‘Èdè Wọn Ò Pa Pọ̀ àmọ́ Ìfẹ́ So Wọ́n Pọ̀’
Ìdáǹdè. Òmìnira. Ìgbàlà. Láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn làwọn èèyàn ti ń wá báwọn ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ìnira àti ìbànújẹ́. Báwo la ṣe lè fara da àwọn ìṣòro ìgbésí ayé? Ǹjẹ́ ìdáǹdè máa dé láé? Tó bá máa dé, ọ̀nà wo ló máa gbà dé?
OHUN táwọn ìpàdé àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò rẹ̀ tó sì bẹ̀rẹ̀ lóṣù May, ọdún 2006 dá lé lórí nìyẹn. Àkòrí rẹ̀ ni “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!”
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè ló wá sí mẹ́sàn-án lára àwọn ìpàdé àgbègbè yìí. Oṣù July àti August ọdún 2006 ni wọ́n ṣe àwọn ìpàdé àgbègbè náà ní ìlú Prague, tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Czech Republic; ní Bratislava, tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Slovakia; ní Chorzow àti Poznan, nílẹ̀ Poland;a àti láwọn ìlú márùn-ún ní orílẹ̀-èdè Jámánì. Àwọn ìlú náà ni: Dortmund, Frankfurt, Hamburg, Leipzig, àti Munich. Àpapọ̀ àwọn tó wá sáwọn ìpàdé àgbègbè wọ̀nyí ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́tàlá [313,000] lọ.
Báwo ni nǹkan ṣe rí láwọn ìpàdé àgbègbè wọ̀nyí? Kí làwọn oníròyìn sọ nípa wọn? Báwo ni ìpàdé àgbègbè náà sì ṣe rí lára àwọn tó wá síbẹ̀?
Ìmúrasílẹ̀
Ara àwọn àlejò tó ń dé àtàwọn Ẹlẹ́rìí tó wà láwọn ìlú tá a ti ṣe ìpàdé náà ti wà lọ́nà, nítorí wọ́n mọ̀ pé mánigbàgbé ni àpéjọ tẹ̀mí náà yóò jẹ́. Iṣẹ́ ńlá ló jẹ́ láti pèsè ibi tó bójú mu táwọn tó wá sípàdé náà máa dé sí. Bí àpẹẹrẹ, ní ìpàdé àgbègbè tí wọ́n ṣe ní Chorzow, àwọn Ẹlẹ́rìí nílẹ̀ Poland sọ pé àwọn á gba àwọn èèyàn bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàlá tó ń bọ̀ láti Ìlà Oòrùn Yúróòpù sílé àwọn. Àwọn orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn ti wá sípàdé àgbègbè yẹn nìwọ̀nyí: Amẹ́ríkà, Armenia, Belarus, Estonia, Georgia, Kazakhstan, Kyrgyzstan, Latvia, Lithuania, Moldova, Rọ́ṣíà, Tajikistan, Turkmenistan, Ukraine, àti Uzbekistan.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń bọ̀ nípàdé yìí ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ láti ọ̀pọ̀ oṣù ṣáájú àkókò yẹn. Tatiana, tó jẹ́ ajíhìnrere tó máa ń fi àkókò púpọ̀ wàásù nílùú Kamchatka, ìyẹn ìlú kan tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí po nílẹ̀ Rọ́ṣíà, ti bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú owó tó máa fi rìnrìn àjò yìí láti nǹkan bí ọdún kan ṣáájú ìgbà yẹn. Ó ní láti rìnrìn àjò ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ààbọ̀ kìlómítà. Ó kọ́kọ́ wọ ọkọ̀ òfuurufú fún wákàtí márùn-ún, ó tún wà nínú ọkọ̀ ojú irin fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọjọ́ mẹ́ta, níkẹyìn ó wá wọ bọ́ọ̀sì fún ọgbọ̀n wákàtí láti dé ìlú Chorzow.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló yọ̀ǹda ara wọn fún àwọn iṣẹ́ tó yẹ ní ṣíṣe ṣáájú ìpàdé àgbègbè náà, wọ́n mú káwọn pápá ìṣeré náà àti àyíká wọn di ibi tó bójú mu fún ìjọsìn. (Diutarónómì 23:14) Àpẹẹrẹ kan ni ti ìlú Leipzig, níbi táwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ti ṣe iṣẹ́ ribiribi láti gbá pápá ìṣeré náà mọ́ tónítóní, tí wọ́n sì ṣèlérí pé àwọn á tún ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí ìpàdé àgbègbè náà bá parí. Nítorí èyí, àwọn aláṣẹ pápá ìṣeré náà fagi lé owó gọbọi táwọn ará ì bá san lórí iṣẹ́ ìmọ́tótó.
