ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 10/8 ojú ìwé 19-21
  • Rédíò—Ìhùmọ̀ Tó Yí Ayé Padà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Rédíò—Ìhùmọ̀ Tó Yí Ayé Padà
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Tuntun Nínú Ìmọ̀ Ẹ̀rọ
  • Ọgọ́rùn-ún Ọdún Tí Rédíò Ti Wà
  • Àwọn Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù—Gbogbo Ọ̀nà La Fi Ń Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Ṣíṣiṣẹ́sìn Pẹ̀lú Ètò-Àjọ Tí Ń Tẹ̀síwájú Jùlọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpéjọ Agbègbè Lórí Tẹlifíṣọ̀n àti Rédíò
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • 1924—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 10/8 ojú ìwé 19-21

Rédíò—Ìhùmọ̀ Tó Yí Ayé Padà

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍTÁLÌ

ÌRÓ ìbọn kan fòpin sí ìdákẹ́rọ́rọ́ agbègbè àrọko Ítálì náà. Àmì ìsọfúnni yẹn fún Guglielmo Marconi ní ẹ̀rí ìdánilójú pé ohun èèlò àfiṣèpìlẹ̀ tí òún ń lò náà ti ṣiṣẹ́. Àwọn ìgbì ìtànṣán tí ẹ̀yà agbàsọfúnni gbé jáde, tí ó sì tàn ṣán sínú gbalasa òfuurufú ni ìhùmọ̀ tí ń yí ìgbì àmì dà sí ìró ohùn kan ti rí gbà ní ibi tí ó jìnnà tó kìlómítà 2.5. Ó jẹ́ ní 1895. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà náà lọ́hùn-ún, kò sí ẹni tí ó lè lóye gbogbo ohun tí ó túmọ̀ sí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ìró ìbọn yẹn ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kan tí ó ti mú ìyípadà tegbòtigaga wá bá ayé wa—ìgbésọfúnnijáde lórí rédíò.

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ mélòó kan ti ṣèwádìí tẹ́lẹ̀ nípa àbùdá àwọn ìgbì ìtànṣán. Ní 1831, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ England, Michael Faraday, fi hàn kedere pé ìgbì mànàmáná kan lè gbé agbègbè agbára òòfà kan jáde, kí ó sì mú kí ìgbì mànàmáná ṣiṣẹ́ nínú àyíká ìgbì kejì tí a yà sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ ti àkọ́kọ́ ṣùgbọ́n tí a fi sítòsí rẹ̀. Ní 1864, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Scotland, James Maxwell, gbé àbá èrò orí náà jáde pé agbára tí irú agbègbè agbára òòfà bẹ́ẹ̀ ń gbé jáde lè máa tàn ṣán nínú ìgbì—tí ó jọ ìṣẹ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ orí omi ìkudù kan—ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n ìyára iná. Lẹ́yìn náà, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Germany, Heinrich Hertz, fi ẹ̀rí ìjótìítọ́ àbá èrò orí Maxwell hàn, nípa ṣíṣàgbéjáde àwọn ìgbì ìtànṣán, kí ó sì rí wọn ní ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà, gẹ́gẹ́ bí Ernest Rutherford (tí ó wá ń jẹ́, Lord Rutherford, lẹ́yìn náà) ní New Zealand, ti ṣe. Ṣùgbọ́n nípa mímú ohun èèlò tí ó wà bá àyíká mu, tí ó sì sunwọ̀n sí i, àti ní fífi àgbélẹ̀rọ mọ̀galà tí òun fúnra rẹ̀ ṣe sí i, Marconi gbìyànjú fi ìsọfúnni orí wáyà ránṣẹ́ sí ìwọ̀n ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà. Ìfìsọfúnniránṣẹ́ láìta wáyà ń bọ̀ lọ́nà!

