Mo Rí Òtítọ́ Nígbẹ̀yìngbẹ́yín
Nígbà tí oṣù August 1939 ń parí lọ, mo dúró ní Moscow nígbà tí mo ń lọ sílé ní Budapest, Hungary. Ó ti tó ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn tí Germany àti Soviet fọwọ́ sí Ìwé Àdéhùn Àlàáfíà, ní August 23, wọ́n sì fi àwọn àsíá swastika ti ìjọba Nazi ṣe ògiri Kremlin lọ́ṣọ̀ọ́. Kí ni mo ń ṣe ní Rọ́ṣíà, kí ló sì ń dúró dè mí ní ilé?
LÁKỌ̀Ọ́KỌ́, ẹ jẹ́ kí n sọ fún yín nípa ìlú kékeré Veszprém, ní Hungary níbi tí wọ́n bí mi sí ní January 15, 1918. Èmi ni mo dàgbà jù lọ lára àwa ọmọ mẹ́rin, àwọn òbí wa sì rí sí i pé a ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún márùn-ún, mo ń ṣèrànwọ́ níbi ìsìn Máàsì ní ilé ìjọsìn Roman Kátólíìkì kan. Ní ilé, mo máa ń fi dídarí ìsìn Máàsì fún àwọn àbúrò mi ṣe ṣeréṣeré, ní wíwọ aṣọ àlùfáà tí mo fi pépà ṣe nítorí ìsìn náà.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́jọ, Dádì pa ìdílé wa tì, Màmá ló sì ń tọ́jú wa pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìyá rẹ̀. Lọ́dún tí ó tẹ̀ lé ìyẹn, àrùn jẹjẹrẹ pa Màmá. Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, wọ́n ya àwa ọmọ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n sì kó wa lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn àti ilé àwọn alágbàtọ́ tí ó yàtọ̀ síra. Ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn tí mo gbé kẹ́yìn sún mọ́ Budapest. Frères Maristes (Àwọn Arákùnrin Màríà), òtú ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ Kátólíìkì ará Faransé kan, ló ni ín. Mo ní ìfẹ́ gidi fún Ọlọ́run, nítorí náà, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún 13, mo tẹ́wọ́ gba ìfilọni, tí òtú ẹgbẹ́ wọn nawọ́ rẹ̀ sí mi, láti kẹ́kọ̀ọ́.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Jíjinlẹ̀ Nípa Ìsìn
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n rán mi lọ sí Gíríìsì, níbi tí mo ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Frères Maristes níbi tí wọ́n ti ń fi èdè Faransé, tí ó múra mi sílẹ̀ láti di olùkọ́, kọ́ni. Lọ́dún mẹ́rin lẹ́yìn náà, ní 1936, mo jáde ilé ẹ̀kọ́, níbi tí mo ti gba ìwé ẹ̀rí kan tí ó mú mi tóótun láti ṣe olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́jáde, mo di arákùnrin nínú òtú ẹgbẹ́ onísìn náà, ní jíjẹ́jẹ̀ẹ́ onípa mẹ́ta ti ipò òṣì, ìgbọràn, àti ìjẹ́mímọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa arákùnrin máa ń wọ aṣọ ìsìn, tí a sì ń kọ́ àwọn ènìyàn ní katikísìmù, a kò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí.
Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, mo kọ̀wé béèrè láti lọ ṣe olùkọ́ ní China, wọ́n sì gbà fún mi. Ní October 31, 1936, mo bá ọkọ̀ òkun kúrò ní Marseilles, ilẹ̀ Faransé. Ní December 3, 1936, mo gúnlẹ̀ sí Shanghai. Láti ibẹ̀, mo bá ọkọ̀ ojú irin lọ sí Beijing, olú ìlú orílẹ̀-èdè náà tí ó wà ní ìhà àríwá China.
Òtú ẹgbẹ́ Frères Maristes ní ilé ẹ̀kọ́ kan tí ó tóbi, àwọn gbọ̀ngàn ilé gbígbé, àti àwọn ilé oko ní àgbègbè olókè kan tí ó wà ní nǹkan bíi kìlómítà 25 sí Beijing. Ibi tí ó wà sún mọ́ ilé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti olú ọba, àwọn ọgbà àti èso tí a tọ́jú dáradára sì wà níbẹ̀. Ibẹ̀ ni mo ti kira bọ kíkẹ́kọ̀ọ́ èdè Chinese àti Gẹ̀ẹ́sì jinlẹ̀jinlẹ̀. Àmọ́, a kò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí.