Ìwé Ìkésíni
Gbogbo ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ló polongo Ìpàdé Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” Tayọ̀tayọ̀ làwọn tó fẹ́ lọ sáwọn tó jẹ́ àkànṣe lára àwọn ìpàdé àgbègbè náà fi pín ìwé ìkésíni fáwọn èèyàn. Wọ́n polongo ìpàdé àgbègbè yìí fáwọn èèyàn títí di alẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí ìpàdé náà bẹ̀rẹ̀. Ǹjẹ́ ìtara wọn yìí mú àbájáde rere kankan wá?
Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ará Poland, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bogdan rí bàbá àgbàlagbà kan tó fẹ́ wá sípàdé àgbègbè náà, àmọ́ tó sọ pé owó ìfẹ̀yìntì tí ò tó nǹkan tí wọ́n ń san fóun ó lè jẹ́ kóun rìnrìn àjò ọgọ́fà kìlómítà wá sílùú Chorzow. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé àyè ìjókòó kan máa ṣẹ́ kù nínú ọkọ̀ tí ìjọ tó wà ládùúgbò náà háyà. Arákùnrin Bogdan sọ pé: “A sọ fún bàbá náà pé ó lè bá wa lọ láìsan kọ́bọ̀ tó bá lè débi tá a ti máa gbéra ní aago márùn-ún ààbọ̀ àárọ̀.” Bàbá náà gbà, ó sì wá sípàdé àgbègbè ọ̀hún. Ó kọ̀wé sáwọn arákùnrin lẹ́yìn náà pé: “Lẹ́yìn wíwá tí mo wá sípàdé àgbègbè yìí, mo ti múra tán láti jẹ́ kí ìwà mi túbọ̀ dára sí i.”
Ní ìlú Prague, ọkùnrin kan tó wà ní ọ̀kan lára àwọn òtẹ́ẹ̀lì táwọn ará tó ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá sípàdé àgbègbè náà dé sí sọ fáwọn ará nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan pé òun náà lọ sípàdé àgbègbè náà lọ́jọ́ yẹn. Kí ló mú kí ọkùnrin yìí lọ sípàdé náà? Ọkùnrin náà sọ pé lẹ́yìn tóun ti gba ìwé ìkésíni lọ́wọ́ àwọn akéde mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láwọn ojú pópó ìlú náà, òun rí i pé ó di dandan fóun láti lọ! Inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì fẹ́ túbọ̀ mọ̀ sí i.—1 Tímótì 2:3, 4.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tẹ̀mí Tó Rọ̀ṣọ̀mù
Nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, wọ́n jíròrò béèyàn ṣe lè bójú tó onírúurú ìṣòro. Àwọn ìmọ̀ràn tààrà látinú Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ọ̀nà tá a lè gbà yanjú àwọn ìṣòro náà tàbí ọ̀nà tá a lè gbà fara dà wọ́n.
Àwọn tí ọjọ́ ogbó ń dà láàmú, àwọn tí àìsàn ń ṣe, àwọn tí èèyàn wọn kú, tàbí àwọn tó láwọn ìṣòro mìíràn rí ìṣírí tó máa mú wọn láyọ̀ gbà látinú Bíbélì. (Sáàmù 72:12-14) Àwọn tọkọtaya àtàwọn òbí gbọ́ ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀nà tí ìgbéyàwó wọn fi lè láyọ̀ àti bí wọ́n ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ wọn ní àtọ́yanjú. (Oníwàásù 4:12; Éfésù 5:22, 25; Kólósè 3:21) Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́, tí wọ́n máa ń wà láàárín àwọn ọmọléèwé tó ń ṣe ohun tí kò dáa, àmọ́ tí wọ́n máa ń gbọ́ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nílé àti nínú ìjọ rí ẹ̀kọ́ kọ́. Wọ́n rí ìmọ̀ràn tó wúlò gan-an gbà lórí bí wọ́n ṣe lè kojú ipa búburú táwọn ojúgbà wọn lè ní lórí wọn àti bí wọ́n ṣe lè “sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.”—2 Tímótì 2:22.
