Wíwo Ayé
Omi Àìmọ́
Ó ka oníṣẹ́ abẹ kan láyà ní Ireland nígbà tí obìnrin ẹni ọdún 72 kan ní àwọn àrùn ojú tí ó nira lẹ́ẹ̀mejì kété kí ó tó ṣe iṣẹ́ abẹ ẹbọ́ ojú. Kí ní fa àwọn àrùn ojú náà? Omi “mímọ́” láti Lourdes tí obìnrin náà ti fi bọ́jú. Ìwé agbéròyìnjáde The Irish Times sọ pé: “Ìṣòro náà ni pé àwọn bakitéríà eléwu sábà máa ń sọ omi mímọ́ yẹn di eléèérí.” Bí ó bá ṣe pé wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ náà bí wọ́n ṣe wéwèé rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni, ì bá ti rọrùn fún àrùn náà láti fọ́ obìnrin náà lójú. Ìwé agbéròyìnjáde The Irish Times ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Gbígbàdúrà lásán kì í pa kòkòrò àrùn. Fífọ́n omi mímọ́ tí a pète láti woni sàn síni lára, sì lè ṣokùnfà àrùn tí ń wu ìwàláàyè léwu ní ti gidi nínú àwọn ọ̀ràn kan.” Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe wí, àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí elérò rere tí ń fọ́n omi “mímọ́” sí ọ lára nígbà tí o wà nílé ìwòsàn lè jẹ́ “ewu títóbi jù lọ fún lílàájá rẹ.”
Ẹtì Àwọn Ohun Abúgbàù Abẹ́lẹ̀
Ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal sọ pé: “Ìgbétásì kárí ayé láti kásẹ̀ àwọn ohun abúgbàù abẹ́lẹ̀ nílẹ̀ lágbàáyé ti rí i pé èròǹgbà náà kò yéni bí àwọn ohun abúgbàù náà fúnra wọn kò ṣe yéni. Kò sí àwọn ohun èlò yíyẹ láti mú kíkó àwọn ohun abúgbàù abẹ́lẹ̀ kúrò dáni lójú.” Àwọn ológun òde òní ṣì ń lo àwọn ohun èèlò kan náà tí ìran àwọn baba ńlá wọn ti lò nígbà Ogun Àgbáyé Kejì—ìhùmọ̀ agbésọfúnni láti ojúde òfuurufú tí ó rí bí ọ̀pá àti ìhùmọ̀ aṣàwárí mẹ́táàlì. Ṣùgbọ́n, ó túbọ̀ ṣòro láti ṣàwárí àwọn oríṣi ohun abúgbàù tuntun, nítorí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ kìkì ike tán, a sì rì wọ́n mọ́ àárín àwọn èérún bọ́ǹbù àti àwọn pàǹtírí mìíràn tí ń ké gbàjarè èké. Nígbà tí ìhùmọ̀ aṣàwárí mẹ́táàlì náà bá róye ohun kan, a ń ki ọ̀pá onígíláàsì kan wọ ilẹ̀ náà ni ìwọ̀n ìdagun kan. Ète rẹ̀ ni kí a lè rí ohun abúgbàù náà nípa gígún un lẹ́gbẹ̀ẹ́. Bí ohun abúgbàù náà bá dagun, tí a sì gún-un lórí, yóò bú gbàù mọ́ olúwa rẹ̀ lójú. Nígbà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun abúgbàù kì í náni tó dọ́là márùn-ún, pípalẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mọ́ lè náni ju 1,000 dọ́là lọ. Lọ́dọọdún, wọ́n ń ri mílíọ̀nù 1.5 sí mílíọ̀nù 2 àwọn ohun abúgbàù mọ́lẹ̀, ìwọ̀nyí sì ń sọ àwọn ènìyàn tí ó lé ní 25,000—tí ó ní ọ̀pọ̀ ọmọdé nínú—di aláàbọ̀ ara tàbí kí ó pa wọ́n.
