Àìsàn Bára Kú—Àníyàn Ló Jẹ́ fún Ìdílé
KÍ NI àìsàn bára kú? Ní ṣókí, ó jẹ́ àìsàn tí kì í yé ṣeni. Láfikún sí i, ọ̀jọ̀gbọ́n kan ṣàlàyé pé àìsàn bára kú ni “àìsàn tí iṣẹ́ abẹ lásán kan tàbí lílo oògùn fúngbà díẹ̀ ò lè wò sàn.” Fífara da àìsàn bára kú fún ìgbà pípẹ́ ló ń mú kí àìsàn náà àti ìyọrísí rẹ̀ máa dani láàmú gan-an kì í ṣe nítorí irú àìsàn tó jẹ́ tàbí ìtọ́jú tí a fún un.
Síwájú sí i, ìyọnu tí àìsàn bára kú ń fà kì í sábà mọ sọ́dọ̀ ẹni tí ń ṣàìsàn nìkan. Ìwé Motor Neurone Disease—A Family Affair sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tinú ìdílé kan tàbí òmíràn wá, ìjayà àti àníyàn tó bá ìwọ fúnra rẹ [tó jẹ́ aláìsàn] yóò bá àwọn tó sún mọ́ ọ.” Ìyá kan, tí ọmọ rẹ̀ ní àrùn jẹjẹrẹ, jẹ́rìí sí èyí. Ó sọ pé: “Kò sẹ́ni tí ọ̀ràn náà kò gbò nínú ìdílé wa, yálà ó hàn lójú wọn tàbí kò hàn, yálà wọ́n mọ̀ tàbí wọn ò mọ̀.”
Lóòótọ́, kò lè rí bákan náà lára gbogbo èèyàn. Ṣùgbọ́n bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá lóye ipa tí àìsàn bára kú ń ní lórí àwọn ènìyàn lápapọ̀, wọ́n á lè múra sílẹ̀ dáadáa láti kojú àwọn ìpèníjà pàtó tí ìṣòro tí wọ́n dojú kọ náà ń fà. Láfikún sí i, bí àwọn tí kì í ṣe ara ìdílé wọn—àwọn alájọṣiṣẹ́ wọn, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, àwọn aládùúgbò wọn, àwọn ọ̀rẹ́ wọn—bá lóye ipa tí àìsàn bára kú náà ń ní lórí wọn, wọ́n á lè ṣèrànlọ́wọ́ tó mọ́yán lórí tó fi hàn pé wọ́n gba tiwọn rò. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ọ̀nà kan tí àìsàn bára kú lè gbà nípa lórí àwọn ìdílé.
Gbígba Ilẹ̀ Àjèjì Kọjá
A lè fi ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ìdílé kan tí ọ̀kan lára wọ́n ní àìsàn bára kú wé gbígba ilẹ̀ àjèjì kan kọjá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé náà á rí àwọn ohun kan tí kò yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n ń rí nílùú wọn, síbẹ̀, àwọn ohun míì á ṣàjèjì sí wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ yàtọ̀ pátápátá. Bí àìsàn bára kú bá ń ṣe ẹnì kan nínú ìdílé, ọ̀pọ̀ nǹkan tí ìdílé náà ń ṣe á ṣì wà láìyípadà. Ṣùgbọ́n, àwọn ohun kan yóò yàtọ̀ pátápátá.
Níbẹ̀rẹ̀, àìsàn náà lè nípa lórí ohun tí ìdílé náà ń ṣe déédéé, á sì fọ̀ràn-anyàn mú olúkúlùkù mẹ́ńbà ìdílé náà láti ṣe àwọn ìyípadà kan kó bàa lè borí ìṣòro náà. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Helen, tí ìyá rẹ̀ ní àìsàn ìsoríkọ́ tí ó lé kenkà, tó jẹ́ bára kú, jẹ́rìí sí èyí. Ó sọ pé: “A jẹ́ kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa bá ohun tí Mọ́mì lè ṣe mu àti èyí tí kò lè ṣe ní àkókò kan pàtó.”
