Pípànìyàn Lórúkọ Ọlọ́run
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ
“A Ń Pànìyàn Lórúkọ Ọlọ́run a Óò sì Máa Pànìyàn Lọ”
LÁBẸ́ àkọlé tí a yọ lò lókè yí, ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune sọ pé: “Ìtẹ̀sí amúnifòyà tí àwọn ènìyàn ní láti pa ara wọn lórúkọ Ọlọ́run ti tàbàwọ́n sí ọ̀rúndún yìí, tí àwọn tí wọ́n máa ń ní ẹ̀mí nǹkan yóò dára lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan fẹ́ láti kà sí ọlọ́làjú, bíi ti èyíkéyìí lára àwọn ọ̀rúndún tó ti ṣáájú rẹ̀.”
Ẹni tí ó kọ ọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí àpẹẹrẹ ìpakúpa ti ìsìn ní àwọn ọ̀rúndún ìṣáájú. Lẹ́yìn náà, ní títọ́ka sí àwọn ìpakúpa tí ó ti ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún ogún, ó parí ọ̀rọ̀ pé: “Ohun tí a rí jẹ́ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ìwà àìlọ́làjú ti àìráragba-ǹkan ti ayé àtijọ́ tí ń bá a lọ. Ìjọsìn ṣì jẹ́ àwíjàre kan fún ìwà ipá òṣèlú àti ìjagunmólú lórí àgbègbè ìpínlẹ̀.”
Àwọn kan gbìyànjú láti dá àwọn ogun ìsìn òde òní láre nípa sísọ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí pípa tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ń pa àwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì. Síbẹ̀, kò sí àwíjàre kankan nínú ìyẹn fún àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni láti máa jagun lónìí. Èé ṣe? Nítorí pé Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítọ̀ọ́ni tààràtà láti ṣiṣẹ́ bí amúdàájọ́ òdodo rẹ̀ ṣẹ lòdì sí àwọn olùjọ́sìn ẹ̀mí èṣù, tí ìjọsìn wọn ní ìwà pálapàla takọtabo bíburú lékenkà àti fífi ọmọdé rúbọ nínú.—Diutarónómì 7:1-5; Kíróníkà Kejì 28:3.
Irú ìjagunmólú oníṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè náà jẹ́ ẹ̀rí kan pé àwọn ogun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì jà kì í ṣe ìforígbárí lásán. Fún àpẹẹrẹ, ó darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì nígbà kan láti lo ìwo, ìṣà, àti ògùṣọ̀—dájúdájú wọn kì í ṣe àwọn ohun èèlò ogun tí a sábà ń lò! Ní àkókò míràn, a fi àwọn akọrin síwájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí ń kojú ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan tí ó pọ̀ jọjọ, tí ń gbógun tì wọ́n láti àwọn orílẹ̀-èdè mélòó kan.—Onídàájọ́ 7:17-22; Kíróníkà Kejì 20:10-26.
Síwájú sí i, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá lọ ja ogun tí Ọlọ́run kò pàṣẹ rẹ̀, òun kì í bù kún wọn, a sì máa ń ṣẹ́gun wọn. (Diutarónómì 28:15, 25; Onídàájọ́ 2:11-14; Sámúẹ́lì Kíní 4:1-3, 10, 11) Nítorí náà, a kò lè tọ́ka sí àwọn ogun tí Ísírẹ́lì jà gẹ́gẹ́ bí ìdí láti dá àre fún àwọn ogun tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ń jà.
Lórúkọ ìsìn, àwọn onísìn Híńdù ti gbógun ti àwọn Mùsùlùmí àti àwọn Sikh; àwọn Mùsùlùmí ẹ̀ka Shia ti gbógun ti àwọn Mùsùlùmí ẹ̀ka Sunni; àti ní Sri Lanka, àwọn onísìn Búdà àti ti Híńdù ti pa ara wọn.
Àpẹẹrẹ ìpànìyàn lórúkọ Ọlọ́run ni àwọn ogun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ Faransé ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Ìtàn àwọn ogun wọ̀nyí ní díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ní ìtàjẹ̀sílẹ̀ nínú jù lọ nínú ìtàn ìsìn Roman Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì ní Europe nínú. Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ogun wọ̀nyí, kí a sì wo ohun tí a lè rí kọ́ nínú wọn.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọ́tò U.S. Army