Ṣíṣiṣẹ́sìn Pẹ̀lú Ètò-Àjọ Tí Ń Tẹ̀síwájú Jùlọ
GẸ́GẸ́ BÍ ROBERT HATZFELD TI SỌ Ọ́
Lónìí ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ènìyàn ń tan tẹlifíṣọ̀n nípasẹ̀ ẹ̀rọ agbókèèrè darí tẹlifíṣọ̀n lati wo ìròyìn ìrọ̀lẹ́ bí ó ti ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, láì tilẹ̀ kà á sí ohun àrà-ọ̀tọ̀ kan. Síbẹ̀, ṣe ni ó dàbí àná nígbà tí mó jẹ́ ọmọkùnrin ọlọ́dún 12 tí mo ń fi pẹ̀lú ìyàlẹ́nu wo àwòrán ọkùnrin kan tí ìrísí rẹ̀ tóbi ju ti ojú ayé lọ, tí ó sì ń sọ̀rọ̀ lórí àwo sinimá!
ÌWỌ lè ronú pé ìyẹn kìí ṣe ohun tí ojú kò rí rí. Ṣùgbọ́n níti gidi ó dàbí iṣẹ́-ìyanu ìgbàlódé sí mi nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1915, nígbà tí àwọn àwòrán sinimá aláwọ̀ dúdú-òun-funfun tí kìí gbóhùnjáde ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Ọkùnrin onírùngbọ̀n tí ó ní ìrísí fífanimọ́ra kan farahàn lára ògiri ó sì wí pé: “Àwòrán Photo-Drama of Creation ni a óò fihàn láti ọwọ́ I.B.S.A., àwùjọ International Bible Students Association.” Fún wákàtí méjì tí ó tẹ̀lé e, ìtàn Bibeli náà ṣípayá ní ojú wa. Ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ tí a gbékarí Ìwé Mímọ́ ṣe kedere ó sì tunilára. Síbẹ̀ ó jẹ́ àwòrán ara ògiri tí ń rìn, èyí tí a ń fi àwọn àwòrán mèremère, àti ọ̀rọ̀ adúnbárajọ tí ó gba àfiyèsí mi niti gidi bọ̀ ní àárín.
N kò lóye rẹ̀ nígbà náà, ṣùgbọ́n ìtara mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ fún ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ àmúpìtàn yẹn jẹ́ ìtọ́wò fún iṣẹ́ ìgbésí-ayé pẹ̀lú ètò-àjọ tí ń tẹ̀síwájú jùlọ lórí ilẹ̀ ayé.
Àwọn Ọjọ́ Ìbẹ̀rẹ̀
Ní 1891 baba mi ti Dillenburg, ní Germany, wá sọ́dọ̀ àwùjọ àwọn ará Germany ní Allegheny, Pennsylvania, U.S.A. Lẹ́yìn náà ó pàdé ọmọbìnrin kan nínú ìdílé ará Germany kan níbẹ̀, wọ́n sí ṣègbéyàwó. A bí mi ní July 7, 1903, mo sì dàgbà láti máa sọ èdè German àti Gẹ̀ẹ́sì. Kété ṣáájú kí Ogun Àgbáyé I tó bẹ̀rẹ̀ ní 1914, àjàkálẹ̀ àrùn ikọ́ jẹ̀dọ̀jẹ̀dọ̀ já àwọn òbí mi méjèèjì gbà tí mo sì wá di ọmọ òrukàn. Baba mi àgbà ni àìsàn rọlọ́wọ́-rọlẹ́sẹ̀ ṣekú pa ní èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní àsìkò kan náà.
Àbúrò bàbá mi obìnrin, Minna Boemer, fi inúrere gbà mí sínú ìdílé rẹ̀. Ó sọ pẹ́ “mo ní ọmọ márùn-ún. Mo lè ní ọ̀kan síi kẹ̀.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣàárò àwọn òbí mi, àbúrò bàbá mi obìnrin, Minna, pèsè ilé rere fún mi.
