ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/22 ojú ìwé 17-19
  • Èé Ṣe Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èé Ṣe Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Èé Ṣe Tí Èyí Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Sí Mi?’
  • Kíkojú Ìbẹ̀rù Náà
  • Ìpèníjà Ṣíṣàìsàn
  • Lílọ Gbàwòsàn—Kò Yáni Lórí
  • Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Báyìí?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Àìsàn Bára Kú—Àníyàn Ló Jẹ́ fún Ìdílé
    Jí!—2000
  • Báwo Lo Ṣe Lè Fara Da—Àmódi Tí Ń Ṣe Ọ́?
    Jí!—2001
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ṣíṣàìsàn Tó Báyìí?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 4/22 ojú ìwé 17-19

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Èé Ṣe Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Bẹ́ẹ̀?

NÍGBÀ tí Jason wà lọ́mọ ọdún 13, ó pinnu pé lọ́jọ́ kan ṣáá, òun yóò máa ṣiṣẹ́ sìn bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan ní Bẹ́tẹ́lì, orílé iṣẹ́ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York. Ó kan àpótí onígi kan fún ara rẹ̀, ó sì pè é ní àpótí Bẹ́tẹ́lì òun. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn nǹkan tí ó rò pé yóò wúlò nígbà tí òun bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìgbésí ayé òun ní Bẹ́tẹ́lì jọ sínú àpótí náà.

Bí ó ti wù kí ó rí, ní oṣù mẹ́ta péré lẹ́yìn tí ó pé ọmọ ọdún 18, àyẹ̀wò fi hàn pé Jason ní àrùn Crohn—ìṣiṣẹ́gbòdì aronilára kan tí kì í dẹwọ́, nínú ìfun. Ó sọ pé: “Ó wulẹ̀ dà mí lọ́kàn rú ni. Gbogbo ohun tí mo lè ṣe ni kí n tẹ Dádì mi láago níbi iṣẹ́, kí n sì sọkún. Mo mọ̀ pé, ó kéré tán, ó túmọ̀ sí pé ìfẹ́ ọkàn mi láti lọ sí Bẹ́tẹ́lì ti ní ìdènà.”

Àìsàn jẹ́ ìdí pàtàkì kan tí ‘gbogbo ìṣẹ̀dá fi ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.’ (Róòmù 8:22) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọ̀dọ́ wà lára àwọn aláìsàn. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ń sàn nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Àmọ́, àwọn mìíràn ní láti máa kojú àwọn àrùn líle koko tàbí, nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn àrùn tí ń wu ìwàláàyè léwu. Lára àwọn àrùn tí àwọn ọ̀dọ́ sábà ń ní ni òtútù àyà, àtọ̀gbẹ, fòníkú-fọ̀larùn, àwọn àrùn àkóràn, wárápá, àrùn ọpọlọ, àti àrùn jẹjẹrẹ. Àwọn èwe kan ń ní àkànpọ̀ àrùn.

‘Èé Ṣe Tí Èyí Fi Ń Ṣẹlẹ̀ Sí Mi?’

Àìsàn sábà máa ń fa másùnmáwo ti èrò orí àti ti ìmọ̀lára, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ti wàhálà ara. Bí àpẹẹrẹ, bí àìsàn kò bá jẹ́ kí o lọ sílé ẹ̀kọ́ fún ọ̀pọ̀ oṣù, kì í ṣe kìkì pé o lè má lè kájú ìtòlẹ́sẹẹsẹ iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n o lè nímọ̀lára pé a ta ọ́ nù ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà pẹ̀lú. Nígbà tí Sunny, ọmọ ọdún 12, ṣàìlọ sílé ẹ̀kọ́ nítorí pé ó máa ń dúró sílé ìwòsàn látìgbàdégbà, ó dààmú wí pé, ‘Kí ni àwọn ọmọ kíláàsì mi ń ṣe? Kí ni mo ń pàdánù lónìí?’

