“Pípa Ìṣẹ̀dá Run”
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ IRELAND
ÌWỌRA ń halẹ̀ mọ́ ibùgbé àdánidá rẹ. Ó ń jin agbára tí ilẹ̀ ayé ní láti pèsè oúnjẹ àti ibùgbé tí gbogbo wa nílò láti máa wà nìṣó lẹ́sẹ̀. Láìsí iyè méjì, o ti mọ̀ nípa bí ìwọra ṣe ń ba ilẹ̀ ayé jẹ́, ṣùgbọ́n àwọn ìránnilétí díẹ̀ nìyí.
Bíba Pílánẹ́ẹ̀tì Jẹ́
Nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1962, Rachel Carson kìlọ̀ nínú ìwé rẹ̀, Silent Spring, nípa fífi oògùn apakòkòrò àti pàǹtírí èròjà onímájèlé ba pílánẹ́ẹ̀tì jẹ́. Ìwé náà, The Naked Savage, sọ pé: “Àwọn aráyé ń ba àyíká wọn jẹ́, wọ́n sì ń sọ ibùgbé àdánidá wọn di eléèérí, èyí jẹ́ àmì ìkìlọ̀ tí ń ṣàfihàn ìparun àwọn irú ọ̀wọ́.” Aráyé ṣì ń fi ìwọra ba pílánẹ́ẹ̀tì jẹ́. Ìwé náà, World Hunger: Twelve Myths sọ pé: “Ní wíwá èrè tí ó pọ̀ jọjọ láàárín àkókò kúkúrú, àwọn olùṣèmújáde nǹkan oko tí wọ́n jẹ́ aládàá-ńlá ṣe tán láti lo ilẹ̀, omi, àti àwọn kẹ́míkà lálòjù láìronú pé àwọn lè máa ba ilẹ̀ jẹ́, kí àwọn máa pọn omi inú ilẹ̀ gbẹ, kí àwọn sì máa ba àyíká jẹ́.”
Dípò dídáàbò bo àwọn igbó kìjikìji ṣíṣeyebíye ní ayé—tí ó ṣe pàtàkì fún wíwà nìṣó ilẹ̀ ayé—ńṣe ni àwọn ènìyàn ń yára bà wọ́n jẹ́ ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ. Àwọn tí wọ́n kọ ìwé Far From Paradise—The Story of Man’s Impact on the Environment (1986) sọ pé: “Ojúlówó àwọn igbó ilẹ̀ olóoru yóò ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá pátápátá láàárín àádọ́ta ọdún bí ìwọ̀n tí wọ́n fi ń lò ó nísinsìnyí bá ń bá a lọ láìyípadà.”
Àwọn apẹja aláìtẹ̀lé-lànà ń lo ohun abúgbàù àti kẹ́míkà onímájèlé láti pa ẹja ní àyíká àwọn òkìtì ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀—tí a ti ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “alábàádọ́gba àwọn ẹgàn ilẹ̀ olóoru lábẹ́ òkun” nítorí ọ̀pọ̀ yanturu ohun alààyè tí ń gbé inú wọn. Àwọn ọ̀nà oníwà òǹrorò tí a ń gbà pẹja, pa pọ̀ pẹ̀lú fífi kẹ́míkà ba àyíká jẹ́ làìgbatẹnirò yí ti “ṣèbàjẹ́ gan-an” fún ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀ tí wọ́n wà láàyè.—The Toronto Star.
“Àwa Là Ń Fa Ìpọ́njú Tí Ń Bá Wa”
Alàgbà Shridath Ramphal, tí ó jẹ́ ààrẹ IUCN-Ẹgbẹ́ Ìdáàbòbò Ìṣẹ̀dá Àgbáyé láti 1991 sí 1993, ṣàpèjúwe irú àìtọ́jú búrùjí ilẹ̀ ayé dáradára yìí bíi “pípa ìṣẹ̀dá run.” Báwo ni ó ṣe burú tó gan-an? Ní títọ́ka sí àpẹẹrẹ kan, Ramphal kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn odò Íńdíà ni wọ́n wulẹ̀ jẹ́ ibi ìdàdọ̀tísí tí a kò bò, èyí tí ń gbé pàǹtírí eléèérí láti àwọn àgbègbè ìlú ńlá àti ìgbèríko lọ sínú òkun.” Ibo ló fẹnu ọ̀rọ̀ jóná sí? Ó kọ̀wé pé: “Àwa là ń fa ìpọ́njú tí ń bá wa.”
Ìwọra ti jọba nínú ìtàn ènìyàn fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ṣùgbọ́n ìhalẹ̀mọ́ sípa wíwànìṣó pílánẹ́ẹ̀tì lónìí ti pọ̀ sí i. Èé ṣe? Nítorí pé agbára tí ènìyàn ní láti ṣèparun ti wá pọ̀ gan-an. Ìwé Far From Paradise sọ pé: “Ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn ni a ṣẹ̀ṣẹ̀ ní kẹ́míkà àti ohun èèlò iṣẹ́ ẹ̀rọ láti fi pa àwọn irú ìwàláàyè míràn run lọ́nà gbígbéṣẹ́ nínú pílánẹ́ẹ̀tì wa. . . . Homo sapiens [ní Látìn, ọlọgbọ́n ènìyàn], gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti ń pe ara rẹ̀ láìwà-níwọ̀ntún-wọ̀nsì, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ní agbára pátápátá, ó sì ti jáwọ́ kíká ara rẹ̀ lọ́wọ́ kò lọ́nàkọnà.” Láìpẹ́ yìí, àjọ Greenpeace tí ń rí sí ọ̀ràn àyíká gbé ẹ̀sùn àríwísí lílágbára kan jáde, tí ó sọ pé: “Ènìyàn Ìwòyí ti sọ Párádísè [ilẹ̀ ayé] di àkìtàn, . . . ó sì wá dúró bí ọmọ jòjòló tí kò ní òye . . . sí bèbè . . . pípa ibi ìlùmọ́ fún ìwàláàyè yí run yán-ányán-án.”
Ṣùgbọ́n ìwọra ń ṣe ju híhalẹ̀ mọ́ ìfojúsọ́nà ọjọ́ iwájú ilẹ̀ ayé lọ. Ó ń halẹ̀ mọ́ ayọ̀ àti àìléwu ìwọ àti ìdílé rẹ ní lọ́wọ́lọ́wọ́. Báwo ni èyí ṣe rí bẹ́ẹ̀? Yẹ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e wò.