ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 10/22 ojú ìwé 5-7
  • Títúdìí Gbòǹgbò Èébú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Títúdìí Gbòǹgbò Èébú
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ó Ṣe Máa Ń Bẹ̀rẹ̀
  • Agbára Àwọn Aninilára
  • Láti Ọ̀rọ̀ Dídunni sí Ọ̀rọ̀ Atunilára
    Jí!—1996
  • Bí Ẹ Ṣe Lè Yẹra Fún Sísọ Ọ̀rọ̀ Líle Síra Yín
    Jí!—2013
  • Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Máa Bọlá fún Ìyàwó Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 10/22 ojú ìwé 5-7

Títúdìí Gbòǹgbò Èébú

“Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.”—MÁTÍÙ 12:34.

NÍ NǸKAN bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, Jésù Kristi sọ ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè yìí. Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan ń sọ sábà máa ń ṣàgbéyọ àwọn èrò ìmọ̀lára àti ìsúnniṣe rẹ̀ jíjinlẹ̀. Wọ́n lè wuyì. (Òwe 16:23) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, wọ́n lè kún fún àdàkàdekè.—Mátíù 15:19.

Obìnrin kan sọ nípa ọkọ rẹ̀ pé: “Ó jọ pé ó máa ń bínú láìròtẹ́lẹ̀, gbígbé pẹ̀lú rẹ̀ sábà máa ń dà bíi rírìn kọjá lórí pápá tí àwọn ọta abúgbàù wà—o kò mọ ohun tí yóò fa ìbúgbàù kan.” Richard ṣàpèjúwe ipò jíjọra kan nínú ọ̀ràn aya rẹ̀. Ó wí pé: “Ìgbà gbogbo ni Lydia máa ń wà ní ìmúrasílẹ̀ fún ìjà. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ nìkan ló máa ń sọ; ó máa ń nani ní pàṣán ọ̀rọ̀ bí aríjàgbà, tí yóò máa nàka sí mi bíi pé ọmọdé ni mí.”

Dájúdájú, iyàn jíjà lè bẹ́ sílẹ̀ nínú àwọn ìgbéyàwó tí ó dára jù lọ pàápàá, gbogbo ọkọ àti aya ni ó sì máa ń sọ àwọn ohun tí wọ́n máa ń kábàámọ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Jákọ́bù 3:2) Ṣùgbọ́n èébú nínú ìgbéyàwó ju ìyẹn lọ; ó ní nínú, ọ̀rọ̀ ìtẹ́nilógo, tí ó sì le koko, tí a pète láti fi jọba lórí, tàbí láti darí, alábàágbéyàwó ẹni. Nígbà míràn, a máa ń dọ́gbọ́n pọ́n ọ̀rọ̀ apanilára sínú ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́. Fún àpẹẹrẹ, olórin náà, Dáfídì, ṣàpèjúwe ọkùnrin kan tí ó máa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, síbẹ̀ tí inú rẹ̀ kún fún ibi pé: “Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí àmọ́ lọ, ṣùgbọ́n ogun jíjà ni ó wà ní àyà rẹ̀: ọ̀rọ̀ rẹ̀ kúnná ju òróró lọ, ṣùgbọ́n idà fífàyọ ni wọ́n.” (Orin Dáfídì 55:21; Òwe 26:24, 25) Yálà ó fi àránkan hàn ní gbangba tàbí ó ní ìrísí bojúbojú, ọ̀rọ̀ tí ń dáni lágara lè ba ìgbéyàwó jẹ́.

Bí Ó Ṣe Máa Ń Bẹ̀rẹ̀

Kí ní ń mú kí ẹnì kan máa búni? Ní gbogbogbòò, a lè tọpa lílo irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ padà lọ sórí ohun tí ẹnì kan ń rí, tí ó sì ń gbọ́. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn, ìfìwọ̀sí kanni, àti ọ̀rọ̀ ìtẹ́ni ni a kà sí ohun ìtẹ́wọ́gbà, kódà ohun adẹ́rìn-ín pani pàápàá.a Ní pàtàkì, àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde, tí wọ́n ti sábà máa ń fi àwọn “ojúlówó” ọkùnrin hàn gẹ́gẹ́ bí ajẹgàba àti òfínràn lè ní ipa lórí àwọn ọkọ.

Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ àwọn tí ń lo ọ̀rọ̀ tí ń buni kù jẹ́ àwọn tí a tọ́ dàgbà ní àwọn ilé tí òbí kan ti máa ń sọ̀kò ìbínú, ìfìbínúhàn, àti ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn léraléra. Nípa bẹ́ẹ̀, láti ìgbà ọmọdé, wọ́n ti lóye pé irú ìhùwà yìí ṣètẹ́wọ́gbà.