Nínú Pákáǹleke
Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930, Japan fipá gba Manchuria, apá kan ilẹ̀ China. Ní July 1937, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Japan àti ti China forí gbárí nítòsí Beijing. Àwọn ará Japan tí wọ́n ṣẹ́gun gbé ìjọba tuntun kan kalẹ̀, nínú èyí tí wọ́n ti yan àwọn ará China gẹ́gẹ́ bí alákòóso. Èyí ṣamọ̀nà sí kí àwọn agbábẹ́lẹ̀jagun ará China máa bá ìjọba tuntun náà jà.
Níwọ̀n bí wọ́n ti mọ̀ pé ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìsìn wa tí kò sí ní Beijing wà lábẹ́ àkóso ilẹ̀ Faransé, wọn kò kógun tì í ní tààràtà. Síbẹ̀, àwọn ọta bọ́ǹbù àti ọta ìbọn tí ó tàsé ìfojúsùn ń dé ọ̀dọ̀ wa, wọ́n sì ṣèpalára fún àwọn mélòó kan lára àwọn ará China tí wọ́n lé ní 5,000 tí wọ́n wá ìsádi wá sí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìsìn wa. Láàárín àkókò kan náà, àwọn agbábẹ́lẹ̀jagun ará China ni wọ́n ń ṣàkóso àgbègbè àrọko.
Ní September 1937, nǹkan bí 300 àwọn agbábẹ́lẹ̀jagun ará China tí wọ́n dìhámọ́ra kọ lu àwọn ilé wa, wọ́n ń wá ohun ìjà, owó, àti oúnjẹ. Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ará Europe mẹ́wàá tí wọ́n mú ní àmúdá. Lẹ́yìn tí wọ́n mú wa ní àmúdá fún ọjọ́ mẹ́fà, mo wà lára àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ dá sílẹ̀. Oúnjẹ eléèérí tí mo jẹ níbẹ̀ ti kó àìsàn bá mi, nítorí náà, mo lo oṣù kan ní ilé ìwòsàn.
Lẹ́yìn tí wọ́n dá mi sílẹ̀ ní ilé ìwòsàn, wọ́n gbé mi lọ sí ilé ẹ̀kọ́ mìíràn tí òtú ẹgbẹ́ onísìn náà ń darí, ní àgbègbè kan tí ó túbọ̀ láàbò ní Beijing. Ní January 1938, wọ́n rán mi lọ sí Shanghai láti lọ ṣe olùkọ́, àmọ́, ní September, mo pa dà sí Beijing láti lọ ṣe olùkọ́ níbẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn tí ọdún ìkẹ́kọ̀ọ́ parí, n kò tún ẹ̀jẹ́ ìsìn mi ṣe. Mo ti lépa ìgbésí ayé onísìn àti ti ẹ̀kọ́ fún ọdún méje, ṣùgbọ́n n kò rí ìtẹ́lọ́rùn nínú wíwá tí mo ń wá òtítọ́ kiri. Nítorí náà, mo kúrò nínú òtú ẹgbẹ́ onísìn náà láti darí sí ilé, sí Budapest.
Ogun Àgbáyé Kejì ti ń kóra jọ nígbà yẹn. Àwọn ọ̀gá mi ará Faransé fún mi níṣìírí láti wọ Ọkọ̀ Ojú Irin Tí Ń Lọ Ré Kọjá Òkè Òkun, tí ó máa ń gba apá kan Soviet Union kọjá. Ẹnu ìrìn àjò yí ni mo wà, tí mo fi dé Moscow ní August 27, 1939, tí mo sì rí i tí wọ́n fi àwọn àsíá Nazi ṣe ògiri Kremlin lọ́ṣọ̀ọ́.
Ayé Kan Nínú Ogun
Mo dé ilé ní Budapest ní August 31, 1939. Lọ́jọ́ kejì, Germany kọ lu Poland, Ogun Àgbáyé Kejì sì bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà, Germany já àdéhùn àlàáfíà tí ó ṣe pẹ̀lú Soviet Union, nígbà tí ó sì di June 22, 1941, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Hitler kọ lu Soviet Union. Wọ́n dé àwọn àrọko àgbègbè ìlú ńlá Moscow, ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣẹ́gun ìlú ńlá náà.