Àbúrò bàbá mi obìnrin jẹ́ mẹ́ḿbà ọlọ́jọ́ pípẹ́ nínú Ìjọ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli (bí a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àwọn ọjọ wọ̀nyẹn) ní Allegheny. Ṣáájú 1909, Arákùnrin C. T. Russell, tí ó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà, ń darapọ̀ mọ́ ìjọ yẹn pẹ̀lú. Àbúrò bàbá mi obìnrin, Minna máa ń mú mi lọ sí àwọn ìpàdé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé wa kò ṣe ìsapá kankan papọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ tàbí wàásù nígbà yẹn lọ́hùn-ún, a ń ṣàjọpín ohun yòówù tí a bá gbọ́ ní ìpàdé pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí a mọ̀ láìjẹ́-bí-àṣà.
Láàárín àsìkò yìí ní àwòrán “Photo-Drama” fi mú mi ṣe kàyéfì. Níwọ̀n bí mo ti ní ìfẹ́-ọkàn sí iṣẹ́ tí ó ba ti jẹmọ́ ẹ̀rọ, àwọn ọgbọ́n ìyafọ́tò àti ìdúnbárajọ ohùn àti àwòrán titun náà gbá mí lọ́kàn, gẹ́gẹ́ bí yíyafọ́tò lásìkò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ṣe. Ṣíṣe àkíyèsí àwọn òdòdó tí ń tú jẹ́ ohun tí ń runisókè!
Ní 1916 ikú Arákùnrin Russell bà wá nínú jẹ́. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ní Allegheny gan-an ni a ń gbé, a lọ sí ibi ìsìnkú rẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Carnegie. Ibí yìí ni gbọ̀ngàn tí Arákùnrin Russell ti jiyàn pẹ̀lú E. L. Eaton ní 1903. Mo ti gbọ́ àwọn ìtàn nípa òjíṣẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Episcopal ti Methodist yìí tí ó pe C. T. Russell níjà síbi ìjiyàn ọlọ́jọ́ mẹ́fà, ní ìrètí láti tàbùkù sí jíjẹ́ tí Arákùnrin Russell jẹ́ ọ̀mọ̀wé nínú Bibeli. Kàkà bẹ́ẹ̀, a sọ ọ́ pé, Russell ‘bu omi paná hẹ́ẹ̀lì.’ Sara Kaelin, olùpínwèé ìsìn kiri tí a mọ̀ dáradára ní Pittsburgh, mọ ìdílé Russell dáradára. Ní ibi ìsìnkú o rí Maria Russell tí ń gbé àwọn òdòdó sórí pósí pẹ̀lú àkọsílẹ̀ kékeré náà, “Sí Ọkọ Mi Àyànfẹ́.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọdún mélòókan ṣáájú, síbẹ̀ Maria mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí ọkọ rẹ̀.
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, mo ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti gba ìmọ̀ iṣẹ́-ọnà-ẹ̀rọ tí ó wúlò fún iṣẹ́ ìgbésí-ayé mi ọjọ́ iwájú. Ẹ̀gbọ́n ìyá mi ọkùnrin tí ó jẹ́ alágbàtọ́ mi jẹ́ agbaṣẹ́ ilé-kíkọ́ ṣe. Ní àwọn àkókò ìsinmi mi ní ilé-ẹ̀kọ́, ó jẹ́ kí n bá àwọn oníṣẹ́ mànàmáná rẹ̀ ṣiṣẹ́ ní sísọ odidi ilé-ńlá tí ń lo gáàsì amúnáwá di èyí tí ń lo iná mànàmáná. Ní 1918 àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ wa ṣe ohun èèlò ìtẹwáyà alábọ́ọ́dé. A ń pàdé ní ìrọ̀lẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ kí a sì fi iná mànàmáná àti irin-tútù ṣe àṣeyẹ̀wò ẹ̀kọ́. Ní 1926 èmi àti ọ̀rẹ́ mi pinnu láti lépa ohun tí a ti ń fọkàn rò láti ìgbà ọmọdé—láti ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ ojú-omi kí a sì rìnrìn-àjò kárí-ayé. A forúkọ sílẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ Radio Corporation of America gẹ́gẹ́ bí adarí ẹ̀rọ ìtẹwáyà.
