Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà ní Ìlà Oòrùn Europe
ÀWỌN adití ń gbọ́rọ̀! A ń tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀! Àwọn ọlọ́pàá fẹ́rẹ̀ẹ́ máà rí nǹkan ṣe! Kí ni a ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? A ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ó wáyé láìpẹ́ yìí, tí a ṣe ní Ìlà Oòrùn Europe láàárín July sí August ọdún tó kọjá.
“Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì rí i pé láìka àwọn wàhálà tí àwùjọ àlùfáà ní Romania ru sókè sí,a Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àlàáfíà tí ń wá láti inú mímọ Ọlọ́run àti Kristi Jésù.—Aísáyà 26:2, 3; Fílípì 4:7.
A ṣe àwọn àpéjọpọ̀ ní Prague, Orílẹ-Èdè Olómìnira Czech; Budapest, Hungary; Warsaw àti Lodz, Poland; Tallinn, Estonia; àti Brasov òun Cluj-Napoca, Romania.
Àwọn àyànṣaṣojú láti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ òkèèrè wá sí àwọn àpéjọpọ̀ yí, wọ́n sì fi adùn gidi láti orílẹ̀-èdè jákèjádò àgbáyé kún ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Àwùjọ àwọn ènìyàn púpọ̀ ló wá sí Prague láti Germany, Japan, Poland, àti United States. Ìròyìn kan tí ó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Czechia sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn olùpa ìwà títọ́ mọ́ olùjọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run láti àwọn ilẹ̀ míràn ru wá sókè gan-an. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn àyànṣaṣojú láti Japan jẹ́ aṣáájú ọ̀nà, aṣọ mímọ́ tónítóní àti ìwàlétòlétò wọn ṣe ìhà ibi tí wọ́n jókòó ní pápá ìṣeré náà lọ́ṣọ̀ọ́ lọ́nà híhàn gbangba. A tún ṣàkíyèsí ìwà ọ̀yàyà àwọn àyànṣaṣojú láti Poland, ẹ̀mí ìmoore àwọn ará láti Slovakia, ìwà ọ̀làwọ́ àwọn ará Germany, àti ìṣíkànpayá tí àwọn ará America ní. Gbogbo rẹ̀ jẹ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n fún wa.”
Báwo ni àwọn àpéjọpọ̀ náà ṣe nípa lórí àwọn ẹni tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀? Ẹni ọdún 85 kan, tí ó jẹ́ ọ̀mọ̀wé, òǹkọ̀wé, tí ó sì jẹ́ onímọ̀ èdè, wá sí àpéjọpọ̀ náà, láìka pé ó ní àrùn àtọ̀gbẹ àti àrùn kan ní ẹsẹ̀ sí. Ó ti ń lo ìwé Ìmọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún nǹkan bí oṣù mẹ́fà. Nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ń lọ lọ́wọ́, kò darí àfiyèsí sí ìhà ti ìmọ̀ èdè àti gírámà inú àwọn ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ sórí ohun mìíràn. Ó lahùn pé: “Ó kàmàmà! Ìfẹ́ àti ìgbatẹnirò tí ẹ ní láàárín ara yín ń sọ púpọ̀ ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ.”—Jòhánù 13:34, 35; Kọ́ríńtì Kíní 13:1-8.
Àwọn àlejò láti ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n wá sí Prague gbádùn àkókò tí wọ́n lò láti ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi àfipìtàn àti wíwàásù láìjẹ́ bí àṣà ní gbogbo àkókò. Nínú ilé gogoro kan ní gúúsù Prague, Ẹlẹ́rìí kan tí ó wá láti America, tí ó jẹ́ ìyàwó amòfin kan, dúró lókè ilé gogoro náà láti pín àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú lédè Czech fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gùnkè. Àwọn mìíràn pín àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú nígbà tí wọ́n pàdé àwùjọ àwọn ọmọdébìnrin akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n wá bẹ itẹ́ ògbólógbòó ti àwọn Júù náà wò. Dájúdájú, gbogbo àwọn amọṣẹ́dunjú afinimọlẹ̀ àti àwọn awakọ̀ bọ́ọ̀sì sì gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́.—Pétérù Kíní 3:15.
Afinimọlẹ̀ kan tí ó fi ìmoore hàn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí àti ìwà wọn kọ̀wé pé: “N kò tí ì pàdé àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́, tí wọ́n sì lọ́yàyà ọkàn púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí, láyé mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kátólíìkì ni mí, ìṣarasíhùwà yín nípa tẹ̀mí fà mí mọ́ra. Gbogbo yín fún mi ní ìrètí díẹ̀ pé ọjọ́ ọ̀la kan ṣì wà fún aráyé. Ẹ jẹ́ kí n dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún inú rere yín. Kí Ọlọ́run bù kún yín!”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òjò ńlá rọ̀ ní ọjọ́ Friday ní Prague, àwọn ìdílé jókòó ní gbangba pápá ìṣeré náà, tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tí wọ́n jẹ́ ará àdúgbò àti àwọn ti ilẹ̀ òkèèrè ń gbé jáde. Àwọn ọmọ ọwọ́ pọ̀ níbẹ̀ débi pé láti lè yẹra fún ìjàǹbá ní àwọn ọ̀nà àárín ìjókòó, a ṣètò àkànṣe ibi tí a lè gbé kẹ̀kẹ́ ọmọdé sí lóde pápá ìṣeré náà.
Àwọn tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ ti Prague náà lé ní 22,000, a sì ṣèrìbọmi fún Àwọn Ẹlẹ́rìí 432 tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèyàsímímọ́, àwọn méjì kan tí wọ́n wà lórí àga arọ àti àwọn márùn-ún mìíràn tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara sì wà lára wọn.
Àwọn Adití “Gbọ́rọ̀” ní Budapest
Ìlú ńlá ẹlẹ́wà náà, Budapest, tí ó wá jẹ́ ìlú ńlá tí ó gbàlejò àpéjọpọ̀ àgbáyé ní July, wà lórí Odò Danube náà. Iye gíga jù lọ àwọn tó wá síbẹ̀ jẹ́ 23,893, tí àwọn 3,341 àyànṣaṣojú láti orílẹ̀-èdè 11 ní àfikún sí Hungary wà lára wọn.
Nínú àgọ́ kan tí ó wà nítòsí pèpéle, wọ́n ṣe ògbufọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí a sọ fún àwọn adití, tí iye wọn tó 100. Nínú ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀ sí àwọn àyànṣaṣojú ní lílo àwọn èdè míràn tí ó yàtọ̀ sí èdè Hungary, a kí àwọn adití káàbọ̀ ní pàtàkì, pé: “Èdè kan tí a kò ní fẹ́ láti gbàgbé láti mẹ́nu kàn, tí a óò ṣe ògbufọ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí a óò sọ sí ni èdè adití. Inú wa dùn láti ní àwọn adití láàárín wa.”
Ṣíṣàjọpín Òtítọ́ Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn
Ní àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí, a mú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun jáde, ọ̀kan lára wọn ni, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Lẹ́yìn gbígba ìtẹ̀jáde yìí, àwọn àyànṣaṣojú kan láti ilẹ̀ Faransé wọ bọ́ọ̀sì kan láti darí sí hòtẹ́ẹ̀lì wọn. Nígbà tí wọ́n ń lọ, wọ́n rí tọkọtaya àṣẹ̀ṣẹ̀gbé kan pẹ̀lú àwọn tí wọ́n pè síbi ìgbéyàwó wọn. Àwọn ará ní kí awakọ̀ náà dúró. Ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí náà sọ̀ kalẹ̀, ó sì fún tọkọtaya náà ní ẹ̀dà kan tí ó jẹ́ èdè Hungary lára ìwé tuntun náà. Wọ́n fi ìmoore gbà á, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí ìwé náà wò lọ́gán. Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dà àkọ́kọ́ tí a fi sóde lẹ́yìn tí ìwé náà jáde!
Láti Kátólíìkì sí Kọ́múníìsì sí Ẹlẹ́rìí
Àwọn 510 tí wọ́n ṣèrìbọmi ní àpéjọpọ̀ yí dúró fún iye tí ó lé ní ìpín 2 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n wà níbẹ̀. Mẹ́ta lára Àwọn Ẹlẹ́rìí tuntun yìí ṣì wà lẹ́wọ̀n, wọ́n ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí àwọn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n ti hù kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì. Àwọn ará ládùúgbò máa ń bẹ̀ wọ́n wò déédéé, wọ́n sì máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn mìíràn. Ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ní Budapest, nǹkan bí 50 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni a ń bá àwọn ẹlẹ́wọ̀n ṣe.
