Àrùn Arunmọléegun—Ìmọ̀ Ni Ààbò Dídára Jù Lọ
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NÀÌJÍRÍÀ
ÈNÌYÀN 32 wà nínú iyàrá àpérò náà, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ló pọ̀ jù níbẹ̀. Tọ́pẹ́ tí ó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà, tí ara rẹ̀ kò yá, tí ó wọ aṣọ aláwọ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú, jókòó jẹ́ẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyá rẹ̀, lórí àga onípákó kan. Ó ń tẹ́tí sílẹ̀ bí nọ́ọ̀sì ṣe ń sọ fún wọn nípa ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe nígbà tí ìrora náà bá dé.
Tọ́pẹ́ mọ̀ nípa ìrora—ìrora tí ó máa ń le gan-an, tí ó máa ń wá lójijì, tí ó sì máa ń ṣeni fún ọjọ́ púpọ̀ kí ó tó rọlẹ̀. Bóyá ìrora náà ni kò jẹ́ kí ó ṣe ṣámúṣámú bí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
Ìyá rẹ̀ sọ pé: “Òun ni àkọ́bí mi. Láti ìgbà tí mo ti bí i, kò yéé ṣàìsàn. Mo ti lọ sí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n sì ti gbàdúrà fún un. Àmọ́ ó ṣì máa ń ṣàìsàn. Níkẹyìn, mo gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Wọ́n yẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò, wọ́n sì rí i pé alárùn arunmọléegun ni.”
Kí Ni Ó Jẹ́?
Ní Ibùdó Ìtọ́jú Àrùn Arunmọléegun ní Benin City, Nàìjíríà, ìyá Tọ́pẹ́ gbọ́ pé àrùn arunmọléegun jẹ́ ìṣiṣẹ́gbòdì ẹ̀jẹ̀. Ní ìlòdì sí àwọn èrò ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, kò ní ohunkóhun í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ àjẹ́ tàbí ẹ̀mí àwọn òkú. Ara àwọn òbí ni àwọn ọmọ ti ń jogún àrùn arunmọléegun. Kì í ranni. Kò sí ọ̀nà kankan tí o lè gbà kó àrùn náà láti ara ẹlòmíràn. Ó lè jẹ́ pé wọ́n bí i mọ́ ọ ni, tàbí kí wọ́n máà bí i mọ ọ. Ìyá Tọ́pẹ́ tún gbọ́ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé wò sàn, a lè tọ́jú àwọn àmì àrùn náà.a
Àrùn arunmọléegun máa ń ṣẹlẹ̀ jù lọ sí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá láti ilẹ̀ Áfíríkà. Dókítà I. U. Omoike, olùdarí Ibùdó Ìtọ́jú Àrùn Arunmọléegun náà, wí fún Jí! pé: “Àwọn adúláwọ̀ pọ̀ ní Nàìjíríà ju orílẹ̀-èdè èyíkéyìí lọ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ní àwọn alárùn arunmọléegun tí iye wọ́n pọ̀ ju ti orílẹ̀-èdè èyíkéyìí lọ. Èyí ló mú kí orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ olú ìlú àrùn arunmọléegun lágbàáyé.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Daily Times ti Lagos ṣe sọ, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan ará Nàìjíríà ló ní àrùn arunmọléegun, tí ó sì ń pa 60,000 ènìyàn lọ́dọọdún.
Ìṣòro Nínú Ẹ̀jẹ̀
Láti lóye ìṣiṣẹ́gbòdì náà, ó yẹ kí a mọ ohun tí ẹ̀jẹ̀ ń ṣe àti bí ó ṣe ń káàkiri nínú ara. Àpèjúwe kan yóò ṣèrànwọ́. Finú wòye orílẹ̀-èdè kan tí ó gbára lé oúnjẹ tí a kó wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè láti bọ́ àwọn ènìyàn tí ń gbé abúlé ìgbèríko. A óò wa àwọn ọkọ̀ akẹ́rù lọ sí ìlú ńlá tí ó jẹ́ olú ìlú, níbi tí a óò ti di oúnjẹ kún inú wọn. Wọ́n ń gba àwọn òpópónà ńlá lọ kúrò nínú ìlú ńlá náà, àmọ́ bí wọ́n ti ń dé àwọn agbègbè ìgbèríko náà, àwọn ọ̀nà náà ń di kékeré.