Ìgbésí-Ayé Titun ní Beteli
Ilé-ẹ̀kọ́ rédíò tí a lọ wà ní New York City, nítorí náà mo rìnrìn-àjò sọdá odò lọ sí Brooklyn fún àwọn ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, tí wọn ń ṣe ní gbọ̀ngàn ńlá tí a háyà ní Tẹ́ḿpìlì Masonic àtijọ́. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ìjọ kan péré ni ó wà fún gbogbo agbègbè olú-ìlú New York. Nígbà tí àwọn arákùnrin láti Beteli (ilé ìdílé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí wọ́n wà ní orílé-iṣẹ́) gbọ́ pé mo ń kẹ́kọ̀ọ́ láti gba ìwé-àṣẹ rédíò àfiṣòwò, wọ́n sọ pé: “Èéṣe tí o fi fẹ́ láti lọ sí òkun? A ní ilé-iṣẹ́ rédíò kan níhìn-ín yìí a sì nílò adarí ẹ̀rọ kan.” Wọ́n pè mí láti wá sí ọ́fíìsì fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. N kò mọ ohunkóhun nípa Beteli, ju pé ó jẹ́ orílé-iṣẹ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
Àwọn arákùnrin náà fi ọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò wọ́n sì dábàá kí n parí ilé-ẹ̀kọ́ mi, kí n gba ìwé-àṣẹ, kí n sì wá sí Beteli. Lẹ́yìn tí mo kẹ́kọ̀ọ́yege, dípò dídarapọ̀ mọ́ ọkọ̀ ojú-omi fún lílọ sí ojú òkun ní orílẹ̀-èdè ẹ̀yìn-odi, mo di ìwọ̀nba aṣọ tí mo ní mo sì gba ọ̀nà abẹ́lẹ̀ lọ sí Beteli. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jehofa mo sì ti ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ wíwàásù fún ọ̀pọ̀ ọdún, n kò ṣe ìrìbọmi títí di December 1926, ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí mo dé sí Beteli. Èyí kò ṣàjèjì nígbà yẹn lọ́hùn-ún.
Pẹ̀lú 150 mẹ́ḿbà, Beteli kún àkúnya ní àwọn ọjọ́ wọnnì. Ọkùnrin mẹ́rin ní ń gbé nínú iyàrá kọ̀ọ̀kan. Láìpẹ́ mo di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ jùlọ nínú wọn, níwọ̀n bí gbogbo wa ti ń jẹun, tí a ń ṣiṣẹ́ tí a sì ń sùn papọ̀ nínú àpapọ̀ ilé kan náà, àti pé, ìjọ kanṣoṣo náà tí ó wà ní New York City ni gbogbo wa ń lọ. Ilé Beteli titun tí ó wà ní 124 Columbia Heights ni a kọ́ parí ní 1927, ó wá ṣeéṣe fún wa láti gbé ní méjì-méjì nínú iyàrá kan.
Bákan náà ní 1927 ilé-iṣẹ́-ẹ̀rọ titun tí ó wà ní 117 Òpópónà Adams ni a ṣí. Mo ṣèrànwọ́ láti kó àwọn ohun èèlò ilé-iṣẹ́-ẹ̀rọ àtijọ́ tí ó wà ní 55 Òpópónà Concord. Ní àfikún sí àwọn ohun èèlò rédíò, ní ilé-iṣẹ́-ẹ̀rọ náà, àwọn ẹ̀rọ agbẹ́rùròkè, àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, ohun èèlò ìfọṣọ, ẹrọ ajó nǹkan tí ń lo epo—tí ó bá ní wáyà, ni mo tún ń ṣiṣẹ́ lé lórí.
Ṣùgbọ́n, Beteli ju ilé-iṣẹ́-ẹ̀rọ kan lásán lọ. Ọ̀pọ̀ àwọn onírẹ̀lẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ òṣìṣẹ́ kára, ni ó wà lẹ́yìn gbogbo ìwé, gbogbo ìwé-àṣàrò-kúkúrú, àti gbogbo ìwé ìròyìn. Ète wọn kìí ṣe láti jẹ́ olókìkí nínú ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n wulẹ̀ fẹ́ láti jẹ́ kí iṣẹ́ Oluwa di ṣíṣe—ọ̀pọ̀ sì wà láti ṣe!
Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Arákùnrin Rutherford
Mo jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ láti inú àǹfààní ṣíṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Joseph F. Rutherford, ààrẹ Society kejì. Ó jẹ́ ọkùnrin gbọ̀gbọ̀rọ̀ kan, tí ó ju sẹ̀ǹtímítà 183 lọ ní gíga, kò sanra, ṣùgbọ́n ó síngbọnlẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ arákùnrin ní Beteli ni ó máa ń múpayà bá kí ó tó di pé wọ́n mọ̀ ọ́n. Ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nígbà gbogbo, ní mímúra àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ sílẹ̀.
Arákùnrin Rutherford jẹ́ aláwàdà. Àwọn àgbàlagbà arábìnrin méjì kan wà lára ìdílé Beteli tí wọ́n ti wà níbẹ̀ láti ìgbà Arákùnrin Russell. Ojú wọn máa ń le wọn sí gbàgbọ́ pé kò tọ́ láti rẹ́rìn-ín síta àní bí ohunkóhun bá tilẹ̀ panilẹ́rìn-ín pàápàá. Nígbà mìíràn nídìí oúnjẹ Arákùnrin Rutherford yóò sọ ìtàn kan tí yóò pa gbogbo ènìyàn lẹ́rìn-ín èyí sì ń bí àwọn arábìnrin méjì yìí nínú. Bí ó ti wù kí ó rí, ó sábà máa ń darí àwọn ìjíròrò Bibeli tí ń múni ronú jinlẹ̀ nígbà oúnjẹ.
Arákùnrin Rutherford jẹ́ ọlọ́wọ́ ṣíbí ó sì máa ń gbádùn gbígbọ́únjẹ fún àwọn ọ̀rẹ́. Ní ìgbà kan àwọn tí ń se oúnjẹ ní Beteli fọ́ àwọn egungun adìyẹ nígbà tí wọ́n ń gé àwọn adìyẹ náà. Ó rìn lọ sínú ilé ìdáná ó sì fi ọ̀nà tí ó tọ́ láti gé adìyẹ hàn wọ́n. Kó fẹ́ràn èérún egungun nínú oúnjẹ rẹ̀!
Mo sábà máa ń wà nítòsí Arákùnrin Rutherford ní àwọn ipò tí kìí ṣe bí àṣà, irú bíi ní ilé-iṣẹ́ rédíò, WBBR, tàbí nínú iyàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ni Staten Island. Ó jẹ́ ọkùnrin tí ó láàánú tí ó sì ń fi ohun tí ó ń wàásù rẹ̀ ṣèwàhù. Kò retí ohun ti òun tìkárarẹ̀ kò lè ṣe lọ́dọ̀ ẹlòmíràn. Láìdàbí àwọn kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ní ẹrù-iṣẹ́ nínú ètò ìsìn mìíràn, Arákùnrin Rutherford dàgbà nípa tẹ̀mí ó sì jẹ́ oníwà títọ́. Ó ń gbé ìgbésí-ayé ní kedere fún Ìjọba Jehofa.
Àwọn Ìgbà Ìṣúnná-Owó Lílekoko
Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn tí mo dé Beteli, ayé wọ inú Ìlọsílẹ̀ Ètò Ọrọ̀-Ajé Ńlá. Àwọn ọjà káràkátà dojúdé, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú iye-owó àwọn ọjà. Iṣẹ́ wọ́n, owó kò sì tó nǹkan. Àwọn owó tí a fi ṣètọrẹ ni Beteli ń rí lò, Jehofa sì ń rí síi nígbà gbogbo pé iye tí ó pọ̀ tó wà láti bójútó iṣẹ́ náà. Oúnjẹ kò wọ́n wa rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má jẹ́ ohun náà gan-an tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ń fẹ́. A ń ṣọ́wóná bí a ti lè ṣe tó, àwọn ará tí wọ́n wà lóde Beteli sì ràn wá lọ́wọ́ dé ibi tí agbára wọn mọ.
