ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/8 ojú ìwé 13-17
  • Ọlọ́run—Eléèṣì Tàbí Ẹlẹ́dàá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run—Eléèṣì Tàbí Ẹlẹ́dàá?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ojútùú sí “Àdììtú” Náà
  • “Ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ Àwọn Èèṣì Rẹpẹtẹ”
  • Ìdáhùn Tí Bíbélì Pèsè
  • Ìjónírúurú Aláìlópin Lórí Ilẹ̀ Ayé—Báwo Ló Ṣe Déhìn-ín?
    Jí!—1997
  • Ta Ni Ó Lè Sọ Fun Wa?
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Ẹlẹ́dàá Lè Mú Kí Ayé Rẹ Nítumọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìṣẹ̀dá?
    Jí!—2006
Jí!—1997
g97 5/8 ojú ìwé 13-17

Ọlọ́run—Eléèṣì Tàbí Ẹlẹ́dàá?

“KÒ SÍ iyè méjì pé ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni wọ́n ta ko oríṣi àlàyé èyíkéyìí nípa ohun tí kò ṣeé fojú rí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé nípa ohun tẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí. Wọ́n ń pẹ̀gàn èrò náà pé ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run kan wà, tàbí kí ìlànà ìṣẹ̀dá kan tí kì í ṣe ẹni gidi kan wà . . . Ní tèmi, n kò fara mọ́ ìpẹ̀gàn wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni Paul Davies, ọ̀jọ̀gbọ́n ìmọ̀ físíìsì oníṣirò ní Yunifásítì Adelaide, Gúúsù Australia, ṣe sọ nínú ìwé rẹ̀, The Mind of God.

Davies tún sọ pé: “Ìwádìí àfìṣọ́raṣe kan tọ́ka sí i pé àwọn òfin àgbáálá ayé bá ìyọjáde àwọn ohun alààyè dídíjú àti onírúurú mu lọ́nà gbígbàfiyèsí. Ní ti àwọn ohun alààyè, ó jọ pé wíwà tí wọ́n wà sinmi lórí iye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kòńgẹ́ àrìnnàkore mélòó kan tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí ti kéde pé wọ́n jẹ́ aṣeni-níkàyéfì gidigidi.”

Ó tún sọ síwájú sí i pé: “Ìwákiri lọ́nà ti sáyẹ́ǹsì jẹ́ ìrìn àjò kan sínú ohun tí a kò mọ̀. . . . Àmọ́, jálẹ̀jálẹ̀ ìwákiri yìí ni kókó tí ń bá a lọ náà wà, ti làákàyè àti ìṣètò. A óò rí i pé, àwọn òfin ìṣirò tí ó ṣe gúnmọ́, tí ó wé mọ́ ara wọn fún ìjáfáfá àti ìsopọ̀sọ̀kan ni ó gbé ìwàlétòlétò àgbáyé yìí ró. Àwọn òfin náà rọrùn lọ́nà rírẹwà.”

Davies parí ọ̀rọ̀ ní wíwí pé: “Ìdí náà gan-an tí Homo sapiens fi gbọ́dọ̀ ní agbára láti mọ àwọn ànímọ́ àgbáálá ayé jẹ́ àdììtú jíjinlẹ̀ kan. . . . N kò lè gbà gbọ́ pé wíwà tí a wà nínú àgbáálá ayé yìí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn kan tí a kò pinnu tẹ́lẹ̀, èèṣì kan nínú ìtàn, àìṣedéédéé kan tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ìforígbárí lílekoko kan nínú àgbáyé. A wà ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àgbáálá ayé. . . . Ní tòótọ́, a pète wa láti wà níhìn-ín.” Bí ó ti wù kí ó rí, Davies kò dórí ìparí èrò náà pé Olùpète kan wà, Ọlọ́run kan. Ṣùgbọ́n orí ìparí èrò wo ni ìwọ dé? A ha pète aráyé láti wà níhìn-ín bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni ó pète pé kí a wà níhìn-ín?

