ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/08 ojú ìwé 10-11
  • Ṣó Dáa Kéèyàn Máa Lo Oògùn Máàjóyúndúró?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó Dáa Kéèyàn Máa Lo Oògùn Máàjóyúndúró?
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Pàtàkì Lọ̀ràn Ẹ̀mí
  • Ọgbọ́n Ọlọ́run Yàtọ̀ sí Ọgbọ́n Orí
  • Ṣé Ó Burú Kí Kristẹni Lo Oògùn Tí Kì Í Jẹ́ Kéèyàn Lóyún?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ta Ló Yẹ Kó Pinnu Bí Ìdílé Yóò Ṣe Tóbi Tó?
    Jí!—1996
  • Bíbélì Dáhùn Ìbéèrè Mẹ́wàá Nípa Ìbálòpọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • O Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nínú Ayé Oníṣekúṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 1/08 ojú ìwé 10-11

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Dáa Kéèyàn Máa Lo Oògùn Máàjóyúndúró?

KÍ LO ti rò ó sí? Ṣó dáa káwọn lọ́kọláya máa lo oògùn máàjóyúndúró? Ó ṣeé ṣe kí ìdáhùn rẹ sinmi lórí ohun tí ẹ̀sìn rẹ bá fi kọ́ ẹ. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé “ìwà ibi pátápátá gbáà ni” ohun yòówù téèyàn bá ṣe láti dènà ọmọ bíbí. Ẹ̀kọ́ míì tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tún fi ń kọ́ni ni pé tọkọtaya tí ò bá fẹ́ oyún ò gbọ́dọ̀ bára wọn lò pọ̀. Nítorí náà, Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì gbà pé, “kò bójú mu” kéèyàn máa lo oògùn máàjóyúndúró.

Ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbà pé bó ṣe yẹ kí ọ̀ràn rí nìyẹn. Àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Pittsburgh Post-Gazette kan tó dá lórí kókó yìí sọ pé “bá a bá dá gbogbo ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ́nà mẹ́rin, ó ju ìdámẹ́ta lọ lára wọn tó gbà pé ó tọ́ kí ṣọ́ọ̀ṣì yọ̀ǹda fáwọn èèyàn láti máa lo oògùn máàjóyúndúró. . . . Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì ni ò sì fara mọ́ ọn.” Linda, tó ti ní ọmọbìnrin mẹ́ta, wà lára àwọn térò wọn yàtọ̀ sí ti ṣọ́ọ̀ṣì, ó gbà pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa lo oògùn máàjóyúndúró. Ó ní: “Mi ò gbà lọ́kàn ara mi pé ẹ̀ṣẹ̀ ni.”

Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní í sọ sí i?

Pàtàkì Lọ̀ràn Ẹ̀mí

Ọlọ́run ka ẹ̀mí ọmọdé sí pàtàkì, kódà nígbà tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà níkùn ìyá rẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọ́run darí Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì láti kọ̀wé pé: “Ìwọ ni ó yà mí sọ́tọ̀ nínú ikùn ìyá mi. . . . Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀.” (Sáàmù 139:13, 16) Bóyún bá ti dúró lára ìyá, ìwàláàyè tuntun ti bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, Òfin Mósè sì fi hàn pé béèyàn bá ṣe ọmọ tí wọn ò tíì bí ní jàǹbá, ó máa dáhùn fún un. A tiẹ̀ rí i kà nínú ìwé Ẹ́kísódù 21:22, 23 pé báwọn ọkùnrin méjì bá ń jìjàkadì, tí wọ́n sì kọlu obìnrin tó lóyún tí oyún rẹ̀ sì wálẹ̀, ọ̀rọ̀ náà gbọ́dọ̀ dé iwájú àwọn adájọ́. Àwọn adájọ́ á gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò kí wọ́n lè mọ̀ bóyá wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é léṣe ni, bó bá sì jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí, ó lè jẹ́ pé ẹ̀mí wọn ni wọ́n máa fi dí i, ìyẹn ni Bíbélì pè ní “ọkàn fún ọkàn.”

Àwọn ìlànà yìí jẹ mọ́ lílo oògùn máàjóyúndúró nítorí pé a rí lára ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń dènà oyún tó máa ń ba oyún jẹ́. Irú àwọn oògùn máàjóyúndúró bẹ́ẹ̀ ò sì bá ìlànà Ọlọ́run tó ní ká má ṣe fọ̀ràn ẹ̀mí ṣeré mu. Àmọ́ ṣá o, èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn oògùn máàjóyúndúró ni kì í ba oyún jẹ́. Béèyàn bá wá ń lo irú àwọn oògùn máàjóyúndúró tí kì í ba oyún jẹ́ yìí ńkọ́?