Ọmọ kan tí a tọ́ dàgbà nínú irú àyíká bẹ́ẹ̀ lè kọ́ ju irú ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ kan lọ; ó tún lè kọ́ níní ojú ìwòye tí kò tọ́ nípa ara rẹ̀ àti àwọn ẹlòmíràn. Fún àpẹẹrẹ, bí a bá ń sọ ọ̀rọ̀ tí ń dáni lágara sí ọmọ náà, ó lè dàgbà di ẹni tí ń nímọ̀lára àìjámọ́ǹkankan, tàbí kí a tilẹ̀ tán an ní sùúrù láti di onínúfùfù. Ṣùgbọ́n, bí ọmọ náà bá wulẹ̀ ṣèèṣì gbọ́ tí bàbá rẹ̀ ń fi ọ̀rọ̀ gún ìyá rẹ̀ lára ńkọ́? Kódà bí ọmọ náà bá kéré gan-an, ó lè kọ́ fífojú tín-ínrín obìnrin lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀. Ọmọdékùnrin kan lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìwà bàbá rẹ̀ pé ọkùnrin ló yẹ kí ó máa darí obìnrin àti pé ọ̀nà tí a lè gbà rí ìdarí jẹ́ láti dáyà fò wọ́n tàbí láti ṣe ohun tí yóò dùn wọ́n.

Òbí tí ó máa ń bínú lè tọ́ ọmọ dàgbà di oníbìínú, tí òun pẹ̀lú lè dàgbà kí ó sì di “ọ̀gá nínú ìbínú” tí ń ṣe “ọ̀pọ̀ ìrékọjá.” (Òwe 29:22, NW, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé) Ogún ọ̀rọ̀ aṣèpálára lè wá tipa bẹ́ẹ̀ máa lọ láti ìran kan dé òmíràn. Pẹ̀lú èrò ọkàn rere, Pọ́ọ̀lù gba àwọn bàbá níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara.” (Kólósè 3:21) Lọ́nà pàtàkì, gẹ́gẹ́ bí ìwé Theological Lexicon of the New Testament ṣe sọ, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a túmọ̀ sí “máa dá lágara” lè ní ìtumọ̀ “mímúra ẹni sílẹ̀ àti ríruni sókè fún ìjà.”

Dájúdájú, ipa òbí lórí ẹni kì í ṣe àwíjàre fún sísọ̀kò ọ̀rọ̀ lu àwọn ẹlòmíràn tàbí gbígbógun tì wọ́n lọ́nà míràn; ṣùgbọ́n ó ṣèrànwọ́ láti ṣàlàyé bí títẹ̀ sí ipa ọ̀rọ̀ tí ń dáni lágara ṣe lè fìdí múlẹ̀ gbọn-ingbọn-in nínú ẹni. Ọ̀dọ́kùnrin kan lè má lu aya rẹ̀ ní ti gidi, ṣùgbọ́n ńjẹ́ ó máa ń bú u, kí ó sì máa fi ìrunú rẹ̀ jẹ ẹ́ níyà bí? Àyẹ̀wò ara ẹni lè fi han ẹnì kan pé ó kọ́ fífojú tín-ínrín obìnrin láti lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀.

O hàn kedere pé àwọn ìlànà òkè yìí lè kan obìnrin pẹ̀lú. Bí ìyá kan bá ń bú ọkọ rẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ lè ṣe bákan náà sí ọkọ tirẹ̀ náà nígbà tí ó bá ṣèyàwó. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ó sàn láti máa gbé ní aṣálẹ̀ kan, ju pẹ̀lú obìnrin aláhọ́n kíkorò àti oníbìínú.” (Òwe 21:19, The Bible in Basic English) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ọkùnrin, pàápàá jù lọ, máa lo ìṣọ́ra nínú ọ̀ràn yìí. Èé ṣe?

