-12; Tímótì Kejì 3:1-5, 13; Ìṣípayá 6:5, 6) Ojúlówó ìfẹ́ fún àwọn ọmọ yóò ran tọkọtaya lọ́wọ́ láti lo ìwòye gidi nípa ayé tí a ń gbé inú rẹ̀, ní mímọ̀ pé títọ́ ọmọ ní àkókò wa jẹ ìpèníjà ńlá. Nítorí náà, dípò wíwulẹ̀ jẹ́ kí àwọn nǹkan máa ṣẹlẹ̀, kí a sì bímọ bí ó bá ṣe wá tó, pẹ̀lú èrò pé gbogbo nǹkan yóò ṣẹnuure, ọ̀pọ̀ ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí yíyan bí ìdílé wọn yóò ṣe tóbi tó, kí àwọn ọmọ wọ́n baà lè gbádùn ìwọ̀n ayọ̀ àti àìléwu ńláǹlà.
Ní àfikún sí ríràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó bọ́gbọ́n mu nípa ọ̀ràn ìdílé, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wa ní ìrètí fífìdí múlẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Bíbélì fi hàn pé ó jẹ́ ète Ẹlẹ́dàá fún ẹ̀dá ènìyàn láti wà láàyè títí láé ní àlàáfíà àti ayọ̀ nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé kan. Láti ṣàṣeparí èyí, Ọlọ́run yóò mú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí wá sí òpin láìpẹ́. Lẹ́yìn náà, nínú ayé tuntun òdodo tí kì yóò ti sí ipò òṣì àti àkúnya ènìyàn, a kì yóò tún gbé àwọn ọmọ sọnù láé nítorí pé a kò fẹ́ wọn.—Áísáyá 45:18; 65:17, 20-25; Mátíù 6:9, 10.
Ní kedere, gbígba ti ẹnìkìíní kejì àti ti àwọn ọmọ rò, àti ojú ìwòye wíwà déédéé nípa ìmúrú-ọmọ-jáde, yóò ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ láti pinnu bí ìdílé wọn yóò ṣe tóbi tó. Dípò wíwulẹ̀ jẹ́ kí àwọn nǹkan máa ṣẹlẹ̀ láìsí ìwéwèé, ó yẹ kí wọ́n máa fi tàdúràtàdúrà wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. “Ìbùkún Olúwa ní í mú ni í là, kì í sì í fi làálàá pẹ̀lú rẹ̀.”—Òwe 10:22.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé-Ìṣọ́nà, November 1, 1985, ojú ìwé 31.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọmọdé ni a ń kọ̀ tì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn ọmọ nílò àbójútó onífẹ̀ẹ́