Arákùnrin Robert Martin, olùṣòtítọ́ alábòójútó ilé-iṣẹ́-ẹ̀rọ wa kú ní 1932. Nathan Knorr ọmọ ọdún 27 ni a yàn dípò rẹ̀. Ó jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó tóótun kan. N kò lè rántí ẹnikẹ́ni tí ó ṣòro fún láti gbà á bí alábòójútó ilé-iṣẹ́-ẹ̀rọ. Àwọn arákùnrin olùṣòtítọ́ mìíràn, nínú wọn ni John Kurzen, George Kelly, Doug Galbraith, Ralph Leffler, àti Ed Becker—gbogbo àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi ọ̀wọ́n—tí wọ́n fínnú-fíndọ̀ ya ọgbọ́n iṣẹ́-ọnà wọn àti ọgbọ́n ìhùmọ̀ wọn sọ́tọ̀ fún iṣẹ́-ìsìn Ìjọba náà.—Fiwé Eksodu 35:34, 35.
Ṣíṣiṣẹ́ Pẹ̀lú Rédíò
Ètò-àjọ wa látòkèdélẹ̀, ni a yàsọ́tọ̀ fún títan ìhìnrere kálẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀nà yòówù tí ó bá ṣeéṣe. Gbogbo ayé níláti mọ̀ nípa Ìjọba náà, ṣùgbọ́n a wulẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún díẹ̀ péré. Ìmọ̀ iṣẹ́-ẹ̀rọ rédíò ṣì jẹ́ titun lẹ́yìn Ogun Àgbáyé I. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn arákùnrin tí wọ́n ní ìfòyemọ̀ nímọ̀lára pé ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ yìí ni ohun tí Jehofa pèsè ní àsìkò yẹn. Nítorí náà ní 1923 wọ́n bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé-iṣẹ́ rédíò WBBR ni Staten Island, ọ̀kan nínú ẹ̀ka márùn-ún tí a pín New York City sí.
Nígbà mìíràn èmi nìkan ní adarí ẹ̀rọ ní ilé-iṣẹ́ wa. Mo ń gbé níbẹ̀ ní Staten Island mo sì ń wọ ọkọ̀ ojú-omi àti ọkọ̀ ojú-irin tí ó gba wákàtí mẹta lọ sí ilé-iṣẹ́-ẹ̀rọ ní Brooklyn láti ṣe iṣẹ́ mànàmáná àti iṣẹ́ ẹ̀rọ. Láti mú kí ilé-iṣẹ́ rédíò wa jẹ́ ti aládàáni, a ṣe ìgbékalẹ̀ ẹ̀rọ amúnáwá tí ń lo epo diesel. Ní Staten Island a tún ní kànga omi tiwa àti ọgbà tí ń pèsè oúnjẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ mélòókan tí wọ́n wà níbẹ̀, àti àwọn ìdílé Beteli ní Brooklyn.
Títí di ìgbà tí ìrànlọ́wọ́ púpọ̀ síi wá lẹ́yìn náà, ẹrù-iṣẹ́ ìṣiṣẹ́ rédíò náà dín lílọ mi sí ìpàdé àti iṣẹ́-ìsìn pápá kù gan-an ni. Kò sí àyè kankan fún àwọn ìgbòkègbodò ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tàbí ìrìn-àjò òpin-ọ̀sẹ̀ ju àkókò ìsinmi wa ọdọọdún. Ẹnìkan bi mí nígbà kan pé: “Pẹ̀lú àwọn ìṣètò tí ó gba ìsapá àti àkókò bẹ́ẹ̀, ìwọ kò ha fìgbà kankan ronú kíkúrò ní Beteli bí?” Nítòótọ́, mo níláti sọ pé: “Bẹ́ẹ̀kọ́.” Ó ti jẹ́ àǹfààní àti ayọ̀ láti gbé àti láti ṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin olùfọkànsìn. Iṣẹ́ máa ń fìgbà gbogbo wà láti ṣe, àwọn ìdáwọ́lé titun díẹ̀ sì máa ń wà láti bójútó.
A ń ṣe ìmújáde a sì ń kéde àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ orí rédíò tí ó runisókè. Láìsí àwọn àwo rẹ́kọ́ọ̀dù láti pèsè àwọn àkànṣe ìró ohùn, a níláti hùmọ̀ àwọn ọgbọ́n tiwa. A ṣe ẹ̀rọ tí ó lè ṣe ìgbéjáde ìró afẹ́fẹ́ tí ó dára tàbí ti ìjì tí ń ru gùdù. Ìró ègé pádi àgbọn tí ń gbá àwọn pákó tí a lẹ nǹkan mọ́ wá di ìró pátákò ẹṣin lórí àwọn òpópónà olókùúta. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìdáwọ́lé ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀. Àwọn ènìyàn sì ń fetísílẹ̀. Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn tí ohun tí ń pín ọkàn níyà kò pọ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń jókòó wọ́n sì ń fetísílẹ̀.
