Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nípa Ìṣẹ̀dá?
“Nígbà tí wọ́n dá ọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n sílẹ̀ ní kíláàsì wa, ó yàtọ̀ pátápátá gbáà sí gbogbo ohun tí wọ́n ti fi kọ́ mi. Wọ́n ṣàlàyé ẹ̀ bíi pé òótọ́ ni, ìyẹn sì dojú ọ̀rọ̀ náà rú mọ́ mi lọ́wọ́.”— Ryan, ọmọ ọdún méjìdínlógún.
“Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjìlá, ẹni tó nígbàgbọ́ jíjinlẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ni olùkọ́ mi. Kódà àmì Darwin, ẹni tó dá ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n sílẹ̀, wà lára ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀! Ìyẹn ló mú kí n máa lọ́ tìkọ̀ láti ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá.”— Tyler, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún.
“Jìnnìjìnnì bò mí nígbà tí tíṣà tó ń kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá sọ pé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ló kàn tá a máa kọ́. Mo mọ̀ pé á di dandan kí n ṣàlàyé ibi tí mo dúró sí lórí ọ̀ràn tó máa ń fa àríyànjiyàn yìí fáwọn ọmọ kíláàsì mi.”— Raquel, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá.
BÓYÁ, bíi ti Ryan, Tyler àti Raquel, ìwọ náà máa ń ṣàníyàn nígbà tọ́rọ̀ ẹfolúṣọ̀n bá wáyé nínú kíláàsì, nítorí pé o gbà pé Ọlọ́run ló “dá ohun gbogbo.” (Ìṣípayá 4:11) O rí àwọn nǹkan mèremère láyìíká ẹ tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá olóye kan wà. Àmọ́ ohun tó wà nínú ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ni ni pé ńṣe la kàn hú yọ, ohun tí tíṣà yín sì ń kọ́ ẹ náà nìyẹn. Ó wá lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kí nìwọ mọ̀ tí wàá fi máa bá àwọn táyé ń pè ní ògbógi jiyàn? Ojú wo sì làwọn ọmọ kíláàsì ẹ á fi máa wò ẹ́ nígbà tírú ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa . . . Ọlọ́run?
Báwọn ìbéèrè bí irú èyí bá ń yọ ẹ́ lẹ́nu, má mikàn! Ìwọ nìkan kọ́ lo gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dá. Òótọ́ tó wà ńbẹ̀ ni pé, a tiẹ̀ rí lára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ò gba ẹfolúṣọ̀n gbọ́. Ọ̀pọ̀ olùkọ́ gan-an ni ò gbà á gbọ́. Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó tó mẹ́rin lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ márùn-ún márùn-ún tó gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà, láìka ohun tó wà nínú ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ wọn sí!
Síbẹ̀, o lè bi ara ẹ léèrè pé, ‘Kí ni màá sọ tó bá di pé mo ní láti ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá?’ Mọ̀ dájú pé bí ẹ̀rù bá tiẹ̀ ń bà ẹ́ pàápàá, o ṣì lè fìgboyà ṣàlàyé ara ẹ. Àmọ́ ṣá o, ó máa gba pé kó o múra sílẹ̀ díẹ̀ o.
Yẹ Ohun Tó O Gbà Gbọ́ Wò!
Bó bá jẹ́ pé Kristẹni làwọn òbí ẹ, ó lè jẹ́ ohun tí wọ́n fi kọ́ ẹ ló mú kó o gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà. Àmọ́, bó o ṣe wá ń dàgbà sí i báyìí, o fẹ láti sin Ọlọ́run pẹ̀lú “agbára ìmọnúúrò” rẹ, kó o sì gbé ìgbàgbọ́ rẹ karí ìpìlẹ̀ tó dúró gbọn-in. (Róòmù 12:1) Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní níyànjú pé kí wọ́n “wádìí ohun gbogbo dájú.” (1 Tẹsalóníkà 5:21) Báwo lo ṣe lè yẹ ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá wò?
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ronú lórí ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ nípa Ọlọ́run: “Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá.” (Róòmù 1:20) Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn lọ́kàn ẹ, túbọ̀ ro àròjinlẹ̀ nípa ara àwa èèyàn, ilẹ̀ ayé, àgbáyé tó fẹ̀ lọ salalu, àtàwọn agbami òkun. Ro àròjinlẹ̀ nípa onírúurú kòkòrò, ewéko, àtàwọn ẹranko tí gbogbo wọn fani mọ́ra, tàbí àwọn ohun ìṣẹ̀dá èyíkéyìí tó bá ṣáà ti wù ẹ́. Lẹ́yìn náà ni kó o wá lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ láti fi bi ara ẹ léèrè pé, ‘Kí ló mú kí n gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá kan wà?’