Gómìnà Hungary fọwọ́ sí àdéhùn àlàáfíà kan pẹ̀lú Germany, wọ́n sì fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun Germany lómìnira láti gba àárín Hungary kọjá. Mo gbéyàwó ní 1942, nígbà tí ó sì di 1943, wọ́n yàn mí sínú Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Hungary. Ní March 1944, Germany kọ lu Hungary nítorí pé ìtìlẹ́yìn tí Hungary ṣe fún Hitler nínú ìsapá ogun rẹ̀ kò tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ọdún yẹn ni a bí ọmọkùnrin wa. Láti yẹra fún òjò ọta púpọ̀ tí ń rọ̀ sórí Budapest, ìyàwó mi àti ọmọkùnrin mi kó lọ sí àgbègbè àrọko láti máa gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀.
Bí ogun ṣe ń lọ sí yí pa dà, Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Soviet sì wọ Budapest ní December 24, 1944. Àwọn ará Rọ́ṣíà mú mi, mo sì di ẹni tí a kó ní ìkógun. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwa ẹlẹ́wọ̀n ni wọ́n fipá mú láti rin ìrìn tí ó tó 160 kìlómítà dé ìlú ńlá Baja, ní Hungary. Níbẹ̀, wọ́n kó wa síbi ìkẹ́rù tí màlúù ń fà, wọ́n sì kó wa lọ sí Timisoara, wọ́n kó wa sí àgọ́ ńlá kan. Ó kéré tán, 20,000 lára àwa 45,000 ẹlẹ́wọ̀n náà ló kú ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1945 nígbà tí ibà typhoid jà.
Ní August, wọ́n kó àwa 25,000 tí a là á já ní àgọ́ náà lọ sí Òkun Dúdú. Láti ibẹ̀, àwọn bí 20,000 ni wọ́n dá pa dà sí Soviet Union. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n dá àwa bí 5,000 míràn, tí ara wa kò yá, pa dà sí Hungary, wọ́n sì dá wa sílẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, oṣù líle koko mẹ́jọ ní ìgbèkùn dópin. Lọ́sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo tún wà pẹ̀lú ìyàwó mi àti ọmọkùnrin mi, a sì pa dà sí Budapest láti máa gbé níbẹ̀.
Lẹ́yìn ogun náà, ìyà ṣì ń jẹ ọ̀pọ̀ ènìyàn. Oúnjẹ ṣọ̀wọ́n, ọ̀wọ́n gógó ọjà sì ń boni mọ́lẹ̀ pátápátá. Ohun tí a lè rà ní pengö kan owó Hungary ní 1938 ni a ń rà ní nonillion kan pengö (1,000,000,000,000,000,000,000,000,000,000) ní 1946! Bí àkókò ti ń lọ, ìgbésí ayé ń sunwọ̀n sí i fún wa nígbà tí mo rí iṣẹ́ ọ́fíìsì ní ilé iṣẹ́ ọlọ́kọ̀ ojú irin.
Rírí Òtítọ́
Ní 1955, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń gbé ilé wa ní Budapest bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìyàwó mi, Anna, sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Ọkàn ìfẹ́ mi ru sókè nígbà tí Anna wí fún mi pé Bíbélì kò fi kọ́ni pé ibi ìdálóró ni hẹ́ẹ̀lì jẹ́. (Oníwàásù 9:5, 10; Ìṣe 2:31) Gẹ́gẹ́ bíi Kátólíìkì kan, n kò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí, kódà nígbà tí mo ń gba àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì. Mo wulẹ̀ tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ Kátólíìkì tí kò wá láti inú Ìwé Mímọ́, bí ọ̀run àpáàdì. Nísinsìnyí, mo ti wá nífẹ̀ẹ́ àwọn òtítọ́ Bíbélì, ní pàtàkì àwọn tí ó jẹ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti bí yóò ṣe mú ète Ọlọ́run ti sísọ ilẹ̀ ayé di párádísè ṣẹ. (Mátíù 6:9, 10; Lúùkù 23:42, 43; Ìṣípayá 21:3, 4) Mo ní ayọ̀ àgbàyanu tí n kò ní irú rẹ̀ rí.
Ní ìgbà yẹn, wọ́n ń dọdẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Hungary, wọ́n sì ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n nítorí pé wọ́n ń fi ìgboyà kọ́ni ní àwọn òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Mo ka gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí tí mo lè rí ní èdè Hungarian, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti gba àwọn ìtẹ̀jáde wọn tí ó wà lédè Gẹ̀ẹ́sì àti lédè Faransé tí wọn kò tí ì túmọ̀ sí èdè Hungarian. Ẹ wo bí mo ti kún fún ọpẹ́ tó pé mo ti kọ́ àwọn èdè míràn wọ̀nyí!