Ní àwọn ọdún 1920 àti ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930, Society ṣe ohun tí o di mánigbàgbé nínú ìtàn rédíò, léraléra ni wọn ń so iye àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó pọ̀ jùlọ papọ̀ fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ kanṣoṣo. Nípa báyìí ìròyìn Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ kárí-ayé.
Ẹ̀rọ tí Ń Lu Àwo Rẹ́kọ́ọ̀dù
Ní agbedeméjì àwọn ọdún 1930 àti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940, a hùmọ̀ a si ṣe àwọn ẹ̀rọ agbóhùnjáde, àwọn ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù, àti àwọn ohun èèlò orin mìíràn. Pẹ̀lú àkànṣe ẹ̀rọ tí ń gé wọn gún, a óò gé àwọn ojúlówó àwo rẹ́kọ́ọ̀dù láti inú ike dídán mólómóló tí a fi ìda oyin ṣe. A óò wá ṣe àyẹ̀wò ojúlówó awò rẹ́kọ́ọ̀dù kọ̀ọ̀kan tìṣọ́ratìṣọ́ra lábẹ́ ẹ̀rọ amóhuntóbi láti rí i pé kò ní àlèébù. Bí àbùkù kankan bá wà, àkókò ìjókòó ìgbohùnsílẹ̀ náà ni a gbọ́dọ̀ túnṣe kí a sì fi ẹ̀rọ gé òmíràn gún. A óò fi ẹ̀dà ojúlówó rẹ́kọ́ọ̀dù tí a fi ìda oyin ṣe náà ránṣẹ́ sí ilé-iṣẹ́ rẹ́kọ́ọ̀dù kan, tí ń ṣe ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù àti àwọn àwo tí ń gbóhùnjáde.
Ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó runisókè ti mo rántí dáradára ni àsọyé Arákùnrin Rutherford ní 1933 tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Àbájáde Ọdún Mímọ́ Lórí Àlàáfíà àti Aásìkí.” Póòpù ti ya ọdún yẹn sọ́tọ̀ bí “ọdún mímọ́,” nípa ìṣèròyìn lórí rédíò àti ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù, a tú u fó a sì fihàn pé kò sí ohun mímọ́ kan tí yóò jáde láti inú rẹ̀. Bí ó ti jásí, Hitler gba ìjọba ní ọdún yẹn pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki, nítorí náà ìrètí èyíkéyìí fún àlàáfíà parẹ́.
Ní orílẹ̀-èdè United States, ètò-àjọ Ajagun Katoliki ni a dásílẹ̀ láti ṣe ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì náà fẹ́ jáde. Wọ́n fi àwọn ènìyàn wọn sí ipò ẹgbẹ́ àwùjọ lọ́gàálọ́gàá ìwé ojoojúmọ́, ìwé ìròyìn fún olóòtú àti àwọn olùṣèwéjáde. Wọn lọ́wọ́ nínú òṣèlú wọ́n sì ń halẹ̀ láti jáwọ́ nínú àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ èyíkéyìí tí ó bá ń gbé àsọyé Bibeli wa jáde. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni ẹgbẹ́ àwọn Ajagun Katoliki kọlù, pàápàá ní New Jersey tí ó wà nítòsí. Àwọn ọjọ́ arùmọ̀lárasókè nìwọ̀nyẹn!
Iṣẹ́ Aláyọ̀ Nínú Pápá
Nígbà tí ó fi máa di agbedeméjì àwọn ọdún 1950, òtú àwọn akéde Ìjọba tí ń pọ̀ síi ń dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn púpọ̀ síi ní ẹnu ọ̀nà ilé wọn gan-an. Èyí wá gbéṣẹ́ dáradára láti ran ẹnìkọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ Bibeli ju rédíò lọ. Nítorí náà ní 1957 ìpinnu wáyé láti ta WBBR kí a sì darí àwọn ohun àmúṣọrọ̀ sórí mímú kí iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní àwọn ilẹ̀ mìíràn gbòòrò síi.