Kódà oògùn tẹ́ni náà ń lò—nítorí kí ara rẹ̀ lè balẹ̀—lè tún da ètò tuntun tí ìdílé náà ṣe nípa ìgbòkègbodò wọn rú. Gbé ọ̀ràn Braam àti Ann tí a sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí yẹ̀ wò. Braam sọ pé: “A yí àwọn ohun kan tí a máa ń ṣe lójoojúmọ́ padà pátápátá nítorí oògùn tí àwọn ọmọ wa ń lò.” Ann ṣàlàyé pé: “A ń pààrà ilé ìwòsàn lójoojúmọ́. Bákan náà, láfikún sí ìyẹn, dókítà tún ní ká máa fún àwọn ọmọ náà ní oúnjẹ ṣẹ́ẹ́ṣẹ̀ẹ̀ṣẹ́, lẹ́ẹ̀mẹfà lójúmọ́ láti kájú àìtó àwọn èròjà oúnjẹ kan tí àìsàn náà máa ń fà. Ọ̀nà ìgbọ́únjẹ tuntun gbáà ló jẹ́ fún mi.” Èyí tó tún jẹ́ ìṣòro jù níbẹ̀ ni bíbá àwọn ọmọ náà fa iṣan wọ́n kó lè mókun, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe júwe pé ká máa ṣe. Ann sọ pé: “Bóo fẹ́ bóo kọ̀, ìyẹn ò gbọ́dọ̀ já létí lójoojúmọ́.”
Bí aláìsàn náà ṣe ń mú àìfararọ náà mọ́ra, àti nígbà míì, ìrora tí ìtọ́jú àti àyẹ̀wò fínnífínní táwọn oníṣègùn ń ṣe ń fà, ìdílé rẹ̀ ni yóò máa gbára lé fún ìrànlọ́wọ́ tó gbéṣẹ́ àti fún mímú kí èrò rẹ̀ gún régé. Ní àbájáde rẹ̀, kò wá ní jẹ́ àwọn ọ̀nà tuntun tí àwọn mẹ́ńbà ìdílé náà á fi tọ́jú ara aláìsàn náà nìkan ni wọ́n á kọ́ nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún di dandan fún gbogbo wọn láti ṣàtúnṣe ìṣarasíhùwà wọn, ìmọ̀lára wọn, ọ̀nà ìgbésí ayé wọn, àti ìgbòkègbodò wọn.
A mọ̀ pé, gbogbo ṣe tibí, ṣe tọ̀ún wọ̀nyí ló ń béèrè ìfaradà púpọ̀ lọ́dọ̀ ìdílé. Ìyá kan tí ọmọ ẹ̀ wà nílé ìwòsàn tí wọ́n ti ń tọ́jú ẹ̀ nítorí àrùn jẹjẹrẹ sọ pé ó “máa ń tánni lókun gan-an ju bí ẹnikẹ́ni ti lè rò lọ.”
Àìdánilójú Tí Kò Lópin
Ìwé Coping With Chronic Illness—Overcoming Powerlessness sọ pé: “Ìsásókè-sásódò tí ò lópin tí àìsàn bára kú ń fà ń gbé èrò àìdánilójú tí ń wuni léwu ka èèyàn láyà.” Ìgbà tí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá ṣì ń ṣe ìyípadà láti mú ara wọn bá àwọn ipò kan mu, ó lè jẹ́ ìgbà yẹn làwọn nǹkan tó yàtọ̀ pátápátá, tó tún lè jù ìyẹn lọ á tún yọjú. Àwọn àmì àrùn náà lè ṣàjèjì tàbí kí wọ́n tiẹ̀ wá le sí i, àti pé ìtọ́jú tí wọ́n ń fún un lè máà mú kára ẹ̀ le bí wọ́n ṣe retí. Ó lè jẹ́ pé wọ́n ní láti máa yíwọ́ ìtọ́jú náà padà látìgbàdégbà bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fa ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀. Bí aláìsàn náà ò ti lè dá nǹkan ṣe, tó jẹ́ pé ńṣe ló gbára lé ìrànlọ́wọ́ táwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ tí ṣìbáṣìbo ti bá ń tiraka láti ṣe fún un, àwọn ìmọ̀lára tó ti ń pa mọ́ra tẹ́lẹ̀ rí lè wá tú síta.