Agbára Àwọn Aninilára

Ọkọ sábà máa ń ní agbára tí ó pọ̀ ju ti aya lọ nínú ìgbéyàwó. Òun ni ó sábà máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ lágbára jù lọ ní ti ara ìyára, tí ń mú kí híhalẹ̀ àtiṣèpalára ti ara ìyára lọ́nàkọnà túbọ̀ máa dáyà foni.b Ní àfikún, ọkùnrin sábà máa ń ní òye iṣẹ́ tí ó sàn jù, òye púpọ̀ ní gbígbọ́ bùkátà ara rẹ̀ láìsinmi lé àwọn ẹlòmíràn, àti àǹfààní níní owó jù lọ. Nítorí èyí, ó ṣeé ṣe kí obìnrin kan tí a ń fi ọ̀rọ̀ gún lára ronú pé a kẹ́dẹ mú òun, tí òún sì dá nìkan wà. Ó lè fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì náà pé: “Bẹ́ẹ̀ ni mo padà, mo sì ro ìnilára gbogbo tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn; mo sì wo omijé àwọn tí a ń ni lára, wọn kò sì ni olùtùnú; àti lọ́wọ́ aninilára wọn ni ipá wà; ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú.”—Oníwàásù 4:1.

Ó lè rú aya kan lójú bí ìmọ̀lára ọkọ rẹ̀ bá ń ti orí ìkangun kan lọ sí ìkejì—ayẹnisí lákòókò kan, alekoko lákòókò míràn. (Fi wé Jákọ́bù 3:10.) Síwájú sí i, bí ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ ẹni tí ń pèsè ohun ti ara dáradára, aya tí a ń darí ọ̀rọ̀ tí ń dáni lágara sí lè nímọ̀lára ẹ̀bi fún ríronú pé ohun kan ṣàìtọ́ nínú ìgbéyàwó náà. Ó tilẹ̀ lè dẹ́bi fún ara rẹ̀ nítorí ìwà ọkọ rẹ̀. Obìnrin kan jẹ́wọ́ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí aya kan tí a fìyà jẹ ní ti ara ìyára, mo sábà máa ń ronú pé èmi ni mo fà á.” Aya mìíràn sọ pé: “Ó sún mi láti gbà gbọ́ pé bí mo bá wulẹ̀ lè gbìyànjú sí i láti lóye rẹ̀, tí mo sì ‘ní sùúrù’ fún un, àlàáfíà yóò tó mi lọ́wọ́.” Lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, ìfìyàjẹni náà sábà máa ń bá a lọ.

Ó jẹ́ ohun tí ń bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ máa ń ṣi agbára wọn lò nípa jíjọba lórí obìnrin tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn yóò nífẹ̀ẹ́, tí àwọn yóò sì ṣìkẹ́ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) Ṣùgbọ́n kí ni a lè ṣe nípa irú ipò bẹ́ẹ̀? Aya kan sọ pé: “N kò fẹ́ láti fi í sílẹ̀, mo wulẹ̀ fẹ́ kí ó yé fìyà jẹ mí ni.” Lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn-án tí wọ́n ṣègbéyàwó, ọkọ kan gbà pé: “Mo mọ̀ pé mo wà nínú ipò ìbátan fífi ọ̀rọ̀ gúnni lára àti pé èmi ni olùfìyàjẹni náà. Láìsí àníàní, mo fẹ́ láti yí padà, n kò fẹ́ láti fi í sílẹ̀.”

Ìrànlọ́wọ́ wà fún àwọn tí ọ̀rọ̀ dídunni ti pọ́n ìgbéyàwó wọn lójú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò ṣe fi hàn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lọ́nà híhàn gbangba, ohun kan náà jẹ́ òtítọ́ ní ọ̀rúndún kìíní. Ìwé atúmọ̀ èdè The New International Dictionary of New Testament Theology sọ pé “ní ti àwọn ará Gíríìsì, ó jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà ìgbésí ayé láti mọ bí a ṣe ń fi ìwọ̀sí kan àwọn ẹlòmíràn tàbí bí a ṣe ń fara mọ́ ìwọ̀sí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn.”

b Wíwẹ èébú síni lára lè jẹ́ ìgbésẹ̀ ìṣáájú sí ìwà ipá nínú ilé. (Fi wé Ẹ́kísódù 21:18.) Ẹnì kan tí ń gba àwọn obìnrin tí a fìyà jẹ nímọ̀ràn sọ pé: “Gbogbo obìnrin tí ń wá fún àṣẹ ìdáàbòbò lòdì sí ìluni, ìgúnni lọ́bẹ, tàbí fífúnni lọ́rùn, tí ń fi ìwàláàyè sínú ewu, ló ti ní ìtàn gígùn ti ìfìyàjẹni tí kò ṣeé fojú rí, tí ó kún fún ìpalára ní àfikún.”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ máa ń ṣi agbára wọn lò nípa jíjọba lórí obìnrin tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn yóò nífẹ̀ẹ́, tí àwọn yóò sì ṣìkẹ́ rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọ̀nà tí àwọn òbí ń gbà bá ara wọn lò máa ń nípa lórí ọmọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́