Bí gbogbo nǹkan bá ṣẹnuure, àwọn ọkọ̀ akẹ́rù náà yóò dé ibi tí wọ́n ń lọ, wọn óò já oúnjẹ inú wọn, wọn óò wá padà sí ìlú ńlá láti kó oúnjẹ̀ mìíràn sí i, tí wọn óò lọ já lẹ́yìn náà. Bí ó ti wù kí ó rí, bí púpọ̀ lára àwọn ọkọ̀ akẹ́rù náà bá dẹnu kọlẹ̀, oúnjẹ náà yóò bà jẹ́, wọn óò sì dínà fún àwọn ọkọ̀ akẹ́rù míràn láti kọjá ní ọ̀nà náà. Àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní àwọn abúlé náà kò ní rí oúnjẹ púpọ̀ jẹ nígbà náà.
Lọ́nà kan náà, àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ ń lọ sínú ẹ̀dọ̀fóró, níbi tí wọ́n ti ń gba ìpèsè afẹ́fẹ́ oxygen—tí í ṣe oúnjẹ fún ara. Wọ́n óò wá kúrò nínú ẹ̀dọ̀fóró, wọn óò sì yára gba inú àwọn lájorí òpó ẹ̀jẹ̀ kọjá lọ sí gbogbo ẹ̀yà ara. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, “àwọn ọ̀nà” náà yóò wá kéré gan-an débi pé orí ìlà tóóró kan péré ni àwọn sẹ́ẹ̀lì pupa tí ń gba àárín àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ kọjá lè wà. Ibẹ̀ ni wọ́n ń já ẹrù afẹ́fẹ́ oxygen tí wọ́n kó, tí ń pèsè oúnjẹ fún àwọn sẹ́ẹ̀lì ara sí.
Sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa tí ó lera máa ń rí roboto bí owó ṣílè, ó sì máa ń fi tìrọ̀rùntìrọ̀rùn gan-an gba àárín àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ kíkéré jù lọ kọjá. Àmọ́ nínú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àrùn arunmọléegun, àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ náà máa ń tú ká. Wọ́n máa ń pàdánù ìrísí roboto wọn, wọn óò wá ní ìrísí ọ̀gẹ̀dẹ̀ tàbí akọ́rọ́—irin iṣẹ́ àgbẹ̀. Àwọn ẹ̀jẹ̀ títẹ̀ kọrọdọ yìí yóò lẹ̀ mọ́ àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ kéékèèké inú ara, bí ọkọ̀ akẹ́rù tí ó rì sínú ẹrẹ̀, wọn ó sì dínà fún àwọn sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa mìíràn láti kọjá. Nígbà tí ìṣàn ẹ̀jẹ̀ tí ń lọ sí apá kan ara bá dín kù, ìpèsè afẹ́fẹ́ oxygen ni a ti dínà fún, ìkìmọ́lẹ̀ aronilára ló sì máa ń yọrí sí.
Ìkìmọ́lẹ̀ aronilára ti àpẹẹrẹ àrùn arunmọléegun máa ń yọrí sí ìrora gógó nínú àwọn egungun àti oríkèé ara. Ènìyàn kì í mọ ìgbà tí àwọn ìkìmọ́lẹ̀ aronilára náà yóò ṣẹlẹ̀; wọ́n lè ṣàìmá máa ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ tàbí kí wọ́n máa ṣẹlẹ̀ lóṣooṣù. Nígbà tí wọ́n bá ṣẹlẹ̀, wọ́n máa ń fa ìrora ọkàn fún ọmọ àti òbí. Ihunde jẹ́ nọ́ọ̀sì kan tí ń ṣiṣẹ́ ní ibùdó ìtọ́jú àrùn arunmọléegun. Ó wí pé: “Kò rọrùn láti tọ́ ọmọ alárùn arunmọléegun. Mo mọ̀ bẹ́ẹ̀, nítorí pé ọmọbìnrin mi ní àrùn náà. Ìrora náà máa ń wá lójijì. Ó máa ń lọgun, ó sì máa ń sunkún, èmi náà sì máa ń sunkún. Kìkì lẹ́yìn ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta, tàbí bóyá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, ni ìrora náà yóò rọlẹ̀.”