Ọkùnrin kan, tí a tọ́ dàgbà ní ilé ẹ̀kọ́ Kátólíìkì ti Benedict, kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì mọ́, nígbà tí ó sì pé ẹni 20 ọdún, ó di mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì. Níkẹyìn, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ológun, ó sì ròkè dé ipò lẹ́fútẹ́náǹtì. Gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà Àwọn Òṣìṣẹ́ Ẹgbẹ́ Ológun, ó jẹ́ olùkọ́ àbá èrò orí àti ìṣe Kọ́múníìsì ti Lenin òun Marx ní yunifásítì. Ọ̀rọ̀ ìwúrí ti Kọ́múníìsì náà, “òmìnira, ẹ̀mí ará, èròǹgbà àparò kan kò ga ju ọ̀kan lọ,” ló ru ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ sókè. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ṣíṣì tí àwọn aláṣẹ ń ṣi ọ̀rọ̀ apàfiyèsí náà, “ìjọba tiwa-n-tiwa,” lò, mú kí ó tún inú rò nípa ètò ìjọba Kọ́múníìsì. Ó ronú pé ohun kan kò sí níbẹ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó fẹ̀yìn tì. Nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ilẹ̀kùn rẹ̀, ó ṣe tán láti tẹ́tí sílẹ̀. Ó ròyìn pé: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ ṣèbẹ̀wò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó wá dá mi lójú pé ẹ̀mí arákùnrin tòótọ́ wà níhìn-ín. Ìfẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ wà yí mi ká. Ìyípadà mi láti Kọ́múníìsì di Ẹlẹ́rìí gba ọdún mẹ́rin gbáko. Àmọ́, mo ti yan òtítọ́ ná.” Ó ṣèrìbọmi ní àpéjọpọ̀ náà.
Ní ti àwọn ọlọ́pàá, ṣíṣiṣẹ́ ní ibi àpéjọpọ̀ kan sábà máa ń jẹ́ yíyí ọwọ́ pa dà lọ́nà híhàn kedere. Ọlọ́pàá kan tí wọ́n yan láti ṣiṣẹ́ ní ibi àbáwọnú pápá ìṣeré náà sọ pé, ṣíṣiṣẹ́ níbi àpéjọpọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí ṣòro gan-an. Èé ṣe? Nítorí pé gbogbo nǹkan ní ń lọ geere débi pé ó ṣòro fún àwọn ọlọ́pàá láti má sùn!
Ìròyìn Àwọn Agbéròyìnjáde ní Poland Fọre
Àpéjọpọ̀ àgbáyé méjì ní a ṣe ní Poland, tí àwọn tí iye wọ́n lé ní 20,000 sì wà níbẹ̀ ní Warsaw, ìlú ńlá tí ó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ náà, iye àwọn ti Lodz, ìlú ńlá tí ó tóbi jù lọ ṣìkejì ní Poland, sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 12,000.
Ìwé agbéròyìnjáde tí ó gbawájú jù lọ ní Warsaw, Życie Warszawy, gbé ìròyìn tí ó tẹ̀ lé e yìí: “Carey Barber, mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ pé: ‘Ìròyìn rere wà tí a óò pòkìkí rẹ̀! Ìròyìn àlàáfíà ni, ojúlówó àlàáfíà. Ìfẹ́ wa fún Jèhófà àti fún àwọn aládùúgbò wa ń sún wa láti máa bá a lọ láti wàásù láìsí ìdáwọ́dúró títí Ọlọ́run yóò fi wí pé a ti ṣe iṣẹ́ náà tán.’”
Ẹnì kan tí ń kọ̀wé fún ìwé agbéròyìnjáde Sztandar Młodych sọ pé: “Fún ọjọ́ méjì, nǹkan bí 12,000 lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kóra jọ ní àpéjọpọ̀ ìjọsìn kan ní Pápá Ìṣeré Legia, ní Warsaw. Ibẹ̀ wà létòlétò lọ́nà tí ó ṣeé wò fi ṣàpẹẹrẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo fara balẹ̀ wò yíká, n kò rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ àwọn ọlọ́pàá tàbí àwọn òṣìṣẹ́ ológun tí ń bójú tó àyíká.
“Gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti rò, gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè Poland ló fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ Kátólíìkì tán. Àmọ́, nígbà tí àwọn èwe Kátólíìkì wa bá pé jọ ní pápá ìṣeré kan náà, agbo àwọn ọlọ́pàá púpọ̀ sábà máa ń wà níbẹ̀, ní ìmúratán láti ṣiṣẹ́.
