Báwo Ni Ìsìn Ṣe Ń Jẹ Àwọn Ọ̀dọ́ Lọ́kàn Tó?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ
LÓJÚ 750,000 ọ̀dọ́ tó wà nínú àwùjọ náà, ìrọ̀lẹ́ alárinrin kan ni èyí jẹ́. Wọ́n ń ju àwọn àsíá, wọ́n ń kọrin, wọ́n ń pàtẹ́wọ́. Wọ́n ń tan iná laser, àwọn akọrin sì ń ta àwùjọ náà jí. Ipò náà dà bí “àtọwọ́dá ibi ijó dísíkò ńlá” kan. Níkẹyìn, bí wọ́n ti ń hó gèè, ẹni tí wọ́n ti ń dúró dè jáde sórí pèpéle.
Ṣé ẹgbẹ́ olórin rock kan ló ń gbéra ìrìn àjò kárí ayé ni? Rárá o. Ìpàdé máàsì ìsìn kan ní Paris ni, nígbà ayẹyẹ Àwọn Ọjọ́ Èwe Lágbàáyé ti Kátólíìkì, ẹni tí wọ́n ń retí náà kì í sì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe Póòpù John Paul Kejì!
Lójú àwọn kan, ìfẹ́ tí àwọn ọ̀dọ́ ní sí àwọn àjọyọ̀ ìsìn bí irú èyí lè ṣàjèjì. Àmọ́ ní báyìí, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń sọ nípa ìmúsọjí ìsìn láàárín àwọn èwe.
Àwọn Ìrísí Òde
Lóréfèé, ó lè jọ pé ìsìn ń gbèrú. Nǹkan bí ìpín 68 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ ará Yúróòpù sọ pé àwọn jẹ́ onísìn, iye náà sì ju ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lọ ní Ireland. Ní Armenia, orílẹ̀-èdè olómìnira kan ní Soviet àtijọ́, níbi tí ọ̀pọ̀ ti ka ìsìn sí ohun àtijọ́ nígbà kan, àlùfáà kan sọ nípa àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí a ti pa tì nígbà kan rí, tí wọ́n wá ń kún nísinsìnyí pé: “Bí ìsìn ṣe ń fa ìran àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra ń yà mí lẹ́nu.”
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ti polongo bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń lọ́wọ́ sí ẹgbẹ́ òkùnkùn àti àwọn ẹgbẹ́ alágbára àrà ọ̀tọ̀ lọ́nà tó gbilẹ̀ gan-an. Àwọn àjọ̀dún ìsìn, bí irú èyí tí a mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀ wọ́pọ̀. Àmọ́, bí a bá wò kọjá oréfèé, kí la ń rí?
Wíwò Ó Jinlẹ̀
Àwòjinlẹ̀ fi hàn pé ní 1967, ìpín 81 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èwe ọmọ ilẹ̀ Faransé gba Ọlọ́run gbọ́, ṣùgbọ́n ní 1997, ìpín náà kò tó ìdajì mọ́. Ní Yúróòpù lápapọ̀ ìpín 28 péré nínú ọgọ́rùn-ún ni àwọn ọ̀dọ́ tó gbà pé Ọlọ́run kan wà. Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, ìpín 12 péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èwe Yúróòpù ní ń gbàdúrà lọ́pọ̀ ìgbà. Báwo ni èyí ṣe fi ojú tí àwọn èwe fi ń wo ìsìn hàn tó?
Ní Denmark, ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún ọ̀dọ́ sọ pé àwọn jẹ́ ọmọ ìjọ orílẹ̀-èdè. Ìpín 3 péré nínú ọgọ́rùn-ún ṣàpèjúwe ara wọn bí ẹni tí ń ṣèsìn lójú méjèèjì. Ní 1997, ìwádìí tí ìwé ìròyìn La Croix ti Kátólíìkì ṣe ní ilẹ̀ Faransé fi hàn pé, ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ Faransé gbà pé ìsìn kò kó ipa pàtàkì kankan nínú ìgbésí ayé àwọn. Ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin wọn ka ìrírí ara ẹni sí pàtàkì ju ẹ̀kọ́ ìsìn èyíkéyìí lọ. Bákan náà lọmọ ṣorí ní ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè Yúróòpù mìíràn.
Kí ló ń mú kí àwọn ọ̀dọ́ sá fún ṣọ́ọ̀ṣì? Ní ti ọ̀pọ̀ lára wọn, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó lórúkọ kò fúnni ní ìgbọ́kànlé. Bí àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Faransé, ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀dọ́ rò pé ìsìn jẹ́ ohun kan tí ń pín ayé níyà. Láfikún sí i, àwọn èwe tó ń ronú bí Judith, ọmọ ọdún 15, tó jẹ́ Kátólíìkì, láti Sípéènì, wọ́pọ̀. Ó wí pé: “N kò fara mọ́ ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì ń sọ nípa ìwà rere.” Lọ́nà kan náà, Joseph, ọmọ 20 ọdún, láti Taiwan, rí ìsìn bí ohun tó “jẹ́ ti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ jù.” Ṣùgbọ́n bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀dọ́ kò bá fara mọ́ ohun tí àwọn ìsìn wọn ń kọ́ wọn, kí ni wọ́n wá gbà gbọ́?