Àwọn Àmì Rẹ̀
Àwọn àmì rẹ̀ sábà máa ń fara hàn lẹ́yìn tí ọmọ náà bá ti pé oṣù mẹ́fà. Ọ̀kan lára àwọn àmì àkọ́kọ́ ni kí ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ tàbí tọwọ́tẹsẹ̀ wúlé, kí wọ́n sì máa roni. Ọmọ náà lè máa sunkún léraléra, kí ó má sì lè jẹun púpọ̀. Funfun ojú rẹ̀ lè di aláwọ̀ ìyeyè. Ahọ́n, ètè, àti àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ lè di ràndànràndàn ju bí ó ti yẹ lọ. Ó yẹ kí a gbé àwọn ọmọ tí irú àmì báwọ̀nyí bá ń hàn lára wọn lọ sí ilé ìwòsàn, níbi tí àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ti lè fi hàn bí ó bá jẹ́ pé àrùn arunmọléegun ni ìṣòro wọn.
Nígbà tí àwọn sẹ́ẹ̀lì títẹ̀ kọrọdọ bá dínà àwọn òpó ẹ̀jẹ̀, ìrora náà sábà máa ń kan àwọn oríkèé ara. Ìkìmọ́lẹ̀ líle koko kan tún lè ṣèdíwọ́ fún ìṣiṣẹ́ ọpọlọ, ẹ̀dọ̀fóró, ọkàn-àyà, àwọn kíndìnrín, àti ọlọ inú—nígbà míràn, pẹ̀lú ìyọrísí ikú. Egbò ẹsẹ̀ ní ibi kókósẹ̀ lè wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ọmọdé máa ń wà nínú ewu gìrì tàbí àrùn ẹ̀gbà. Ní pàtàkì, àwọn tí wọ́n ní àrùn arunmọléegun lè tètè ní àwọn àrùn àkóràn, níwọ̀n bí àrùn náà ti máa ń sọ àwọn odi ìgbèjà àdánidá di aláìlera. Níní àrùn yìí sábà máa ń yọrí sí ikú.
Dájúdájú, kì í ṣe gbogbo alárùn arunmọléegun ló máa ń ní gbogbo àmì wọ̀nyí. Àwọn kan kì í sì í ní ìṣòro títí di ìgbà tí wọ́n bá ń sún mọ́ ogún ọdún.
Ìtọ́jú Rẹ̀
Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ti lo àkókò àti owó dà nù ní lílépa àwọn ìtọ́jú tí ó jọ pé ó lè pèsè ìwòsàn fún àwọn ọmọ wọn. Síbẹ̀, ní lọ́wọ́lọ́wọ́ kò sí ìwòsàn kankan fún àrùn arunmọléegun; àrùn tí ń ṣeni dọjọ́ ikú ni. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí a lè ṣe láti dín ìṣelemọ́lemọ́ ìkìmọ́lẹ̀ kù wà, àwọn ọ̀nà tí a sì lè gbà kápá wọn wà tí wọ́n bá ṣẹlẹ̀.