Kò síbì kankan tí Bíbélì ti pàṣẹ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa bímọ. Ọlọ́run fẹ́ kí tọkọtaya àkọ́kọ́ àti ìdílé Nóà fi ọmọ kún ilẹ̀ ayé. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.” Àmọ́ kò pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fáwọn Kristẹni. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 9:1) Nítorí náà, àwọn tọkọtaya lè dá pinnu bóyá wọ́n á fẹ́ láti bímọ, iye ọmọ tí wọ́n á fẹ́ láti bí àti ìgbà tí wọ́n á fẹ́ láti bí wọn. Bákan náà, Ìwé Mímọ́ ò sọ pé kéèyàn má lo oògùn máàjóyúndúró. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ọwọ́ tọkọtaya ló kù sí láti pinnu bóyá wọ́n á fẹ́ láti máa lo oògùn máàjóyúndúró tí kì í ba oyún jẹ́ tàbí wọn ò ní lò ó. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló wá fà á tí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi sọ pé kò dáa láti máa lo oògùn máàjóyúndúró?

Ọgbọ́n Ọlọ́run Yàtọ̀ sí Ọgbọ́n Orí

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia ṣàlàyé pé ó ti tó ọgọ́rùn-ún ọdún mọ́kàndínlógún báyìí tí àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ti kọ́kọ́ fara mọ́ òfin Sítọ́íkì tó dá lórí ìwà híhù, èyí tó fi kọ́ni pé ìdí kan ṣoṣo tó bófin mu tí tọkọtaya fi lè bára wọn lò pọ̀ ni láti bímọ. Nítorí náà, èrò yìí ò bá Bíbélì mu, ọgbọ́n orí lásán ni. Ọgbọ́n orí yìí ti ń bá a nìṣó látìgbà náà wá, ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì sì fẹ̀ ẹ́ lójú.a Lédè kan ṣá, ibi tí ẹ̀kọ́ náà wá parí sí ni pé wíwulẹ̀ gbádùn ìbálòpọ̀ jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, àti pé ìṣekúṣe gbáà ni ìbálòpọ̀ tí kò bá la ọmọ bíbí lọ. Àmọ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ fi kọ́ni kọ́ nìyẹn o.

Nínú Bíbélì, ìwé Òwe lo èdè ewì láti fi hàn pé bí ìbálòpọ̀ bá wáyé láàárín tọkọtaya, ó máa ń mú kí wọ́n láyọ̀. Ó sọ pé: “Mu omi láti inú ìkùdu tìrẹ, àti omi tí ń sun láti inú kànga tìrẹ. . . . Jẹ́ kí orísun omi rẹ jẹ́ èyí tí ó ní ìbùkún, kí o sì máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ, egbin dídára lẹ́wà àti ewúrẹ́ olóòfà ẹwà ti orí òkè ńlá. Jẹ́ kí ọmú tirẹ̀ máa pa ọ́ bí ọtí ní gbogbo ìgbà. Kí o máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo.”—Òwe 5:15, 18, 19.

Ìbálòpọ̀ láàárín tọkọtaya jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Kì í ṣe ọmọ bíbí nìkan ló wà fún. Ó tún máa ń mú kó ṣeé ṣe fún tọkọtaya láti fìfẹ́ bára wọn lò. Nítorí náà, bí tọkọtaya bá pinnu pé àwọn ò fẹ́ kí ìbálòpọ̀ doyún nípa lílo oògùn máàjóyúndúró, ìpinnu tiwọn nìyẹn, ẹnikẹ́ni ò sì gbọ́dọ̀ dá wọn lẹ́jọ́.—Róòmù 14:4, 10-13.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] ọdún sẹ́yìn ni Ọba Gregory Kẹsàn-án ṣòfin tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia pè ní “òfin gbogbo gbòò àkọ́kọ́ tí póòpù ṣe lòdì sí lílo oògùn máàjóyúndúró.”

KÍ LÈRÒ Ẹ?

◼ Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ wà nínú kí tọkọtaya máa bára wọn lò pọ̀?—Òwe 5:15, 18, 19.

◼ Kí ló yẹ káwọn Kristẹni máa fi sọ́kàn bí wọ́n bá ń lo oògùn máàjóyúndúró?—Ẹ́kísódù 21:22, 23.

◼ Ojú wo ló yẹ káwọn míì fi wo tọkọtaya tó bá ń lo oògùn máàjóyúndúró?—Róòmù 14:4, 10-13.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Ọlọ́run sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ àti ìdílé Nóà pé kí wọ́n fi ọmọ kún ilẹ̀ ayé. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.” Àmọ́ kò pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fáwọn Kristẹni

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́