Wíwo Ayé
Iye Mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Ń Dín Kù
A lérò pé lára àwọn tí a bí sínú àwọn ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì tó lórúkọ ní United States, láàárín 30 ọdún tó kọjá, iye àwọn tí ó dúró sínú ẹ̀ka ìsìn tí a bí wọn sí nígbà tí wọ́n dàgbà tán kò tó ìdajì. Mílíọ̀nù 78 ènìyàn ni a fojú díwọ̀n ní United States pé wọ́n jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì “lórúkọ lásán.” Èyí túmọ̀ sí pé, wọ́n ń fi ara wọn hàn bí ọmọ ìjọ Onítẹ̀bọmi, Episcopal, Mẹ́tọ́díìsì, Presbyterian, tàbí ti àwọn ìjọ Pùròtẹ́sítáǹtì míràn, àmọ́ a kò mọ̀ wọ́n ní ṣọ́ọ̀ṣì, wọn kì í sì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò.
Àwọn Oníṣòwò Egungun
Ilé iṣẹ́ ìròyìn Reuters ròyìn pé: “Àwọn olùgbékútà olùgbé Kabul tí ogun ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ń hú egungun òkú ènìyàn tà láti fi ṣe oúnjẹ adìyẹ.” Nítorí tí egungun ní ọ̀pọ̀ èròjà calcium, phosphate, àti carbonate, a máa ń fi ṣe oúnjẹ ẹranko, ọṣẹ, àti epo ìseǹkan. Wọ́n ń ta egungun òkú tí ó bá wọn nǹkan bíi kìlógíráàmù mẹ́fà ní iye owó tó pọ̀ tó 50 sẹ́ǹtì, tí ó jẹ́ owó ńlá gan-an ní ìlú tí kò lọ́rọ̀ rárá yẹn. Faizdeen, ọmọ ọdún 14, sọ pé: “Òwò tó pé ni. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, mo sábà máa ń ṣa egungun ẹranko, ó túbọ̀ rọrùn láti rí egungun ènìyàn níhìn-ín.” Ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti fi jagun ní Afghanistan ti mú kí ọjà tó ní ọ̀pọ̀ mineral nínú yìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹpẹtẹ.
Àwọn Agogo Ọwọ́ Tí Ń Sọ Ju Àkókò Lọ
Ìwé agbéròyìnjáde O Globo ròyìn pé, ní Rio de Janeiro, wọ́n já àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 77 bọ́ lẹ́yìn tí wọ́n rí agogo ọwọ́ tí wọ́n fi ń ṣe awúrúju nínú ìdánwò àṣewọ-yunifásítì kan. Àwọn agogo náà ń ṣiṣẹ́ gan-an bí ẹ̀rọ tí ń gba nọ́ńbà tẹlifóònù; àmọ́, kàkà kí wọ́n máa gba nọ́ńbà tẹlifóònù, àwọn ìdáhùn yíyẹ fún àwọn ìbéèrè ìdánwò ni wọ́n ń mú jáde. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń ra ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn agogo náà ní iye tí ó tó 14,000 dọ́là. Ó dùn mọ́ni pé, láti ọdún 1987 ni àwọn ìgbìmọ̀ ìdánwò ilé ẹ̀kọ́ ní ilẹ̀ England àti Wales ti ń kìlọ̀ fún àwọn olùkọ́ pé kí wọ́n máa wà lójúfò nítorí àwọn aláwúrúju tí ń lo àwọn agogo ọwọ́ oníkọ̀ǹpútà
Ìríran Dídojúrú
Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn tí ń wo dígí ń fara mọ́ ohun tí wọ́n ń rí—ara wọn. Àmọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn tí ó ní àrùn kan tí a mọ̀ sí àrùn àìgúnrégé ìrísí ara bá wo dígí, ìrísí ara wọn tí kò gún régé ni wọ́n máa ń rí. Ìwé agbéròyìnjáde The Province, ti British Columbia, Kánádà, sọ pé: “Ó jẹ́ àrùn kan tí ń mú kí àwọn ènìyàn finú rò pé apá kan ara wọn burẹ́wà, nígbà tí ó ṣe pé, ní gidi, kò sí ohun tó ṣe é.” Oníṣègùn ọpọlọ, Eric Hollander, láti New York, sọ pé ìrora ẹ̀dùn lórí àwọn àìgúnrégé tí a finú rò lè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí nǹkan bí ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí àrùn náà ń ṣe fi ń gbìdánwò láti fúnra wọn para wọn.
Fífi Àdúrà Ránṣẹ́ Lórí Kọ̀ǹpútà
Ó pẹ́ tí àwọn Júù onítara-ìsìn ti máa ń kóra jọ níbi Àwókù Odi tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù láti sunkún, kí wọ́n sì gbàdúrà. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn olùjọ́sìn ń kọ àdúrà sórí ègé pépà, wọ́n sì ń fi wọ́n há ara àlàpà ògiri náà. Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí, àwọn Júù kárí ayé lè fi àdúrà ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà tí a so mọ́ àgbékalẹ̀ Internet. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Computerworld ṣe sọ, àwọn òṣìṣẹ́ Ibùdó Ìsọfúnni ti Virtual Jerusalem ń ṣàkójọ àwọn àdúrà náà, wọ́n ń tẹ̀ wọ́n jáde, wọ́n sì ń kó wọn lọ síbi Àwókù Odi náà, níbi tí “Ọlọ́run ti lè kó wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù ṣe sọ.”