Àwọn Ọmọdé Kò Ríbi Yẹ̀ Ẹ́ Sí
Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé: “Àwọn ọmọdé ní gbogbogbòò bẹ̀rẹ̀ sí í jìyà nítorí aáwọ̀ tí ó wà láàárín àwọn àgbàlagbà nígbà tí ogun bá di aláìmààlà: àwọn bọ́ǹbù àti àwọn ohun ìjà kì í pààlà sí ọjọ́ orí àwọn ènìyàn tí wọ́n ń pa. Àwọn ogun abẹ́lé—tí ó wọ́pọ̀ lóde òní—sábà máa ń kó àwọn orílẹ̀-èdè pọ̀ lódindi. Ní àwọn ibì kan, àwọn elétò ìrànwọ́ ní láti fiyè sí bíbọ́ṣọ ogun lọ́rùn àwọn ọmọdé tí ń jagun nísinsìnyí, lọ́nà kan náà tí wọ́n ń gbà fiyè sí pípèsè oúnjẹ tí kò ṣeé máà ní. Níbi yòó wù kí wọ́n lọ, wọ́n lè retí láti rí àwọn ọmọdé láàárín àwọn olùwá-ibi-ìsádi, àwọn tí ó fara pa àti àwọn òkú.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni gbogbo ní ń sọ pé òun fẹ́ràn àwọn ọmọdé, àwọn ọmọdé ní ń jìyà ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Àwọn elétò ìrànwọ́ fojú bù ú pé mílíọ̀nù 24 àwọn ọmọdé tí kò tí ì pé ọmọ ọdún 18 ni ogun lé kúrò nílé lọ́dún tó kọjá, àti pé nǹkan bíi mílíọ̀nù 2 ni ó kú láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá. Àfikún mílíọ̀nù mẹ́rin sí márùn-ún di aláàbọ̀ ara. Ìwé ìròyìn The Economist sọ pé: “A kàn wulẹ̀ lè méfò ipa tí ó ní lórí ìrònú òun ìhùwà ni.”
Àríyànjiyàn Lórí Ẹ̀jẹ́ Ànìkàngbé
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí a tẹ̀ jáde nínú lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin ṣe sọ: “Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ń pàdánù ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ títóótun nítorí ìrinkinkin rẹ̀ lórí ẹ̀jẹ́ ànìkàngbé fún àwọn àlùfáà.” Níbi Àpérò Àgbáyé Kẹrin ti Àwọn Àlùfáà Tí Wọ́n Gbéyàwó, tí wọ́n ṣe ní Brasília, a gbọ́ ìròyìn pé 100,000 àlùfáà Roman Kátólíìkì ti fiṣẹ́ àlùfáà sílẹ̀ jákèjádò ayé, wọ́n sì ti yọwọ́ nínú ẹ̀jẹ́ ànìkàngbé. Gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àtijọ́, Jorge Ponciano Ribeiro, tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní Yunifásítì Brasília nísinsìnyí ṣe wí, ìpín 1 nínú 5 gbogbo àlùfáà ti fi iṣẹ́ àlùfáà sílẹ̀, kí wọ́n lè gbéyàwó. Ní Brazil nìkan, àwọn àlùfáà tó ti gbéyàwó jẹ́ 3,500. Ribeiro sọ pé: “Láti yẹra fún ìṣòro láàárín ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn tí ì bá jẹ́ ajogún àwọn àlùfáà ni wọ́n ṣe gbé ẹ̀jẹ́ ànìkàngbé kalẹ̀, kì í ṣe nítorí pé àwọn tí kò bá kó sínú ìbátan oníbàálòpọ̀ yóò lè fúnni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà sísàn jù.”
Àwọn Erin Tó Ya Pòkíì
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Bíi ti àwọn ọmọdé, ó yẹ kí a máa bá àwọn ọ̀dọ́ erin wí, kí wọ́n lè dàgbà di mẹ́ńbà tó ṣeé fọkàn tán láwùjọ àwọn erin. Àwọn onímọ̀ nípa àwọn ohun alààyè tí a kò fi dọ́sìn sọ pé, àwọn akọ erin kan tí kò lóbìí ní Igbó Àìro Pilanesberg ti Gúúsù Áfíríkà ti ya pòkíì, nítorí pé àwọn tó dàgbà jù wọ́n lọ kì í bá wọn wí.” Àwọn òǹrorò erin náà ti gbéjà ko àwọn ènìyàn, wọ́n ti kan ẹranko rhinoceros funfun 19 pa láàárín ọdún mẹ́ta tó kọjá, wọ́n sì tilẹ̀ ti gbìyànjú láti gun àwọn ẹranko rhino. Wọ́n ti pa ènìyàn méjì tí ó ní amọṣẹ́dunjú ọdẹ kan, tí wọ́n rán pé kí ó lọ pa erin kan tí ó kù gììrì mọ́ àwùjọ àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ kan, nínú. Nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, ẹranko tó ya pòkíì náà jẹ́ lára àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ akọ erin tí a kó wá sí igbó àìro náà láti Ọgbà Ẹranko Orílẹ̀-Èdè ti Kruger lẹ́yìn tí wọ́n ti pa agbo wọn kù, láti dín iye àwọn erin náà kù. Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn kókó abájọ kan ti fa másùnmáwo fún àwọn erin náà, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ rò pé àìsí ìbáwí àti ìtọ́dàgbà láti ọwọ́ àwọn àgbà ẹranko, tí ó jẹ́ ẹ̀ka pàtàkì kan nínú ọ̀nà ìgbésí ayé yíyẹ fún àwọn ìdílé erin, jẹ́ apá kan, ó kéré tán, tí ó fa ìhùwàsí ìṣetinú-ẹni wọn. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé, ní báyìí, kìkì odindi ìdílé erin ni wọn yóò máa ṣí nípò kí àwọn ọ̀dọ́ akọ erin lè “máa bá gbígba ìbáwí fífẹsẹ̀múlẹ̀ tí wọ́n nílò láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn lọ.”
Ìjàǹbá Ìkọlunisálọ Kìíní ní Gbalasa Òfuurufú
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, ìjàǹbá ìkọlunisálọ kìíní ní gbalasa òfuurufú tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní èyí tí ó lé ní 700 kìlómítà sí ilẹ̀ ayé. Sátẹ́láìtì Faransé kan tí ń jẹ́ Cerise gbókìtì nídoríkodò nígbà tí apá rẹ̀ kan pòórá lẹ́yìn tí àfọ́kù rọ́kẹ́ẹ̀tì Ariane ọlọ́dún mẹ́wàá kan, tí ń rìnrìn àjò ní ìwọ̀n ìyára 50,000 kìlómítà ní wákàtí kan ní ọ̀gangan kan náà lókè, forí sọ ọ́. Lọ́dọọdún ni ṣíṣeéṣe irú ìforígbárí bẹ́ẹ̀ ń pọ̀ sí i bí pàǹtí ṣe ń kóra jọ sí i ní àwọn ojú òpó ilẹ̀ ayé. Ní báyìí ná, àwọn pàǹtírí tí a mọ̀ tí ń fò káàkiri ní gbalasa òfuurufú yí ká àgbáyé lé ní 20,000. Nígbà tí a sábà ń palẹ̀ àwọn tó wà ní ojú òpó tó sún mọ́ àgbáyé mọ́ lọ́nà àdánidá, irú bí afẹ́fẹ́ àyíká bá fẹ̀ sí i, àwọn tó jìnnà sí àgbáyé lè wà níbẹ̀ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Nígbà tí wọ́n bá forí sọ àwọn pàǹtírí mìíràn, wọ́n ń fọ́ sí wẹ́wẹ́ sí i, èérún wọn sì ń lè la aṣọ tí àwọn arìnrìn-àjò ré kọjá gbalasa òfuurufú ń wọ̀ tàbí ìbòjú ọkọ̀ arékọjá gbalasa òfuurufú já. Kódà, èérún ọ̀dà pẹ̀lú lè di eléwu. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, nǹkan bíi sátẹ́láìtì tí kò ṣiṣẹ́ mọ́ 4 sí 1 tó ń ṣiṣẹ́ ló wà ní ojú òpó, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn rọ́kẹ́ẹ̀tì tí kò lókun nínú mọ́, tí wọ́n ti tú ká ní ojú òpó, jẹ́ ìdámẹ́rin àwọn pàǹtí tí a mọ̀ ní gbalasa òfuurufú.
Àwọn Sponge Ló Kọ́kọ́ Ní In
Ìwé agbéròyìnjáde The Washington Post sọ pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn èrò onílàákàyè tí ẹ̀dá ènìyàn ní máa ń jẹ́ ògbólógbòó ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ti ìṣẹ̀dá. Mú fọ́nrán gíláàsì atàtagbà ìmọ́lẹ̀ bí àpẹẹrẹ. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe àwọn fọ́nrán tí ó jọ gíláàsì láti máa gba ìmọ́lẹ̀ sára, kí ó sì máa gbé e karí orígun-orígun ní 1951. Ó wá já sí pé àwọn sponge abẹ́ omi jíjìn ti Òkun Ross ní Antarctica ti ń ṣe ohun kan náà láti ọdún gbọ́nhan.” Àwọn arabaríbí sponge náà, tí a ń rí nínú omi tí ó bá jìn tó mítà 30.5, ní ìyọgọngọ onífọ́nrán kan lára wọn tí ń gba ìmọ́lẹ̀ sára, tí ó sì lè fi í ránṣẹ́, kódà, ní ìwọ̀n ìdámẹ́rin òbírí, sí èèhọ̀n afọ́mọ̀ọ́lẹ̀ sí wẹ́wẹ́ tí ń gbé àárín gbùngbùn ara sponge náà. Àwọn àṣeyẹ̀wò ti fi hàn pé ó ń gbá ìmọ́lẹ̀ tí ó bá kàn án ní igun kan pàápàá mọ́ra, tí ń tọ́ka sí i pé àwọn ìyọgọngọ ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ sponge náà pẹ̀lú lè fún èèhọ̀n náà ní ìmọ́lẹ̀.
Àwọn Atatẹ́tẹ́ Ń Pàdánù
Ricardo Gazel, onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé, ará Brazil náà sọ pé: “A ṣe àwọn ẹ̀rọ tẹ́tẹ́ casino lọ́nà tí ẹni tí ó ni wọ́n kò fi lè pàdánù owó lọ́nàkọnà. Ṣíṣeéṣe pé ẹnì kan yóò rí owó nípasẹ̀ tẹ́tẹ́ títa kéré gan-an lórí ìwọ̀n ìṣirò.” Nígbà tí ó ń kìlọ̀ pé ó ṣeé ṣe gan-an pé mímú kí ó rọrùn láti rí ẹ̀rọ tẹ́tẹ́ casino lò lè mú kí àwọn tí ń sọ títa tẹ́tẹ́ di bárakú, tí wọ́n ń yíjú sí ìwà ọ̀daràn àti jìbìtì pọ̀ sí i, Gazel fi kún un pé: “Àlá àbámodá ti rírí owó láìlàágùn jìnnà wà níbẹ̀. Àwọn ènìyàn ń lálàá pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ta oríire lẹ́ẹ̀kan, kí àwọn sì di olówó kíámọ́sá.” Síwájú sí i, ìwé ìròyìn Veja fa ọ̀rọ̀ tí ó sọ nípa pé kò sí ìdí rere kankan fún ṣọ́ọ̀ṣì àti ìjọba láti ṣe àríwísí yọ pé: “Ìjọba ni ètò ìgbékalẹ̀ tẹ́tẹ́ títa títóbi jù lọ ní orílẹ̀-èdè yí. Ìjọba àpapọ̀ ń ṣagbátẹrù oríṣi tẹ́tẹ́ mẹ́fà, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àwọn tí ìjọba ìpínlẹ̀ ń ṣagbátẹrù wọn. Ṣọ́ọ̀ṣì kò lè ṣàríwísí fífi òfin ti tẹ́tẹ́ títa lẹ́yìn nítorí pé, kí wọ́n lè kówó jọ fún àwọn ẹ̀ka wọn, ṣọ́ọ̀ṣì ń gbé àṣà tẹ́tẹ́ títa lárugẹ nígbà ọjà bàsá, níbi tí ìsọ̀ kékeré kan sábà máa ń wà, nínú èyí tí àwọn ọmọ ìjọ ti máa ń pàdánù owó tí wọ́n fi lérí.” Gẹ́gẹ́ bí Gazel ṣe sọ, ‘àwọn ògbógi sọ pé, àwọn atatẹ́tẹ́ láìníjàánu tí kò bá wá ìrànwọ́ ń fi ṣíṣẹ̀wọ̀n, pípa ara ẹni, tàbí dídi ayírí ṣeré.’
Àwọn Ìgárá Agbéjòṣeré
Àwọn olè ti ń pa àwọn olùgbé Diriamba, ìlú kan ní Nicaragua, tí ó wà ní 50 kìlómítà ní ìhà gúúsù Managua, nípa lílo àwọn ejò olóró. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde El Nuevo Diario ṣe sọ, àwọn àjọ ìpàǹpá náà yóò kó àwọn ejò àgbàfúùfúù jọ láti inú ìgbẹ́ àdúgbò, wọn yóò gba oró wọn, wọn yóò sì máa ja àwọn ènìyàn lólè bí wọ́n ṣe ń lọ ní àwọn títì ẹ̀yìn odi ìlú nípa híhalẹ̀ mọ́ wọn pé àwọn yóò jẹ́ kí ejò bù wọ́n jẹ. Nígbà tí ọmọbìnrin kan tí ó dá kú nígbà tí ó rí àwọn eyín ejò náà ta jí, ó rí i pé wọ́n ti jí àwọn gbẹ̀dẹ̀ wúrà òun lọ. Àjọ ìpàǹpá náà tún ń ja àwọn mẹ̀kúnnù lólè oúnjẹ àti owó.