Àwọn Ojútùú sí “Àdììtú” Náà

Nínú Bíbélì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pèsè amọ̀nà kan nípa lílóye ohun tí Davies pè ní “àdììtú jíjinlẹ̀ kan.” Pọ́ọ̀lù ṣàfihàn bí Ọlọ́run ṣe fi ara rẹ̀ hàn pé: “Nítorí pé ohun tí a lè mọ̀ nípa Ọlọ́run fara hàn kedere láàárín wọn [“àwọn ènìyàn tí wọ́n ń tẹ òtítọ́ rì”], nítorí Ọlọ́run mú kí ó fara hàn kedere sí wọn. Nítorí àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní àwíjàre.” (Róòmù 1:18-20)a Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí ìjónírúurú láìlópin àwọn ohun alààyè, ìdíjúpọ̀ wọn kíkàmàmà, ọ̀nà ìgbékalẹ̀ wọn kíkọyọyọ, sún ẹnì kan tí ó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, tí ó sì lọ́wọ̀, láti gbà pé agbára, làákàyè, tàbí iyè inú gígalọ́lá kan, tí ó ju ohunkóhun tí ènìyàn tí ì mọ̀ rí lọ, wà.—Orin Dáfídì 8:3, 4.

Àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù síwájú sí i nípa àwọn tí wọ́n kọ Ọlọ́run sílẹ̀ ń fúnni ní ìdí láti sinmẹ̀dọ̀, kí a sì baralẹ̀ ronú, pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fi ìtẹnumọ́ kéde pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, wọ́n di òmùgọ̀ . . . , àní àwọn wọnnì tí wọ́n fi irọ́ ṣe pàṣípààrọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń júbà, tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn [ọlọ́wọ̀] fún ìṣẹ̀dá dípò Ẹni náà tí ó ṣẹ̀dá, tí ó jẹ́ ẹni ìbùkún títí láé. Àmín.” (Róòmù 1:22, 25) Dájúdájú, àwọn tí ń júbà fún “ẹ̀dá,” tí wọ́n sì kọ Ọlọ́run sílẹ̀, kò gbọ́n ní ojú ìwòye Jèhófà. Bí ìdàrúdàpọ̀ inú àwọn àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n ṣe ń dè wọ́n lọ́nà, wọ́n kùnà láti mọ Ẹlẹ́dàá náà àti àìṣeélóye òun ìgbékalẹ̀ ìṣẹ̀dá rẹ̀.

“Ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ Àwọn Èèṣì Rẹpẹtẹ”

Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé pé: “Láìsí ìgbàgbọ́, kò ṣeé ṣe láti wù ú [Ọlọ́run] dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun di olùsẹ̀san fún àwọn wọnnì tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ìgbàgbọ́ tí a gbé karí ìmọ̀ pípéye, kì í ṣe ìgbàgbọ́ oréfèé, lè mú wa lóye ìdí tí a fi wà. (Kólósè 1:9, 10) Dájúdájú, ó jẹ́ ọ̀ràn ìgbàgbọ́ oréfèé nígbà tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan bá ń fẹ́ kí a gbà gbọ́ pé ìwàláàyè wà, nítorí tí ó jọ “bíi pé a ti jẹ tẹ́tẹ́ oríire aláàádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là nígbà àádọ́ta ọ̀kẹ́ léraléra.”

Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ọmọ ilẹ̀ Britain náà, Fred Hoyle, dábàá èrò orí pé àwọn ìyírapadà átọ̀mù tí ó ṣamọ̀nà sí ìmújáde àwọn èròjà méjì tí ó jẹ́ kòṣeémánìí fún ìwàláàyè, èròjà carbon àti afẹ́fẹ́ oxygen, ṣàmújáde ìwọ̀n wíwàdéédéé bíbáramu nínú àwọn èròjà wọ̀nyí kìkì nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ oríire kan. “Nípasẹ̀ oríire,” ìgbésẹ̀ náà yọrí sí èròjà carbon.—The Intelligent Universe; The Mind of God.

Ó fúnni ní àpẹẹrẹ mìíràn pé: “Bí àpapọ̀ ìwọ̀n ìwúwo proton àti electron bá ní láti lọ sókè lójijì, kí ó sì pọ̀ díẹ̀ ju ti neutron lọ, dípò kí ó kéré díẹ̀ sí ti neutron, ìyọrísí rẹ̀ yóò bani nínú jẹ́. . . . Jákèjádò Àgbáálá Ayé ni gbogbo átọ̀mù afẹ́fẹ́ hydrogen yóò fọ́ sí wẹ́wẹ́ lọ́gán, tí yóò sì di neutron àti neutrino. Láìsí agbára átọ̀mù, Oòrùn yóò kógbá sílé, yóò sì fọ́ yángá.” Ohun kan náà ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù àwọn ìràwọ̀ míràn ní àgbáálá ayé.