Àìlèsọ pàtó nípa irú àìsàn tó ń ṣeni àti bí a ó ṣe tọ́jú wọ́n gbé àwọn ìbéèrè tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ dìde pé: Yóò ti pẹ́ tó tí èyí yóò fi máa bá a lọ? Báwo ni àìsàn náà yóò ṣe le tó? Báwo ni a ó ṣe lè fara dà á tó bá tún lọ jù báyìí lọ? Àrùn tó la ikú lọ ló sábà máa ń fa iyèméjì jù lọ—“Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kó tó kú?”
Pa gbogbo ẹ̀ pọ̀ ná, ìyẹn àìsàn náà, ìlànà ìtọ́jú, rírẹni tọwọ́tẹsẹ̀, àti àìdánilójú, wàá rí i pé wọ́n á yọrí sí àwọn ohun mìíràn tí a ò rò tẹ́lẹ̀.
Bó Ṣe Kan Àjọṣe Wa Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn
Kathleen, tí ọkọ rẹ̀ ní ìsoríkọ́ tó ti di bára kú, sọ pé: “Mo ní láti bá ìmí ẹ̀dùn lílágbára jà, èyí tí ìdáwà àti àhámọ́ ń fà.” Ó tún sọ pé: “Kò jọ pé ìṣòro náà ń dín kù, nítorí a ò lè ké sí àwọn èèyàn wá ṣe fàájì pẹ̀lú wa, a ò sì lè lọ sáwọn òde tí wọ́n pè wá sí. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ di pé a ò ní àwọn alájọṣe mọ́.” Ọ̀pọ̀ èèyàn lọ̀ràn wọ́n dà bíi ti Kathleen, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ìmí ẹ̀dùn náà jà pé àwọn jẹ̀bi nítorí pé àwọn ò fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sáwọn èèyàn mọ́, pé àwọn ò sì lè lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń ké sí wọn. Kí ló ń fa èyí?
Àìsàn náà fúnra rẹ̀ tàbí ìyọrísí búburú tí ìtọ́jú tí wọ́n ń fún ẹni náà ń fà lè mú kó ṣòro láti lọ sóde tàbí kó tiẹ̀ má ṣeé ṣe láti lọ sóde. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé àti aláìsàn náà lè rò pé àìsàn tó ń tàbùkù ẹni láwùjọ ni tàbí kí wọ́n máa bẹ̀rù pé ó lè dójú tini. Ìsoríkọ́ lè mú kí aláìsàn náà ronú pé òun ò bẹ́gbẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ tóun ní tẹ́lẹ̀ mu mọ́, tàbí kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé má tiẹ̀ ní okun láti máa ròde. Oríṣiríṣi nǹkan ló lè mú kí ìdílé lápapọ̀ máa sá sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tàbí kí wọ́n máà bẹ́gbẹ́ ṣe nítorí àìsàn bára kú náà.
Síwájú sí i, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa mọ ohun tó yẹ kí wọ́n sọ tàbí bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe tí wọ́n bá wà nítòsí ẹni tó láìsàn lára. (Wo àpótí “Bóo Ṣe Lè Ṣèrànlọ́wọ́,” lójú ìwé 11.) Ann sọ pé: “Bí ọmọ rẹ kò bá dà bí àwọn ọmọ yòókù, púpọ̀ àwọn èèyàn á máa wò wọ́n, wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀ tí ò ní láárí. Ibẹ̀ ni wàá ti wá máa dá ara rẹ lẹ́bi nítorí àìsàn náà, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ á wá máa dá kún ẹ̀dùn ẹ̀bi tí o ní.” Ohun tí Ann sọ yẹn kan ohun mìíràn tó lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn mẹ́ńbà ìdílé.