Ìsìn Lọ́nà Tó Wu Kálukú
Ní báyìí, ohun tó wọ́pọ̀ ni kí àwọn ọ̀dọ́ máa yan ìsìn bí wọ́n ṣe ń yan oúnjẹ tó bá wù wọ́n. Ìwé ìròyìn kan pè é ní “ṣíṣe” ìsìn “lọ́nà tó wu kálukú.” Ìwé ìròyìn Kátólíìkì kan pè é ní “fífojúrajà ìsìn.” Àwọn èrò tó ti ń di tàtijọ́ tẹ́lẹ̀ ló wá wọ́pọ̀ báyìí. Nípa bẹ́ẹ̀, ní Yúróòpù, nǹkan bí ìpín 33 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́ gbà gbọ́ nínú lílo àwúre, ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún gbà gbọ́ pé àwọn aláfọ̀ṣẹ lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la, ìpín 27 nínú ọgọ́rùn-ún sì gbà pé àwọn ìràwọ̀ ń nípa lórí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn. Àwọn èrò bí àtúnwáyé ti wá di apá kan nínú ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ èwe ará Yúróòpù báyìí.
Onírúurú ìgbàgbọ́ ìsìn wá pọ̀ débi pé àwọn ọ̀dọ́ lè yan àwọn èrò tó bá wù wọ́n. Àwọn díẹ̀ péré ló gbà pé ìsìn kan ṣoṣo ló lè jẹ́ òtítọ́. Níwọ̀n bí àwọn ọ̀dọ́ ti lè yan èyí tó bá wù wọ́n, ìyàtọ̀ àárín àwọn ìgbàgbọ́ ìsìn wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere. Nípa bẹ́ẹ̀ ni àwọn onímọ̀ ìbágbépọ̀-ẹ̀dá fi ń sọ nísinsìnyí nípa “ìgbádànù díẹ̀díẹ̀” tàbí “ìṣànlọ lápapọ̀” àwọn ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ aláyẹyẹ. Nínú àyíká tó rí báyìí nípa tẹ̀mí, èwo ni àwọn ẹ̀sìn ìbílẹ̀ ń ṣe?
Bí Ìsìn Ṣe Ń Wá Àwọn Ọ̀dọ́ Kiri
Ó ti di ìpèníjà fún àwọn ìsìn láti fa àwọn èwe mọ́ra. Àlùfáà ará ilẹ̀ Faransé kan béèrè nípa àwùjọ tó lọ síbi àjọyọ̀ Àwọn Ọjọ́ Èwe Lágbàáyé ti Kátólíìkì ní Paris pé: “Ibo ni àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ti wá? Kò sí àwọn èwe kankan nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì mi. N kì í rí wọn.” Látàrí bí Ìjọ Kátólíìkì ṣe ń fẹ́ fa àwọn èwe lọ́kàn mọ́ra, kí ó sì gbàfiyèsí wọn, ó ń ní láti yí ọ̀nà ìkọ́ni rẹ̀ àti èrò àwọn ènìyàn nípa rẹ̀ padà.
Ìwé ìròyìn Le Figaro ti ilẹ̀ Faransé polongo pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì ń yí ọ̀nà ìṣeǹkan rẹ̀ padà!” Ṣọ́ọ̀ṣì náà gba àwọn ilé iṣẹ́ tó nírìírí púpọ̀ nídìí ìṣètò ijó rọ́ọ̀kì láti bójú tó ètò fún ayẹyẹ kejìlá Àwọn Ọjọ́ Èwe Lágbàáyé ní Paris. Wọ́n ṣe àwọn àfihàn tó lé ní 300 láti dá àwọn èwe tó wá láti orílẹ̀-èdè tó lé ní 100 lára yá, wọ́n sì ṣe àkànṣe aṣọ tó ní orúkọ ilé iṣẹ́ tó ṣe é lára fún àwọn àlùfáà.
Nítorí pé ọ̀pọ̀ ìsìn kò lóye àwọn ọ̀dọ́ òde òní, tí wọ́n sì rí i pé ó di dandan kí àwọn mú ara bá ipò mu, wọ́n wá di ìsìn tajátẹran. Nígbà tí Michel Dubost, àlùfáà tó ṣètò ayẹyẹ Àwọn Ọjọ́ Èwe Lágbàáyé ní Paris ń sọ̀rọ̀ lórí ìlànà yìí, ó wí pé: “Dájúdájú, ì bá wù mí kí gbogbo àwọn tí a ti batisí ṣòtítọ́ sí Kristi. Àmọ́, ká tilẹ̀ ní wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀, a tẹ́wọ́ gbà wọ́n ní ṣọ́ọ̀ṣì.”