Hoyle parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ . . . àwọn èèṣì híhàn gbangba tí kì í ṣe abẹ̀mí, èyí tí ìwàláàyè tí ó sinmi lórí èròjà carbon àti nítorí náà, tí ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn kò lè ṣeé ṣe láìsí i, gbòòrò, ó sì pọ̀ rẹpẹtẹ.” Ó wí pé: “Ó jọ pé irú àwọn nǹkan [kòṣeémánìí ìgbésí ayé] bẹ́ẹ̀ wà káàkiri nínú ìṣètò àgbáyé àdánidá bí apá kan tí ń bá a lọ nínú àwọn èèṣì ìrìnnàkore. Ṣùgbọ́n àwọn ìṣekòńgẹ́ títagọngọ tí kò ṣeé máà ní nínú ìgbésí ayé wọ̀nyí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jọ pé, a nílò àwọn àlàyé díẹ̀ nípa wọn.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.

Ó tún sọ pé: “Ìṣòro náà jẹ́ ti pípinnu yálà àwọn ìmúbáǹkanmu tí ó ṣe kòńgẹ́ lọ́nà híhàn gbangba wọ̀nyí jẹ́ èèṣì ní ti gidi tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ pinnu bóyá ìwàláàyè jẹ́ èèṣì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Kò sí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kankan tí ń fẹ́ láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀, ó yẹ kí a béèrè rẹ̀. Àwọn ìmúbáǹkanmu náà ha lè jẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀ṣe onílàákàyè bí?”

Paul Davies kọ̀wé pé: “‘Ọ̀wọ́ àwọn èèṣì ṣíṣàjèjì’ yí wọ Hoyle lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ní láti sọ pé ńṣe ni ó dà bíi pé ‘a mọ̀ọ́mọ̀ wéwèé àwọn òfin físíìsì alátọ̀mù pẹ̀lú ipa tí wọ́n ń ní nínú àwọn ìràwọ̀ lọ́kàn.’” Ta ni, tàbí kí ni ó ṣokùnfà “ọ̀wọ́ àwọn èèṣì [ìrìnnàkore] ṣíṣàjèjì” yí? Ta ni, tàbí kí ni ó mú pílánẹ́ẹ̀tì kékeré, tí ó kún fún onírúurú àìlópin àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ewéko àti ẹ̀dá kíkọyọyọ, yìí jáde?

Ìdáhùn Tí Bíbélì Pèsè

Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni onísáàmù náà fi kọ̀wé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún sẹ́yìn pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! Gbogbo wọn ni o fi ọgbọ́n ṣe. Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ. Ní ti òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì gbòòrò gan-an, ibẹ̀ ni àwọn ohun tí ń rìn ká wà láìníye, àwọn ẹ̀dá alààyè, èyí tí ó kéré àti èyí tí ó tóbi.”—Orin Dáfídì 104:24, 25, NW.

Àpọ́sítélì Jòhánù wí pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣípayá 4:11) Ìwàláàyè kì í ṣe àbáyọrí èèṣì aláìlọ́gbọ́n-nínú, ti tẹ́tẹ́ oríire àgbáyé kan tí ó ṣèèṣì mú àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ohun alààyè jáde gẹ́gẹ́ bí ajẹtẹ́tẹ́.

Òtítọ́ rírọrùn náà ni pé, Ọlọ́run “dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú [rẹ̀] ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Jésù Kristi fúnra rẹ̀ sọ fún àwọn Farisí pé: “Ẹ̀yin kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo?” Jésù mọ Ẹlẹ́dàá náà! Gẹ́gẹ́ bí Àgbà Òṣìṣẹ́ fún Jèhófà, òun ti wà pẹ̀lú Rẹ̀ nígbà ìṣẹ̀dá.—Mátíù 19:4; Òwe 8:22-31.

