Bí Àwọn Ìdílé Ṣe Lè Kojú Ìṣòro Àìsàn Bára Kú
A LÈ túmọ̀ kíkojú sí “agbára láti bójú tó hílàhílo tó dé báni lọ́nà tó gbéṣẹ́.” (Taber’s Cyclopedic Medical Dictionary) Ó kan kíkojú ìṣòro àìsàn bára kú láìwulẹ̀ dààmú jù, kí ọkàn rẹ sì balẹ̀ dé àyè kan. Àti pé nítorí pé gbogbo ẹni tó wà nínú ìdílé ni bíbójútó àìsàn bára kú kàn, ó yẹ kí olúkúlùkù mẹ́ńbà ìdílé fi tọkàntọkàn àti tìfẹ́tìfẹ́ ṣètìlẹ́yìn kí ìdílé náà lè kojú rẹ̀ bó ṣe yẹ. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí ìdílé ń gbà kojú àìsàn bára kú yẹ̀ wò.
Ìmọ̀ Ṣe Pàtàkì
Ó ṣeé ṣe kí àrùn náà má sàn, ṣùgbọ́n bí èèyàn bá mọ bó ṣe lè fara dà á, ìyẹn lè dín ipa tí yóò ní lórí èrò inú àti ìmọ̀lára ẹni kù. Èyí wà níbàámu pẹ̀lú òwe àtijọ́ kan tó sọ pé: “Ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń mú kí agbára túbọ̀ pọ̀ sí i.” (Òwe 24:5) Báwo ni ìdílé kan ṣe lè mọ bí wọn ó ṣe lo ìfaradà?
Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni láti wá dókítà tó máa ń gbọ́ni yé, tó lè ṣèrànwọ́, tó sì ṣe tán láti fara balẹ̀ ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ àìsàn náà fún aláìsàn àti ìdílé rẹ̀. Ìwé A Special Child in the Family sọ pé: “Ẹni tó bá jẹ́ ojúlówó dókítà máa ń gba tí ìdílé lápapọ̀ rò láfikún sí mímọ̀ tí yóò mọ gbogbo ìlànà ìṣègùn tó yẹ kó lò.”
Ìgbésẹ̀ tó kàn lẹ́yìn náà ni láti máa béèrè àwọn ìbéèrè pàtó títí tí ẹ ó fi lóye àìsàn náà dáadáa. Ṣùgbọ́n o, ẹ rántí pé tí ẹ bá dé ọ̀dọ̀ dókítà, ojora lè tètè mú un yín kí ọkàn yín sì dà rú, ẹ sì lè tipa bẹ́ẹ̀ gbàgbé ohun tẹ́ẹ fẹ́ béèrè. Àbá kan tó lè ṣèrànwọ́ ni láti kọ àwọn ìbéèrè tí ẹ bá ní kẹ́ẹ tó lọ. Ní pàtàkì, ẹ lè fẹ́ láti mọ ohun tó ṣeé ṣe kí àìsàn náà fà àti ìtọ́jú tí ẹ óò lò àti ohun tí ẹ óò ṣe sí i.—Wo àpótí náà, “Àwọn Ìbéèrè Tí Ìdílé Kan Lè Bi Dókítà.”
Pàápàá, ó ṣe pàtàkì láti ṣàlàyé kíkún fún àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ọmọ tó ní àìsàn bára kú náà. Ìyá kan dámọ̀ràn pé: “Ẹ ṣàlàyé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ fún wọn. Wọ́n lè rò pé ẹ ta àwọn nù kúrò lára ìdílé ni bí wọn ò bá lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀.”
Bákan náà, àwọn ìdílé kan rí ìsọfúnni tó wúlò nípa ṣíṣe ìwádìí ní ibi ìkówèésí ládùúgbò wọn, tàbí ní ilé ìtàwé, tàbí nínú Íńtánẹ́ẹ̀tì—wọ́n sábà máa ń rí ìsọfúnni kíkún nípa àwọn àìsàn kan pàtó.
Gbígbé Ìgbésí Ayé Lọ́nà Tó Bójú Mu
Ó bá ìwà ẹ̀dá mu pé kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé fẹ́ kí aláìsàn náà gbé ìgbésí ayé tó bójú mu. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Neil du Toit yẹ̀ wò, tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́. Sísọ tí àìsàn tó ń ṣe é sọ ọ́ di aláìlágbára ṣì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ń lo nǹkan bí àádọ́rin wákàtí lóṣù nídìí ṣíṣe iṣẹ́ tó gbádùn láti máa ṣe jù lọ—bíbá àwọn ará àdúgbò rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tí a gbé karí Bíbélì. Ó sọ pé: “Inú mi máa ń dùn láti máa ṣàlàyé Bíbélì nínú ìjọ.”
Gbígbé ìgbésí ayé tó bójú mu tún wé mọ́ níní agbára láti fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn káwọn náà sì fìfẹ́ hàn síni, láti gbádùn àwọn ìgbòkègbodò tó ń fúnni ní ìtẹ́lọ́rùn, àti láti ní ìrètí. Àwọn tí ń ṣàìsàn yóò ṣì fẹ́ láti gbádùn ayé wọn dé ìwọ̀n tí àìsàn àti ìtọ́jú tí wọ́n ń gbà bá gbà wọ́n láyè mọ. Bàbá kan tí ìdílé rẹ̀ ti ń fara da àìsàn fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ṣàlàyé pé: “A nífẹ̀ẹ́ sí ṣíṣeré jáde, ṣùgbọ́n nítorí pé ó ní bí ọmọ mi ṣe lè ṣe mọ, a ò lè ṣeré jáde. Nítorí náà, ọ̀nà míì la ń gbà ṣe é. A máa ń lọ́ sí àwọn ibi tí a kò ti ní ṣe eré tó gba agbára jù.”
Dájúdájú, àwọn tí ń ṣàìsàn ṣì máa ń lè ṣe àwọn nǹkan kan tó máa jẹ́ kí wọ́n ní ìwọ̀n ìtẹ́lọ́rùn nínú ìgbésí ayé. Púpọ̀ nínú wọ́n ṣì lè fẹ́ láti máa rí àwọn ibi tó fani mọ́ra, kí wọ́n sì máa gbọ́ àwọn orin alárinrin, ó sinmi lé irú àìsàn tó ń ṣe wọ́n. Bí wọ́n bá ṣe rò pé àwọn kápá onírúurú apá ìgbésí ayé àwọn sí tó ni wọn óò ṣe lè gbé ìgbésí ayé tó bójú mu tó.
Yíyanjú Ìṣòro Ìrònú
Apá pàtàkì kan nínú kíkojú ìṣòro àìsàn bára kú kan kíkọ́ bí a ṣe ń ṣàkóso èrò tó lè ṣèpalára. Ọ̀kan lára wọn ni ìbínú. Bíbélì sọ pé ẹnì kan lè ní ìdí láti bínú. Ṣùgbọ́n ó tún rọ̀ wá pé ká “lọ́ra láti bínú.” (Òwe 14:29) Èé ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu láti ṣe bẹ́ẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan ti sọ, ìbínú “lè máa pa ọ́ lára díẹ̀díẹ̀, ó sì lè sọ ẹ́ di ẹni tó ní ẹ̀mí ìkórìíra tàbí kó mú kóo sọ àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí wàá wá kábàámọ̀ tó bá yá.” Kódà, èèyàn lè balẹ̀ jẹ́ tó bá fara ya lẹ́ẹ̀kan tínú bá bí i, ó sì lè pẹ́ ká tó ṣàtúnṣe ohun tó bà jẹ́.
Bíbélì dámọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” (Éfésù 4:26) Ó dájú pé a ò lè ṣe ohunkóhun láti dá oòrùn dúró kó má wọ̀. Ṣùgbọ́n a lè gbégbèésẹ̀ láti yanjú ohun tó mú ká wà ní “ipò ìbínú” ní kíá ká má bàa máa pa ara wa àti àwọn ẹlòmíràn lára. Ìgbà tí inú ẹ bá rọ̀ ni yóò sì ṣeé ṣe fún ẹ láti yanjú ọ̀ràn lọ́nà tó dára.
Kò sí àní-àní pé, nígbà míì nǹkan á dáa, ìṣòro sì lè wà nígbà míì nínú ìdílé yín, àní bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ láwọn ìdílé mìíràn náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti rí i pé ó ń ṣeé ṣe fún àwọn láti fara dà á tí àwọn bá lè finú han ẹnì kìíní-kejì àwọn tàbí táwọn bá finú han ẹlòmíràn tó jẹ́ oníyọ̀ọ́nú tó sì ń gba tẹni rò. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kathleen gan-an nìyẹn. Ó kọ́kọ́ ń tọ́jú ìyá rẹ̀, tí àrùn jẹjẹrẹ ń ṣe, lẹ́yìn náà ló tún tọ́jú ọkọ rẹ̀, tí ìsoríkọ́ tó ti di bára kú ń yọ lẹ́nu, tí àrùn Ọdẹ Orí Abọ́jọ́-ogbó-rìn wá ṣe níkẹyìn. Ó sọ pé: “Ọkàn mi máa ń balẹ̀, ara sì máa ń tù mí tí mo bá rí àwọn ọ̀rẹ́ tó ń gba tẹni rò.” Rosemary, tí òun náà tọ́jú ìyá rẹ̀ fún ọdún méjì, gbà pẹ̀lú rẹ̀. Ó sọ pé: “Bíbá ọ̀rẹ́ kan tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn sọ̀rọ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti fọkàn balẹ̀.”
Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu bó bá jẹ́ gbogbo ìgbà tóo bá ń bá èèyàn sọ̀rọ̀ lo máa ń sunkún. Ìwé náà, A Special Child in the Family, sọ pé: “Ẹkún máa ń dín àìfararọ àti ìrora kù, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn rẹ.”a
Ní Èrò Tó Tọ́
Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ tí o ní fún ìwàláàyè lè gbé ọ ró tí o bá ń ṣàìsàn.” (Òwe 18:14, Today’s English Version) Àwọn olùwádìí lóde òní ti ṣàkíyèsí pé ó jọ pé ohun táwọn aláìsàn ń retí kí ó ṣẹlẹ̀—ì bá jẹ́ ire tàbí ibi—sábà máa ń nípa lórí bí ìtọ́jú tí wọ́n ń gbà ṣe ṣiṣẹ́ sí. Nígbà náà, báwo ni ìdílé kan ṣe lè retí kí nǹkan tó dáa ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń bá àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ yí?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mẹ́ńbà ìdílé ò ní gbọ́kàn kúrò nínú àìsàn náà, tí wọ́n bá darí àfiyèsí sí àwọn ohun tí wọ́n ṣì lè ṣe nípa rẹ̀, wọ́n á lè kápá ìṣòro náà dáadáa. Bàbá kan sọ pé: “Ìṣòro náà lè sọ èèyàn di ẹni tí kò ro rere rárá, ṣùgbọ́n ẹ ní láti mọ̀ pé ó bà ni, kò bàjẹ́. Ẹ̀mí yín ṣì wà, ẹ ṣì wà fún ara yín, àwọn ọ̀rẹ́ ṣì wà fún yín pẹ̀lú.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn bára kú kì í ṣe ohun tí a lè fọwọ́ yẹpẹrẹ mú, mímọ bí a ṣe ń ṣàwàdà tó bójú mu yóò ràn yín lọ́wọ́ láti dènà èrò pé nǹkan ò ní dáa. A lè fi bí ìdílé Du Toit ṣe máa ń ṣàwàdà fàlàlà ṣàpẹẹrẹ èyí. Collette, àbúrò Neil du Toit obìnrin tó kéré jù, ṣàlàyé pé: “Nítorí pé a ti kọ́ láti fara da àwọn ìṣòro kan, a lè máa fi àwọn ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí wa ṣe yẹ̀yẹ́, tó jẹ́ pé, ká ní àwọn míì ló ṣẹlẹ̀ sí ni, ṣe ni wọ́n á bínú rangbandan. Ṣùgbọ́n ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí pákáǹleke wa dín kù gan-an ni.” Bíbélì mú un dá wa lójú pé “ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.”—Òwe 17:22.
Àwọn Ìwà Ẹ̀yẹ Tẹ̀mí Tó Ṣe Pàtàkì
Apá kan tó ṣe pàtàkì tó ní í ṣe pẹ̀lú wíwà tí àwọn Kristẹni wà ní ipò tẹ̀mí tó jíire kan ‘sísọ àwọn ohun tí wọ́n ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.’ Ìyẹn á wá yọrí sí ohun tí Bíbélì ṣèlérí, pé: “Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.” (Fílípì 4:6, 7) Lẹ́yìn nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún tí ìyá kan ti ń tọ́jú àwọn ọmọ tó ń ṣàìsàn, ó sọ pé: “A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà máa ń ranni lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro. Ó máa ń gbéni ró gan-an ni.”
Síwájú sí i, àwọn ìlérí tí Bíbélì ṣe pé ayé á di párádísè, níbi tí kò ti ní sí ìrora àti ìyà mọ́, máa ń fún ọ̀pọ̀ lókun. (Ìṣípayá 21:3, 4) Braam sọ pé: “Nítorí àìsàn bára kú tí ìdílé wa ti dojú kọ, ìlérí Ọlọ́run ń ní ìtumọ̀ tó pọ̀ sí fún wa nígbà tó sọ pé, ‘ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.’” Bí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ṣe ń retí, ìdílé Du Toit ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún àkókò tí “kò ní sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí’” mọ́, nínú Párádísè.—Aísáyà 33:24; 35:6.
Ṣe ọkàn gírí. Ìyà àti ìrora tó ń pọ́n aráyé lójú fúnra rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀rí pé ipò nǹkan yóò dára láìpẹ́. (Lúùkù 21:7, 10, 11) Ṣùgbọ́n, kó tó dìgbà yẹn, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tí ń tọ́jú aláìsàn àti àwọn aláìsàn fúnra wọn lè jẹ́rìí sí i pé ní ti gidi, Jèhófà ni “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti rí àlàyé sí i nípa bí o ṣe lè kápá ìmí ẹ̀dùn tí àìsàn máa ń fà, jọ̀wọ́ wo “Ṣíṣètọ́jú—Kíkojú Ìpèníjà Náà,” nínú Jí!, February 8, 1997, ojú ìwé 3 sí 13.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn Ìbéèrè Tí Ìdílé Kan Lè Bi Dókítà
• Báwo ni àìsàn náà ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀, ibo ni yóò sì yọrí sí?
• Àwọn àmì wo ni àá máa rí, báwo sì ni a ṣe lè kápá wọn?
• Àwọn oríṣi ọ̀nà wo la lè gbà tọ́jú ẹni náà?
• Àwọn ìyọrísí búburú, ewu, àti àǹfààní wo ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìtọ́jú wọ̀nyí ní?
• Kí la lè ṣe láti mú kí ìṣòro náà dín kù, kí sì ni a ní láti yẹra fún?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Bí O Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
Àwọn èèyàn kan ò ní fẹ́ lọ bẹ̀ wọ́n wò tàbí kí wọ́n lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ nítorí pé wọn ò mọ ohun tí wọ́n lè sọ tàbí bí wọ́n á ṣe ṣe níbẹ̀. Àwọn míì lè jẹ́ ayọnilẹ́nu, wọ́n sì lè dá kún ìṣòro tó ń yọ ìdílé náà lẹ́nu tí wọ́n bá ń fagbára mú wọn láti gba ohun tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, báwo ni èèyàn ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ẹnì kan nínú ìdílé wọn ní àìsàn bára kú, tí a ò sì ní yọjúràn sí ohun tí wọn ò pè wá sí?
Fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò gbọ́ wọn. Jákọ́bù 1:19 sọ pé: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́.” Fi hàn pé o bìkítà nípa jíjẹ́ ẹni tó ń fetí sílẹ̀ dáadáa, kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé náà lè sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn bí wọ́n bá fẹ́ sọ̀rọ̀. Wọ́n lè fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá róye pé o ní “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì.” (1 Pétérù 3:8) Ṣùgbọ́n, rántí pé ẹni méjì tàbí ìdílé méjì ò lè hùwà bákan náà tó bá kan ọ̀ràn àìsàn bára kú. Ìdí nìyẹn tí Kathleen, tó tọ́jú ìyá rẹ̀ àti lẹ́yìn náà, ọkọ rẹ̀ tí àìsàn bára kú kọ lù, fi sọ pé, “má ṣe gbà wọ́n nímọ̀ràn àyàfi tóo bá mọ̀ nípa àìsàn náà tàbí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí dáadáa.” (Òwe 10:19) Tún rántí pé bóo bá tiẹ̀ mọ nǹkan kan nípa ìṣòro náà, ẹni tí àìsàn ń ṣe àti ìdílé rẹ̀ lè pinnu láti máà wá ìmọ̀ràn wá sọ́dọ̀ rẹ tàbí láti má gba ìmọ̀ràn rẹ.
Ṣe ìrànwọ́ tó ṣàǹfààní. Bí o ti ń ṣọ́ra kóo má yọjúràn sí ohun tí wọn ò pè ẹ́ sí, wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ìrànlọ́wọ́ rẹ ní gidi. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Braam, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ tí àwọn Kristẹni arákùnrin wá ṣe fún wa kàmàmà. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí a ń sun ilé ìwòsàn mọ́jú nítorí pé àìsàn Michelle le gan-an, ẹni mẹ́rin sí mẹ́fà lára àwọn ará wa sábà máa ń jókòó tì wá mọ́jú. Ìgbàkigbà táa bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́, a kì í ṣàìrí i.” Ann tí í ṣe ìyàwó Braam tún sọ pé: “Ó bọ́ sí ìgbà òtútù tó le gan-an, oríṣiríṣi ọbẹ̀ sì ni àwọn ará ń sè wá fún wa lójoojúmọ́, fún ọ̀sẹ̀ méjì gbáko. Wọ́n fi ọbẹ̀ gbígbóná àti ìfẹ́ ọlọ́yàyà rẹpẹtẹ ṣìkẹ́ wa.”
Ẹ gbàdúrà pẹ̀lú wọn. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ sí ohun pàtàkì kan tóo lè ṣe. Bó ti wù kó rí, ọ̀kan lára àwọn ohun díẹ̀ tó lè fún wọn níṣìírí jù lọ lè jẹ́ ṣíṣàjọpín ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú wọn tàbí gbígbàdúrà àtọkànwá pẹ̀lú àwọn aláìsàn náà àti ìdílé wọn. (Jákọ́bù 5:16) Nicolas, ọmọ ọdún méjìdínlógún, tí ìṣòro ìsoríkọ́ di àìsàn bára kú fún ìyá rẹ̀, sọ pé: “Má ṣe fojú kéré agbára tí gbígbàdúrà fún àwọn ẹni náà àti gbígbàdúrà pẹ̀lú àwọn àti ìdílé wọ́n ní.”
Òótọ́ ni, ìrànlọ́wọ́ tó tọ́ lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ gan-an ni láti kojú másùnmáwo tí àìsàn bára kú ń fà. Bíbélì sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Ọ̀rẹ́ gidi ni alábàákẹ́gbẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, arákùnrin ni a sì bí láti ṣàjọpín wàhálà ẹni.”—Òwe 17:17, The New English Bible
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Bí Àìsàn Náà Bá La Ikú Lọ
Àwọn ìdílé kan lè máà fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ikú tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ẹni tí wọ́n fẹ́ràn tí àìsàn bára ku ń ṣe. Bó ti wù kó rí, ìwé Caring—How to Cope sọ pé, “bí ẹ bá mọ ohun tó yẹ kí ẹ máa retí àti ohun tó yẹ kí ẹ ṣe, ó lè ṣèrànwọ́ láti dín ìpayà kù.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òfin àti àṣà àdúgbò lè jẹ́ kí àwọn ìgbésẹ̀ pàtó tí ẹ lè gbé yàtọ̀, àmọ́ àwọn àbá díẹ̀ rèé nísàlẹ̀ yìí tí ìdílé lè gbé yẹ̀ wò nígbà tí wọ́n bá ń tọ́jú ẹni tí wọ́n fẹ́ràn nílé, tí àìsàn rẹ̀ yóò la ikú lọ.
Ohun Tí Ẹ Ó Ṣe Ṣáájú Àkókò
1. Ẹ béèrè lọ́wọ́ dókítà nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ àti wákàtí tí yóò kẹ́yìn ìgbésí ayé aláìsàn náà àti ohun tó yẹ kí ẹ ṣe tó bá ṣẹlẹ̀ pé òru ló kú.
2. Ẹ kọ orúkọ àwọn tí ẹ fẹ́ sọ nípa ikú rẹ̀ fún.
3. Ẹ jíròrò nípa bí ẹ ó ṣe sìnkú rẹ̀:
• Báwo ni aláìsàn náà ṣe fẹ́ kí ẹ ṣe é?
• Ṣé ẹ fẹ́ sìnkú rẹ̀ ni àbí ẹ fẹ́ sun ún? Ẹ ṣèfiwéra iye tí onírúurú àwọn tí ń bójú tó ìsìnkú ń gbà àti bí wọ́n ṣe ń ṣe é.
• Ìgbà wo ló yẹ kí ẹ fi ìsìnkú sí? Ẹ ṣètò kí àwọn ẹbí tó wà ní ìdálẹ̀ lè dé bá ìsìnkú.
• Ta ni yóò sọ àsọyé ìsìnkú tàbí àsọyé ìrántí ẹni tó kú?
• Ibo ni ẹ óò ti ṣe é?
4. Bí aláìsàn náà ò bá tiẹ̀ lè sọ̀rọ̀, ó ṣì lè máa gbọ́ ohun tí ẹ ń sọ àti ohun tí ẹ ń ṣe nítòsí rẹ̀. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má lọ sọ ohun tí ẹ ò fẹ́ kó gbọ́ níwájú ẹ̀. Ẹ lè máa fi í lọ́kàn balẹ̀ nípa sísọ̀rọ̀ tí yóò tù ú lára àti nípa dídì í lọ́wọ́ mú.
Bí Ẹni Tí Ẹ Fẹ́ràn Náà Bá Kú
Àwọn ohun díẹ̀ tí àwọn ẹlòmíràn lè ṣe láti ran ìdílé náà lọ́wọ́ nìyí:
1. Ẹ fún ìdílé náà láyè dáadáa kí wọ́n lè dá wà pẹ̀lú òkú náà kí wọ́n baà lè bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ bí wọn óò ṣe fara da ikú ẹni náà.
2. Ẹ gbàdúrà pẹ̀lú ìdílé náà.
3. Bí ìdílé náà bá ti ṣe tán, wọ́n lè fẹ́ kí àwọn èèyàn ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bá wọn fọ̀rọ̀ náà tó àwọn tí a tò sísàlẹ̀ yìí létí:
• Dókítà tí yóò ṣàyẹ̀wò láti rí i pé ẹni náà kú lóòótọ́, kó sì kọ ìwé ẹ̀rí pé ẹni náà ti kú.
• Ẹni tí ń sìnkú, mọ́ṣúárì, tàbí ilé iṣẹ́ tí ń báni sun òkú, láti bójú tó òkú náà.
• Àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́. (O lè fọgbọ́n sọ báyìí pé: “Nítorí ọ̀ràn [sọ orúkọ aláìsàn náà] ni mo ṣe tẹ̀ yín láago. Ó dùn mí láti sọ fún yín pé nǹkan burúkú ti ṣẹlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe mọ̀, ó pẹ́ tí [dárúkọ àìsàn náà] ti ń ṣe é, ó ti wá kú báyìí [sọ ìgbà tó kú àti ibi tó kú sí].”
• Ilé iṣẹ́ ìwé ìròyìn, láti fi ikú ẹni náà tó wọn létí bí ìdílé bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.
4. Ìdílé náà lè fẹ́ kí ẹnì kan wà pẹ̀lú àwọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe gbogbo ètò nípa ìsìnkú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ó yẹ kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé sapá láti gbé ìgbésí ayé tó bójú mu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Gbígbàdúrà pẹ̀lú ìdílé náà lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro náà