Àwọn Èwe Ń Fẹ́ Ìdáhùn
Nígbà tí ìwé ìròyìn kan ń tẹnu mọ́ ìjótìítọ́ pé àwọn èwe ń fẹ́ ìdáhùn, ó ṣàpèjúwe pípésẹ̀ tí àwọn èwe pésẹ̀ síbi ayẹyẹ ìsìn náà ní Paris bí “àfihàn wíwá ìgbàgbọ́ kiri, dípò kó jẹ́ àfihàn níní ìgbàgbọ́.” Ǹjẹ́ Ìjọ Kátólíìkì dáhùn irú ìwákiri bẹ́ẹ̀?
Bí o bá ká ìbòjú kúrò lójú àwọn ayẹyẹ ìsìn ńláńlá, tàbí tí o wo kọjá ohun tí ìwé ìròyìn Kátólíìkì kan pè ní “ìrísí ẹlẹ́tàn” tí wọ́n ní, kí lo máa rí? Ìwé ìròyìn Le Monde ti ilẹ̀ Faransé sọ̀rọ̀ nípa “àìsí ohun gidi kan” lẹ́yìn ìrísí oréfèé náà.
Nígbà tí ó yẹ kí àwo oúnjẹ wuni, ó sá yẹ kí oúnjẹ náà lè ṣara lóore. Àwọn ìbéèrè tí àwọn ọ̀dọ́ ń béèrè nípa ìtumọ̀ ìgbésí ayé nílò àwọn ìdáhùn tí ń ṣara lóore nípa tẹ̀mí. Àwọn ìdáhùn asán tí ń fani mọ́ra tí a ń fún àwọn èwe kò tẹ́ wọn lọ́rùn.
Ǹjẹ́ irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìsìn tí kò ní ohun gidi kankan nínú bẹ́ẹ̀ ń nípa pípẹ́ títí lórí àwọn èwe lónìí? Onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Danièle Hervieu-Léger, sọ pé: “Àwọn ìran àpéwò tí a ṣètò wọ̀nyí kò lè mú ipa pípẹ́ títí ní ti àjọṣe ẹ̀dá wá.” Ibo ni àwọn ọ̀dọ́ wá lè yíjú sí láti rí àwọn ìdáhùn tí ń tẹ́ni lọ́rùn fún àwọn ìbéèrè wọn?
Àwọn Ìdáhùn Tí Ń Tẹ́ni Lọ́rùn
Ní 1997, ìwé ìròyìn Le Point ti ilẹ̀ Faransé tẹ àpilẹ̀kọ kan jáde nípa àwọn ìṣòro tí àwọn ọ̀dọ́ ń dojú kọ. Láfikún sí àwọn ìbéèrè nípa ìtumọ̀ ìgbésí ayé tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́, wọ́n tún ní láti kojú ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti borí èyí? Àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Nígbà tí David wà ní ọmọ 30 ọdún, ó bẹ̀rẹ̀ sí dààmú nípa ipa tí ọtí líle, oògùn líle, àti ìwà ipá ń ní lórí ara rẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kanlẹ̀kùn ilé rẹ̀, wọ́n sì fún un ní ìdáhùn sí àwọn ìrètí rẹ̀ láti sọ ara rẹ̀ di mímọ́. Ó kẹ́kọ̀ọ́. Ó yí padà. Ó san àwọn gbèsè to jẹ nídìí tẹ́tẹ́, ó sì san àsanpadà fún gbogbo àwọn tí wọn kò tilẹ̀ mọ̀ pé ó ti rẹ́ àwọn jẹ nídìí ayò oníkáàdì. Kò mu sìgá mọ́, kò mutí mọ́, kò sì ń jà mọ́.”
Nípa àwọn èwe mìíràn tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àpilẹ̀kọ náà tẹ̀ síwájú pé: “Wọ́n ti rí ìdáhùn sí gbogbo ìbéèrè wọn.” Lọ́nà rírọrùn, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan sọ pé: “Bíbélì ti ń sọ òtítọ́ láti ẹgbàá ọdún wá, nítorí náà, èé ṣe tí n ó fi wá ìtọ́sọ́nà lọ síbòmíràn?”
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní àwọn ìsọfúnni fún àwọn èwe nínú. Àwọn ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ rẹ̀ ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro òde òní, ó sì ń fún wọn ní ìpìlẹ̀ tó fìdí múlẹ̀ fún gbígbàgbọ́ pé ọjọ́ ọ̀la alálàáfíà àti oníṣọ̀kan wà. Nínú ayé kan tí ń yí padà léraléra ṣáá, ìrètí tí Bíbélì ń fúnni jẹ́ “ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in,” ó ń múni dúró, ó sì ń tuni nínú. (Hébérù 6:19) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èwe ti rí ìtumọ̀ gidi nínú ìgbésí ayé wọn nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ti fúnra wọn rí bí Bíbélì ṣe ń mú ìyípadà tí kì í ṣe ti oréfèé lásán wá. Nípa títẹ́wọ́ gba àwọn ìdáhùn tí Bíbélì fúnni, àwọn èwe ń rí i pé a ń san èrè fún wíwá tí wọ́n ń wá ìgbàgbọ́ tòótọ́ kiri.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ayẹyẹ ìsìn ń fa ẹgbẹẹgbẹ̀rún èwe mọ́ra ní Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn Ọjọ́ Èwe Lágbàáyé ní Paris—ojúlówó ìmúsọjí ìsìn ni bí?