Èrò Tó Ń Fa Ìpalára
Olùwádìí kan sọ pé: “Nígbà tí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá lọ gbọ́ irú àìsàn tó jẹ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn lẹnu máa ń yà, tí wọn kì í gbà gbọ́, wọ́n sì máa ń sọ pé kò lè jóòótọ́. Ó ti le jù láti fàyà rán.” Òótọ́ ni, ó lè bani nínú jẹ́ gan-an táa bá gbọ́ pé ẹnì kan tí a fẹ́ràn ń ṣàìsàn tó lè gbẹ̀mí ẹ̀ tàbí tó lè sọ ọ́ di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Ìdílé kan lè rò pé ìrètí àti gbogbo èrò àwọn ti já sásán, pé ọjọ́ ọ̀la ṣókùnkùn, tí àdánù àti ìbànújẹ́ yóò sì wá dorí àwọn kodò.
Lóòótọ́, ní tàwọn ìdílé púpọ̀ tí wọ́n ti rí àmì àrùn tí kì í lọ bọ̀rọ̀, tó sì ń kó ìrora ọkàn báni yìí lára mẹ́ńbà ìdílé wọn, tí wọn ò sì mọ okùnfà rẹ̀, gbígbọ́ irú àìsàn tó jẹ́ lè fọkàn wọn balẹ̀ díẹ̀. Ṣùgbọ́n bí àwọn ìdílé míì ṣe máa ṣe tí wọ́n bá gbọ́ irú àìsàn tó jẹ́ lè yàtọ̀. Ìyá kan tó ń gbé Gúúsù Áfíríkà sọ pé: “Níkẹyìn, inú mi bà jẹ́ gan-an nígbà tí wọ́n sọ irú àìsàn tó ń yọ àwọn ọmọ wa lẹ́nu, débi pé, ì bá dáa kí ń máà kúkú gbọ́ ọ rárá.”
Ìwé A Special Child in the Family—Living With Your Sick or Disabled Child ṣàlàyé pé, “ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé kí ọkàn rẹ dà rú . . . bóo ti ń gbìyànjú láti ṣàtúnṣe láti kojú àwọn ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ yìí. Nígbà míì, ó lè gbòdì lára rẹ gan-an tí wàá fi máa bẹ̀rù pé o ò ní lè fara dà wọ́n.” Ẹni tó kọ ìwé náà, Diana Kimpton, táwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì ní àìsàn tí kì í jẹ́ kí oúnjẹ dà nínú, sọ pé: “Ìṣesí tèmi fúnra mi ń bà mí lẹ́rù, mo sì ní láti mọ̀ pé ó bójú mu pé kí ọkàn èèyàn bà jẹ́ gan-an.”
Kò sí ohun tó ṣàjèjì nínú kí ẹ̀rù máa ba àwọn mẹ́ńbà ìdílé ẹni náà—ìbẹ̀rù ohun tí wọn ò rò tẹ́lẹ̀, ìbẹ̀rù àìsàn náà, ìbẹ̀rù ìtọ́jú tí wọ́n á fún un, ìbẹ̀rù ìrora, àti ìbẹ̀rù pé ó lè kú. Ní pàtàkì àwọn ọmọ lè máa bẹ̀rù ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n ò ní lè sọ—pàápàá tí wọn ò bá ṣàlàyé tó mọ́gbọ́n dání fún wọn nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀.