Ẹgbẹ́ Ará Tó Kárí Ayé Ni Wọ́n Lóòótọ́
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń rí ìtọ́sọ́nà tó dára gbà látinú Ìwé Mímọ́ láwọn àpéjọ wọn. (2 Tímótì 3:16) Àmọ́, ohun tó mú kí ìpàdé àgbègbè wọ̀nyí yàtọ̀ ni pé onírúurú orílẹ̀-èdè làwọn ará ti wá. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí kan náà ló wáyé ní gbogbo àkànṣe ìpàdé àgbègbè náà lónírúurú èdè. Ojoojúmọ́ làwọn tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀, bí wọ́n sì ṣe máa ń ròyìn bí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń lọ sí láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tún jẹ́ kí àpéjọpọ̀ náà túbọ̀ lárinrin sí i. Ńṣe ni wọ́n túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àti ìròyìn wọ̀nyí káwọn tó péjọ síbẹ̀ tí wọ́n ń sọ onírúurú èdè lè jàǹfààní.
Ara àwọn tó wá sípàdé náà ti wà lọ́nà láti rí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn tó wá láti orílẹ̀-èdè mìíràn. Ọ̀kan lára àwọn tó wá sọ pé: “Èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá à ń sọ kò fa ìṣòro kankan. Dípò ìyẹn, ńṣe ló fi kún ayọ̀ ìpàdé náà. Àṣà ìbílẹ̀ àwọn tó wá síbẹ̀ yàtọ̀ síra wọn, àmọ́ ẹ̀sìn kan náà so wọ́n pọ̀.” Ọ̀nà táwọn tó wá sípàdé àgbègbè ti ìlú Munich gbà sọ ọ́ ni pé: “Èdè wa ò pa pọ̀ àmọ́ ìfẹ́ so wá pọ̀.” Ìlú yòówù kí wọ́n ti wá, èdè yòówù kí wọ́n máa sọ, àwọn tó wá sípàdé náà rí i pé àárín àwọn tó jẹ́ ojúlówó ọ̀rẹ́ làwọ́n wà, ìyẹn àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn.—Sekaráyà 8:23.
Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìmọrírì
Bí ojú ọjọ́ ṣe rí nígbà tí ìpàdé àgbègbè náà ń lọ lọ́wọ́ nílẹ̀ Poland jẹ́ ká mọ irú ẹni táwọn tó wá síbẹ̀ jẹ́ àti bí wọ́n ṣe ní ìfaradà tó. Yàtọ̀ sí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìgbà tí wọ́n fi wà níbẹ̀ lòjò ń rọ̀, òtútù ibẹ̀ tún légbá kan. Arákùnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Mi ò tíì rí kí òjò rọ̀ tó báyìí nípàdé àgbègbè kankan rí, òtútù sì tún mú bí nǹkan míì. Ìwọ̀nba díẹ̀ ló sì yé mi nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ. Àmọ́, wíwá táwọn èèyàn wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè, ayọ̀ ìpàdé náà tó légbá kan, àti ìfẹ́ àlejò táwọn ará fi hàn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ kò jẹ́ ká mọ gbogbo ìyẹn lára. Mánigbàgbé ni ìpàdé àgbègbè yìí!”
Ohun tó jẹ́ mánigbàgbé fáwọn tó ń sọ èdè Polish tí wọ́n wà ní àpéjọpọ̀ náà ni ìkéde mímú tí wọ́n mú ìwé Insight on the Scriptures jáde lédè Polish. Èrè ńlá nìyẹn jẹ́ fún òtútù àti òjò tí wọ́n fara dà. Gbogbo ibi tá a ti ṣe Ìpàdé Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” làwọn ará ti láyọ̀ gan-an nígbà tí wọ́n gba ìwé tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, tá a pè ní Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn.