Nígbà tí ó bá kini mọ́lẹ̀, àwọn òbí gbọ́dọ̀ fún ọmọ wọn ní omi púpọ̀ mu. Wọ́n tún lè fún un ní egbòogi adẹ̀rọ̀ ìrora tí kò lágbára jù. Ìrora líle koko lè béèrè fún àwọn egbòogi tí ó túbọ̀ lágbára tí a lè rí gbà lọ́dọ̀ dókítà nìkan. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó bani nínú jẹ́ pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìwọ̀nba ìdẹ̀ra díẹ̀ ni àwọn egbòogi lílágbára pàápàá máa ń mú wá. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò sí ìdí láti páyà. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ púpọ̀ jù lọ, lẹ́yìn wákàtí tàbí ọjọ́ díẹ̀, ìrora náà máa ń rọlẹ̀, tí aláìsàn náà yóò sì kọ́fẹ padà.
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ń wá àwọn egbòogi tí wọn óò fi wo àrùn náà. Fún àpẹẹrẹ, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1995, Àjọ Ìtọ́jú Ọkàn-Àyà, Ẹ̀dọ̀fóró, àti Ẹ̀jẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè United States kéde pé egbòogi hydroxyurea ń dín ìṣelemọ́lemọ́ ìkìmọ́lẹ̀ aronilára tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn alárùn arunmọléegun kù ní ìwọ̀n ìdajì. A ronú pé yóò ṣe èyí nípa ṣíṣèdíwọ́ fún sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa láti má ṣe yí ìrísí wọn padà, kí wọ́n sì dínà àwọn òpó ẹ̀jẹ̀.
Irú àwọn egbòogi bẹ́ẹ̀ kì í wà lárọ̀ọ́wọ́tó níbi gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe inú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ ni wọ́n ti wúlò. Láìka àwọn ewu tí a mọ̀ dáradára sí, àwọn dókítà ní ilẹ̀ Áfíríkà àti ní àwọn ibòmíràn máa ń fa ẹ̀jẹ̀ síni lára déédéé láti tọ́jú àwọn alárùn arunmọléegun nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì.
Dídènà Ìkìmọ́lẹ̀
Alumona, olùgbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn apilẹ̀ àbùdá ní ibùdó ìtọ́jú àrùn arunmọléegun náà, sọ pé: “A máa ń wí fún àwọn aláìsàn pé kí wọ́n mu omi púpọ̀ gan-an láti dènà ìkìmọ́lẹ̀. Omi máa ń mú kí ẹ̀jẹ̀ lè ṣàn dáradára nínú àwọn òpó ẹ̀jẹ̀ inú ara. Àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ní àrùn arunmọléegun gbọ́dọ̀ máa mu omi lítà mẹ́ta tàbí mẹ́rin lójoojúmọ́. Dájúdájú, àwọn ọmọdé kì yóò mu tó ìyẹn. A ń kọ́ àwọn ọmọdé tí wọ́n ní àrùn arunmọléegun láti máa gbé ike ìrọmi lọ sí ilé ẹ̀kọ́. Àwọn olùkọ́ gbọ́dọ̀ lóye pé àwọn ọmọ wọ̀nyí lè máa tọrọ àyè lemọ́lemọ́ láti jáde lọ tura. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ mọ̀ pé àwọn ọmọ wọ̀nyí lè máa tọ̀ọ́lé lemọ́lemọ́ ju àwọn tí wọn kò ní àrùn náà lọ.”
Níwọ̀n bí àìlera ti lè fa ìkìmọ́lẹ̀ tí ó léwu, àwọn alárùn arunmọléegun ní láti sapá gidigidi láti máa wà ní ipò ìlera dáradára. Wọ́n lè ṣe èyí nípa wíwà ní ìmọ́tótó, nípa yíyẹra fún ìgbòkègbodò atánnilókun tí a fà gùn, àti nípa jíjẹ oúnjẹ dáradára tí èròjà rẹ̀ pé. Àwọn dókítà tún dámọ̀ràn pé kí a tún máa lo egbòogi multivitamins àti folic acid láti ran oúnjẹ náà lọ́wọ́.
Ó jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu kí àwọn alárùn arunmọléegun tí ń gbé àwọn agbègbè tí ibà ti wọ́pọ̀ máa dáàbò bo ara wọn, nípa yíyẹra fún ìbunijẹ ẹ̀fọn àti nípa lílo egbòogi láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àrùn náà. Níwọ̀n bí ibà ti máa ń pa sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa, ní pàtàkì, ó lè léwu fún ẹni tí ó jẹ́ alárùn arunmọléegun.
Àwọn tí wọ́n jẹ́ alárùn arunmọléegun gbọ́dọ̀ máa ṣàyẹ̀wò ìlera déédéé. Wọ́n gbọ́dọ̀ fún àkóràn àrùn, àìlera, tàbí ìfarapa èyíkéyìí ní àfiyèsí ìtọ́jú ìṣègùn. Nípa fífi tìṣọ́ratìṣọ́ra tẹ̀ lé irú ìlànà ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀, ó lè ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ alárùn arunmọléegun láti gbé ìgbésí ayé aláyọ̀, tí ó wà déédéé.
Bí A Ṣe Ń Tàtaré Rẹ̀ sí Àwọn Ọmọ
Láti lóye bí a ṣe ń tàtaré àrùn náà láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí sí àwọn ọmọ wọn, a ní láti mọ̀ nípa àwọn ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀ yàtọ̀ sí ọ̀wọ́ ẹ̀yà ẹ̀jẹ̀; ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ní í ṣe pẹ̀lú àwọn apilẹ̀ àbùdá. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ní ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀ tí a ń pè ní AA. Àwọn tí wọ́n jogún apilẹ̀ àbùdá A láti ọ̀dọ̀ òbí kan àti apilẹ̀ àbùdá S láti ọ̀dọ̀ òbí kejì ní ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀ AS. Àwọn ẹni tí ẹ̀jẹ̀ wọ́n jẹ́ AS kò ní àrùn arunmọléegun, ṣùgbọ́n wọ́n lè tàtaré àrùn náà sí àwọn ọmọ wọn. Àwọn ẹni tí wọ́n jogún apilẹ̀ àbùdá S láti ọ̀dọ̀ òbí kan àti apilẹ̀ àbùdá S mìíràn láti ọ̀dọ̀ òbí kejì ní ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀ SS, tí í ṣe ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá àrùn arunmọléegun.
Nípa bẹ́ẹ̀, kí ọmọ kan tóó lè jogún ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀ SS, ó gbọ́dọ̀ jogún apilẹ̀ àbùdá S tí ó lábùkù náà láti ọ̀dọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òbí rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé ẹni méjì ní í bí ọmọ, bẹ́ẹ̀ gan-an ni ó ṣe jẹ́ pé ẹni méjì ní í tàtaré àrùn arunmọléegun. Bí ó ti sábà máa ń rí, a máa ń tàtaré àrùn náà tí àwọn òbí méjèèjì bá ní ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀ AS. Tí ẹni tí ó ní ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀ AS bá fẹ́ ẹlòmíràn tí ó ní ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀ AS, ó ṣeé ṣe kí ọmọ 1 lára ọmọ 4 tí wọ́n bá bí ní ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀ SS.
Èyí kò túmọ̀ sí pé bí wọ́n bá bí ọmọ mẹ́rin, ọ̀kan lára wọn yóò ní àrùn arunmọléegun tí àwọn mẹ́ta yòó kù kì yóò sì ní. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ọ̀kan lára àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jẹ́ SS, ó tún lè ṣẹlẹ̀ pé kí méjì, mẹ́ta, tàbí kí àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tilẹ̀ jẹ́ SS. Ó tún lè ṣẹlẹ̀ kí ọ̀kankan lára àwọn ọmọ náà má jẹ́ SS.
