ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/8 ojú ìwé 3-4
  • Ìjónírúurú Aláìlópin Lórí Ilẹ̀ Ayé—Báwo Ló Ṣe Déhìn-ín?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjónírúurú Aláìlópin Lórí Ilẹ̀ Ayé—Báwo Ló Ṣe Déhìn-ín?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ẹyẹ Àgbàyanu
  • Onírúurú Fífani-Lọ́kànmọ́ra ti Àwọn Ewéko
  • Àwọn Òkun Tí Ó Ní Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ Ohun Alààyè Nínú
  • Ọpọlọ Kíkàmàmà Náà
  • Ọlọ́run—Eléèṣì Tàbí Ẹlẹ́dàá?
    Jí!—1997
  • Ta Ni Ó Lè Sọ Fun Wa?
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Bi A Ṣe Lè Mọ̀ Pe Ọlọrun kan Wà
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
Jí!—1997
g97 5/8 ojú ìwé 3-4

Ìjónírúurú Aláìlópin Lórí Ilẹ̀ Ayé—Báwo Ló Ṣe Déhìn-ín?

LÁRA iye irú ọ̀wọ́ ohun alààyè tí kì í ṣe ewéko, tí ó lé ní mílíọ̀nù 1.5, tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ì sọ lórúkọ, nǹkan bíi mílíọ̀nù kan jẹ́ kòkòrò. Yóò gba 6,000 ojú ewé inú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ láti to gbogbo kòkòrò tí a mọ̀ sí! Báwo ni àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí ṣe pilẹ̀ ṣẹ̀? Èé ti rí tí wọ́n fi jẹ́ onírúurú tí kò lópin bẹ́ẹ̀? Èyí ha jẹ́ ìyọrísí èèṣì aláìlọ́gbọ́n-nínú, nínú èyí tí ìṣẹ̀dá ti ń “ṣèèṣì ṣàṣeyọrí” ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìgbà bí? Tàbí ó jẹ́ nípasẹ̀ àpilẹ̀ṣe?

Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ kí a kíyè sí díẹ̀ lára àwọn onírúurú ohun alààyè míràn tí ó wà lórí pílánẹ́ẹ̀tì wa ní ṣókí.

Àwọn Ẹyẹ Àgbàyanu

Àwọn ẹyẹ tí a ṣẹ̀dá lọ́nà àgbàyanu, tí iye oríṣiríṣi irú ọ̀wọ́ wọn lé ní 9,000 ńkọ́? Àwọn ẹyẹ akùnyùnmù mélòó kan kéré tó ìwọ̀n kòkòrò oyin ńlá, síbẹ̀, wọ́n ń fi ìjáfáfá òun ìrọ̀rùn àti ọlá ńlá fò ju ọkọ̀ hẹlikópítà, tí a fi ìmọ̀ ẹ̀rọ gíga jù lọ ṣe, lọ. Àwọn ẹyẹ mìíràn ń ṣí kiri ní fífo ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà lọ́dọọdún, bí ẹyẹ tern ti ilẹ̀ olótùútù tí ń fo iye tí ó pọ̀ tó 35,000 kìlómítà nínú ìrìn tàlọtàbọ̀ kọ̀ọ̀kan. Kò ní ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà, kò ní àwọn ohun èlò àfimọ̀nà, síbẹ̀, ó ń gúnlẹ̀ síbi tó ń lọ láìṣìnà. Agbára ìṣe àdánidá yìí ha wà nípasẹ̀ èèṣì tàbí nípasẹ̀ àpilẹ̀ṣe ni bí?

Onírúurú Fífani-Lọ́kànmọ́ra ti Àwọn Ewéko

Ní àfikún, onírúurú rẹpẹtẹ àti ẹwà àwọn ewéko tún wà—irú ọ̀wọ́ àwọn ewéko lé ní 350,000. Nǹkan bí 250,000 lára ìwọ̀nyí ń yọ òdòdó! Ohun alààyè títóbi jù lọ lórí ilẹ̀ ayé—òmìrán igi sequoia—jẹ́ ewéko.

Oríṣi òdòdó mélòó ní ń hù nínú ọgbà rẹ tàbí ní àgbègbè rẹ? Ẹwà, ìbáramudélẹ̀, àti nígbà púpọ̀, òórùn ìtasánsán àwọn òdòdó wọ̀nyí—láti orí òdòdó aṣálẹ̀ tí ó kéré jù lọ, òdòdó daisy, tàbí òdòdó buttercup, títí dé orí òdòdó orchid, àti onírúurú dídíjú ti ó ní—ń múni ṣe kàyéfì. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a béèrè pé: Báwo ni wọ́n ṣe di ohun tí ó wà? Nípasẹ̀ èèṣì ni tàbí nípasẹ̀ àpilẹ̀ṣe?

Àwọn Òkun Tí Ó Ní Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ Ohun Alààyè Nínú

Àwọn oríṣiríṣi ohun alààyè inú àwọn odò, adágún, àti àwọn òkun àgbáyé ńkọ́? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé nǹkan bí 8,400 irú ọ̀wọ́ ẹja la mọ̀ tí ń gbé inú omi tí kò níyọ̀, tí àwọn tí ń gbé inú òkun sì jẹ́ nǹkan bí 13,300. Èyí tí ó kéré jù lọ nínú ìwọ̀nyí ni ẹja goby tí a rí nínú Òkun Íńdíà. Ó gùn ní kìkì nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà kan. Èyí tí ó tóbi jù lọ ni ẹja ekurá àbùùbùtán, tí ó lè gùn tó mítà 18. Iye àwọn irú ọ̀wọ́ tí a sọ yìí kò kan àwọn ẹ̀dá tí kò léegun ẹ̀yìn tàbí àwọn irú ọ̀wọ́ tí a óò ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí wọn!

Ọpọlọ Kíkàmàmà Náà

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọpọlọ ẹ̀dá ènìyàn—tí ó ní bílíọ̀nù mẹ́wàá iṣan ọpọlọ, ó kéré tán, tí ó ṣeé ṣe kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojúkò iṣan ọpọlọ tí ó lé ní 1,000—kàmàmà. Onímọ̀ nípa ètò ìgbékalẹ̀ àti àrùn iṣan ara, Dókítà Richard Restak, sọ pé: “Àròpọ̀ ìsokọ́ra tí ó wà nínú àgbékalẹ̀ títóbi ti ìgbékalẹ̀ iṣan inú ọpọlọ pọ̀ lọ́nà tí kò ṣeé finú wòye.” (The Brain) Ó ṣàfikún pé: “Ó ṣeé ṣe kí iye àwọn ojúkò iṣan ọpọlọ wà láàárín tírílíọ̀nù mẹ́wàá sí ọgọ́rùn-ún tírílíọ̀nù nínú ọpọlọ.” Lẹ́yìn náà ni ó wá béèrè ìbéèrè ṣíṣekókó kan pé: “Báwo ni ẹ̀yà ara kan bí ọpọlọ, tí ó ní bílíọ̀nù mẹ́wàá sí ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù sẹ́ẹ̀lì, ṣe lè dàgbà láti ara sẹ́ẹ̀lì kan ṣoṣo, ẹyin?” Ọpọlọ ha jẹ́ ìyọrísí àwọn èèṣì àti àkọsẹ̀bá àbínibí tí kò lọ́wọ́ ẹ̀dá kankan nínú bí? Tàbí ìwéwèé onílàákàyè kan ni ó ṣe é bí?

Bẹ́ẹ̀ ni, báwo ni ìjónírúurú ìwàláàyè àti iṣẹ́ ọnà tí ó jọ pé kò lópin náà ṣe wáyé? Wọ́n ha ti fi kọ́ ọ pé èyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn èèṣì, ti dányìíwò, ti èyíjẹ-eyíòjẹ nínú tẹ́tẹ́ oríire èèṣì aláìlọ́gbọ́n-nínú ti ẹfolúṣọ̀n lásán bí? Nígbà náà, máa bá kíkà nìṣó, kí o lè rí àwọn ìbéèrè tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mélòó kan ń fi gbogbo òótọ́ inú béèrè, nípa àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n, tí a ti tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ gbogbo ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa ìwàláàyè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Bí kámẹ́rà kan lásán bá nílò olùwéwèé kan, ojú ẹ̀dá ènìyàn tí ó díjú lọ́nà gíga ńkọ́?

Àgbègbè Lens

(Tí A Sọ Di Ńlá)

“Aqueous humor”

“Pupil”

“Cornea”

“Lens”

“Iris”

Ẹran ara “cilia”

“Lens”

Odindi Ojú

“Vitreous humor”

Iṣan ìríran

Rẹ̀tínà

“Choroid”

“Sclera”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́