Bí ó ti wù kí ó rí, ó gba ìgbàgbọ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ láti mọ òtítọ́ ìpìlẹ̀ yí nípa Ẹlẹ́dàá, kí a sì tẹ́wọ́ gbà á. Ìgbàgbọ́ yìí kì í ṣe ìgbàgbọ́ oréfèé ti ìfọ́jú. A gbé e karí ojúlówó ẹ̀rí ṣíṣe kedere, tí ó ṣeé fojú rí. Bẹ́ẹ̀ ni, “Àwọn ànímọ́ [Ọlọ́run] tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú.”—Róòmù 1:20.

Pẹ̀lú ìwọ̀nba ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí a ní lọ́wọ́lọ́wọ́, a kò lè ṣàlàyé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ṣẹ̀dá. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ gbà pé ní báyìí ná, a kò lè mọ̀ tàbí kí a lóye ohun gbogbo nípa orírun ìwàláàyè. A ń rán wa létí èyí nígbà tí a bá ń ka ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé: “Ìrònú yín kì í ṣe ìrònú mi, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi kì í ṣe ọ̀nà yín . . . Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.”—Aísáyà 55:8, 9, NW.

Yíyàn náà jẹ́ tìrẹ: yálà ìgbàgbọ́ oréfèé nínú ẹfolúṣọ̀n onírìnnàkore tó fọ́jú, àwọn àìlóǹkà èèṣì tí a sọ pé ó kẹ́sẹ járí níkẹyìn, tàbí ìgbàgbọ́ nínú Olùṣàgbékalẹ̀-Ẹlẹ́dàá-Olùpète náà, Jèhófà Ọlọ́run. Wòlíì tí a mí sí náà sọ ọ́ lọ́nà yíyẹ pé: “Jèhófà, Ẹlẹ́dàá àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé, jẹ́ Ọlọ́run fún àkókò tí ó lọ kánrin. Àárẹ̀ kì í mú un, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a. Kò sí àwárí òye rẹ̀.”—Aísáyà 40:28, NW.

Nítorí náà, kí ni ìwọ yóò gbà gbọ́? Ìpinnu rẹ yóò mú gbankọgbì ìyàtọ̀ wá nínú ìfojúsọ́nà rẹ fún ọjọ́ ọ̀la. Bí ẹfolúṣọ̀n bá jẹ́ òtítọ́, nígbà náà, ikú yóò jẹ́ kókó ọ̀ràn ìgbàgbé pátápátá, láìka àwọn ìjiyàn afojújòótọ́ lílọ́júpọ̀ ti ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì sí, èyí tí ó gbìyànjú láti mú “ọkàn” wọnú ẹfolúṣọ̀n.b Ènìyàn kò ní ọkàn tí kò lè kú láti bomi pa ìrònú tí ń páni láyà nípa ikú tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4, 20.

Bí a bá gbà pé Bíbélì jẹ́ òtítọ́, àti pé Ọlọ́run alààyè ni Ẹlẹ́dàá, nígbà náà, ìlérí àjíǹde wà sí ìyè ayérayé, ìyè pípé, lórí ilẹ̀ ayé kan tí a mú pa dà sí ipò ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti ìbáradọ́gba àti ìṣọ̀kan. (Jòhánù 5:28, 29) Níbo ni ìwọ yóò gbé ìgbàgbọ́ rẹ kà? Lórí èèṣì àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n tí Darwin gbé kalẹ̀, tí kò ṣeé gbà gbọ́ ni bí? Tàbí nínú Ẹlẹ́dàá, tí ó ti fi ète gbégbèésẹ̀, tí ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó?c

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Láti ìgbà tí Ọlọ́run ti ṣẹ̀dá àgbáyé, agbára ayérayé àti ìjọ́lọ́run rẹ̀—bí ó ti wù kí ó má ṣeé rí tó—ti wà níbẹ̀, kí òye inú lè rí i nínú àwọn ohun tí ó ti dá.”—Róòmù 1:20, Jerusalem Bible.

b Wo “Wíwo Ayé,” ojú ìwé 28, “Póòpù Tún Fìdí Ẹ̀rí Ẹfolúṣọ̀n Múlẹ̀.”

c Fún ìjíròrò kíkún rẹ́rẹ́ lórí ọ̀ràn náà, wo ìwé náà, Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe jáde.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]

Lọ́nà yí, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n mélòó kan sọ pé wíwà tí a wà lórí ilẹ̀ ayé jọ “bíi pé a ti jẹ tẹ́tẹ́ oríire aláàádọ́ta ọ̀kẹ́ dọ́là nígbà àádọ́ta ọ̀kẹ́ léraléra.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ìjónírúurú àti Ìgbékalẹ̀ Tí Kò Lópin