“Dájúdájú, ó jẹ́ ohun tí ń dáni níjì pé àwọn tí wọ́n kọ ìsìn Kátólíìkì sílẹ̀, àwọn oníyapa, tàbí ohun yòó wù kí o pè wọ́n [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] lè pé jọ ní iye púpọ̀ jọjọ, láìṣe ìjàǹbá kankan fún ìwàlétòlétò àti ààbò ará ìlú, nígbà tí ó jẹ́ pé bí àwọn èwe Kátólíìkì tiwa bá kóra jọ nínú àwùjọ, wọ́n máa ń jẹ́ eléwu, ààbò àwọn ọlọ́pàá lòdì sí ìwà jàgídíjàgan tí àìdàgbàdénú ń sún wọn hù sì pọn dandan. Ohun púpọ̀ wà láti ronú lé lórí.”
Ìrìbọmi àwọn ẹni tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ṣẹlẹ̀ níhìn-ín pẹ̀lú, tí 462 ènìyàn sì ṣèrìbọmi ní Warsaw, àwọn 278 sì ṣe ní Lodz. Ọ̀kan lára wọn ni Sylwia, ọmọ ọdún 19, tí ó ní ẹ̀tanú sí Àwọn Ẹlẹ́rìí. Ní ọjọ́ kan tí òjò ń rọ̀ gan-an, Ẹlẹ́rìí kan tọ̀ ọ́ lọ lójú pópó. “Mo rọ́nà ṣeé láti mú kí ó máa lọ, mo sì bá tèmi lọ. Àmọ́, mo fi agboòrùn mi bo ọmọdébìnrin kan tí òjò ń pa. Òun pẹ̀lú jẹ́ Ẹlẹ́rìí! Ó ní òun yóò mú ìwé náà, Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, wá fún mi. Láti lè fi ìwà ọmọlúwàbí hàn, mo fún un ní àdírẹ́sì mi, . . . mo sì ṣèrìbọmi lónìí!”
Estonia Kóńkó Rí Ìjẹ́rìí Ńlá Gbà
Estonia, Latvia, àti Lithuania ni ó para pọ̀ jẹ́ àwọn Orílẹ̀-Èdè Baltic. Iye àwọn ènìyàn Estonia jẹ́ nǹkan bí 1.5 mílíọ̀nù péré, ìlú ńlá tí ó sì jẹ́ olú ìlú rẹ̀ ní nǹkan bí 450,000 olùgbé. A ṣe àwọn àpéjọpọ̀ méjì níbẹ̀ ní August 1996.
Ipa tí àwọn àpéjọpọ̀ ńláńlá wọ̀nyí ní pọ̀ débi tí ìwé agbéròyìnjáde kan fi sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí a ti lè rí i, a fi ìjọsìn Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kún Tallinn. Àpéjọpọ̀ wọn tí wọ́n ṣe ní Linnahall ni a sọ pé àwọn tí wọ́n wá síbẹ̀ tí ì pọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n ti ń wá sí Estonia fún ìjọsìn.” Àwọn Ẹlẹ́rìí gba gbogbo hòtẹ́ẹ̀lì ibẹ̀.
Arákùnrin Carey Barber sọ ìròyìn kan lẹ́yìn náà nínú èyí tí ó ti wí pé: “Kò yani lẹ́nu pé àwọn ará láti Finland àti àwọn mìíràn tí a yàn sí Estonia fẹ́ràn wíwà ní orílẹ̀-èdè yẹn. Àwọn orílẹ̀-èdè ńláńlá ti jẹ gàba lé orílẹ̀-èdè kékeré tí ó sì lẹ́wà yí lórí, wọ́n ti ni ín lára, ó sì ti forí ti ọ̀pọ̀ ìjìyà. Nísinsìnyí, àwọn ará Estonia . . . ń fojú sọ́nà gan-an fún níní ọjọ́ ọ̀la alálàáfíà àti aláàbò pípẹ́ títí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” Ó lé ní 3,100 Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń ṣiṣẹ́ ní Estonia, tí ìdajì lára wọn ń sọ èdè Rọ́ṣíà.
Àpéjọpọ̀ náà jẹ́ fún àwọn ará Estonia, àwọn ará Estonia àti ti Latvia tí ń sọ èdè Rọ́ṣíà, àwọn ará Lithuania, àti àwọn àyànṣaṣojú tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè 15, tí àwọn 155 láti Britain àti àwọn 300 láti Finland wà lára wọn.
