TAPANI VIITALA | ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Bí Ọwọ́ Mi Ṣe Tẹ Ohun Tó Wù Mí
Nígbà tí mo kọ́kọ́ pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n fi hàn mí nínú Bíbélì pé ‘etí àwọn adití máa ṣí.’ (Àìsáyà 35:5) Àmọ́, torí pé adití ni mí látìgbà tí wọ́n ti bí mi, mi ò rò ó rí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí adití lè gbọ́rọ̀. Ìyẹn sì mú kó ṣòro fún mi láti gba ohun tí wọ́n kà yẹn gbọ́. Àmọ́, inú mi dùn gan-an nígbà tí wọ́n fi hàn mi nínú Bíbélì bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ, ogun, àìsàn àti ikú. Ó wá ń ṣe mí bíi pé ki ń tètè lọ sọ ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì fáwọn adití bíi tèmi.
Ìlú Virrat lórílẹ̀-èdè Finland ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1941. Àwọn òbí mi, àwọn àbúrò mi méjèèjì àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa míì ló jẹ́ adití. Èdè àwọn adití la sì fi máa ń bára wa sọ̀rọ̀.
Mo Kọ́ Àwọn Nǹkan Tó Yà Mí Lẹ́nu Nínú Bíbélì
Ilé ìwé tí mo lọ ni mò ń gbé, wọn ò sì gbà ká sọ èdè àwọn adití níbẹ̀, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì o lé ogójì (240) kìlómítà ló sì fi jìnnà sílé wa. Nígbà yẹn lórílẹ̀-èdè Finland, ilé ìwé àwọn adití ò gbà ká máa fi èdè àwọn adití sọ̀rọ̀. Torí náà, ó pọn dandan káwa akẹ́kọ̀ọ́ kọ́ bá a ṣe lè máa fẹnu sọ̀rọ̀, ká sì máa wo ẹnu àwọn míì bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ ká lè mọ ohun tí wọ́n ń sọ. Kódà, ó le débi pé tí àwọn tíṣà wa bá rí i pé à ń fi ọwọ́ bá ara wa sọ̀rọ̀, ṣe ni wọ́n máa gbá igi mọ́ wa lọ́wọ́ tí ọwọ́ náà sì máa wú fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.
Àwọn òbí mi ní oko, ó sì wu èmi náà kí n kọ́ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀. Torí náà, lẹ́yìn tí mo parí ilé ẹ̀kọ́ girama, mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ṣẹ́ àgbẹ̀. Lẹ́yìn tí mo pa dà sílé, mo rí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lórí tábìlì. Bàbá mi wá sọ fún mi pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó yani lẹ́nu látinú Bíbélì ló wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà àti pé àwọn tọkọtaya kan tí kì í ṣe adití ti ń kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí wọ́n lè bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀, ṣe ni wọ́n máa ń kọ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ sínú ìwé.
Bàbá mi sọ pé ayé máa di Párádísè lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, àti pé àwọn òkú máa jíǹde. Àmọ́ ohun tí mo máa ń gbọ́ ni pé ọ̀run ni ẹni tó kú ń lọ. Torí náà, mo rò pé ohun táwọn Ẹlẹ́rìí náà sọ ò yé bàbá mi dáadáa torí kì í ṣe èdè àwọn adití ni wọ́n fi bá wọn sọ̀rọ̀.
Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí yẹn pa dà wá, mo bi wọ́n nípa ohun tí bàbá mi sọ fún mi. Wọ́n ní “bọ́rọ̀ ṣe rí ni bàbá ẹ̀ sọ yẹn.” Wọ́n wá fi ohun tí Jésù sọ nínú Jòhánù 5:28, 29 hàn mí. Wọ́n sọ pé Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà burúkú àti pé àwọn èèyàn máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì ní ìlera pípé àti àlàáfíà.—Sáàmù 37:10, 11; Dáníẹ́lì 2:44; Ìfihàn 21:1-4.
Torí pé mo fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Antero, tí kì í ṣe adití. Ṣe ni mo máa ń kọ ìdáhùn mi sínú ìwé torí pé kò gbọ́ èdè àwọn adití, Antero á wá kà á, á sì tún kọ àwọn àfikún ìbéèrè àti àlàyé míì tó bá ni. Bí Antero ṣe máa ń fi sùúrù kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ fún wákàtí méjì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nìyẹn.
Mo lọ sí àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1960. Ní àpéjọ yẹn, wọ́n tú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí èdè àwọn adití. Ní ọ̀sán Friday, wọ́n ṣe ìfilọ̀ pé ìrìbọmi máa wà láàárọ̀ ọjọ́ kejì. Torí náà, láàárọ̀ Sátidé, mo mú aṣọ tí màá fi ṣèrìbọmi àti tówẹ̀lì dání, bí mo ṣe ṣèrìbọmi nìyẹn o!a Kò pẹ́ sígbà yẹn, àwọn òbí mi àtàwọn àbúrò mi náà ṣèrìbọmi.
Gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé mi ló ṣèrìbọmi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn
Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Kọ́ Àwọn Míì Lẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
Ó wù mí gan-an kí ń máa kọ́ àwọn adití láwọn ohun tí mo kọ́ látinú Bíbélì, ọ̀nà tó dáa tí mo sì lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni kí ń lo èdè àwọn adití. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìtara wàásù fáwọn adití tó wà nílùú mi.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni mo kó lọ sí ìlú Tampere tó jẹ́ ìlú ńlá tó láwọn ilé iṣẹ́ tó pọ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn adití, mo sì ń béèrè láti ilé dé ilé bóyá wọ́n mọ àwọn adití kankan ládùúgbò. Ohun tí mo ṣe yìí ló jẹ́ kí n láwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láàárín ọdún díẹ̀, a sì ti ní àwọn akéde tó jẹ́ adití tó ju mẹ́wàá lọ ní ìlú Tampere.
Lọ́dún 1965, mo pà dé arábìnrin arẹwà kan tó ń jẹ́ Maire, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Kò pẹ́ rárá tí Maire fi mọ èdè àwọn adití. Jálẹ̀ àádọ́ta ọdún tá a jọ lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló fi tì mí lẹ́yìn, olóòótọ́ ni, ó sì máa ń ṣiṣẹ́ kara.
Ọjọ́ ìgbéyàwó wa lọ́dún 1966
Lẹ́yìn ọdún méjì tá a ṣègbéyàwó la bí ọmọ wa ọkùnrin tó ń jẹ́ Marko, àmọ́ òun kì í ṣe adití. Ó kọ́ èdè Finnish tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ wa, ó sì tún mọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Finnish. Nígbà tí Marko pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13), ó ṣèrìbọmi.
Nígbà tó yá, àwọn ẹni tuntun bẹ̀rẹ̀ sí i wá sí ìpàdé àwùjọ tó ń sọ èdè àwọn adití ní ìlú Tampere. Torí náà, a kó lọ sí ìlú Turku lọ́dún 1974, àmọ́ kò sí Ẹlẹ́rìí kankan tó jẹ́ adití níbẹ̀. Ìyẹn sì gba pé ká tún máa wá àwọn adití kiri láti ilé dé ilé. Àmọ́ inú mi dùn pé méjìlá (12) lára àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ṣèrìbọmi láwọn ọdún tá a lò níbẹ̀.
A Ṣiṣẹ́ Láwọn Ìpínlẹ̀ Baltic
Wọ́n pe Marko sí Bẹ́tẹ́lì lọ́dún 1987. Àwùjọ tó ń sọ èdè adití nílùú Turku ti fìdí múlẹ̀ dáadáa nígbà yẹn, torí náà á bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò bá a ṣe máa kó lọ síbòmíì.
Láwọn ìgbà yẹn, a lómìnira láti wàásù lápá Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Ní January 1992, èmi àti arákùnrin adití kan jọ lọ sílùú Tallinn, lórílẹ̀-èdè Estonia.
A pàdé arábìnrin kan tí ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ọkùnrin jẹ́ adití. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin yẹn ò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, ó ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti rí àwọn adití tó jẹ́ ọmọ ìlú Estonia. Ní alẹ́ ọjọ́ tá a lò kẹ́yìn, ó mú wa lọ sí ìpàdé Ẹgbẹ́ Àwọn Adití ti Orílẹ̀-Èdè Estonia tí wọ́n ṣe ní ìlú Tallinn. A tètè dé sí ìpàdé yẹn, a sì kó àwọn ìwé wa tó wà ní èdè Estonia àti Rọ́ṣíà sórí tábìlì. Ìwé ńlá ọgọ́rùn-ún (100) àti ọgọ́rùn-ún méjì (200) ìwé ìròyìn la fún àwọn èèyàn lọ́jọ́ yẹn, àwọn àádọ́rin (70) ló sì fún wa ní àdírẹ́sì bí a ṣe lè kàn sí wọn. Alẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà ni iṣẹ́ ìwàásù bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu lédè àwọn adití lórílẹ̀-èdè Estonia!
A fẹ́ lọ wàásù ní ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ Baltic
Kò pẹ́ sígbà yẹn, èmi àti Maire bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí orílẹ̀-èdè Estonia déédéé láti máa wàásù. A dín iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa kù, a sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lọ́dún 1995, a kó lọ sí tòsí Helsinki, kó lè rọrùn fún wa láti máa wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Tallinn. Iṣẹ́ ìwàásù tá a ṣe ní Estonia sèso rere ju bí a ṣe rò lọ!
