ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 6/8 ojú ìwé 16-17
  • Àrùn Àìlágbára Egungun—Àrùn ‘Egungun Kògbókògbó’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àrùn Àìlágbára Egungun—Àrùn ‘Egungun Kògbókògbó’
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2002
  • Àwọn Kẹ́míkà Tó Ń Ṣe Oríṣiríṣi Iṣẹ́ Nínú Ara
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Jí!—1997
g97 6/8 ojú ìwé 16-17

Àrùn Àìlágbára Egungun—Àrùn ‘Egungun Kògbókògbó’

“Àrùn àìlágbára egungun jẹ́ ipò kan tí egungun kò ti nípọn débi ti àwọn egungun fi máa ń tètè dá bí ohun tí kò tó nǹkan bá gbá a. Ẹnì kan tí ó ní àrùn àìlágbára egungun lè dá lọ́rùn ọwọ́ tàbí ní ìgbáròkó bí ó bá ṣubú sórí omi dídì tàbí kí ó dá ní egungun ìhà bí a bá gbá a mọ́ra tìfẹ́nitìfẹ́ni. . . . Ní tòótọ́, egungun lè ṣàìnípọn gan-an débi pé okùn ògóró ẹ̀yìn ẹnì kan lè dá bí ó bá wulẹ̀ gbéra rẹ̀ nílẹ̀.”—“Osteoporosis—A Guide to Prevention & Treatment,” tí John F. Aloia, M.D., kọ.

ÀRÙN àìlágbára egungun ha ń bá ọ jà bí? Àrùn sísọ egungun di tín-ínrín yìí wọ́ pọ̀ láàárín àwọn obìnrin tí wọ́n ti kọjá àkókò ìmọ́wọ́dúró nǹkan oṣù. Síbẹ̀, ó lè ṣe àwọn obìnrin àti ọkùnrin tí wọn kò dàgbà tó bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ètò Ìlera Àpapọ̀ Orílẹ̀-Èdè United States ti sọ, àrùn àìlágbára egungun ń ṣe “àwọn ènìyàn tí iye wọ́n tó mílíọ̀nù 15 sí 20 ní United States.” Lọ́dọọdún, ní United States, àrùn àìlágbára egungun ló ń fa nǹkan bí 1.3 mílíọ̀nù ìṣẹ̀lẹ̀ egungun dídá láàárín àwọn tí wọ́n wà ní ẹni ọdún 45 àti àwọn tí wọ́n dàgbà jù bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí ń náni ní bílíọ̀nù 3.8 dọ́là lọ́dọọdún.

Ìwé Health Tips, ìtẹ̀jáde Àjọ Ẹ̀kọ́ àti Ìṣèwádìí Ìmọ̀ Ìṣègùn ní California, ṣàlàyé pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àmì àrùn àìlágbára egungun máa ń hàn jù lọ nígbà tí ènìyàn bá ti darúgbó, ìṣẹ̀lẹ̀ àdánidá tí ń sọ egungun di aláìlera máa ń bẹ̀rẹ̀ ní gidi ní 30 sí 40 ọdún kí egungun tó dá fún ìgbà àkọ́kọ́. Lẹ́yìn ọdún 35, egungun àwọn ọkùnrin àti obìnrin yóò bẹ̀rẹ̀ sí í joro. Bí àwọn egungun náà ti ń fúyẹ́, tí wọ́n sì ń tín-ínrín sí i, ó lè dá lọ́nà tí ó túbọ̀ rọrùn, ó sì lè má jinná kíákíá nítorí pé kọ̀ rọrùn fún ara láti mú egungun tuntun jáde lọ́nà tí ó ń gbà ṣe é nígbà kan mọ́. A kò mọ ohun tí ń ṣokùnfà àìlágbára egungun, àmọ́ àìtó èròjà calcium àti fítámì D nínú oúnjẹ, ìwọ̀n omi ìsúnniṣe estrogen tí ó dín kù nínú obìnrin àti àìtó eré ìmárale le ṣàlékún mímú kí ó ṣẹlẹ̀.”

Ìwé náà, Understanding Your Body—Every Woman’s Guide to a Lifetime of Health, sọ pé, ọ̀kan lára àwọn àmì wíwọ́pọ̀ tí ó tan mọ́ ìmọ́wọ́dúró nǹkan oṣù ni ìpàdánù agbára egungun. Ó wí pé: “Àrùn àìlágbára egungun, ní olówuuru, àwọn egungun oníhò, jẹ́ àìlera wíwọ́pọ̀, tí ó sì ṣe kókó sí àwọn obìnrin lẹ́yìn ìmọ́wọ́dúró nǹkan oṣù.”

Ìwádìí fi hàn pé a lè dènà àrùn àìlágbára egungun, a sì lè ṣètọ́jú rẹ̀. Ìgbésẹ̀ ìṣèdílọ́wọ́ kan ni láti rí i dájú pé ara ní ìwọ̀n yíyẹ èròjà calcium àti fítámì D tí ó pọn dandan fún ṣíṣàmúlò calcium ara. Ìgbésẹ̀ ìṣèdílọ́wọ́ mìíràn ni eré ìmárale ti fífún egungun ní iṣẹ́ púpọ̀ sí i ṣe, bíi rírìn tàbí sísáré kúṣẹ́kúṣẹ́.