Àwọn Adití Tún “Gbọ́rọ̀” ní Estonia
Ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, alàgbà kan tí ó jẹ́ adití láti Finland lọ sí Tallinn, Estonia, láti lọ wo ohun tí òun lè ṣe fún àwọn adití níbẹ̀. Kò mọ adití kankan níbẹ̀, nítorí náà, ó lọ sí ilé tí àwọn adití ti ń ṣèpàdé ní Tallinn, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn lọ́wọ́. Àwọn adití ará Estonia gbà á tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì yán hànhàn láti rí ohun tí ó mú wá. Ó fi gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó ní lọ́wọ́ síta nígbà ìbẹ̀wò rẹ̀ àkọ́kọ́, ó sì kọ orúkọ àti àdírẹ́sì àwọn olùfìfẹ́hàn sílẹ̀, gbogbo orúkọ tí ó gbà jẹ́ 70.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ni wọ́n fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, arákùnrin náà sì rí i pé òun kò lè dá ṣe gbogbo ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tán. Nítorí náà, ó ní láti ṣàṣàyàn àwọn tí wọ́n fìfẹ́ hàn jù lọ. Láìpẹ́ lẹ́yìn ìbẹ̀wò rẹ̀ àkọ́kọ́ sí Estonia, ó ti ní 30 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí àwọn 40 sì ń dúró láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́! Àwọn mẹ́rin sì ti wà nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ògbufọ̀ èdè àwọn adití ní Tallinn.
“Ìṣẹ̀lẹ̀ Yíyàtọ̀ Nínú Àkọsílẹ̀ Gbígbádùnmọ́ni Inú Májẹ̀mú Tuntun”
Ẹlẹ́rìí kan tí ń ṣiṣẹ́ ní ibùdókọ̀ akérò gba ojú omi ń kí àwọn àyànṣaṣojú tí wọ́n wá sí àpéjọpọ̀ náà. Ó tọ ará Estonia kan tí ń mú àwọn arìnrìn-àjò mọlẹ̀ lọ, ó sì béèrè ohun tí ó rò nípa àpéjọpọ̀ gígọntiọ yìí lọ́wọ́ rẹ̀. Afinimọlẹ̀ wí fún un pé òun ti mú àwùjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan láti onírúurú ilẹ̀ Europe mọlẹ̀, òún sì ti ṣàkíyèsí pé Àwọn Ẹlẹ́rìí sábà máa ń hùwà dáadáa, wọ́n sì jẹ́ ènìyàn rere. Wọ́n ti ké sí i láti wá wo ọ́fíìsì Watch Tower Society tí ó wà ní Òpópónà Puhangu, ó sì yà á lẹ́nu láti rí ìwàlétòlétò dáradára àti àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn onínúure, tí wọ́n sì jẹ́ aláyọ̀ níbẹ̀. Kò lóye ìdí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ń kojú àtakò rírorò àti ìfẹ̀sùn-èké-kanni nígbà tí òkodoro òtítọ́ fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ẹ̀sùn náà kì í ṣe òtítọ́. Ó wí pé: “Nínú èrò inú mi, ńṣe ni iṣẹ́ yín, iṣẹ́ ìsìn yín, dà bí ìṣẹ̀lẹ̀ yíyàtọ̀ nínú àkọsílẹ̀ gbígbádùnmọ́ni inú Májẹ̀mú Tuntun.”
Dájúdájú, gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fojú sọ́nà láti fìdí ìfùsí rere múlẹ̀ jákèjádò ayé nítorí ìwà ọlọ́wọ̀ wọn àti inúrere wọn sí àwọn àlejò. (Pétérù Kíní 3:16) Àwọn àpéjọpọ̀ tí a ṣe ní Ìlà Oòrùn Europe wọ̀nyí fi hàn pé láìka ìfọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ àti ìkọ̀wé-èké-banijẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn onísìn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àti àwọn apẹ̀yìndà sí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rí ìbùkún Ọlọ́run gbà bí wọ́n ti ń pòkìkí ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà tí ayé wa tí ogun ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí ó kún fún ìkórìíra, nílò gidigidi.—Aísáyà 2:2-4; Máàkù 13:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni lórí àwọn àpéjọpọ̀ ní Romania, wo àpilẹ̀kọ náà, “A Ṣe Àwọn Àpéjọpọ̀ Romania Láìka Àtakò Sí,” nínú Jí!, February 22, 1997. Fún ìsọfúnni lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a gbé sáfẹ́fẹ́, wo àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run Péjọ,” nínú Ilé Ìṣọ́, January 15, 1997.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Láìka òjò tí ń rọ̀ sí, àwọn ìdílé fiyè sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà gan-an
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn Ẹlẹ́rìí aláyọ̀ ará Poland mú ìtẹ̀jáde wọn tuntun lọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn Ẹlẹ́rìí onídùnnú ará Estonia wọ aṣọ ìbílẹ̀