Kí Sam, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá bàa lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ara àwa èèyàn ló fara balẹ̀ kíyè sí. Ó wá sọ pé: “Iṣẹ́ ńlá ni Ọlọ́run ṣe sára àwa ẹ̀dá, gbogbo ẹ̀yà ara ló sì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan. Kò tiẹ̀ sí ọ̀nà tára èèyàn lè gbà hú yọ ni!” Holly, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, gbà pẹ̀lú ohun tó sọ yìí. Òun náà wá sọ pé: “Látìgbà tí àyẹ̀wò dókítà ti fi hàn pé mo ní àrùn àtọ̀gbẹ, mo ti wá mọ ohun tó pọ̀ nípa bí ara èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀nà tí ẹ̀yà ara kékeré kan tó wà lábẹ́ ikùn tó ń jẹ́ pancreas, máa ń gbà ṣiṣẹ́ pabanbarì gan-an ni, iṣẹ́ ńlá ló ń ṣe láti mú kí ẹ̀jẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní káwọn ẹ̀yà ara yòókù sì máa ṣiṣẹ́ geerege.”
Àwọn ọ̀dọ́ míì tún gba apá ibòmíì wo ọ̀ràn náà. Jared, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, sọ pé: “Ní tèmi o, ẹ̀rí tó ga jù lọ tí mo ní lọ́wọ́ ni òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro náà pé ó ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti sin Ọlọ́run a sì máa ń fẹ́ sìn ín, tá a bá róhun tó lẹ́wà ó máa ń wù wá, bẹ́ẹ̀ la sì tún máa ń fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Ohun tí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n fi kọ́ni ni pé àwọn ànímọ́ yìí ò ṣe pàtàkì fún èèyàn láti máa wà láàyè. Àlàyé kan ṣoṣo tó mọ́gbọ́n dání lójú tèmi ni pé ẹnì kan ló dá wá sáyé, ṣe ló sì fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa.” Tyler, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí náà gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo bá ronú nípa ipa táwọn ewéko ń kó láti mú ká lè máa wà láàyè nìṣó, àti bí wọ́n ṣe wà lónírúurú lọ́nà àrà, ó máa ń dá mi lójú pé Ẹlẹ́dàá kan wá.”
Ó máa ń rọrùn láti sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá bó o bá ti ronú lórí ohun tó o fẹ́ sọ dáadáa, tí ohun tó o fẹ́ sọ náà sì ti dá ọ lójú. Nítorí náà, bíi ti Sam, Holly, Jared àti Tyler, wá àkókò díẹ̀ láti fi ronú lórí àgbàyanu iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, “gbọ́” ohun táwọn nǹkan wọ̀nyẹn “ń sọ” fún ẹ. Ó dájú pé ibi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù parí ọ̀rọ̀ sí ni ìwọ náà á parí ẹ̀ sí, ìyẹn ni pé kì í wulẹ̀ ṣe wíwà Ọlọ́run nìkan la lè ‘fi òye mọ̀ nípasẹ̀ àwọn ohun tó dá,’ a tún lè yára fi mọ àwọn ànímọ́ rẹ̀ pẹ̀lú.a
Mọ Ohun Tí Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an
Yàtọ̀ sí fífara balẹ̀ kíyè sí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti dá, kó o bàa lè ṣàlàyé ara ẹ dáadáa lórí ọ̀ràn ìṣẹ̀dá, ó tún yẹ kó o mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn náà gan-an. Kò sídìí láti máa jiyàn lórí àwọn nǹkan tí Bíbélì ò ṣàlàyé lé lórí ní tààràtà. Ìwọ gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
◼ Ìwé tí mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́ sáyẹ́ǹsì sọ pé ilẹ̀ ayé, oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ ti wà láti àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ọdún sẹ́yìn. Bíbélì ò ṣàlàyé lórí iye ọdún tí ilẹ̀ ayé tàbí oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ ti wà. Ohun tí Bíbélì sọ ṣe wẹ́kú pẹ̀lú èrò náà pé ó ti tó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọdún tí àgbáyé ti wà kí “ọjọ́” àkọ́kọ́ ìṣẹ̀dá tó bẹ̀rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:1, 2.
◼ Tíṣà mi sọ pé kò sí ọ̀nà tí Ọlọ́run lè gbà dá ayé láàárín ọjọ́ mẹ́fà péré. Bíbélì ò sọ pé wákàtí mẹ́rìnlélógún [24] ni gígùn “ọjọ́” ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan. Bó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo ojú ìwé 28 sí 30 nínú ìwé ìròyìn yìí.
◼ Nínú kíláàsì wa, a jíròrò àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan nípa ìyàtọ̀ tó ti bá àwọn ẹranko àtàwọn èèyàn látìgbà yìí wá. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá àwọn nǹkan alààyè “ní irú tiwọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:20, 21) Kò fara mọ́ èrò tó sọ pé látinú àwọn nǹkan aláìlẹ́mìí ni ìwàláàyè ti wá tàbí pé látinú ohun tín-ń-tín kan ni Ọlọ́run ti mú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í hú yọ. Síbẹ̀, “irú” kọ̀ọ̀kan ní agbára láti mú oríṣiríṣi irú tirẹ̀ jáde. Nítorí náà, Bíbélì gbà pé ó ṣeé ṣe kí ìyípadà wáyé nínú “irú” kọ̀ọ̀kan.