Ọ̀pọ̀ èèyàn là ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kódà mẹ́rìndínlógún (16) nínú wọn ló ṣèrìbọmi. Tẹ̀gbọ́ntàbúrò kan wà nínú wọn tó jẹ́ adití tí wọn ò sì tún ríran. Ṣe ni mo máa ń fọwọ́ ṣàpèjúwe sọ́wọ́ wọn tí mo bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, kò rọrùn láti kọ́ àwọn adití lẹ́kọ̀ọ́, ìdí sì ni pé kò sí fídíò àwọn ìwé wa lédè àwọn adití. Torí náà, ṣe ni mo kó àwọn àwòrán tó ń fani mọ́ra tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa jọ sínú ìwé kan, òun ni mo sì máa ń lò.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Finland ní kí ń lọ sórílẹ̀-èdè Latvia àti Lithuania ká lè wo bá a ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó wà níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àwọn adití láwọn ìpínlẹ̀ Baltic. Léraléra la lọ sáwọn orílẹ̀-èdè yìí, a sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará tó wà níbẹ̀ ká lè wá àwọn adití. Ó fẹ́ẹ̀ jẹ́ pé gbogbo orílẹ̀-èdè ló ní bí wọ́n ṣe ń sọ èdè àwọn adití. Torí náà, mo kọ́ èdè àwọn adití lọ́nà ti Estonia, Latvia àti Lithuania. Yàtọ̀ síyẹn mo tún kọ́ èdè àwọn adití kan táwọn tó wá láti Rọ́ṣíà tó ń gbé ní Baltics ń sọ.
Ó bani nínú jẹ́ pé lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ tá a ti fi ń ṣiṣẹ́ yìí ní Estonia àtàwọn ìpínlẹ̀ Baltic, àyẹ̀wò fi hàn pé Maire ìyàwó mi ní àìsàn Parkinson tó máa ń mú kí ọwọ́ àtẹsẹ̀ gbọ̀n, bó ṣe di pé a ò lè tẹ̀ síwájú mọ́ nìyẹn.
Bí Wọ́n Ṣe Ṣètò Láti Ran Àwọn Adití Lọ́wọ́
Lọ́dún 1997, ètò Ọlọ́run ṣètò àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè kan sí Ẹ̀ka ọ́fíìsì Finland tá á máa túmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè àwọn adití. Torí pé ibi tá à ń gbé ò jìnnà sí Bẹ́tẹ́lì, èmi àtìyàwó mi máa lọ ń ran àwọn atúmọ̀ èdè yìí lọ́wọ́. Títí di báyìí mo ṣì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Inú wa dùn pé a bá Marko ọmọ wa àti Kirsi ìyàwó ẹ̀ ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tó yá, ètò Ọlọ́run ní kí Marko lọ máa dá àwùjọ àwọn àtúmọ̀ èdè lẹ́kọ̀ọ́ láwọn orílẹ̀-èdè míì.
À ń ṣèrànwọ́ láti ṣe àwọn fídíò ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Finnish
Láfikún síyẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì tún ṣètò láti da àwọn ará wa tó lè sọ̀rọ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè kọ́ èdè àwọn adití. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí, torí ó ti ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn ará wa láti máa wá sí àwọn ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití. Wọ́n ń kópa tó jọjú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì ń bójú tó ìjọ Ọlọ́run.
Ó Ṣì Ń Wù Mí Gan-an Láti Ran Àwọn Adití Lọ́wọ́
Ní 2004, èmi àti Maire ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ àkọ́kọ́ tó ń sọ èdè àwọn adití lọ́nà ti Finnish sílẹ̀ nílùú Helsinki. Nígbà tó fi máa pé ọdún mẹ́ta, ìjọ náà ti fìdí múlẹ̀, àwọn tó wà níbẹ̀ sì nítara. Kódà, wọ́n ní ọ̀pọ̀ aṣáájú-ọ̀nà.
Bá a ṣe máa ń ṣe, a bẹ̀rẹ̀ sí í ronú láti lọ síbi tí àìní wà. Torí náà, nígbà tó di ọdún 2008 a kó lọ sí tòsí ìlú Tampere tá a ti kúrò lọ́dún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34) sẹ́yìn, a sì ń lọ sí àwùjọ tó ń sọ èdè àwọn adití tó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn ọdún kan péré, àwùjọ yẹn di ìjọ kejì tó ń sọ èdè àwọn adití lorílẹ̀-èdè Finland.
Ní gbogbo ìgbà yẹn, ṣe ni ìlera ìyàwó mi ń burú sí í. Inú mi sì dùn pé mo ṣe gbogbo ohun ti mo le ṣe láti tọ́jú ẹ̀ títí tó fi kú lọ́dún 2016. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo àárò ìyàwó mi ọ̀wọ́n ṣì máa ń sọ mi gan-an, mò ń fojú sọ́nà láti rí i nínú ayé tuntun níbi tí kò ti ní sí àìsàn mọ́.—Àìsáyà 33:24; Ìfihàn 21:4.
Inú mi dùn gan-an pé ohun tó nítumọ̀ ni mo fi ìgbésí ayé mi ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó ọgọ́ta (60) ọdún tí mo ti ń sọ ìhìn rere fáwọn aládùúgbò mi tó jẹ́ adití, iṣẹ́ náà ò sú mi, mi ò sì ní dáwọ́ dúró.
a Èyí jẹ́ ìgbà tí wọn ò tíì ṣètò pé káwọn alàgbà nínú ìjọ máa kọ́kọ́ rí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi.