Ìbànújẹ́ Ikú Èwe
“Mo lérò yìí ṣáá, pé ìran wa ń kú lọ.”—Johanna P., ọmọ ọdún 18, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ yunifásítì, Connecticut, U.S.A.
OJÚ àwọn ọlọ́pàá rí ìran ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ní oko kan, lẹ́yìn odi ìlú Hobart, olú ìlú ilẹ̀ Tasmania, ìpínlẹ̀ erékùṣù kan ní Ọsirélíà. Àwọn ọmọbìnrin ọlọ́dún 10 sí 18 mẹ́rin ló wà nínú ilé náà. Gbogbo wọn ti kú, baba wọn, tó ní àpá ọta ìbọn aṣekúpani kan lórí, tí òun náà kú sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nítòsí, ló pa wọ́n. Ó ti fi àáké kan gé ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ̀ sọ nù. Ìpànìyàn àti ìpara-ẹni yìí kó ṣìbáṣìbo bá gbogbo ará Tasmania. Ó sì mú kí àwọn ènìyàn máa ronú lórí ìbéèrè tí ń da ọkàn láàmú kan—Èé ṣe? Èé ṣe tí àwọn ọmọbìnrin aláìmọwọ́mẹsẹ̀ mẹ́rin wọ̀nyẹn fi kú bẹ́ẹ̀?
Bí afipábánilò kan tí a tú sílẹ̀ lábẹ́ àyẹ̀wò ṣe bá àwọn ọmọbìnrin mẹ́fà ṣèṣekúṣe, tó sì pa mẹ́rin nínú wọn, ṣì ń rú àwọn ará Belgium lójú. Ìbéèrè kan náà ṣì wà níbẹ̀—Èé ṣe? Ní Ajẹntínà, àwọn ìyá kan gbà gbọ́ pé 30,000 ènìyàn, tí púpọ̀ nínú wọn jẹ́ ọmọ tiwọn náà, kú sínú ohun tí a wá ń pè ní ogunkóguna nísinsìnyí. Àwọn kan lára àwọn tó kàgbákò wọ̀nyí ni wọ́n dá lóró, tí wọ́n lo oògùn líle fún, tí wọ́n wá fi ọkọ̀ òfuurufú gbé lọ sọ sókun. Wọ́n ju àwọn kan sókun lóòyẹ̀. Èé ṣe tí wọ́n fi ní láti kú? Àwọn ìyá wọn ṣì ń retí ìdáhùn.
Ní 1955, Àpérò Àwọn Ìyá Lágbàáyé bẹnu àtẹ́ lu bí ogun ṣe jẹ́ ìmúlẹ̀mófo, wọ́n sì polongo pé, “ju ohun gbogbo lọ,” àpérò náà jẹ́, “ìkégbàjarè ẹlẹ́hòónú kíkankíkan, ìkégbàjarè ẹlẹ́hòónú tí gbogbo obìnrin tí ń tiraka láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn, àti kékeré àti àgbà, lọ́wọ́ ibi tí ogun àti ìmúrafógun ń mú wá, fi ń ṣèkìlọ̀.” Lọ́nà títakora, iye àwọn èwe tí wọ́n ń kàgbákò àwọn ìjà tó la ikú lọ láti ìgbà àpérò yẹn ń pọ̀ sí i kárí ayé—ìpàdánù ìran ènìyàn tí ì bá ṣe aráyé ní onírúurú àǹfààní.
Ikú Èwe Látọjọ́ Pípẹ́
Àìlóǹkà èwe ni ìtàn fi hàn pé a ti pa. Nínú ọ̀rúndún ogún wa tí a sọ pé ojú ti là pàápàá, ìjà láàárín àwọn ẹ̀yà àti àwọn ìran ti dájú sọ àwọn èwe. Ńṣe ló jọ pé àwọn èwe wulẹ̀ ní láti máa fi ẹ̀mí wọn dí àwọn àṣìṣe àti ìlépa ara ẹni ti àwọn àgbàlagbà.
Ìwé ìròyìn The New Republic ròyìn pé, ní orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, wọ́n ti kọ́ ọ̀wọ́ àwọn ọ̀dọ́ jagunjagun ìsìn kan tí ń pe ara wọn ní Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Aṣèdènà ti Olúwa lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn láti gbà gbọ́ pé ọta kò lè ràn wọ́n. Abájọ tí wọ́n fi pe àkọlé ìròyìn náà ní “Àfiṣòfò Ìgbà Èwe”! Nítorí náà, lọ́nà yíyẹ, àwọn mọ̀lẹ́bí tí ń ṣọ̀fọ̀ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin—tí kì í kúkú ṣe ẹni tí ọta ìbọn kò lè ràn tẹ́lẹ̀—ń béèrè pé: Èé ṣe tí àwọn èwe wa fi ní láti kú? Kí ni ète gbogbo rẹ̀?
Láfikún sí gbogbo ìnira àti ìjìyà wọ̀nyí ni àwọn ọ̀dọ́ tí ń pa ara wọn tún wà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ogun tí a wá ń pè ní ogunkógun náà wáyé nígbà ìṣàkóso ológun (1976 sí 1983) tí wọ́n ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ alátakò ìjọba. Àwọn ìdíyelé mìíràn sọ pé, iye àwọn tó kàgbákò náà wà láàárín 10,000 sí 15,000.