Àwọn nǹkan mìíràn sì tún ṣẹlẹ̀ tí kò ní jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ gbàgbé ìpàdé àgbègbè yẹn. Arábìnrin Kristina, tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Chekoslovakia, tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti wà pẹ̀lú àwọn ará tó wá láti òkè òkun tí wọ́n wà nínú bọ́ọ̀sì kan, sọ pé: “Nígbà tá à ń dágbére fúnra wa, arábìnrin kan pè mí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó dì mọ́ mi, ó sì sọ pé: ‘Ẹ tọ́jú wa gan-an ni! Ńṣe lẹ tún wá ń gbé oúnjẹ bá wa níbi tá a jókòó sí, ẹ tiẹ̀ tún fún wa lómi tá a máa mu pàápàá. A dúpẹ́ gan-an fún ìfẹ́ ńláǹlà tẹ́ ẹ fi hàn sí wa.’” Ohun tó ń sọ nípa rẹ̀ ni oúnjẹ ọ̀sán tí wọ́n ṣe fún àwọn tó ti ilẹ̀ òkèèrè wá sípàdé àgbègbè náà. Arákùnrin kan ṣàlàyé pé: “Iṣẹ́ kan tá ò ṣe irú rẹ̀ rí ni. Iṣẹ́ náà gba pé ká máa pèsè oúnjẹ ọ̀sán fún àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ààbọ̀ lójoojúmọ́. Ó wúni lórí gan-an láti rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́, títí kan àwọn ọmọdé pàápàá.”
Arábìnrin kan tó rìnrìn àjò láti ilẹ̀ Ukraine wá sí ìpàdé àgbègbè nílùú Chorzow sọ pé: “Inú wa dùn gan-an sí ìfẹ́, aájò, àti ẹ̀mí ọ̀làwọ́ táwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ fi hàn sí wa. A ò lè sọ bí ọpẹ́ wa ṣe pọ̀ tó.” Bẹ́ẹ̀ náà ni Annika tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ láti ilẹ̀ Finland kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Poland pé: “Ìpàdé àgbègbè náà dùn gan-an ju bí mo ṣe rò lọ. Ó dáa kéèyàn wà nínú ètò Jèhófà o, níwọ̀n bó ti ń jẹ́ kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́ káàkiri ayé!”—Sáàmù 133:1.
Ohun Táwọn Èèyàn Sọ Nípa Wọn
Kó tó di pé ìpàdé àgbègbè náà bẹ̀rẹ̀, wọ́n ṣètò fáwọn kan lára àwọn tó wá sí ìpàdé náà láti lọ káàkiri kí wọ́n sì rí oríṣiríṣi nǹkan. Nígbà tí wọ́n dé ìgbèríko ìlú Bavaria, àwọn àlejò náà dúró láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí ibẹ̀ sì ń kí wọn káàbọ̀. Ìfẹ́ táwọn ará fi hàn yìí mórí amúni-mọ̀nà kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà wú gan-an. Ọ̀kan lára àwọn tó wá sí ìpàdé àgbègbè náà ròyìn pé: “Nígbà tá a wà nínú bọ́ọ̀sì tó gbé wa padà sí òtẹ́ẹ̀lì wa, amúni-mọ̀nà náà sọ pé a yàtọ̀ pátápátá sáwọn mìíràn tóun ti máa ń mú mọ̀nà. A múra dáadáa, gbogbo wa la sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń darí wa. Kò sẹ́ni tó ṣépè lára wa, kò sì sí ìdàrúdàpọ̀. Ó yà á lẹ́nu báwọn tí ò mọra wọn rí ṣe lè tètè dí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀.”
Arákùnrin kan tó ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìsọfúnni ní ìpàdé àgbègbè ti ìlú Prague sọ pé: “Ní àárọ̀ ọjọ́ Sunday, ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n yàn síbi ìpàdé àgbègbè náà wá sọ́dọ̀ wa. Ó rí i pé kò sí wàhálà kankan láàárín wa, ó sì sọ pé òun ò rí iṣẹ́ kankan ṣe. Ó tún sọ pé àwọn kan lára àwọn tó ń gbé lágbègbè pápá ìṣeré náà ti béèrè pé àwọn wo ló ń ṣe nǹkan níbẹ̀. Tó bá ti sọ fún wọn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, ńṣe ni wọ́n máa ń pòṣé, ọ̀gá ọlọ́pàá náà á wá sọ fún wọn pé: ‘Tí gbogbo èèyàn bá lè níwà tó dáa tó ìdajì ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kó ní sí nǹkan tó ń jẹ ọlọ́pàá.’”
Ọ̀pọ̀ Ti Rí Ìdáǹdè!
Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, máa ń jẹ́ káwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọ́n yàtọ̀ síra wà níṣọ̀kan, ó sì ti mú káwọn Kristẹni wà pa pọ̀ ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan. (Róòmù 14:19; Éfésù 4:22-24; Fílípì 4:7) Àkànṣe ìpàdé àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” fi èyí hàn kedere. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àìsàn tó ń yọ ayé yìí lẹ́nu. Gbogbo àwọn nǹkan bí àìnífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì, jàgídíjàgan, àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, tí wọ́n jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àìsàn tó ń bá àwùjọ fínra lónìí ló ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kásẹ̀ nílẹ̀ tán láàárín wọn. Wọ́n sì ń dúró de ìgbà tí gbogbo ayé yóò bọ́ lọ́wọ́ irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀.
Àwọn tó wá sáwọn ìpàdé àgbègbè wọ̀nyí fojú ara wọn rí ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè, tí àṣà ìbílẹ̀ kálukú wọn sì yàtọ̀ síra. Èyí hàn kedere nígbà táwọn ìpàdé àgbègbè náà parí. Gbogbo wọn ló ń pàtẹ́wọ́, tí wọ́n ń dì mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ní, tí wọ́n sì ń ya àwọn fọ́tò tí wọ́n máa yà kẹ́yìn níbẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 1:10; 1 Pétérù 2:17) Ìnú àwọn tó wá sípàdé àgbègbè náà dùn, ọkàn wọn sì balẹ̀ pé ìdáǹdè kúró nínú gbogbo ìṣòro àti ìdààmú ti sún mọ́lé, wọ́n sì padà sílé wọn àti sáwọn ìjọ wọn pẹ̀lú ìpinnu tó lágbára ju ti àtẹ̀yìnwá lọ pé àwọn yòó máa di “ọ̀rọ̀ ìyè” tó jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú ṣinṣin.—Fílípì 2:15, 16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orí ẹ̀rọ alátagbà làwọn tó wà láwọn ibi mẹ́fà mìíràn tí wọ́n ti ṣe ìpàdé àgbègbè náà nílẹ̀ Poland àti ọ̀kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Slovakia ti gbọ́ ọ̀rọ̀ táwọn àwọn aṣojú láti onírúurú orílẹ̀-èdè sọ.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Èdè Mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n Ń Dún Bí Èdè Kan Ṣoṣo
Gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe àwọn ìpàdé àgbègbè mẹ́sàn-án yẹn ni wọ́n ti sọ èdè tí wọ́n máa ń sọ láwọn àgbègbè tí wọ́n ti ṣe wọ́n. Nígbà tí wọ́n ń ṣe ìpàdé àgbègbè tilẹ̀ Jámánì, wọ́n tún sọ èdè méjìdínlógún mìíràn. Nílùú Dortmund, àwọn èdè tí wọ́n sọ níbẹ̀ ni: èdè Árábíìkì, Farsi, Potogí, Sípáníìṣì, àti Rọ́ṣíà; nílùú Frankfurt, wọ́n sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, Faransé, àti èdè Serbian tàbí Croatian; nílùú Hamburg, wọ́n sọ èdè Danish, Dutch, Swedish, àti Tamil; nílùú Leipzig, wọ́n sọ èdè Ṣáínà, Polish, àti Turkish; àti nílùú Munich, wọ́n sọ èdè Gíríìkì, Italian àti Èdè Adití Lọ́nà ti Jámánì. Gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ní ìpàdé àgbègbè ti ìlú Prague pátá ni wọ́n sọ ní èdè Czech, Gẹ̀ẹ́sì, àti Rọ́ṣíà. Nílùú Bratislava, gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni wọ́n sọ lédè Gẹ̀ẹ́sì, Hungaria, Slovak, àti Èdè Adití Lọ́nà ti Slovakia. Èdè tí wọ́n sọ nílùú Chorzow ni èdè Polish, Rọ́ṣíà, Ukrainian, àti Èdè Adití Lọ́nà ti Poland. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n lo èdè Polish àti Finnish nílùú Poznan.
Gbogbo èdè tí wọ́n sọ jẹ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè àwọn tó wá sáwọn ìpàdé àgbègbè náà yàtọ̀ síra wọn, àmọ́ ìfẹ́ so wọ́n pọ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Inú àwọn tó ń sọ èdè Croatian dùn gan-an nípàdé àgbègbè ti ìlú Frankfurt, nígbà tí wọ́n rí Ìwé Mímọ́ ní “Ìtumọ̀ Ayé Tuntun” gbà ní èdè wọn