Bákan náà, ó lè jọ pé ìdàgbàsókè tẹ̀mí ń yingin nígbà tí o bá ṣàìsàn tí ó le débi pé o kò lè lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, tàbí kí o tilẹ̀ ka Bíbélì pàápàá. Ní irú ipò yí, o nílò àfikún ìtìlẹ́yìn ti ìmọ̀lára àti ti ẹ̀mí. Lákọ̀ọ́kọ́, o lè kọ̀ láti gba àwárí àrùn náà gbọ́. Lẹ́yìn náà, inú lè bí ọ gidigidi, bóyá sí ara rẹ, ní ríronú pé o ti lè yẹ àìsàn náà sílẹ̀ lọ́nà kan. O lè ronú bíi pé kí o kígbe sókè pé, ‘Èé ṣe tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ sí mi?’ (Fi wé Mátíù 27:46.) Ní gidi, kò ṣàjèjì láti ní ìwọ̀n ìsoríkọ́ díẹ̀, ó kéré tán.

Ní àfikún, èwe kan tilẹ̀ lè ronú pé bí òun bá ṣe ìsapá àrà ọ̀tọ̀ díẹ̀, bíi gbígbìyànjú láti ní ìhùwà dídára ta yọ, Ọlọ́run yóò mú àìsàn òun kúrò. Bí ó ti wù kí ó rí, irú ìrònú bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí ìjákulẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run kò ṣèlérí ìwòsàn oníṣẹ́ ìyanu fún àkókò yí.—Kọ́ríńtì Kíní 12:30; 13:8, 13.

Bóyá o ti retí pé ìwọ kì yóò ní láti kú láé—pé ìwọ yóò wà láàyè nígbà tí Ọlọ́run bá mú “ìpọ́njú ńlá” dé. (Ìṣípayá 7:14, 15; Jòhánù 11:26) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, mímọ̀ pé o ní àrùn kan tí ń wu ìwàláàyè léwu lè fa ìwárìrì onílọ̀ọ́po méjì. O lè ṣe kàyéfì ní ti bóyá o ti ṣẹ Jèhófà lọ́nà kan, tàbí o lè rò pé Ọlọ́run ti dájú sọ ọ́ fún àkànṣe ìdánwò ìdúróṣinṣin kan. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwọ̀nyí kì í ṣe ìparí èrò yíyẹ. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, wí pé: “A kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Àìsàn àti ikú jẹ́ àwọn apá tí kò múni láyọ̀ nínú ipò ẹ̀dá ènìyàn ní lọ́ọ́lọ́ọ́, gbogbo wa ni a sì wà lábẹ́ “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.”—Oníwàásù 9:11, NW.

Kíkojú Ìbẹ̀rù Náà

Níní àrùn líle koko lè mú kí o ní ìbẹ̀rù jíjinlẹ̀ ní ìgbà àkọ́kọ́ pẹ̀lú. Ìwé náà, How It Feels to Fight for Your Life, ṣàkọsílẹ̀ lórí ohun tí a kíyè sí nípa àwọn ọ̀dọ́ 14 tí wọ́n ní àwọn àrùn líle koko. Bí àpẹẹrẹ, Anton, ọmọ ọdún mẹ́wàá, bẹ̀rù pé òun yóò kú nígbà tí ó ní àrùn òtútù àyà líle koko. Elizabeth ọmọ ọdún 16, tí ó ní àrùn jẹjẹrẹ egungun, ń bẹ̀rù pé òun lè lọ sùn, kí òun má sì jí.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn èwe kan ní oríṣi ìbẹ̀rù míràn—ìbẹ̀rù pé kò sí ẹni tí yóò fẹ́ láti fẹ́ àwọn tàbí ìbẹ̀rù pé àwọn ọmọ tí àwọn bá bí lẹ́yìn náà yóò jẹ́ aláìlera. Àwọn èwe mìíràn ń bẹ̀rù pé àwọn yóò kó àrùn náà ran àwọn mẹ́ńbà míràn nínú ìdílé àwọn, yálà àrùn tí wọ́n ní ń ranni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Kódà, bí àrùn náà bá ti dúró sójú kan tàbí tí ó dẹwọ́, bí ìyípadà èyíkéyìí bá ṣẹlẹ̀ sí búburú, àwọn ìbẹ̀rù tún ń jẹ jáde. Bí o bá ti ní irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ rí, o mọ̀ pé wọ́n jẹ́ ojúlówó. Ó dùn mọ́ni pé, ìrusókè ìmọ̀lára òdì tí ó kọ́kọ́ máa ń wá náà máa ń rọlẹ̀ bí àkókò ti ń lọ. Nígbà náà, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í pinnu ipò rẹ lọ́nà tí ó túbọ̀ bá ìrònú mu.

