Nígbà Tí Ọ̀rọ̀ Bá Di Ohun Ìjà
“Àwọn kan ń bẹ tí ń yára sọ̀rọ̀ lásán bí ìgúnni idà.”—ÒWE 12:18.
ELAINE sọ pé: “Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn ìgbéyàwó ni ó bẹ̀rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tí kò dára, àwọn ọ̀rọ̀ ìtẹ́ḿbẹ́lú, àti ìsapá láti tẹ́ mi. N kò bá ọkọ mi mu. Ó lè fi èrò inú gbígbọ́nféfé àti ètè rẹ̀ ayárasọ̀rọ̀ da gbogbo ohun tí mo bá sọ rú, kí ó sì bà á jẹ́.”a
Jálẹ̀jálẹ̀ ìgbéyàwó rẹ̀, Elaine wà lábẹ́ irú ìfìyàjẹni lọ́nà jíjáfáfá, tí kì í fi ìpalára tí ó ṣeé rí hàn, tí ń mú kí a kẹ́dùn rẹ̀ níwọ̀nba. Ó bani nínú jẹ́ pé ipò tí ó wà náà kò sunwọ̀n sí i láti ìgbà náà wá. Ó wí pé: “Ó ti lé ní ọdún 12 tí a ti ṣègbéyàwó. Ọjọ́ kan kò lọ kí ó máà mú nǹkan lé, kí ó má sì pẹ̀gàn mi, ní sísọ àwọn ọ̀rọ̀ àsé, tí ń dáni lágara sí mi.”
Kì í ṣe pé Bíbélì ń sọ àsọdùn nígbà tí ó wí pé ahọ́n lè jẹ́ “ohun ewèlè kan tí ń ṣeni léṣe, ó kún fún panipani májèlé.” (Jákọ́bù 3:8; fi wé Orin Dáfídì 140:3.) Èyí jẹ́ òtítọ́, pàápàá nínú ìgbéyàwó. Aya kan tí ń jẹ́ Lisa wí pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ pé ‘igi àti òkúta lè ṣẹ́ egungun mi ṣùgbọ́n pé ọ̀rọ̀ kò lè pa mí lára’ ṣe àṣìṣe pátápátá.”—Òwe 15:4.
Àwọn ọkọ pẹ̀lú lè jẹ́ ẹni tí a ń wẹ èébú sí lára. Mike, ẹni tí ìgbéyàwó rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́rin pẹ̀lú Tracy ń forí lé ìkọ̀sílẹ̀, béèrè pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ bí ó ṣe máa ń rí bí a bá ń gbé ilé pẹ̀lú obìnrin kan tí ó máa ń fìgbà gbogbo peni ní òpùrọ́, òpònú akídanidání tàbí ohun tí ó tilẹ̀ burú jù bẹ́ẹ̀ lọ? Àwọn ohun tí ó máa ń sọ sí mi kò ṣeé máa sọ láwùjọ àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ọ̀wọ̀ lára. Ìdí nìyẹn tí n kò ṣe lè máa bá a sọ̀rọ̀, tí mo sì fi máa ń pẹ́ níbi iṣẹ́. Mo túbọ̀ ní àlàáfíà ní ibi iṣẹ́ ju kí n wá sí ilé lọ.”—Òwe 27:15.
Pẹ̀lú èrò ọkàn rere, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí àwọn Kristẹni létí pé: “Kí ẹ mú . . . ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Éfésù 4:31) Ṣùgbọ́n kí ni “ọ̀rọ̀ èébú” jẹ́? Pọ́ọ̀lù fìyàtọ̀ sáàárín òun àti “ìlọgun” (Gíríìkì, krau·geʹ), tí ó túmọ̀ sí wíwulẹ̀ gbé ohùn sókè. “Ọ̀rọ̀ èébú” (Gíríìkì, bla·sphe·miʹa) túbọ̀ tọ́ka sí kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a ń sọ. Bí ó bá jẹ́ lọ́nà ìfìkà gboni mọ́lẹ̀, àrankan, tí ń tẹ́ni lógo, tàbí lọ́nà ìfìwọ̀sí kanni, nígbà náà, èébú ni—yálà a sọ ọ́ pẹ̀lú ariwo tàbí ní kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.