Ní 1955, a pín mi si Ìjọ Bedford ní Brooklyn, níbi tí mo ti ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà déédéé. Society tún rán mi jáde gẹ́gẹ́ bí olùbánisọ̀rọ̀ arìnrìn-àjò sí apá òkè New York, Pennsylvania, Connecticut, àti New Jersey. Nígbà tí a pín mi sí Ìjọ Bedford, mo sọ fún araàmi pé, ‘Mo ti lé ní 50 ọdún báyìí. Ó dára jù kí n nípìn-ín nínú iṣẹ́-ìsìn pápá ní bí mo bá ti lè ṣe é tó nísinsìnyí. Bí ó bá yá mo lè lọ ní làkúrègbé tí n kò sì ní gbádùn rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ mọ́.’
Lẹ́yìn ṣíṣiṣẹ́ fún gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí ní ẹ̀ka iṣẹ́-ọnà ti gbígbé irúgbìn Ìjọba jáde nípasẹ̀ rédíò, ó jẹ́ ohun tí ó gbádùn mọ́ mi láti gbìn àti láti bomirin àwọn irúgbìn òtítọ́ Bibeli ní tààràtà pẹ̀lú ẹnìkọ̀ọ̀kan. Mo gbádùn ṣíṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọ náà gan-an. Onírúurú ènìyàn gbá mi mọ́ra, wọ́n jẹ́ kí ń túraká. Púpọ̀ nínú àwọn ọmọdé wọ̀nyẹn, tí wọ́n ti dàgbà nísinsìnyí, ṣì ń pé mi ní baba àgbà. Fún 30 ọdún a gbádùn araawa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, títí di ìgbà tí ìṣòro ẹsẹ̀ àti àtẹ́lẹsẹ̀ kò jẹ́ kí ń lè gun àtẹ̀gùn tàbí rin ìrìn-àjò ní abẹ́lẹ̀ mọ́. Ní 1985, mo ṣípòpadà lọ sí Ìjọ Brooklyn Heights, tí ń pàdé ní Beteli gan-an.
Bí ètò-àjọ Jehofa ti ń gbádùn ìgbòòrò ńláǹlà, emi bí ẹnìkan ní àǹfààní láti rí ìbùkún rẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ àjèjì bí mo ti lọ sí àwọn àpéjọ àgbègbè ńlá ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àwọn ilẹ̀ tí ó jìnnà. Ó ṣetán, ó ṣeéṣe fún mi láti rìnrìn-àjò kárí-ayé! Bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ọdún 1950, díẹ̀ lára awa òṣìṣẹ́ Beteli lọ láti lọ wo àwọn ibi fífanilọ́kànmọ́ra ní London, Paris, Rome, Nuremberg, àti Copenhagen. A ń rìnrìn-àjò pẹ̀lú àwọn ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n fi ń jagun tẹ́lẹ̀, ọkọ̀ ojú-omi, àti ọkọ̀ ojú-irin. Lóòótọ́, ìrìn-àjò kúkúrú náà kún fún ìran jíjojúnígbèsè tí a wò ní àwògbádùn, ṣùgbọ́n ìran fífanilọ́kànmọ́ra jùlọ ni ti ọ̀pọ̀ àwọn ará ọlọ́yàyà, ẹlẹ́mìí ọ̀rẹ́. Àwọn ẹ̀wádún tí ó tẹ̀lé e mú wa rìnrìn-àjò dé ìhà Ìlà-Oòrùn ayé, Ìwọ̀-Oòrun Europe lẹ́ẹ̀kan síi, àti láìpẹ́ yìí Ìlà-Oòrùn Europe. Àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè ní Poland, Germany àti Czechoslovakia kọyọyọ. Ẹ wo bí ìdílé wa tí Ọlọrun ń ṣàkóso ti dàgbà tó láti ìgbà ti mo ti kọ́kọ́ jẹ́ apákan rẹ̀!