Jẹ́ Kí Ohun Tó O Gbà Gbọ́ Dá Ọ Lójú!
Kò sí ìdí fún ẹ láti máa rò pé tìẹ yàtọ̀ tàbí kó o máa tijú torí pé o gbà gbọ́ nínú ìṣẹ̀dá. Bá a bá yẹ ẹ̀rí tó wà lọ́wọ́ wò, ó bọ́gbọ́n mu látòkèdélẹ̀, kódà ó bá ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ mu láti gbà gbọ́ pé ẹni olóye kan ló ṣẹ̀dá wa. Gbogbo ẹ̀, gbògbò ẹ̀, ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gan-an ló gba kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tí kò sí ẹ̀rí bíbọ́gbọ́nmu kankan tó tí ì lẹ́yìn, òun náà sì lèèyàn lè rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìyanu tí kò sì sẹ́ni tó ṣe é. Kódà, lẹ́yìn tó o bá ti ka àpilẹ̀kọ míì tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá nínú Jí! yìí, á wá yé ẹ kedere pé ohun tí ẹ̀rí tó wà ń sọ ni pé ẹnì kan ló ṣẹ̀dá ohun gbogbo. Bíwọ náà bá sì ti fi agbára ìrònú rẹ yiiri ọ̀rọ̀ náà wò síwá sẹ́yìn, wàá túbọ̀ ní ìgboyà láti ṣàlàyé nípa ohun tó o gbà gbọ́ níwájú àwọn ọmọ kíláàsì ẹ.
Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí fún Raquel, ọmọbìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí nìyẹn. Ó sọ pé: “Ó gbà mí ní ọjọ́ mélòó kan kí n tó rí i pé kò yẹ kí n panu mọ́ lórí ohun tí mo gbà gbọ́. Mo fún tíṣà mi ní ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation?, mo sì sàmì sáwọn ibì kan tí mo fẹ́ fi hàn án. Lẹ́yìn náà ló wá sọ fún mi pé ìwé náà ló jẹ́ kóun lè fi ojú tó yàtọ̀ pátápátá wo ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ó sì sọ pé nígbà míì tóun bá ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́, òun ò ní gbàgbé ohun tóun ti kà nípa ẹ̀!”
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti jàǹfààní látinú bí wọ́n ṣe ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé bíi Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? àti Is There a Creator Who Cares About You? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ àwọn ìwé méjèèjì.
ǸJẸ́ Ó TÍÌ ṢE Ọ́ RÍ BÍI KÓ O BÉÈRÈ PÉ
◼ Àwọn ọ̀nà tó rọrùn wo lo lè gbà ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ nípa ìṣẹ̀dá nílé ìwé?
◼ Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì Ẹni náà tó dá ohun gbogbo?—Ìṣe 17:26, 27.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
“Ẹ̀RÍ WÀ JABURATA”
“Kí lo máa sọ fún ọ̀dọ́mọdé kan tí wọ́n ti kọ́ láti kékeré pé Ẹlẹ́dàá wà, àmọ́ tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n nílé ẹ̀kọ́?” Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa àwọn ohun alààyè tíntìntín ni wọ́n bi ní ìbéèrè yìí. Kí ni arábìnrin náà fi dá wọn lóhùn? Ó sọ pé: “Ṣe ni kó o wo ìbéèrè náà bí àǹfààní láti jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ọlọ́run wà, kì í wulẹ̀ ṣe nítorí pé ohun táwọn òbí ẹ fi kọ́ ẹ nìyẹn, bí kò ṣe nítorí pé ìwọ fúnra ẹ ti ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí tó fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, kó o tó gbà bẹ́ẹ̀ lọ́kàn ara ẹ. Nígbà míì, bí wọ́n bá ní káwọn tíṣà ‘fẹ̀rí ti’ ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ‘lẹ́yìn,’ wọ́n máa ń rí i pé kì í ṣeé ṣe fáwọn, wọ́n sì ti wá gbà pé ńṣe làwọn wulẹ̀ gba ẹ̀kọ́ náà nítorí pé ohun tí wọ́n fi kọ́ àwọn nìyẹn. Ohun tó ṣe wọ́n lè ṣe ìwọ náà lórí ọ̀ràn ìgbàgbọ́ tó o ní nínú Ẹlẹ́dàá. Ìdí ẹ̀ nìyẹn táá fi dáa kó o mú un dá ara ẹ lójú pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà. Ẹ̀rí wà jaburata. Kò ṣòro láti rí.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
KÍ LÓ MÚ KÓ O GBÀ GBỌ́?
Kọ àwọn nǹkan mẹ́ta tó mú kí ìwọ fúnra ẹ gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá wà sísàlẹ̀ yìí:
1. ․․․․․
2. ․․․․․
3. ․․․․․