Àwọn Kòkòrò Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣàwárí 7,000 sí 10,000 àwọn irú ọ̀wọ́ kòkòrò tuntun lọ́dọọdún.” Síbẹ̀, “ó ṣeé ṣe kí mílíọ̀nù 1 sí 10 àwọn irú ọ̀wọ́ ṣì wà tí a kò tí ì ṣàwárí wọn.” Ìwé agbéròyìnjáde Faransé náà, Le Monde, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé agbéròyìnjáde Guardian Weekly, nínú àpilẹ̀kọ kan láti ọwọ́ Catherine Vincent, sọ nípa àwọn irú ọ̀wọ́ tí a ti ṣàkọsílẹ̀ nípa wọn, pé wọ́n jẹ́ “iye” kan “tí ó kéré jù, bí a bá fi wé iye pàtó gan-an . . . tí a fojú díwọ̀n sí láàárín mílíọ̀nù 5 sí 50 mílíọ̀nù, tí ó ṣòro láti gbà gbọ́.”

Ronú nípa àwọn àgbàyanu kòkòrò—àwọn oyin, èèrà, agbọ́n, labalábá, aáyán, kòkòrò ladybug, dánádáná, ikán, àfòpiná, eṣinṣin, lámilámi, yànmùyánmú, kòkòrò silverfish, ẹlẹ́ǹgà, iná, ìrẹ̀, yọ̀rọ̀—ká wulẹ̀ fi ìwọ̀nyẹn bẹ̀rẹ̀! Ó jọ pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kò lópin.

Àwọn Ẹyẹ Kí ni a lè sọ nípa ẹyẹ kan tí kò wúwo tó gíráàmù 28? “Fojú inú wò ó, bí ó ṣe ń kó kiri nínú ìrìn àjò tí ó lé ní 10,000 máìlì [16,000 kìlómítà] lọ́dún kan, láti ibi igbó orí òkè gíga ní Alaska lọ sí àwọn igbó kìjikìji ti Gúúsù America, tí ó sì ń pa dà, tí ó ń yára fò kọjá lórí ibi ṣóńṣó àwọn òkè ńláńlá, ní yíyẹra fún àwọn ilé àwòṣífìlà ní àwọn ìlú ńláńlá, tí ó sì ń ré kọjá àwọn alagbalúgbú omi Òkun Àtìláńtíìkì àti ti Ìyawọlẹ̀ Omi ti Mexico.” Ẹyẹ àràmàǹdà wo lèyí? “Ẹyẹ ìbákà olórí dúdú [Dendroica striata], alágbára ẹyẹ kan, tí ìgboyà yíyọrí ọlá rẹ̀ láti rìnrìn àjò fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé bá táákà láàárín àwọn ẹyẹ orí ilẹ̀ ní Àríwá America.” (Book of North American Birds) Lẹ́ẹ̀kan sí i, a béèrè pé: Èyí ha jẹ́ àbájáde ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèṣì àdánidá tí ó wulẹ̀ kẹ́sẹ járí lásán bí? Tàbí ó jẹ́ ìyanu kan nínú ìwéwèé onílàákàyè?

Fi àwọn ẹyẹ tí ó ní àkójọ àwọn orin tí ó dà bí aláìlópin: olóbùró, tí a mọ̀ jákèjádò ilẹ̀ Europe àti ní àwọn apá kan ilẹ̀ Áfíríkà àti Éṣíà fún ìró rẹ̀ tí ń múni láyọ̀; ẹyẹ mockingbird ti ìhà àríwá láti Àríwá America, ẹyẹ kan tí ó jẹ́ “ọ̀jáfáfá asínnijẹ, tí ó sì máa ń fi àwọn àpólà ohùn tí ó kọ́ sórí ṣe apá kan orin rẹ̀”; ẹyẹ lyrebird títayọlọ́lá ti Australia, tí ó máa ń kọ “orin gígalọ́lá, tí ó ní ìsínnijẹ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ yíyanilẹ́nu nínú,” kún àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí.—Birds of the World.