Ní 1896, Marconi ẹni ọdún 21 kó kúrò ní Ítálì lọ sí England, níbi tí a ti fi í han William Preece, ọ̀gá àgbà amojú ẹ̀rọ ní Ilé Ìfìwéránṣẹ́ Àpapọ̀. Preece lọ́kàn ìfẹ́ nínú ṣíṣàmúlò ìlànà ti Marconi nínú ìfìsọfúnniránṣẹ́ nínú iṣẹ́ ọkọ̀ òkun láàárín ibi méjì tí a kò lè ta wáyà dé. Ó pèsè àwọn òṣìṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ àti ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fún Marconi láti ràn án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ àṣeyẹ̀wò rẹ̀. Ní oṣù bíi mélòó kan, Marconi ṣàṣeyọrí ní mímú kí agbára gbígbé àmì ìsọfúnni lọ rìn jìnnà sí i dé ibi tí ó tó kìlómítà mẹ́wàá. Ní 1897, Marconi ṣàgbékalẹ̀ Ilé Iṣẹ́ Aláàlà Okòwò Ìgbésọfúnni àti Àmì Ìsọfúnni Ránṣẹ́ Láìta Wáyà, pẹ̀lú ète sísọ ìgbésọfúnniránṣẹ́ láìta wáyà di ètò ìgbékalẹ̀ ìṣòwò tí ó lè gbèrú.

Ní 1900, wọ́n ṣe ìsokọ́ra ìgbésọfúnniránṣẹ́ onírédíò kan tí ó jẹ́ 300 kìlómítà láàárín àrọko Cornwall àti Erékùṣù Wight ní ìhà gúúsù England, ní ṣíṣàfihàn kedere ohun tí a rò nígbà kan rí pé kò lè ṣeé ṣe—gbígbé ìgbì rédíò kọjá láti igun kan ilẹ̀ ayé sí òmíràn. A ti ronú pé àmì ìsọfúnni kò ní lè kọjá gba ibi ìpàdé ilẹ̀ òun òfuurufú, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ní ọ̀gbanrangandan ni àwọn ìgbì ìtànṣán ń rìn.a Lẹ́yìn náà, àwọn ìwé ìbéèrè pàtàkì pàtàkì àkọ́kọ́ fún rédíò bẹ̀rẹ̀ sí í dé. Ẹ̀ka Ọmọ Ogun Òkun Ilẹ̀ Britain fi ṣíṣe rédíò sínú ọkọ̀ òkun 26 lọ́lẹ̀, títí kan kíkọ́ àti ṣíṣàbójútó ibùdó mẹ́fà lórí ilẹ̀. Ní ọdún tó tẹ̀ lé e, Marconi ṣàṣeyọrí gbígbé àmì ìsọfúnni, alámì mẹ́ta tí ó fi lẹ́tà S hàn ní ẹnà alámì tóótòòtó, tí kò hàn ketekete, kọjá lórí òkun Àtìláńtíìkì. Ọjọ́ iwájú ìhùmọ̀ náà dájú.

Ìṣẹ̀lẹ̀ Tuntun Nínú Ìmọ̀ Ẹ̀rọ

Lákọ̀ọ́kọ́, ìgbésọfúnniránṣẹ́ láìta wáyà kò lè gbé yálà ọ̀rọ̀ tàbí orin, kìkì ẹnà alámì tóótòòtó nìkan ló ń gbé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní 1904, ìtẹ̀síwájú kan wáyé nígbà tí wọ́n ṣe túùbù oníwáyà méjì, àkọ́kọ́ túùbù afẹ́fẹ́ onídèérí, tí ó mú kí ìgbésọfúnniránṣẹ́ àti ìgbàsọfúnni ohùn ṣeé ṣe. Èyí ń yí ìgbésọfúnniránṣẹ́ láìta wáyà padà sí rédíò bí a ṣe mọ̀ ọ́n lónìí.

Ní 1906, ní United States, Reginald Fessenden gbé orin, tí àwọn ọkọ̀ òkun tí wọ́n jìnnà tó 80 kìlómítà ń gbọ́ sáfẹ́fẹ́. Ní 1910, Lee De Forest ṣàgbékalẹ̀ ìgbésọfúnniránṣẹ́ ní tààràtà nípa eré orin kan tí olókìkí olóhùn gbẹ̀du, ara Ítálì náà Enrico Caruso ṣe fún àǹfààní àwọn aláìnírìírí nínú iṣẹ́ rédíò ní New York. Ní ọdún tó ṣáájú, àwọn àmì ìsọfúnni láti ṣàtúnṣe àkókò ojú agogo ni a gbé sáfẹ́fẹ́ láti Ilé Ìṣọ́ Eiffel ní Paris, ilẹ̀ Faransé, ní ìgbà àkọ́kọ́. Ní ọdún yẹn kan náà, 1909, àkọ́kọ́ fífi rédíò ṣèrànwọ́ láti yọ àwọn olùla ìjàm̀bá já wáyé, láti inú àwọn ọkọ̀ òkun Florida àti Republic, tí ó forí sọra wọn nínú òkun Àtìláńtíìkì. Ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó lé ní 700 olùlàájá tí a tún yọ nínú ewu ìjábá Titanic, ọpẹ́lọpẹ́ àmì ìsọfúnni nípa ìjàm̀bá tí a gbé sáfẹ́fẹ́ lórí rédíò.

