ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwwd àpilẹ̀kọ 44
  • Àwọn Kẹ́míkà Tó Ń Ṣe Oríṣiríṣi Iṣẹ́ Nínú Ara

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Kẹ́míkà Tó Ń Ṣe Oríṣiríṣi Iṣẹ́ Nínú Ara
  • Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àrùn Àìlágbára Egungun—Àrùn ‘Egungun Kògbókògbó’
    Jí!—1997
  • Kí Ni Àìbalẹ̀ Ọkàn?
    Jí!—2020
Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
ijwwd àpilẹ̀kọ 44
Obìnrin kan ń yẹ ọrùn ẹ̀ wò nínú dígí kó lè mọ̀ bóyá gbẹ̀gbẹ̀ yọ sí òun lọ́rùn.

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Àwọn Kẹ́míkà Tó Ń Ṣe Oríṣiríṣi Iṣẹ́ Nínú Ara

Kí ara wa lè máa ṣiṣẹ́ dáadáa, àwọn èròjà pàtàkì kan bíi calcium, tó máa ń wà nínú ẹ̀jẹ̀ kò gbọ́dọ̀ pọ̀ jù, kò sì gbọ́dọ̀ kéré jù. Àmọ́ iye àwọn èròjà yìí tó máa ń wà nínú oúnjẹ tá à ń jẹ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan máa ń pọ̀ jura lọ. Báwo ni ara wa ṣe máa ń ṣe é tí èròjà yìí ò fi ní pọ̀ jù tàbí kéré jù nínú ẹ̀jẹ̀ wa?

Ohun tí ara èèyàn tó bá jí pépé máa ń ṣe ni pé ó máa ń pèsè àwọn kẹ́míkà kan tí wọ́n ń pè ní hormones, á tọ́jú ẹ̀ pa mọ́, á sì tú u jáde sínú ẹ̀jẹ̀ nígbà tó bá yẹ. Àwọn kẹ́míkà yìí ni kì í jẹ́ kí àwọn èròjà pàtàkì tá a nílò pọ̀ jù tàbí kéré jù nínú ẹ̀jẹ̀. Oríṣiríṣi iṣẹ́ làwọn kẹ́míkà yìí ń ṣe nínú ara. Kódà, ìwọ̀nba bíńtín nínú kẹ́míkà yìí lè yí ọ̀pọ̀ nǹkan pa dà nínú ara wa. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia Britannica sọ pé àwọn kẹ́míkà yìí “kì í kàn ṣàdédé tú jáde sínú ẹ̀jẹ̀; àmọ́ ó máa ń tú jáde nígbà tí ara bá nílò ẹ̀ àti ní ìwọ̀n tó yẹ gẹ́lẹ́.”

Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀yà ara kéékèèké kan tí wọ́n ń pè ní parathyroid gland tó wà níbi ọrùn ló máa ń mọ̀ tí ìyípadà kékeré bá wáyé nínú iye èròjà calcium tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ wa. Mẹ́rin làwọn ẹ̀yà yìí sábà máa ń jẹ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kì í sì í ju hóró ìrẹsì kan lọ.

Àwòrán: Àwòrán ẹ̀yà thyroid. 1. Àwòrán ibi tí thyroid wà ní ọrùn láti iwájú. 2. Àwòrán thyroid láti ẹ̀yìn tó jẹ́ ká rí ibi táwọn parathyroid gland wà.

Táwọn ẹ̀yà yìí bá ti rí i pé èròjà calcium tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ ti dín kù, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, wọ́n á ti tú kẹ́míkà kan sínú ẹ̀jẹ̀, ìyẹn ló sì máa jẹ́ káwọn egungun tú èròjà calcium tí wọ́n ti tọ́jú pa mọ́ jáde sínú ẹ̀jẹ̀. Bákan náà, kẹ́míkà yìí ló máa ń dá àwọn kíndìnrín dúró kó má bàa sẹ́ èròjà calcium kúrò nínú ẹ̀jẹ̀. Kẹ́míkà yìí náà ló máa ń jẹ́ kí ìfun lè tọ́jú èròjà calcium tó pọ̀ tó látinú oúnjẹ tá à ń jẹ.

Àmọ́ tí èròjà calcium bá ti pọ̀ jù nínú ẹ̀jẹ̀, ẹ̀yà míì nínú ara tó ń jẹ́ thyroid máa tú kẹ́míkà míì jáde. Ìyẹn ló máa jẹ́ káwọn egungun tọ́jú èròjà calcium tó pọ̀ dáadáa, kí àwọn kíndìnrín sì sẹ́ èyí tó bá ṣẹ́ kù kúrò nínú ẹ̀jẹ̀.

Méjì péré la ṣàlàyé yìí nínú àwọn kẹ́míkà tó lé ní ọgọ́rùn-ún tí ara wa ń lò láti ṣe oríṣiríṣi nǹkan nínú ara.

Kí lèrò ẹ? Ṣé àwọn kẹ́míka yìí kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́