Ìpalára Tí Ó Wà Nínú Ọ̀rọ̀
Lílo ọ̀rọ̀ tí ń dáni lágara lè mú kí ìgbéyàwó kan di ahẹrẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ìgbì òkun ṣe lè jẹ àpáta lílágbára. Ọ̀mọ̀wé Daniel Goleman kọ̀wé pé: “Bí ó bá ṣe le, tí ó sì ṣe gùn tó ní ewu ibẹ̀ yóò ṣe pọ̀ tó. . . . Sísọ lámèyítọ́ ṣíṣe di àṣà àti ìfojútín-ínrín ẹni tàbí ìríra ni àwọn àmì tí ń fi ewu hàn nítorí pé wọ́n fi hàn pé ọkọ tàbí aya kan ti dẹ́bi fún alábàágbéyàwó rẹ̀ nínú rẹ̀ lọ́hùn-ún.” Bí ìfẹ́ni ṣe ń dín kù, ọkọ àti aya ń di ẹni tí ìwé kan pè ní “àwọn tí wọ́n ṣègbéyàwó lọ́nà òfin, àmọ́ tí wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà ti èrò ìmọ̀lára.” Bí àkókò ti ń lọ, wọ́n lè kọ ara wọn sílẹ̀.
Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí èébú lè ṣèpalára fún ju ìgbéyàwó náà fúnra rẹ̀ lọ. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Nípa ìbìnújẹ́ àyà, ọkàn a rẹ̀wẹ̀sì.” (Òwe 15:13) Másùnmáwo tí ń jẹ́ àbáyọrí títú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń dúnni léraléra lè fa ìṣòro ńláǹlà fún ìlera ẹni. Fún àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí Yunifásítì Washington (U.S.A.) ṣe fi hàn pé obìnrin kan tí a ń kẹ́gàn rẹ̀ nígbà gbogbo lè tètè máa ní ọ̀fìnkìn, ìṣòro àpò ìtọ̀, abẹ́ yíyúnni, àti ìṣiṣẹ́gbòdì nínú ikùn òun ìfun.
Ọ̀pọ̀ àwọn aya tí wọ́n ti forí ti fífi ọ̀rọ̀ gúnni lára àti ìluni bolẹ̀ gidi sọ pé ọ̀rọ̀ lè dunni gan-an ju ìlunilẹ́ṣẹ̀ẹ́ lọ. Beverly sọ pé: “Bópẹ́-bóyá, àwọn àpá tí ọwọ́ rẹ̀ dá síni lára yóò san, wọn óò sì lọ, àmọ́ n kò lè gbàgbé àwọn ọ̀rọ̀ burúkú tí ó sọ nípa ìrísí mi, bí mo ṣe ń se oúnjẹ, bí mo ṣe ń ṣètọ́jú àwọn ọmọ láé.” Èrò Julia rí bákan náà. Ó wí pé: “Mo mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu, ṣùgbọ́n ó tẹ́ mi lọ́rùn pé kí ó kúkú lù mí, kí n sì gbàgbé rẹ̀ ju kí n máa nírìírí ìdálóró èrò inú fún ọ̀pọ̀ wákàtí lọ.”
Ṣùgbọ́n kí ló dé tí àwọn ènìyàn kan máa ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí àwọn tí wọ́n sọ pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì máa ń nà wọ́n ní pàṣán ọ̀rọ̀? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e jíròrò ìbéèrè yìí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú ọ̀wọ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
“Ó tẹ́ mi lọ́rùn pé kí ó kúkú lù mí, kí n sì gbàgbé rẹ̀ ju kí n máa nírìírí ìdálóró èrò inú fún ọ̀pọ̀ wákàtí lọ”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
“Ǹjẹ́ ẹ mọ bí ó ṣe máa ń rí bí a bá ń gbé ilé pẹ̀lú obìnrin kan tí ó máa ń fìgbà gbogbo peni ní òpùrọ́, òpònú akídanidání, tàbí ohun tí ó tilẹ̀ burú jù bẹ́ẹ̀ lọ?”