Àwọn Ìpinnu Tí A Gbé Karí Ìsọfúnni Ṣáájú Ìgbéyàwó
Yóò jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mu fún àwọn ará Áfíríkà láti wádìí irú ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá ẹ̀jẹ̀ wọn, tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí wọ́n tóó ronú nípa ìgbéyàwó. Wọ́n lè ṣe èyí nípa àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀. A lè mú un dá àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ẹ̀jẹ̀ AA lójú pé, ẹni yòó wù kí wọ́n fẹ́, kò sí èyíkéyìí lára àwọn ọmọ wọn tí yóò ní àrùn arunmọléegun. Àwọn tí wọ́n ní ẹ̀jẹ̀ AS gbọ́dọ̀ lóye pé bí wọ́n bá fẹ́ ẹnì kan tí òun pẹ̀lú ní ẹ̀jẹ̀ AS, wọ́n wà nínú ewu bíbí ọmọ kan tí yóò jẹ́ alárùn arunmọléegun.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn dókítà ṣàìfún kí AS àti AS fẹ́ra wọn níṣìírí, àwọn olùgbaninímọ̀ràn ní ibùdó ìtọ́jú àrùn arunmọléegun náà máa ń jẹ́ kí àwọn ènìyàn ṣe yíyàn wọn fúnra wọn. Dókítà Omoike sọ pé: “Kì í ṣe iṣẹ́ wa láti dẹ́rù ba àwọn ènìyàn tàbí láti sọ ẹni tí ó yẹ tàbí tí kò yẹ kí wọ́n fẹ́ fún wọn. Kò sí ẹni tí ó lè sọ tẹ́lẹ̀ ní gidi pé àwọn ọmọ tí àwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ AS bá bí yóò ní ẹ̀jẹ̀ SS, níwọ̀n bí ìyẹn ti jẹ́ ọ̀ràn èèṣì. Kódà bí wọn bá bí ọmọ tí ó jẹ́ SS, ọmọ yẹn lè máa mú àrùn náà mọ́ra láìsí ìṣòro púpọ̀. Àmọ́, a fẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ ohun tí ẹ̀yà apilẹ̀ àbùdá wọ́n jẹ́. A sì ń gbìyànjú ṣáájú láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ kí ó má baà yà wọ́n lẹ́nu bí wọ́n bá bí àwọn ọmọ tí wọ́n jẹ́ SS. Lọ́nà yẹn, kì í ṣe pé wọ́n wà ní ipò láti ṣe ìpinnu tí a gbé karí mímọ àwọn òkodoro nìkan ni, ṣùgbọ́n láti múra ara wọn sílẹ̀ ní ti èrò orí láti gba ohun tí àwọn ìpinnu wọ̀nyẹn bá yọrí sí.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ìṣiṣẹ́gbòdì àrùn arunmọléegun mìíràn tí ń nípa lórí agbára ẹ̀jẹ̀ láti gbé afẹ́fẹ́ oxygen ni àrùn inú sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ pupa ìpele C alárùn arunmọléegun àti àrùn arunmọléegun ìpele keji.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìjẹ́pàtàkì Ìfẹ́
Joy, tí ó ti lé díẹ̀ ni ẹni ogún ọdún nísinsìnyí, ní àrùn arunmọléegun. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò gba ẹ̀jẹ̀ sára rí. Ọlá, tí ó jẹ́ ìyá rẹ̀, sọ pé: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń rí i dájú pé Joy ń jẹ oúnjẹ dáradára láti fún ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lókun. Mo gbà gbọ́ pé àbójútó onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ òbí lè ṣe púpọ̀. Ìwàláàyè rẹ̀, bíi ti gbogbo àwọn ọmọ mi, ṣeyebíye sí mi gan-an. Dájúdájú, gbogbo ọmọ ló nílò ìfẹ́, síbẹ̀, ẹ wo bí àwọn tí wọ́n ń bá àìsàn kan jìjàkadì ti nílò rẹ̀ tó!”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Tọ́pẹ́ ní àwọn sẹ́ẹ̀lì títẹ̀ kọrọdọ, bí àwọn tí àmì ìtọ́ka fi hàn
[Credit Line]
Àwọn sẹ́ẹ̀lì títẹ̀ kọrọdọ: Image #1164 láti American Society of Hematology Slide Bank. Tí a gbàṣẹ láti lò