ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 3/8 ojú ìwé 26-27
  • Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Yan Ìsìn Tiwọn Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Yan Ìsìn Tiwọn Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyàn Náà
  • Ẹrù Iṣẹ́ Òbí
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ṣé Wọ́n Máa Sin Jèhófà Tí Wọ́n Bá Dàgbà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 3/8 ojú ìwé 26-27

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Yan Ìsìn Tiwọn Bí?

LÁTI ìgbà tí àwọn òbí bá ti bí ọmọ kan dé ìgbà àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà rẹ̀ ni wọ́n ti máa ń ṣe yíyàn fún ọmọ. Lákòókò kan náà, òbí kan tí ó jẹ́ ọlọgbọ́n mọ ìgbà tí ó yẹ kí òun jẹ́ aláìrinkinkin, tí ń ronú nípa ohun tí ọmọ náà yóò yàn láàyò nígbàkígbà tí ó bá ṣeé ṣe.

Síbẹ̀, iye òmìnira tí a lè fún ọmọ kan nípa yíyàn lè jẹ́ ìpèníjà fún àwọn òbí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ òtítọ́ pé àwọn ọmọdé lè ṣe yíyàn tí ó tọ́, kí wọ́n sì jàǹfààní láti inú ìwọ̀nba òmìnira, bákan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ pé wọ́n lè ṣe yíyàn tí kò tọ́, tí ó lè yọrí sí ìbànújẹ́.—Àwọn Ọba Kejì 2:23-25; Éfésù 6:1-3.

Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọmọdé sábà máa ń yan àwọn oúnjẹ tí èròjà aṣaralóore inú rẹ̀ kò pọ̀. Èé ṣe? Nítorí pé nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé, wọn kò lè dá ṣe àwọn yíyàn tí ó yè kooro. Yóò ha bọ́gbọ́n mu fún àwọn òbí láti wulẹ̀ fàyè gba àwọn ọmọ wọn fàlàlà nínú ọ̀ràn náà, ní ríretí pé bópẹ́bóyá wọn óò yan oúnjẹ tí ń ṣara lóore bí? Rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn òbí gbọ́dọ̀ ṣe àwọn yíyàn fún àwọn ọmọ wọn pẹ̀lú ire ọjọ́ iwájú àwọn ọmọ wọn lọ́kàn.

Nítorí náà, àwọn òbí ń yan oúnjẹ, aṣọ, ìmúra, àti ìwà rere fún àwọn ọmọ wọn. Àmọ́ nípa ti ìsìn ńkọ́? Ó ha yẹ kí àwọn òbí ṣe yíyàn ìyẹn náà pẹ̀lú bí?

Yíyàn Náà

Àwọn kan yóò jiyàn pé kò yẹ kí àwọn òbí fipá mú àwọn ọmọ láti tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ ìsìn tiwọn. Ní tòótọ́, ní ohun tí ó lé ní 160 ọdún sẹ́yìn, àwọn kan tí wọ́n sọ pé àwọn ní èrò ìgbàgbọ́ Kristẹni ṣègbélárugẹ èrò náà pé, “kò yẹ kí a kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn nítorí ìbẹ̀rù kí wọ́n má baà ní ẹ̀tanú sí àwọn ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ kan, àmọ́ ó yẹ kí a fi wọ́n sílẹ̀ títí di ìgbà tí wọ́n bá tóótun láti dá ṣe yíyàn kan, kí wọ́n sì yàn láti ṣe ọ̀kan.”

Bí ó ti wù kí ó rí, èrò yí kò bá ojú ìwòye Bíbélì mu. Bíbélì tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì títẹ àwọn èrò ìgbàgbọ́ ìsìn mọ́ àwọn ọmọ lọ́kàn láti ìgbà tí a ti bí wọn. Òwe 22:6 sọ pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.”

Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí a túmọ̀ sí “ọmọdé” ní nínú, láti ọjọ́ orí láti ìgbà ọmọ ọwọ́ dé ìgbà àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà. Ọ̀mọ̀wé Joseph M. Hunt, láti Yunifásítì Illinois, U.S.A., sọ nípa ìjẹ́pàtàkì kíkẹ́kọ̀ọ́ láti ìgbà ọmọdé pé: “Láàárín ọdún mẹ́rin tàbí márùn-ún àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé ni ìdàgbàsókè ọmọdé kan ń yára kánkán jù lọ, tí ó sì ṣeé tún ṣe jù lọ. . . . Bóyá ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn lájorí agbára ìṣe [rẹ̀] ní ń dàgbà kí ó tó pé ọmọ ọdún kan, bóyá ìdajì kí ó tó pé ọmọ ọdún mẹ́rin.” Èyí wulẹ̀ tẹnu mọ́ ìmọ̀ràn onímìísí ti Bíbélì pé ó ṣe kókó fún àwọn òbí láti pèsè ìdarísọ́nà ọlọgbọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ọmọ kan, ní kíkọ́ ọ ní àwọn ọ̀nà Ọlọ́run.—Diutarónómì 11:18-21.