Ní àfikún sí i, ìgúnrégé ìgbékalẹ̀ àwọn àwọ̀ àti apá àti ìyẹ́ ọ̀pọ̀ ẹyẹ ń ṣeni ní kàyéfì. Fi ìjáfáfá wọn níbi híhun ìtẹ́ àti ṣíṣe ìtẹ́, yálà lórí ilẹ̀, lórí ibi dídagun, tàbí lórí àwọn igi kún èyí. Ó dájú pé irú làákàyè àbínibí bẹ́ẹ̀ yóò wọ àwọn ènìyàn onírẹ̀lẹ̀ lọ́kàn. Báwo ni wọn ṣe dé? Nípasẹ̀ èèṣì ni tàbí nípasẹ̀ àpilẹ̀ṣe?

Ọpọlọ Ẹ̀dá Ènìyàn “Ó ṣeé ṣe kí a ní ojúkò iṣan ọpọlọ tí ó wà láàárín tírílíọ̀nù mẹ́wàá sí ọgọ́rùn-ún tírílíọ̀nù nínú ọpọlọ, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń ṣiṣẹ́ bí ẹ̀rọ ìṣèṣirò tí ń gba àwọn àmì ìsọfúnni tí ń dé bí ìsúnniṣe oníná mànàmáná wọlé.” (The Brain) A ní ìtẹ̀sí láti má ṣe ka ọpọlọ sí, síbẹ̀, ó jẹ́ ìdìpọ̀ ìgbékalẹ̀ kan tí a fi sínú agbárí, tí a sì ń dáàbò bò ó níbẹ̀. Báwo ni a ṣe di ẹni tí ó ní ẹ̀yà ara yìí, tí ń jẹ́ kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn lè máa ronú, kí wọ́n rorí, kí wọ́n sì máa sọ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èdè? Ṣé nípasẹ̀ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèṣì tó kẹ́sẹ járí ni? Tàbí nípasẹ̀ ìwéwèé ọlọ́gbọ́n-nínú?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Àwòrán Òde Ọpọlọ Tí A Mú Rọrùn

Awọ agbàsọfúnni tí ó bo ọpọlọ

Ó máa ń ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ìsúnniṣe ìmọ̀lára láti gbogbo ara

Awẹ́ ìríran

Ó ń ṣàtúpalẹ̀ àwọn àmì ìríran

Cerebellum

Ó ń darí agbára ìséraró àti àjọṣe àwọn ẹ̀yà ara

Awọ tí ó bo ẹ̀ka ìṣiṣẹ́ iṣu ara

Ó ń darí àjọṣe àwọn iṣu ara

Awọ ìdarí ìgbéṣẹ́ṣe

Ó ń ṣèrànwọ́ láti darí ìyírapadà àmọ̀ọ́mọ̀ṣe

Awẹ́ apá iwájú

Ó ń ṣèrànwọ́ láti darí èrò ọkàn, ìmọ̀lára, ọ̀rọ̀ sísọ, ìyírapadà

Awẹ́ ìgbọ́ròó

Ó ń ṣàtúpalẹ̀ ìró; ó ń darí àwọn apá tí ó kan ìkẹ́kọ̀ọ́, ìrántí, èdè, ìmọ̀lára

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ìpẹ̀kun iṣan adarí- ìsọfúnni- jáde

Àwọn iṣan agbésọfúnni-kiri

Àwọn irun atàtaré-ìsọfúnni

Ojúkò iṣan ọpọlọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Sẹ́ẹ̀lì iṣan

Àwọn irun atàtaré-ìsọfúnni

Iṣan adarí-ìsọfúnni

Àwọn irun atàtaré-ìsọfúnni

Ojúkò iṣan ọpọlọ

Sẹ́ẹ̀lì iṣan

Iṣan adarí-ìsọfúnni-jáde

“Ó ṣeé ṣe kí àwọn ojúkò iṣan inú ọpọlọ wà láàárín tírílíọ̀nù mẹ́wàá sí ọgọ́rùn-ún tírílíọ̀nù, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ń ṣiṣẹ́ bí ẹ̀rọ ìṣèṣirò tín-ń-tín kan tí ń ṣàtòpọ̀ ìsọfúnni tí ń dé gẹ́gẹ́ bí ìsúnniṣe oníná mànàmáná.”—THE BRAIN

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Òṣùpá àti àwọn pílánẹ́ẹ̀tì: Fọ́tò NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́