Ìpèníjà Ṣíṣàìsàn

Jason tí a mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Nígbà tí o bá wà léwe, ìwọ yóò rò pé ara rẹ le, o sì lè ṣe ohunkóhun. Lẹ́yìn náà ni ṣíṣàìsàn líle koko kan lójijì yóò mú kí o mọ̀ pé o kò rí bẹ́ẹ̀. Ìwọ yóò rò pé o ti darúgbó ní ọ̀sán kan òru kan, nítorí pé o ní láti sinmẹ̀dọ̀, kí o sì dín àwọn ìgbòkègbodò rẹ kù.” Bẹ́ẹ̀ ni, dídojú kọ ìdíwọ́ tuntun lè jẹ́ ìpèníjà kan.

Jason rí i pé ìpèníjà títóbi mìíràn máa ń yọjú nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá kùnà láti lóye ipò rẹ. Jason ní àrùn tí a lè pè ní “àrùn tí kò hàn síta.” Ìrísí rẹ̀ ní òde ara gbé ìṣòro tó ní nínú pa mọ́. Jason ṣàlàyé pé: “Oúnjẹ kì í dà lára mi bí ó ṣe yẹ, nítorí náà, mo ní láti máa jẹun nígbà púpọ̀, mo sì ń jẹun púpọ̀ ju èyí tí ọ̀pọ̀ ẹlòmíràn ń jẹ lọ. Síbẹ̀, n kò sanra. Bákan náà ni ó máa ń rẹ̀ mí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tó bẹ́ẹ̀ tí n kò fi ń lè ya ojú sílẹ̀ lọ́sàn-án gangan. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó fi hàn pé, wọ́n rò pé mo jẹ́ akẹ́rabàjẹ́ tàbí òkú ọ̀lẹ. Wọ́n ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ bíi pé: ‘O lè ṣe dáradára sí i. O kò tilẹ̀ ń gbìyànjú páàpáà!’”

Jason ní àwọn àbúrò lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí kì í sábà lóye ìdí tí kò fi lè máa ṣe àwọn nǹkan bí ó ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀, bíi kí ó kó wọn jáde lọ gbá bọ́ọ̀lù. Jason wí pé: “Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé bí mo bá fara pa, ó lè gbà mí lọ́sẹ̀ púpọ̀ kí ó tó san. Wọ́n máa ń fi ìrora tèmi wé tiwọn, wọ́n sì ń wí pé, ‘Ó wulẹ̀ ń kérora láti gbàfiyèsí ni.’ Ìrora búburú jù lọ tí wọ́n ní lè jẹ́ fífi ẹsẹ̀ rọ́ lásán, nítorí náà, wọn kò lè ronú mọ bí ìrora tí mo ní ṣe rí.”

Bí ó bá jọ pé àìsàn rẹ ń di ẹrù ìnira ru ìdílé rẹ, o lè máa bá ìmọ̀lára ẹ̀bi jìjàkadì. Àwọn òbí rẹ pẹ̀lú lè ní ìmọ̀lára ẹ̀bi. Jason wí pé: “Àwọn òbí mi méjèèjì rò pé ó lè jẹ́ pé lọ́dọ̀ àwọn ni mo ti jogún àìsàn náà. Àwọn ọmọ sábà máa ń mú àìsàn mọ́ra lẹ́yìn tí wọ́n bá ti mọ̀ pé ó jẹ́ gidi. Ṣùgbọ́n ó túbọ̀ ń nira fún àwọn òbí. Léraléra ni wọ́n ń bẹ̀ mí. Mo ní láti máa ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nígbà gbogbo láti mú kí wọ́n ní ìtura lọ́wọ́ ìmọ̀lára ẹ̀bi wọn.”