Ní October 1956, àwọn ará Hungary ṣòdì sí àkóso Kọ́múníìsì tí Rọ́ṣíà gbé lé wọn lórí. Ìjà tí ó bẹ́ sílẹ̀ ní Budapest le gan-an. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n ni a dá sílẹ̀, títí kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lákòókò yí ni èmi àti ìyàwó mi ṣèrìbọmi láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà Ọlọ́run hàn. Lọ́sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Rọ́ṣíà paná ọ̀tẹ̀ náà. Wọ́n sì dá Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti dá sílẹ̀ pa dà sí ẹ̀wọ̀n.
Àǹfààní Ṣíṣeyebíye
Níwọ̀n bí púpọ̀ jù lọ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù náà ti wà lẹ́wọ̀n, Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi kan tọ̀ mí wá, ó sì béèrè bóyá mo lè ṣe ìtumọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mélòó kan. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n fún mi ní àwọn lẹ́tà ara ẹni kan láti Switzerland, tí ó ní àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ kan lédè Faransé nínú. Mo túmọ̀ wọn sí èdè Hungarian, lẹ́yìn náà, a ṣe ẹ̀dà àwọn àpilẹ̀kọ náà tí a pín fún ìlò àwọn ìjọ.
Nígbà tí wọ́n tú ìránṣẹ́ ẹ̀ka Hungary, János Konrád, sílẹ̀ ní 1959, lẹ́yìn tí ó ti ṣẹ̀wọ̀n fún ọdún 12 nítorí àìdásí-tọ̀túntòsì Kristẹni, wọ́n yàn mí gẹ́gẹ́ bí olùtumọ̀. Lẹ́yìn náà, mo ń gba àwọn àkójọ ọ̀rọ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì láti túmọ̀. Obìnrin akówèé kan, tí n kò mọ orúkọ rẹ̀, ló sábà máa ń mú un wá. Nípa bẹ́ẹ̀, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n gbá mi mú, tí wọ́n sì dá mi lóró, n kò lè tú u fó.
Lẹ́yìn tí mo bá túmọ̀ Ilé Ìṣọ́ tán, Arákùnrin Konrád yóò ṣàyẹ̀wò rẹ̀ láti rí i pé ó péye. Lẹ́yìn náà, àwọn arábìnrin yóò tẹ àwọn àpilẹ̀kọ tí mo túmọ̀ náà sórí pépà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ní lílo pépà aṣàdàkọ láti ṣe tó ẹ̀dà 12. Nípa bẹ́ẹ̀, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, olúkúlùkù ẹni tó bá wá sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ló ń ní ẹ̀dà tiwọn lára ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí a tẹ̀ náà. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi àwọn ẹ̀dà tiwọn ṣọwọ́ sí àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn. Bí ó ti wù kí ó rí, lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ kan ṣoṣo ni a ń lè ṣe fún àwùjọ ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan. Nígbà náà, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ní láti tẹ́tí sílẹ̀ gan-an, kí wọ́n sì máa ṣàkọsílẹ̀, kí wọ́n lè jàǹfààní kíkún láti inú ìjíròrò Bíbélì náà.
Láti ìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètumọ̀ ní 1956 títí di 1978, a ń pín Ilé Ìṣọ́ lédè Hungarian kiri ní títẹ̀ nìkan. Láti 1978 sí 1990, a ń pèsè àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tí a ṣàdàkọ. Ẹ sì wo irú ìbùkún tí ó ti jẹ́ láti January 1990 tí a ti ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lédè Hungarian ní aláwọ̀ mèremère!
Lábẹ́ àkóso Kọ́múníìsì, olúkúlùkù ló ní láti ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ lọ́wọ́. Nítorí náà, fún ọdún 22, títí di ìgbà tí mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ní 1978, mo máa ń ṣe ìtumọ̀ ní àwọn àkókò tí n kò bá sí lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Ìyẹn sábà máa ń jẹ́ ní ìdájí àti ní alẹ́ pátápátá. Lẹ́yìn ìfẹ̀yìntì mi, mo ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí olùtumọ̀ ní àkókò kíkún. Lákòókò náà, olùtumọ̀ kọ̀ọ̀kan máa ń ṣiṣẹ́ ní ilé, àti nítorí ìfòfindè, ó ṣòro fún wa láti kàn sí ara wa. Ní 1964, àwọn ọlọ́pàá ya lu ilé àwọn olùtumọ̀ nígbà kan náà, wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ẹrù wa. Fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn ọlọ́pàá sábà máa ń bẹ̀ wá wò.