Dókítà Carol E. Goodman sọ nípa nínú ìwé àtìgbàdégbà Geriatrics pé: “Ó yẹ kí a júwe àtúnṣe bí wọ́n ṣe ń dúró àti àwọn eré ìmárale afúnnilókun—bí ìjúwe àwọn oògùn ṣe jẹ wá lógún ni èyí pẹ̀lú sì gbọ́dọ̀ jẹ wá lógún. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ eré ìmárale yíyẹ fún arúgbó alárùn àìlágbára egungun lè rọrùn láti lóye, rọrùn láti ṣe, kò sì léwu.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àrùn àìlágbára egungun kì í ṣe ohun tí a lè wò sàn, àwọn oògùn tuntun ti ń wà fún un. Síwájú sí i, a lè ṣèdíwọ́ fún un nípa oúnjẹ yíyẹ, eré ìmárale tí ó pọ̀ tó, àti fún àwọn kan, ìtọ́jú pípààrọ̀ omi ìsúnniṣe. Kí àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí lè gbéṣẹ́ lọ́nà tí ó dára jù lọ, o gbọ́dọ̀ máa ṣe wọ́n kí egungun tó bẹ̀rẹ̀ sí í joro, o sì gbọ́dọ̀ máa ṣe é lọ ní gbogbo àkókò tí o fi wà láàyè.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Ohun Adáàbòboni Lọ́wọ́ Àrùn Àìlágbára Egungun

1. Èròjà calcium

2. Fítámì D

3. Ìtànṣán oòrùn

4. Dídúró dáradára

5. Ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ fún ṣíṣètọ́jú ẹ̀yìn

6. Eré ìmárale

7. Àìmusìgá

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Èròjà Calcium Nínú Àwọn Oúnjẹ Wíwọ́pọ̀

Èròjà Calcium Inú Oúnjẹ (mílígíráàmù)

Mílíìkì tí kò ní fat nínú, ife 1 300

Wàràkàṣì dídì, ìgàn sẹ̀ǹtímítà 2.5. 130

Yúgọ́ọ̀tì, ife 1 300

Ẹran màlúù, adìyẹ, ẹja, 170 gíráàmù 30 sí 80

Ẹja salmon alágolo, gíráàmù 85 170

Búrẹ́dì, àwọn ọkà, ìrẹsì, ife 1 20 sí 50

Tofu (ẹ̀wà sóyà dídì), 100 gíráàmù 150

Álímọ́ńdì, ìdajì ife 160

Àsálà, ìdajì ife 50

Ewébẹ̀ broccoli, pádi kan 150

Ẹ̀fọ́ Tẹ̀tẹ̀, ife 1 200

Ewébẹ̀ turnip, ife 1 250

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ewébẹ̀ míràn, ife 1 40 sí 80

Èso apricot, gbígbẹ, ife 1 100

Èso date, tí a yọ hóró rẹ̀, ife 1 100

Ewéko rhubarb, ife 1 200

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èso mìíràn, ife 1 20 sí 70

Láti inú ìwé Understanding Your Body, tí Felicia Stewart, Gary Stewart, Felicia Guest, àti Robert Hatcher kọ, ojú ìwé 596.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Díẹ̀ Lára Àwọn Okùnfà Ewu Àrùn Àìlágbára Egungun

Àwọn Kókó Àjogúnbá

Obìnrin

Àìjẹ́ ẹ̀yà adúláwọ̀

Jíjẹ́ ìrandíran ìhà àríwá Europe

Jíjẹ́ ẹni pupa

Ọ̀pẹ́lẹ́ńgẹ́

Ẹni tí kò ga (sẹ̀ǹtímítà 157 tàbí tí kò gà tó bẹ́ẹ̀)

Kókó Ọ̀nà Ìgbésí Ayé

Yíyá oòrùn, tí kò tó wákàtí mẹ́ta lọ́sẹ̀

Jíjẹ èròjà calcium tí kò pọ̀ tó

Jíjẹ kaféènì púpọ̀ jù àti/tàbí ásíìdì phosphate púpọ̀ jù

Àwọn Oògùn

Oògùn adẹ̀rọ̀ ásíìdì tí ó ní aluminum nínú

Oògùn ìṣètọ́jú èkùrọ́ ọrùn tàbí omi ìsúnniṣe levothyroxine

Oògùn aleṣan (cortisone)

Oògùn Dilantin (ìtọ́jú tí a fà gùn)

Oògùn furosemide (tí ó nítẹ̀sí mímúnitọ̀ gan-an)

Àwọn Àìlera

Ìmọ́wọ́dúró nǹkan oṣù láìtó àsìkò

Àìrí nǹkan oṣù

Àrùn àìyánnú fún oúnjẹ

Àpọ̀jù èkùrọ́ ọrùn

Àrùn kíndìnrín tàbí òkúta kíndìnrín

Àtọ̀gbẹ

Àìtó èròjà lactase (àìfẹ́wàrà)

Àrùn inú ìfun (ìwúlé ìfun ńlá, ìwúlé ìfun kékeré)

Ìmukúmu ọtí

Wíwà lórí bẹ́ẹ̀dì tàbí ṣíṣàìlọ-síbikíbi fún àkókò tí ó ju ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lọ

Làkúrègbé oríkèé ara tí ń ṣeni lemọ́lemọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́