ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 6/8 ojú ìwé 3
  • Nígbà Tí Àìsàn Bára Kú Bá Kọ Lu Ìdílé Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nígbà Tí Àìsàn Bára Kú Bá Kọ Lu Ìdílé Kan
  • Jí!—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Àwọn Ìdílé Ṣe Lè Kojú Ìṣòro Àìsàn Bára Kú
    Jí!—2000
  • Àìsàn Bára Kú—Àníyàn Ló Jẹ́ fún Ìdílé
    Jí!—2000
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2000
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Tí Mo Bá Ń Ṣàìsàn Ọlọ́jọ́ Pípẹ́?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 6/8 ojú ìwé 3

Nígbà Tí Àìsàn Bára Kú Bá Kọ Lu Ìdílé Kan

AYỌ̀ ìdílé Du Toit ń ranni gan-an, débi pé ayọ̀ ẹnì kìíní kejì wọn kàn ń pọ̀ sí i ni. Kò sí bórí èèyàn ò ṣe ní wú tó bá rí i bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ bá ara wọn lò. Tóo bá bá wọn pàdé, o ò lè mọ̀ pé wọ́n ti fojú winá ìṣòro tó le.

Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ni pé, ìgbà tí Michelle, àkọ́bí wọn, wà lọ́mọ ọdún méjì ni ìwádìí tí Braam àti Ann ṣe ti fi hàn pé wọ́n bí àìsàn kan mọ́ ọn tí kò ní yéé máa ṣe é, tí yóò sọ iṣan ara rẹ̀ di aláìlágbára.

Ann tó jẹ́ ìyá rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Láìròtẹ́lẹ̀, ó wá di ká bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ bí a óò ṣe kojú àìsàn bára kú tí ń sọni di ahẹrẹpẹ yìí. Ìgbà yẹn la wá rí i pé ìgbésí ayé ìdílé wa ò tún lè rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.”

Ìbànújẹ́ ìdílé yìí tún ń pọ̀ sí i, àgàgà nígbà tí wọ́n bí ọmọbìnrin kan àti ọmọkùnrin kan sí i. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń ṣeré níta, àwọn méjì tó jẹ́ obìnrin sáré wọlé. Wọ́n kébòòsí pé: “Mọ́mì! Mọ́mì! Ẹ tètè máa bọ̀. Nǹkan ń ṣe Neil!”

Bí Ann ṣe sáré jànnàjànnà jáde ló rí orí Neil, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta, tó ti yí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Orí ẹ̀ ò lè dá dúró mọ́.

Ann rántí ọjọ́ náà, ó ní: “Àyà mí já gidigidi, ohun tó ṣẹlẹ̀ kàn mí ku. Ọkàn mí bà jẹ́ pé ọmọ tó ń ta kébékébé yìí á wá di ẹni tó ń fàyà rán wàhálà àìsàn bára kú tó ń sọ iṣan di aláìlágbára, irú èyí tó ń yọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lẹ́nu.”

Braam tó jẹ́ bàbá àwọn ọmọ náà sọ pé: “Láìpẹ́, díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó tíì fojú wa rí màbo jù lọ náà ti yára bo ayọ̀ wa mọ́lẹ̀, èyí táa ní ní ìbẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé tó lera.”

Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tọ́jú Michelle dáadáa nílé ìwòsàn, ó pàpà kú nítorí àwọn ìṣòro tí àìsàn náà tún mú kí ó jẹ yọ. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá péré ni nígbà tó kú. Neil alára ṣì ń bá àwọn ìṣòro àìsàn tiẹ̀ jà.

Èyí ló wá fa ìbéèrè náà pé, Báwo ni àwọn ìdílé bíi ti Du Toit ṣe kojú ìṣòro níní ẹni tí àìsàn bára kú ń yọ lẹ́nu nínú ìdílé wọn? Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká ṣàlàyé díẹ̀ lára ọ̀nà tí àìsàn bára kú ń gbà ní ipa lórí àwọn ìdílé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́