Tasmania—Erékùṣù Kékeré, Onítàn Àrà Ọ̀tọ̀
LÀTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA
“N ÍTORÍ pé ilẹ̀ yí ni a kọ́kọ́ rí ní Gúúsù Òkun Ńlá, tí àwọn orílẹ̀-èdè Europe kankan kò sì mọ̀ ọ́n, a fún un ní orúkọ náà, Anthoony van Diemenslandt, tí a fi dá Ọlọ́lá Gómìnà Àgbà [wa] lọ́lá.” Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí ọmọ ilẹ̀ Netherlands náà, Abel Tasman, sọ ní November 25, 1642, lọ́jọ́ kejì tí ó rí erékùṣù Tasmania, ìpínlẹ̀ tí ó tí ì pẹ́ jù lọ ṣìkejì ní Australia.a Tasman kò rí àwọn ènìyàn, àmọ́, ó rí èéfín iná tí ń rú lọ́nà jíjìn àti àwọn igi ìtòsí tí a gbẹ́ àwọn ihò, tí ó wà ní mítà 1.5 síra wọn sí. Ó kọ̀wé pé, ó lè jẹ́ pé àwọn yòó wù kí wọ́n gbẹ́ àwọn ihò náà ní ọ̀nà ṣíṣàjèjì kan tí wọ́n ń gbà pọ́ngi tàbí kí wọ́n jẹ́ òmìrán! Ní gidi, àwọn ihò náà wà fún pípọ́ngi.
Lẹ́yìn náà, Ilẹ̀ Van Diemen pòórá kúrò ní ojú ọ̀nà àwọn olùyẹ̀wòkiri lórí òkun fún 130 ọdún, títi fi di ìgbà tí ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Marion du Fresne, àti ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Tobias Furneaux, ṣèbẹ̀wò. Ọ̀gákọ̀ James Cook dé ní 1777, bíi ti Du Fresne, ó kàn sí àwọn ènìyàn aláìlẹ́gbẹ́ tí wọ́n wà ní erékùṣù náà, àwọn Aborigine. Bí ó ti wù kí ó rí, ìbẹ̀wò rẹ̀ jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀ràn ìbànújẹ́ kan. John West sọ nínú ìwé The History of Tasmania pé: “Sí àwọn orílẹ̀-èdè kan, [Cook] ṣínà ọ̀làjú àti ti ìsìn, [àmọ́] sí àwọn ẹ̀yà ìran yìí [àwọn Aborigine], ó jẹ́ atọ́nà ikú.” Kí ló ṣamọ̀nà sí irú àbájáde oníbànújẹ́ bẹ́ẹ̀?
Tasmania Di “Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ilẹ̀ Ọba Náà”
Ìlékúrò-nílùú, tàbí líléni lọ sí ìgbèkùn, ni ọ̀nà tí ilẹ̀ Britain ń gbà fìyà jẹni, Tasmania sì di ọ̀kan lára àwọn àgbègbè ìgbókèèrè-ṣàkóso tí ilẹ̀ Britain ń lò bí ibi ìfìyàjẹni. Láti 1803 sí 1852, nǹkan bí 67,500 ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé pàápàá—tí àwọn kan kéré tó ọmọ ọdún méje—ni a lé lọ sí Tasmania láti England, nítorí àwọn ìwà ọ̀daràn tí ó wà láti orí jíjí àwọn ìwé àdúrà dórí ìfipábáni-lòpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí a dẹ́bi fún ṣiṣẹ́ sin àwọn olùtẹ̀dó tàbí níbi iṣẹ́ kan tí ìjọba dáwọ́ lé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Australian Encyclopædia, sọ pé: “Kò tó ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn . . . tí ó rí inú ibùdó ìfìyàjẹni kan rí, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n sì rí i wà níbẹ̀ fún ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ni.” Èbúté Arthur, níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Tasman, ni lájorí ibùdó ìfìyàjẹni, àmọ́, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n burú jù lọ ni wọ́n máa ń fi ránṣẹ́ sí Èbúté Macquarie, tí wọ́n kà sí ojúbọ “mímọ́ sí àwọn ẹgbẹ́ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìdánilóró.” Ọ̀nà àbáwọlé èbúté tóóró náà gba orúkọ adẹ́rùbani náà, Ibodè Ọ̀run Àpáàdì.