Ìtọ́sọ́nà Àtọ̀runwá
Ohun tí ó dàbí àwọn ìgbésẹ̀ kékeré tí ètò-àjò náà gbé wá di ìgbésẹ̀ tí ó ga gan-an nígbà tí ó yá. Nígbà tí a ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìdáwọ́lé titun, kìkì irin iṣẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà, ta ni ó ti lè ríran tẹ́lẹ̀ rí ìlọsókè tí ó gadabú náà? A ti tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́, ní dídáhùnpadà sí ìdarí Jehofa.
Ètò-àjọ tí ń tẹ̀síwájú yìí kò bẹ̀rù láti lo ìmọ̀-iṣẹ́-ẹ̀rọ tí ó dé kẹ́yìn tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó tàbí láti ṣe tirẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún pápá kárí-ayé. Lára ọ̀nà tí a ń lò láti mú ìpòkìkí Ìjọba náà tẹ̀síwájú ni wíwàásù láti ilé-dé-ilé, ìlo rédíò alásokọ́ra, jíjẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù, àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní ilé àwọn ènìyàn. Ṣíṣèdásílẹ̀ ìwé títẹ̀ tiwa ní àwọn ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀ àti nísinsìnyí lílo ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà onífọ́tò atẹ̀wédíwọ̀n àti ẹ̀rọ ìtẹ̀wé alátẹ̀yípo ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè jẹ́ àṣeyọrí tí kò kéré. Ilé-Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, àti Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun, àti àwọn àpéjọpọ̀ déédéé ni gbogbo wọn ti kó ipa nínú mímú ògo wá fún Jehofa Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀. Ó ti jẹ́ àǹfààní mi láti fojú araami rí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí àti láti kópa nínú wọn.
Ó ṣe kedere sí mi pé ètò-àjọ Jehofa tí orí ilẹ̀-ayé tí a ń fi ẹ̀mí darí ń gba ìtọ́sọ́nà lórí ohun tí ó yẹ láti ṣe àti ọ̀nà àtiṣé é. Ètò-àjọ rẹ̀ àgbáyé lódindi, èyí tí ó ṣeé fojúrí àti èyí tí kò ṣeé fojúrí, ń ṣiṣẹ́ papọ̀.
N kò tíì kábàámọ̀ pípa tí mo pá èrò mi tì gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin láti tukọ̀ la òkun já. Họ́wù, ìdàgbàsókè tí ó wúnilórí, tí ó sì nítumọ̀ jùlọ ní ayé ń ṣẹlẹ̀ níhìn-ín gan-an nínú ètò-àjọ Jehofa! Nítorí náà ìrìn-àjò mi lójú ọ̀nà náà sí ‘ìpè ti òkè’ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti ìbùkún àti àìsí àbámọ̀ kankan ti sàmì sí.—Filippi 3:13, 14, NW.
Mo máa ń sọ fún àwọn ọ̀dọ́ nígbà gbogbo láti rántí 1914—ìyẹn ni, Orin Dafidi 19:14, tí ó sọ pé: “Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, àti ìṣàrò ọkàn mi, kí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ, Oluwa, agbára mi, àti olùdáǹdè mi.” A fẹ́ tẹ́ Jehofa lọ́rùn nínú ohun gbogbo kí a sì gbàdúrà bí Dafidi ti ṣe: “Fi ọ̀nà rẹ hàn mi, Oluwa; kọ́ mi ni ipa tìrẹ. Sìn mí ní ọ̀nà òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi: nítorí ìwọ ní Ọlọrun ìgbàlà mi; ìwọ ni mo dúró tì ní ọjọ́ gbogbo.” (Orin Dafidi 25:4, 5) Ìtumọ̀ púpọ̀ wà nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Rírántí wọn lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà ní ipa-ọ̀nà tí ó tọ́, ní bíbá a lọ ní ìhà tí ó tọ́, ní ìṣísẹ̀rìn pẹ̀lú ètò-àjọ Jehofa tí ń tẹ̀síwájú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Arákùnrin Rutherford gbádùn gbígbọ́únjẹ fún àwọn ọ̀rẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Robert Hatzfeld ni ibi ìdarí ilé-iṣẹ́ rédíò WBBR
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Fọ́tò Arákùnrin Hatzfeld ní àìpẹ́ yìí