Ìbínú pẹ̀lú tún sábà máa ń ṣẹlẹ̀. Ìwé ìròyìn Gúúsù Áfíríkà tí ń jẹ́ TLC, ṣàlàyé pé: “Aláìsàn náà lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í fìbínú kanra mọ́ àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀.” Àwọn mẹ́ńbà ìdílé náà lè wá bẹ̀rẹ̀ sí bínú—sí àwọn dókítà pé wọn ò tètè ṣàwárí àìsàn náà, wọ́n lè máa bínú sí ara wọn pé àwọ́n tàtaré àìsàn àbímọ́ni sára ọmọ náà, wọ́n lè bínú sí aláìsàn náà pé kò tọ́jú ara rẹ̀ dáadáa, wọ́n lè bínú sí Sátánì Èṣù pé òun ló fa àìsàn náà, tàbí kí wọ́n bínú sí Ọlọ́run pàápàá, pẹ̀lú èrò pé òun ló lẹ̀bi àìsàn náà. Níní èrò pe àwọn làwọn jẹ̀bi ọ̀ràn náà tún jẹ́ ọ̀nà mìíràn táwọn èèyàn máa ń gbà fi ohun tó wà nínú wọn hàn nípa àìsàn bára kú. Ìwé Children With Cancer—A Comprehensive Reference Guide for Parents sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ olúkúlùkù òbí tàbí àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ọmọ tó ní àrùn jẹjẹrẹ ló ní èrò ẹ̀bi.”
Ìṣòro èrò tó gbòdì yìí ní ìwọ̀n tó ga tàbí tó kéré sábà máa ń yọrí sí ìsoríkọ́. Olùwádìí kan sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé èyí ló wọ́pọ̀ jù nínú bí àwọn èèyàn ṣe ń fi ohun tó wà nínú wọn hàn. Mo ní fáìlì kan tí lẹ́tà kún inú ẹ̀, tí mo lè fi ti ọ̀rọ̀ mi lẹ́yìn.”
Ká Sòótọ́, Àwọn Ìdílé Lè Fara Dà Á
Ó dùn mọ́ni nínú pé ọ̀pọ̀ ìdílé ti wá rí i pé fífarada ìṣòro náà kì í fi bẹ́ẹ̀ le tó bí wọ́n ṣe kọ́kọ́ rò pé yóò rí. Diana Kimpton mú un dáni lójú pé: “Àwọn ohun tí o ń ronú pé yóò ṣẹlẹ̀ á wá burú ju ohun tó lè ṣẹlẹ̀ ní gidi lọ.” Láti inú ìrírí tiẹ̀, ó rí i pé “ìṣòro tí yóò wà lọ́jọ́ iwájú kì í fi bẹ́ẹ̀ burú tó bí èèyàn ṣe rò pé yóò rí nígbà tó kọ́kọ́ gbọ́ nípa àìsàn náà.” A fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé àwọn ìdílé míì ti ṣàṣeyọrí nínú líla ilẹ̀ àjèjì tí àìsàn bára kú náà gbé wọn gbà kọjá àti pé ẹ̀yin náà lè là á já. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí i pé wíwulẹ̀ mọ̀ pé àwọn míì ti fara dà á ti fọkàn àwọn balẹ̀ díẹ̀, àwọ́n sì nírètí pé nǹkan á dáa.
Ṣùgbọ́n ìdílé kan lè ṣiyè méjì lọ́nà tó tọ́ pé, ‘Báwo ni a ṣe lè fara dà á?’ Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára ọ̀nà tí àwọn ìdílé gbà fara da àìsàn bára kú.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Àwọn mẹ́ńbà ìdílé ní láti tọ́jú aláìsàn náà kí wọ́n sì ṣàtúnṣe ìṣarasíhùwà, èrò, àti ọ̀nà ìgbésí ayé tiwọn náà
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Aláìsàn náà àti àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ á máa ní ìmí ẹ̀dùn
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
Ẹ má ṣe sọ̀rètí nù. Àwọn ìdílé míì ti fara dà á, ẹ̀yin náà sì lè fara dà á
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ìpèníjà Díẹ̀ Tí Àìsàn Bára Kú Ń Fà
• Gbígbọ́ nípa àìsàn náà àti bí a ó ṣe kojú rẹ̀
• Yíyí ọ̀nà ìgbésí ayé ẹni àti ìgbòkègbodò ẹni ojoojúmọ́ padà
• Kíkojú ipò tó yí padà nípa bí a ṣe ń ròde
• Níní èrò tó wà déédéé àti ṣíṣàkóso rẹ̀
• Bíbanújẹ́ nípa àwọn àdánù tí àìsàn náà fà
• Kíkojú ìmí ẹ̀dùn
• Níní èrò tó tọ̀nà