Ní 1916, a ronú nípa níní rédíò kan ní ilé kọ̀ọ̀kan. Lílò túùbù onídèérí mú kí ìgbésọfúnnisáfẹ́fẹ́ gbéṣẹ́, ó mú kí àwọn ohun agbàsọfúnni olówó pọ́ọ́kú ṣeé ṣe, ó sì ṣamọ̀nà sí ṣíṣe ìmújáde rédíò àfidókòwò. Ìbúrẹ́kẹ́ náà kọ́kọ́ wáyé ní United States, níbí tí a ti ní ilé iṣẹ́ rédíò 8 ní òpin 1921, tí 564 sì ti gba ìwé àṣẹ́ nígbà tí ó fi máa di November 1, 1922! Ní ọ̀pọ̀ ilé, yàtọ̀ sí ìṣètò iná mànàmáná, rédíò ni ìhùmọ̀ tí ó kọ́kọ́ bá iná ṣiṣẹ́.

Láàárín ọdún méjì tí ìgbésáfẹ́fẹ́ àfipolówó ti bẹ̀rẹ̀, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà, pẹ̀lú ń lo rédíò láti gbé ìhìn iṣẹ́ wọn sáfẹ́fẹ́. Ní 1922, J. F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà lọ́hùn-ún, sọ ọ̀rọ̀ àwíyé rẹ̀ àkọ́kọ́ lórí rédíò, ní California. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ilé iṣẹ́ WBBR, ilé iṣẹ́ rédíò tí ó jẹ́ ti Watch Tower Society, tí wọ́n kọ́ fúnra wọn, bẹ̀rẹ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ láti Erékùṣù Staten, New York. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Society ṣètò ìsokọ́ra karí ayé kan láti gbé àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì sáfẹ́fẹ́. Nígbà tí ó di 1933, ilé iṣẹ́ rédíò 408 ti ń gbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run sáfẹ́fẹ́.—Mátíù 24:14.

Bí ó ti wù kí ó rí, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, rédíò wáá di ohun tí Ìjọba ń dá ní. Ní Ítálì, ìjọba Mussolini wo rédíò gẹ́gẹ́ bí ohun èèlò fún títan èrò ìṣèlú kálẹ̀, ó sì kà á léèwọ̀ fún àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba rẹ̀ láti má ṣe gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àgbésáfẹ́fẹ́ láti ilẹ̀ òkèèrè. A fi ìwọ̀n agbára tí rédíò ní hàn kedere ní 1938. Lákòókò ìgbésáfẹ́fẹ́ ìtàn àròsọ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ní United States, Orson Welles fa ìpayà fún àwọn ará ìlú, tí àwọn kan lára wọ́n lérò pé àwọn olùgbé inú pílánẹ́ẹ̀tì Mars ti gúnlẹ̀ sí New Jersey, tí wọ́n sì ń lo “ìtànṣán olóoru gbígbóná” kan tí ń ṣè jàm̀bá láti pa gbogbo ẹni tí ó bá lòdì sí wọn!

Ọgọ́rùn-ún Ọdún Tí Rédíò Ti Wà

Ní 1954, ohun àṣenajú tí àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ ní Ítálì jẹ́ gbígbọ́ rédíò. Láìka àṣeyọrí tí tẹlifíṣọ̀n ti ṣe sí, rédíò ṣì gbajúmọ̀ gan-an. Ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè ní Europe, nǹkan bí ìpín 50 sí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún wọ́n ló máa ń gbọ́ rédíò láti gbọ́ ìsọfúnni tàbí fún ìnàjú. A fojú díwọ̀n pé ní United States, ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn mọ́tò, ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún iyàrá, àti ohun tí ó lé ní ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún ilé ìdáná, ló ní rédíò.

Ọ̀kan lára ìdí tí rédíò fi gbajúmọ̀ bẹ́ẹ̀, kódà ní sànmánì tí tẹlifísọ̀n pọ̀, ni ìṣeégbékiri rẹ̀. Síwájú sí i, gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ti sọ, rédíò ní “agbára ìpọkànpọ̀ ní ti èrò ìmọ̀lára àti ìrònúwòye tí ó gbayì gan-an ju ti tẹlifíṣọ̀n lọ.”