Lílọ Gbàwòsàn—Kò Yáni Lórí

Lílọ sọ́dọ̀ dókítà léraléra lè jẹ́ orísun ìdààmú. Ó lè mú kí o rò pé o kò já mọ́ nǹkan, o kò sì lè ta pútú. Wíwulẹ̀ jókòó níyàrá ìṣàyẹ̀wò nílé ìwòsàn, tí o ń retí ìgbà tí yóò kàn ọ́ lè máa fa ìdààmú ọkàn. Joseph, ọmọ ọdún 14, tí ó ní àrùn ọkàn àyà, wí pé: “O nímọ̀lára pé . . . ó ṣèwọ nìkan àti pé ì bá dára, ká ní ẹnì kan wà pẹ̀lú rẹ.” Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn èwe kan kò ri irú ìtìlẹ́yìn yẹn gbà, kódà láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn pàápàá.

Àwọn àyẹ̀wò ìṣègùn lè fa àníyàn bákan náà. Ká sọ tòótọ́, àwọn àyẹ̀wò kan lè ṣàìbáramu ní tààrà. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, o lè ní láti fara da ìdàníyàn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ tí o fi ń retí àbájáde náà. Ṣùgbọ́n fi èyí sọ́kàn pé: Ṣíṣe àyẹ̀wò ìlera kò rí bíi ṣíṣe ìdánwò nílé ẹ̀kọ́; níní àìsàn kò túmọ̀ sí pé o fìdí rẹmi lọ́nà kan ṣáá.

Ní gidi, àyẹ̀wò kan lè pèsè ìsọfúnni wíwúlò. Ó lè fi hàn pé o ní àìsàn kan tí ó ṣeé wò sàn. Tàbí, bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àyẹ̀wò kan lè jẹ́ kí o mọ ohun tí o lè ṣe láti máa mú àìsàn náà mọ́ra. Ó tilẹ̀ lè fi hàn pé o kò ní àrùn kan tí o ti ń fura pé o ní tẹ́lẹ̀ pàápàá. Nítorí náà, má ṣe fìkánjú parí èrò síbì kankan nípa ipò rẹ.

Ṣíṣàníyàn púpọ̀ jù yóò wulẹ̀ mú kí ó rẹ̀ ọ́ ni. Bíbélì wí pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba.” (Òwe 12:25, NW) Dípò bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ké sí wa pé kí a sọ àwọn àníyàn wa fún òun. A ní láti gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó ń bìkítà nípa wa àti pé, yóò fún wa ní ìtọ́sọ́nà rẹ̀, àti ọgbọ́n láti kojú ìṣòro náà lọ́nà dídára jù lọ tí ó bá ṣeé ṣe.—Orin Dáfídì 41:3; Òwe 3:5, 6; Fílípì 4:6, 7; Jákọ́bù 1:5.

A lè láyọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, ti ṣe ìpèsè láti mú ayé tuntun òdodo kan wá. Yóò tilẹ̀ jí àwọn òkú dìde pàápàá, ní fífún wọn láǹfààní láti gbádùn ayé tuntun yẹn. Bíbélì mú kí ó dá wa lójú pé, nígbà yẹn, “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24, NW.

Títí dìgbà náà, ìwọ lè ní láti máa mú àìsàn líle koko mọ́ra. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ ohun wíwúlò wà tí o lè ṣe láti kojú ipò rẹ lọ́nà mímúnádóko. A óò jíròrò ìwọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ kan lọ́jọ́ iwájú.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

O lè béèrè pé, ‘Èé ṣe tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ sí mi?’

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́