Nínú ìwé náà, This Is Australia, Ọ̀mọ̀wé Rudolph Brasch ṣàlàyé apá pàtàkì míràn lára àgbègbè ìgbókèèrè-ṣàkóso jòjòló yìí—ipò tẹ̀mí rẹ̀, tàbí àìsí ipò tẹ̀mí níbẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Láti ìbẹ̀rẹ̀, wọ́n ti pa ìsìn tì, wọ́n sì ti kọtí ikún sí i ní Australia [títí kan Tasmania] àti pé, lọ́nà púpọ̀ jù lọ, Òtú Ẹgbẹ́ tí a gbé kalẹ̀ ti kó o nífà, ó sì ti lò ó nílòkulò fún àǹfààní ara rẹ̀. Àgbègbè ìgbókèèrè-ṣàkóso náà ni a gbé kalẹ̀ láìsí àdúrà, ó jọ pé ààtò ìsìn àkọ́kọ́ lórí ilẹ̀ Australia ní èrò àtúnrò.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Àwọn Olùṣèbẹ̀wò sí Ilẹ̀ Àjèjì ti Àríwá America kọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì, ìwé The History of Tasmania sọ pé, “àwọn olùgbé ìhà gúúsù ayé dáná sun ṣọ́ọ̀ṣì wọn àkọ́kọ́ láti jà bọ́ lọ́wọ́ àjàgà lílọ síbẹ̀.”
Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọtí rum tún ń ba ìwà rere tí ó ti lábùkù tẹ́lẹ̀ yí jẹ́ síwájú sí i. Sí àwọn ènìyàn ìlú àti àwọn sójà pẹ̀lú, òpìtàn John West sọ pé, ọtí rum jẹ́ “ọ̀nà dídájú tí ń sọni di ọlọ́rọ̀.”
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, oúnjẹ máa ń wọ́n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Láàárín àkókò yí, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí a dá sílẹ̀ àti àwọn olùtẹ̀dó ń fi ìbọn ṣọdẹ àwọn ẹran ìgbẹ́ kan náà tí àwọn Aborigine ń fi ọ̀kọ̀ lépa. Ó yéni pé, pákáǹleke ń di pelemọ. Ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú ti ẹ̀yà ìran aláwọ̀ funfun, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọtí líle, àti àwọn ìyàtọ̀ tí kò ṣeé mú bára dọ́gba nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ti kún ìbẹ́sílẹ̀ àjọṣepọ̀ àìníwà-bí-ọ̀rẹ́ náà nísinsìnyí. Àwọn ará Europe sàmì sí àwọn ààlà ìpínlẹ̀, wọ́n sì mọ odi yí ká; àwọn Aborigine ń dọdẹ, wọ́n sì ń kó nǹkan jọ bíi ti àwọn alákòókiri. Ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò tó nǹkan kan ló máa ń dá rògbòdìyàn sílẹ̀.
Ẹ̀yà Ìran Ènìyàn Kan Pòórá
Wọ́n tanná ran rògbòdìyàn náà ní May 1804. Àwùjọ àwọn aláàbò kan, tí Ọ̀gágun Moore ṣáájú wọn, yìnbọn fún àwùjọ ńlá àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé Aborigine tí ń ṣọdẹ, láìjẹ́ pé àwọn yẹn ṣe ohunkóhun láti mú wọn bínú—wọ́n sì pa ọ̀pọ̀ lára wọn, wọ́n sì pa wọ́n lára. “Ogun Dúdú Náà”—àwọn ọ̀kọ̀ àti òkúta ní ìdojúkọ ọta ìbọn—bẹ̀rẹ̀.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Europe káàánú nípa ìpakúpa tí wọ́n pa àwọn Aborigine náà. Ọkàn gómìnà náà, Alàgbà George Arthur, kún fún ìdààmú púpọ̀ débi pé ó sọ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ láti ṣe ohunkóhun tí ó bá lè ṣe láti ‘san àsanpadà fún ìpalára tí ìjọba ṣe fún àwọn Aborigine láìmọ̀.’ Nípa bẹ́ẹ̀, ó dá ètò kan sílẹ̀ láti “ṣàkójọ” kí ó sì sọ wọ́n di “ọ̀làjú.” Nínú ìgbétásì kan tí a pè ní “Ààlà Adúláwọ̀,” nǹkan bí 2,000 sójà, olùtẹ̀dó, àti àwọn ẹlẹ́wọ̀n ni wọ́n la igbó kọjá nínú ìsapá láti rí àwọn Aborigine mú, kí wọ́n sì tún mú wọn tẹ̀ dó síbi tí ó láàbò. Àmọ́ iṣẹ́ àgbéṣe náà jẹ́ ìjákulẹ̀ tí ń tẹ́ni lógo; wọ́n rí obìnrin kan àti ọmọdékùnrin kan mú. Lẹ́yìn náà, George A. Robinson, ayọrí-ọlá nínú ìsìn àwọn ọmọlẹ́yìn Wesley, ṣonígbọ̀wọ́ ọ̀nà ìyọsíni kan tí ó túbọ̀ ṣètẹ́wọ́gbà, ó sì gbéṣẹ́. Àwọn Aborigine náà gbẹ́kẹ̀ lé e, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìpèsè ìtúntẹ̀dó sí Erékùṣù Flinders, ní àríwá Tasmania.
Marjorie Barnard sọ nípa àṣeyọrí Robinson nínú ìwé rẹ̀, A History of Australia, pé: “Ní gidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ lè má mọ̀ nípa èyí, ó yọrí sí bìlísì irú èyí tí Júdásì fà. Àwọn ọmọ onílẹ̀ tí wọn kò rìnnà kore náà ni a yà sọ́tọ̀ ní Erékùṣù Flinders ní Itọ́ Odò Bass tí Robinson sì jẹ́ olùṣètọ́jú wọn. Wọ́n lálàṣí, wọ́n sì kú.” Ọ̀nà ìgbésí ayé àti irú oúnjẹ tí a fipá mú wọn láti yí pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn tí ìbọn pa kù. Orísun ìsọfúnni kan sọ pé, “Fanny Cochrane Smith, tí ó kú ní Hobart ní 1905, ni Aborigine ọmọ ilẹ̀ Tasmania gidi tí ó kẹ́yìn.” Èrò àwọn ògbóǹkangí yàtọ̀ síra nípa èyí. Àwọn kan tọ́ka sí Truganini, obìnrin kan tí ó kú ní Hobart ní 1876, àwọn mìíràn tọ́ka sí obìnrin kan tí ó kú sí Erékùṣù Kangaroo ní 1888. Àwọn àtọmọdọ́mọ Aborigine, tí wọ́n jẹ́ àdàlù ẹ̀yà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Tasmania wà láàyè lónìí, ara wọn sì dá ṣáká. Ní àfikún sí àwọn ìfìyàjẹni tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ tí ìran aráyé ń fi jẹni, a ti pe èyí ní “ọ̀ràn ìbìnújẹ́ gíga jù lọ ní Orílẹ̀-Èdè náà” lọ́nà tí ó bá a mu. Síwájú sí i, ó tẹnu mọ́ òtítọ́ Bíbélì náà pé, “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.
Ìyàtọ̀ Tí Ó Hàn Sóde Nípa Tasmania
Lónìí, àyàfi tí o bá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí, ibi ìkówèésí, tàbí àwọn àwókù ọgbà ẹ̀wọ̀n, ni o fi lè mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ iná burúkú tí ó ṣẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ní erékùṣù ẹlẹ́wà yí. Tasmania fẹ́rẹ̀ẹ́ jìnnà sí agbedeméjì ayé ní ìhà gúúsù tó bíi Róòmù, Sapporo, àti Boston ṣe jìnnà sí i ní ìhà àríwá. Àti pé bí ìtàn rẹ̀ ṣe rí ni àwọn ohun tí ó wà ní ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́ èyí tí ó yàtọ̀ gédégédé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ibì kankan ní erékùṣù náà tí ó jìnnà ju kìlómítà 115 sí òkun.
Lára àpapọ̀ ilẹ̀ Tasmania, ìpín 44 nínú ọgọ́rùn-ún ló jẹ́ igbó, ìpín 21 nínú ọgọ́rùn-ún sì jẹ́ ọgbà ìtura orílẹ̀-èdè. Ìwọ̀n tí ó ṣọ̀wọ́n gbáà nìwọ̀nyí! Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Little Tassie Fact Book ṣe sọ, “ibi àkójọ ohun àmúṣọrọ̀ àgbáyé ní Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Tasmania jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgbègbè aginjù kíkàmàmà tí ojú ọjọ́ rẹ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí a kò tí ì bà jẹ́, tí ó kẹ́yìn lágbàáyé.” Àwọn adágún tí òjò àti òjò dídì ń rọ́ sí, àwọn odò, àti ìtàkìtì omi—tí ó kún fún ẹja trout—ń fomi rin àwọn igbó tí ó kún fún igi ahóyaya sóóró, eucalyptus, myrtle, bọn-ọ̀n-ní dúdú, sassafras, leatherwood, ahóyaya tí a lè jẹ ewé rẹ̀, àti ahóyaya Huon, kí a mẹ́nu kan ìwọ̀nba díẹ̀. Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé àwọn ibi ìwòran tí àwọn ibi pẹrẹsẹ gíga ti ìhà àárín gbùngbùn ìwọ̀ oòrùn ìtẹ́jú gíga pèsè, àti àwọn ṣóńṣó orí rẹ̀ tí òjò dídì sábà ń bò, ń fa àwọn olólùfẹ́ ìṣẹ̀dá mọ́ra tí wọ́n fi ń wá léraléra.
Àmọ́, ìdáàbòbo “Àkójọ Ohun Àmúṣọrọ̀ Àgbáyé” kò ṣàìní àtakò. Àwọn ènìyàn tí wọ́n sì lọ́kàn ìfẹ́ ìlòkulò sí àyíká náà ṣì ń ru gùdù ní ìlòdìsí ìwakùsà, ṣíṣe pépà, àti ìṣèmújáde iná mànàmáná láti inú omi. Ìrísí ojú ilẹ̀ tí ó jọ ìtẹ́jú òṣùpá ní Queenstown, ìlú kan tí wọ́n ti ń wa kùsà, jẹ́ ìránnilétí búburú kan nípa àwọn àbájáde kíkó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ nífà láìlérò.
Àwọn ẹranko ìbílẹ̀ pẹ̀lú ti jìyà—ní pàtàkì thylacine, tàbí ẹkùn Tasmania, ẹranko agbọ́mọsápò, onírìísí ajá, tí ó ní àwọ̀ ilẹ̀. Àwọn ilà ṣíṣú tí ó wà ní ẹ̀yìn àti ìbàdí rẹ̀ ló jẹ́ kí ó gba orúkọ náà ẹkùn. Ó dunni pé ẹranko apẹranjẹ tín-ínrín, tí ń tijú yìí, máa ń dọdẹ àwọn ẹyẹ àfidọ́sìn àti àgùtàn. Nítorí ẹ̀bùn owó tí a là sílẹ̀ fún pípa àwọn thylacine, ó kú run ní 1936.
Ẹranko agbọ́mọsápò aláìlẹ́gbẹ́ mìíràn ní Tasmania, èṣù Tasmania, ṣì wà láyé. Ní lílo párì àti eyín rẹ̀ lílágbára, apalẹ̀-ìdọ̀tímọ́ fìrìgbọ̀ngbọ̀n, tí ó tẹ̀wọ̀n tó kìlógíráàmù mẹ́fà sí mẹ́jọ yìí, lè dá jẹ odindi òkú ẹranko kangaroo kan tán tagbárítagbárí.
A tún mọ Tasmania dáradára nítorí ẹyẹ shearwater, tàbí muttonbird. Lẹ́yìn tí ó bá gbéra láti Òkun Tasmania, tí ó bá ti yípo òkun Pacific tán pátápátá, ó máa ń pa dà lọ́dọọdún sínú ihò inú iyanrìn kan náà—ọ̀nà ìgbàṣe kan tí ó jẹ́ sí ìyìn Olùṣègbékalẹ̀ àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀.
Nítòsí nínú ìtẹ́ rẹ̀ tí ó máa ń wọ̀ sí lálaalẹ́ ni ẹyẹ mìíràn—ọ̀kan tí ó “ń fò” lábẹ́ omi—afanimọ́ra, tí ó tẹ̀wọ̀n kìlógíráàmù kan, abi-àgógó kóńkó, tó fi gbogbo ara ṣe irun, tí a ń pè ní penguin jíjojúnígbèsè. Èyí tí ó kéré jù lọ lára gbogbo àwọn penguin yìí ló tún máa ń pariwo jù lọ! Bí àwọn àrà tí ó máa ń dá ti lágbára tó yàtọ̀ síra, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń lo ohùn àti fífi ara dárà lọ́nà lílágbára gan-an. Nígbà tí wọ́n bá ń nímọ̀lára eré ìfẹ́, takọtabo kan tilẹ̀ lè so mọ́ra lọ́nà àrà láti fẹ̀rí hàn pé àwọn ní ìsopọ̀mọ́ra. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ lára wọn ni àwọ̀n apẹja, ìtúdànù epo rọ̀bì, ike tí wọ́n ṣì mú fún oúnjẹ, tàbí àwọn ajá àti ológbò ẹhànnà ti pa.
Apá Tí Ó Tòrò Jù ní Erékùṣù Kékeré Náà
Wo àríwá tàbí ìlà oòrùn láti etí téńté ibi ìtẹ́jú gíga àárín gbùngbùn náà, ìwọ yóò sì rí apá tí ó lálàáfíà jù ní Tasmania, pẹ̀lú àwọn pápá oko rẹ̀ aláwọ̀ ṣokoléètì tí a ro, àwọn odò lílọ́ kọ́lọkọ̀lọ àti àwọn itọ́ odò, àwọn òpópónà ńlá tí a gbin igi sí lọ, àti àwọn ibùjẹ ẹran oníkoríko títutù yọ̀yọ̀ tí àwọn àgùtàn àti màlúù fọ́n sí. Nítòsí ìlú ìhà àríwá náà, Lilydale, àwọn oko irúgbìn lavender máa ń fi àwọ̀ elése àlùkò ṣíṣú àti títàn tí ó ní òórùn dídùn afanimọ́ra kún ẹwà àwọn ohun ìrántí aláwọ̀ mèremère àrọko yìí, nígbà ìtànná òdòdó, ní nǹkan bíi January.
Rírìn nínú Odò Derwent ní yíya ẹsẹ̀, níbi tí kò jìnnà sí àwọn ọgbà igi ápù tí ó mú kí Tasmania gba orúkọ náà, Erékùṣù Kékeré Ápù, ni olú ìlú rẹ̀, Hobart, tí ó ní 182,000 ènìyàn nínú wà. Òkè Ńlá Wellington gíga fíofío ní 1,270 mítà ta yọ lọ́lá. Ní ọjọ́ tí ojú ọjọ́ bá mọ́lẹ̀, òkè ńlá tí òjò dídì sábà máa ń bò mọ́lẹ̀ yí ń mú ìrísí bí ìgbà tí ẹyẹ ń wo ìlú ńlá náà nísàlẹ̀ wá. Àwọn ìyípadà ti ṣẹlẹ̀ ní gidi ní Hobart láti 1803, nígbà tí Ọ̀gágun John Bowen àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ 49, títí kan àwọn ẹlẹ́wọ̀n 35, kọ́kọ́ gúnlẹ̀ ní Risdon Cove. Bẹ́ẹ̀ ni, àkójọ àwọn ìgbín àti àwọn gẹdú tí ń họn gooro ti lọ, àmọ́, lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, eré ìje ọkọ̀ òkun láti Sydney sí Hobart ń ránni létí nípa àwọn ìrìn àjò nínú ojú òkun nígbà láéláé bí àwọn ọkọ̀ òkun ńláńlá àti ara àwọn ọkọ̀ òkun tí a kó ẹrù tí kò wúlò kúrò lára wọn ṣe ń sáré kọjá níwájú àwọn èrò tí ń yẹ́ wọn sí, ní tààràtà lọ sí àárín gbùngbùn Hobart.
Láti Ilẹ̀ Tí A Ti Ń Ṣe Inúnibíni sí Párádísè Tẹ̀mí
Geoffrey Butterworth, ọ̀kan lára àwọn 2,447 ènìyàn tó wá sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìbẹ̀rù Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Launceston, ní 1994, sọ èrò náà pé: “Mo rántí ìgbà tí ó jẹ́ pé nǹkan bí 40 Ẹlẹ́rìí ló wà ní gbogbo Tasmania.” Nísinsìnyí, nǹkan bí ìjọ 26 àti Gbọ̀ngàn Ìjọba 23 ló wà níbẹ̀.
Geoff fi kún un pé: “Àmọ́, nǹkan kì í fìgbà gbogbo ṣẹnuure. Fún àpẹẹrẹ, ní 1938, èmi, Tom Kitto, àti Rod McVilly, tí gbogbo wa gbé àwọn pátákó àgbékọ́rùn níwájú àti lẹ́yìn kọ́rùn, ń polongo àwíyé Bíbélì fún gbogbogbòò náà, ‘Gbọ́ Òtítọ́.’ Ó jẹ́ ìtáṣìírí ìsìn èké lọ́nà tí ń tani wàìwàì, tí a óò gbé sáfẹ́fẹ́ lórí rédíò alátagbà láti London. Nígbà tí mo dara pọ̀ mọ́ àwọn alájọṣepọ̀ mi, àjọ ìpàǹpá àwọn èwe kan ti ń bú mọ́ wọn. Àwọn ọlọ́pàá sì wulẹ̀ ń wòran ni! Mo sáré láti ṣèrànwọ́, kò sì pẹ́ tí wọ́n lu èmi náà. Àmọ́, ọkùnrin kan gbá mi láṣọ mú lẹ́yìn, ó sì fà mí lọ. Dípò kí ọkùnrin náà lù mí, ó fi ohùn kíkẹ̀ lọgun pé: ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’ Lẹ́yìn náà, ó rọra wí fún mi pé: ‘Mo mọ bí ó ṣe rí láti ṣenúnibíni síni, ọ̀rẹ́, ọmọ Ireland ni mí.’”
Jèhófà bù kún àwọn aṣáájú ọ̀nà ìgbà láéláé wọ̀nyẹn, nítorí pé lónìí, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti dé apá ibi gbogbo ní erékùṣù tí ènìyàn 452,000 ń gbé yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn àtọmọdọ́mọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ìgbà láéláé náà àti àwọn Aborigine fojú sọ́nà fún kíkí gbogbo àwọn—adúláwọ̀ àti aláwọ̀ funfun—tí wọn ti kú lọ́nà àìṣòdodo ní àwọn ọjọ́ láéláé rírorò wọ̀nyẹn káàbọ̀ sórí ilẹ̀ ayé tí a ti fọ̀ mọ́ tónítóní, nítorí pé Bíbélì ṣèlérí “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo.” (Ìṣe 24:15) A óò ṣàtúnṣe ipò náà dáradára gan-an débi pé “àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí.”—Aísáyà 65:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ náà, Tasmania, ni a gbà mú lò lábẹ́ ìtìlẹ́yìn àṣẹ ní November 26, 1855. Ìpínlẹ̀ tí ó ti wà pẹ́ jù lọ ní New South Wales.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Lókè: Òkè Ńlá Cradle àti Adágún Dove
Òkè lápá ọ̀tún: Èṣù Tasmania
Ìsàlẹ̀ lápá ọ̀tún: Igbó kìjikìji ní Ìhà Gúúsù Ìwọ̀ Oòrùn Tasmania
Australia
TASMANIA
[Credit Line]
Èṣù Tasmania àti àwòrán ilẹ̀ Tasmania: Department of Tourism, Sport and Recreation – Tasmania; Àwòrán ilẹ̀ Australia: Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.