Ní 1995, àṣeyẹ ní Ítálì fún àyájọ́ ọgọ́rùn-ún ọdún àṣeyẹ̀wò tí Marconi ṣe pèsè àǹfààní láti ronú lórí ìtẹ̀síwájú tí rédíò ti ní. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti lọ́wọ́ nínú sísọ àgbélẹ̀rọ ìhùmọ̀ àkọ́kọ́ náà di ìhùmọ̀ ìgbàlódé tí ń tẹ̀ síwájú. Nísinsìnyí, ọpẹ́ ni fún ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ẹ̀rọ onínọ́ḿbà, tí ó jẹ́ ìṣètò ẹnà àmì ìsọfúnni onínọ́ḿbà, èyí fi ìgbéjáde ojúlówó ohùn tí ó gbámúṣé dáni lójú. Ṣùgbọ́n ju àfikún sí àìmọye ìlò rédíò lójoojúmọ́, láti orí ìhùmọ̀ náà ni tẹlifíṣọ̀n, radar, àti oríṣiríṣi àwọn iṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ mìíràn ti bẹ̀rẹ̀.

Fún àpẹẹrẹ, a gbé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà nípa ìtànṣán ìgbì rédíò karí gbígbà ìgbì rédíò àti ṣíṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ tí àwọn ìṣẹ̀dá òfuurufú tú jáde. Láìsí rédíò, ìdàgbàsókè ìmọ̀ ẹ̀rọ gbalasa òfuurufú ìbá tí ṣeé ṣe. Gbogbo àwọn ìhùmọ̀ satellite—tẹlifíṣọ̀n, tẹlifóònù, ìṣàkójọ ìsọfúnni oníṣirò—sinmi lórí lílo ìgbì rédíò. Ìdàgbàsókè ìmọ̀ ẹ̀rọ ti lílo àwọn ègé ohun èèlò abánáṣiṣẹ́ pélébé pélébé dípò àwọn transistor ṣàmọ̀nà lákọ̀ọ́kọ́ sí ìhùmọ̀ àfiṣèṣirò àtẹ̀bàpò àti kọ̀m̀pútà àti lẹ́yìn náà sí ipa ìsokọ́ra ìfìsọfúnniránṣẹ́ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.

Àwọn tẹlifóònù alágbèérìn tí ó lè so àwọn ibi méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kọ́ra lórí ilẹ̀ ayé, tàbí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ bẹ́ẹ̀, ti ṣẹlẹ̀ ná. Ohun tí a ń fojú sọ́nà fún nísinsìnyí ni ìmújáde ìhùmọ̀ agbàsọfúnni láìta wáyà tí ó jẹ́ ìwọ̀n àtẹ́lẹwọ́—àpapọ̀ tẹlifíṣọ̀n, tẹlifóònù, kọ̀m̀pútà, ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni. Àwọn ìhùmọ̀ agbàsọfúnni wọ̀nyí ni a óò lè yí sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìkànnì fídíò, ìtẹ́tísí, àti ti lẹ́tà àkọsílẹ̀, wọn óò sì jẹ́ kí àwọn tí ń lò ó lè ṣe pàṣípààrọ̀ ìsọfúnni lórí ohun abánáṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.

Ẹnì kan kò lè fi ọwọ́ sọ̀yà nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ní ẹ̀ka ìmọ̀ yìí. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ẹ̀rọ rédíò ń tẹ̀ síwájú, nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí àwọn ìdàgbàsókè àgbàyanu mìíràn wáyé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àlàyé ohun àràméríyìírí náà wáyé ní 1902, nígbà tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá Arthur Kennelly àti Oliver Heaviside gbé àbá èrò orí jáde nípa wíwà ìpele kan nínú òfuurufú tí ń ṣàgbéyọ àwọn ìgbì ìtànṣán—ìpele ionosphere.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

Láìka àṣeyọrí tí tẹlifísọ̀n ti ṣe sí, rédíò ṣì gbajúmọ̀ gan-an

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]

Lókè lápá òsì àti ọ̀tún, nísàlẹ̀ lápá òsì: “MUSEO della RADIO e della TELEVISIONE” RAI--TORINO; nísàlẹ̀ lápá ọ̀tún: Fọ́tò NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́