Lọ́nà tí ó hàn gbangba, Ìwé Mímọ́ darí àwọn òbí olùbẹ̀rù Ọlọ́run láti gbin ìfẹ́ fún Jèhófà sọ́kàn àwọn ọmọ wọn. Diutarónómì 6:5-7 sọ pé: “Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ. Àti ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí mo pa láṣẹ fún ọ ní òní, kí ó máa wà ní àyà rẹ: Kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ rẹ gidigidi, kí ìwọ kí ó sì máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ í sọ nígbà tí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ bá ń rìn ní ọ̀nà, àti nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ bá dìde.” Ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tí a túmọ̀ sí “fi kọ́” ní èrò pípọ́n ohun èèlò kan, bíi lórí òkúta ìpọ́nbẹ. A kò lè ṣàṣeparí èyí pẹ̀lú lílọ̀ ọ́ fún ìgbà díẹ̀ àmọ́ a ní láti ṣe é láṣetúnṣe, taápọntaápọn. The New English Bible túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù náà sí “àṣetúnṣe.” Ní kedere, “fífi kọ́” ní nínú, títẹ èrò pípẹ́ títí kan mọ́ni lọ́kàn.—Fi wé Òwe 27:17.

Nípa bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tòótọ́ fi ọwọ́ gidi mú iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe wọn láti tẹ àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn wọn mọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn. Wọn kò lè fi ẹ̀tọ́ yẹ ẹrù iṣẹ́ yìí sílẹ̀ nípa fífàyè gba àwọn ọmọ wọn láti yàn fún ara wọn. Èyí yóò kan mímú àwọn “ọmọ kéékèèké” dání lọ sí àwọn ìpàdé. Níbẹ̀, àwọn òbí lè jókòó pẹ̀lú wọn, kí wọ́n sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọrírì àǹfààní tẹ̀mí tí ìdílé tí ó ṣọ̀kan lè jèrè nípasẹ̀ fífiyè sí àwọn ìjíròrò Ìwé Mímọ́ àti lílóhùn sí i.—Diutarónómì 31:12, 13; Aísáyà 48:17-19; Tímótì Kejì 1:5; 3:15.

Ẹrù Iṣẹ́ Òbí

Wíwulẹ̀ wí fún ọmọ kan láti jẹ ohun kan nítorí pé ó ń ṣàra lóore kò túmọ̀ sí pé ọmọ náà yóò gbádùn rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ìyá kan tí ó jẹ́ ọlọgbọ́n mọ bí yóò ṣe se àwọn oúnjẹ pípọn dandan yìí lọ́nà tí ń dáni lọ́fun tòló gan-an kí ó baà lè dùn lẹ́nu ọmọ náà. Dájúdájú, ìyá náà máa ń gbọ́únjẹ lọ́nà tí yóò fi lè dà nínú ọmọ náà.

Bákan náà, lákọ̀ọ́kọ́, ọmọ kan lè kọ ìtọ́ni nípa ìsìn, òbí kan sì lè rí i pé gbígbìyànjú láti ṣàṣàrò nípa ọ̀ràn náà kò gbéṣẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdarísọ́nà tí ó wá láti inú Bíbélì ṣe kedere—àwọn òbí gbọ́dọ̀ sa ipá wọn láti kọ́ àwọn ọmọ wọn láti ìgbà ọmọ ọwọ́. Nítorí náà, àwọn òbí tí wọ́n jẹ ọlọgbọ́n ń mú kí ìtọ́ni nípa ìsìn gbádùn mọ́ni nípa gbígbé e kalẹ̀ lọ́nà tí ń fa ọmọ lọ́kàn mọ́ra, ní gbígba ti agbára rẹ̀ láti lóye nǹkan rò.

Àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ ń nímọ̀lára àìgbọdọ̀máṣe jíjinlẹ̀ láti pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé fún àwọn ọmọ wọn, nínú ọ̀ràn tí ó sì pọ̀ jù lọ, kò sí ẹni tí ó mọ àwọn àìní ọmọ kan dáadáa ju àwọn òbí rẹ̀ lọ. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Bíbélì gbé iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe onípò kíní ti pípèsè nípa tí ara àti ti ẹ̀mí lé èjìká àwọn òbí—ní pàtàkì, bàbá. (Éfésù 6:4) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òbí kò ní láti yẹrí fún ẹrù iṣẹ́ wọn nípa wíwá ọ̀nà láti ti iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe náà sórí ẹlòmíràn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè lo àǹfààní ìrànwọ́ tí a pèsè, èyí yóò jẹ́ àfikún, kì í ṣe pé yóò rọ́pò, ẹ̀kọ́ nípa ìsìn tí ń wá láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí.—Tímótì Kíní 5:8.

Ní ìgbà kan nínú ìgbésí ayé, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ń pinnu àwọn èrò ìgbàgbọ́ ìsìn tí yóò pa mọ́, bí èyíkéyìí bá wà. Bí àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni bá fi fífún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́ni nípa ìsìn láti ìgbà ọmọdé ṣe ẹrù iṣẹ́ tiwọn, bí wọ́n bá sì lo àkókò yí ní fífún wọn nítọ̀ọ́ni láti ronú lórí ìpìlẹ̀ fún àwọn ìlànà yíyèkooro, yíyàn tí ọmọ náà bá ṣe lẹ́yìnwá ọ̀la lè jẹ́ èyí tí ó tọ̀nà jù lọ.—Kíróníkà Kejì 34:1, 2; Òwe 2:1-9.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

The Doré Bible Illustrations/Dover Publications, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́