Àwọn Ìbùkún Àgbàyanu
Ní 1969, wọ́n tẹ́wọ́ gba ìwé tí mo kọ béèrè fún ìwé àṣẹ ìrìn àjò, nítorí náà, ó ṣeé ṣe fún èmi àti János Konrád láti rìnrìn àjò láti Hungary lọ sí Paris láti lọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbáyé “Àlàáfíà Lórí Ilẹ̀ Ayé” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀. Ẹ wo irú ìbùkún tí ó jẹ́ láti pàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa láti àwọn ilẹ̀ míràn àti láti lo ọjọ́ mélòó kan ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Bern, Switzerland! Ní àwọn ọdún 1970, ó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí láti Hungary láti lọ sí Austria àti Switzerland fún àpéjọpọ̀.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún ìfòfindè láti ọ̀dọ̀ ìjọba, ní 1986, a ṣe àpéjọpọ̀ wa àkọ́kọ́ tí Ìjọba fọwọ́ sí ní Ọgbà Ìtura Àwọn Ọ̀dọ́ ti Kamaraerdő, Budapest. Àwọn tí iye wọn lé ní 4,000 tí wọ́n wá síbẹ̀ da omijé ayọ̀ lójú bí wọ́n ti ń kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn, tí wọ́n sì ń ka ohun tí wọ́n kọ sára pátákó ìkínikáàbọ̀ sí ìpàdé wa, lókè àbáwọlé ọgbà ìtura náà.
Níkẹyìn, ní June 27, 1989, ìjọba fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìdámọ̀ lábẹ́ òfin. Wọ́n ṣe ìkéde náà lórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò Hungary sí ìdùnnú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. Láìsí ìkálọ́wọ́kò, ní ọdún yẹn, a ṣe àpéjọpọ̀ wa àkọ́kọ́ láti ìgbà tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa ní nǹkan bí 40 ọdún ṣáájú àkókò náà. Àwọn tí wọ́n wá síbi àpéjọpọ̀ náà ní Budapest lé ní 10,000, àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún púpọ̀ sí i sì wá sí àwọn àpéjọpọ̀ mẹ́rin mìíràn ní orílẹ̀-èdè náà. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó láti rí i tí àbúrò mi ọkùnrin tí ó kéré jù lọ, László, àti ìyàwó rẹ̀ ṣèrìbọmi ní Budapest!
Lẹ́yìn náà, ní July 1991, a nírìírí ìbùkún kan tí ó kọjá ohun tí a fọkàn fẹ́ jù lọ—àpéjọpọ̀ kan ní pápá ìṣeré ńlá Népstadion ní Budapest, tí àwọn tí ó lé ní 40,000 àyànṣaṣojú wá. Níbẹ̀, mo ní àǹfààní ṣíṣe ògbufọ̀ àwọn àwíyé tí àwọn mẹ́ńbà àwọn òṣìṣẹ́ ní orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn sọ.
Lónìí, èmi àti Anna, àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin wá ọ̀wọ́n tí wọ́n lé ní 40, ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ó jojú ní gbèsè, ní àrọko ìlú ńlá Budapest kan. Níhìn-ín, mo ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìtumọ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwùjọ dáradára kan ti àwọn ọ̀dọ́, Anna sì ń ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ilé láyìíká ilé náà.
Láìka àwọn ìsapá wa láti kọ́ ọmọkùnrin wa ní òtítọ́ Bíbélì sí, nígbà tí ó dàgbà, kò tẹ́wọ́ gbà á. Àmọ́, ní báyìí, ó ti ń ní inú dídùn sí òtítọ́, a sì nírètí pé bí àkókò ti ń lọ, yóò sin Jèhófà.
Èmi àti ìyàwó mi mọrírì ní tòótọ́ pé a ti rí òtítọ́ nípa Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́, Jèhófà, ó sì ti ṣeé ṣe fún wa láti ṣiṣẹ́ sìn ín fún ohun tí ó ti lé ní 40 ọdún báyìí.—Gẹ́gẹ́ bí Endre Szanyi ṣe sọ ọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Pẹ̀lú ìyàwó mi