Àìdọ́gba Iye Owó Tí Ń Wọlé Ń Pọ̀ Sí I
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé jáde nípa ìdàgbàsókè àwùjọ ṣe sọ, ìpín 83 nínú ọgọ́rùn-ún owó tí ń wọlé lágbàáyé ń wọlé fún ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún tí ó lọ́lá jù lọ nínú iye ènìyàn. Ká sọ ọ́ lọ́nà míràn, àpapọ̀ ọrọ̀ àwọn 358 bilọníà tó wà lágbàáyé dọ́gba pẹ̀lú àpapọ̀ gbogbo owó tí ń wọlé fún 2,400,000,000 ènìyàn tó tálákà jù lọ. Ní 1960, ìpíndọ́gba iye owó tí ń wọlé lọ́dọọdún fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè oníléeṣẹ́ ńláńlá fi 5,700 dọ́là ju ti àwọn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ní 1993, ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìpíndọ́gba owó tí ń wọlé fún ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́dọọdún ní àwọn orílẹ̀-èdè oníléeṣẹ́ ńláńlá àti ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ti lọ sókè sí 15,400 dọ́là.
Ìkórè Àrà Ọ̀tọ̀
Ilé iṣẹ́ ìròyìn Reuters sọ pé: “Fún ìgbà kíní nínú ìtàn China, àwọn ẹ̀rọ ti gbéṣẹ́ ju ènìyàn lọ nínú oko àlìkámà orílẹ̀-èdè náà.” Ó sọ pé wọ́n lo ẹ̀rọ ìkórè tí ó lé ní 800,000. Wọ́n kọ́kọ́ mú àlìkámà dé China ní àkókò kan ṣáájú ọdún 1300 ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n sì ti ṣọ̀gbìn rẹ̀ yọrí nínú oko ìdílé kéékèèké—ní lílo ọwọ́—láti ìgbà náà wá. Ṣùgbọ́n nítorí tí China ní ju ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún iye ènìyàn lágbàáyé lọ, tí ó sì ní kìkì ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ̀ oko, ìròyìn náà sọ pé, “àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀gbìn ń hára gàgà láti mú kí ìlò ẹ̀rọ gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú àwọn oko orílẹ̀-èdè náà.”
Àwọn Ìṣòro Ìbánigbófò Àwùjọ Àlùfáà
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣètò ìbánigbófò láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ewu ìpalára ara ẹni. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé agbéròyìnjáde National Underwriter sọ pé, àwọn ilé iṣẹ́ abánigbófò ní United States ti bẹ̀rẹ̀ sí í yọ “ìwà pálapàla ìbálòpọ̀” tí àwùjọ àlùfáà ń hù kúrò nínú àwọn ohun tí wọ́n lè báni gbófò rẹ̀. John Cleary, olùdámọ̀ràn àgbà fún Ilé Iṣẹ́ Abánigbófò Church Mutual, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ . . . ìlànà ìbánigbófò ni yóò yọ ìwà pálapàla ìbálòpọ̀ kúrò nínú ohun tí ó lè báni gbófò rẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ ìwà àmọ̀ọ́mọ̀hù, ìwà ọ̀daràn ni, ní gidi.” Síwájú sí i, Donald Clark, Kékeré, amòfin kan tí ń ṣojú fún onírúurú àwùjọ onísìn, sọ pé, àwọn ìyípadà ìbánigbófò wọ̀nyí ń tọ́ka sí i pé “ó ṣeé ṣe kí àwọn ewu àbájáde búburú lórí ọ̀ràn ìṣúnná tí irú àwọn ìjábá tí ènìyàn ń fọwọ́ fà wọ̀nyí lè mú wá máa ṣèparun ju àwọn àbájáde tí ń wá láti inú àwọn ìjábá àdánidá lọ.” Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni Cleary ti wí, láti 1984 wá, ilé iṣẹ́ Church Mutual, ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ tí ń bá ṣọ́ọ̀ṣì gbófò ní United States, ti ní láti sanwó lórí 1,500 sí 2,000 ọ̀ràn ìwà pálapàla ìbálòpọ̀.
Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Láti Singapore Gbapò Iwájú
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó lé ní ìdajì mílíọ̀nù láti àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ 41 ṣe ìdánwò tí ó gba 90 ìṣẹ́jú kan láti ṣàfiwéra ìwọ̀n ẹ̀kọ́ yí ká ayé. Kí ni àbájáde rẹ̀? Àwọn máàkì tí wọ́n gbà fi hàn pé Singapore ló ń pèsè àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó dára jù lọ nínú ìṣirò àti sáyẹ́ǹsì. Àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́wàá tó tún gbapò iwájú nínú ìṣirò tẹ̀ lé Singapore ni Gúúsù Korea, Japan, Hong Kong, Belgium, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Slovak, Switzerland, Netherlands, àti Slovenia. Àwọn tó gbapò iwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ni Singapore, Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech, Japan, Gúúsù Korea, Bulgaria, Netherlands, Slovenia, Austria, Hungary, àti ilẹ̀ England. Báwo ni orílẹ̀-èdè kan, tí ó ní kìkì 3,400,000 ènìyàn ṣe gbégbá orókè ju gbogbo ayé yòó kù lọ ní kedere bẹ́ẹ̀? Bóyá nípasẹ̀ iṣẹ́ aláápọn. Ìwé ìròyìn Asiaweek ròyìn pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Singapore ń lo ìpíndọ́gba wákàtí 4.6 lóòjọ́ ní ṣíṣe iṣẹ́ àṣetiléwá, nígbà tí ìpíndọ́gba ti àgbáyé jẹ́ wákàtí 2 sí 3.
Owó Láti Ọ̀run Kẹ̀?
Inú àwọn olùgbé Overtown, àdúgbò tí kò lọ́rọ̀ kan ní Miami, Florida, dùn dẹ́yìn nígbà tí ó jọ pé owó ń já bọ́ láti ojú òfuurufú. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó ti wá já sí, kì í ṣe mánà láti ọ̀run, ṣùgbọ́n ó jẹ́ lára ẹrù owó mílíọ̀nù 3.7 dọ́là tí ó fọ́n ká sí títì nígbà tí ọkọ̀ akẹ́rù ológun kan forí sọ nǹkan ní ọ̀nà àgbégbòkè kan ní àdúgbò náà. Àwọn ọlọ́pàá díye lé e pé, ó kéré tán, 100 ènìyàn ló lọ kó owó náà, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ gan-an. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ṣe wí, “àwọn ọlọ́pàá Miami fún àwọn tí owó náà bá wà lọ́wọ́ wọn láyè wákàtí 48 láti dá a pa dà, láìsí pé a pè wọ́n lẹ́jọ́ olè jíjà.” Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò ojú àánú náà fi parí, ènìyàn mẹ́ta péré ló dá owó kankan pa dà, nǹkan bí 500,000 dọ́là ni a ṣì ń wá. A gbọ́ pé, ọ̀dọ́ ọlọ́dún 18 kan sọ pé: “Àwé, inú ọgbà àwọn ènìyàn ló balẹ̀ sí. Kí lo retí pé kí wọ́n ṣe?”
Àwọn Aláìsàn Tí Ara Wọn Ń Móoru Nígbà Iṣẹ́ Abẹ
Ìwádìí tuntun kan tí Daniel Sessler, oníṣègùn apàmọ̀lárakú kan ní Yunifásítì California, ṣe sọ pé, àwọn iyàrá iṣẹ́ abẹ ilé ìwòsàn tí a mú tutù nini láti dín ìmúdàgbà bakitéríà tí afẹ́fẹ́ ń gbé kiri kù, ń sọ ewu kíkó àrùn di ìlọ́po mẹ́ta. Dókítà Sessler sọ pé: “Ohun tí ń fa kíkó àrùn ojú ọgbẹ́ kì í ṣe bakitéríà tí ń kiri nínú afẹ́fẹ́ ní gidi, ṣùgbọ́n dídín tí a dín agbára ìgbógunti bakitéríà nínú awọ ara tàbí nínú ara aláìsàn náà kù.” Iyàrá iṣẹ́ abẹ títutùnini lè mú kí ìdíwọ̀n ooru ara aláìsàn lọ sílẹ̀ tó ìwọ̀n 2.2 lórí òṣùwọ̀n Celsius. Ìdíwọ̀n ooru ara tó bá sì kéré máa ń dín ìṣàn ẹ̀jẹ̀ tó ní afẹ́fẹ́ oxygen nínú, tó ṣe kókó fún gbígbéjàko-àrùn, kù. Sessler sọ pé, “àwọn sẹ́ẹ̀lì àti èròjà amóúnjẹdà tí ń gbógun ti àrùn kì í ṣiṣẹ́ lọ́nà jíjáfáfá nígbà tí ara bá tutù.” Sessler àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí i pé, láfikún sí dídín ìwọ̀n àrùn kíkó kù, àkókò tí àwọn olùgbàtọ́jú tí ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù ara wọn ń wà bó ti yẹ nígbà iṣẹ́ abẹ ń lò nílé ìwòsàn ń fi èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọjọ́ mẹ́ta dín sí ti àwọn tí ara wọn kò móoru.
Kì Í Ṣe fún Àǹfààní Aráàlú
Ìwé agbéròyìnjáde Mainichi Daily News ròyìn pé, ní Japan, ìpín 49 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ pé, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba wọn wulẹ̀ ń ṣe iṣẹ́ fún ara wọn ni. Kìkì ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò náà ló rò pé àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ń ṣiṣẹ́ fún “àǹfààní aráàlú,” ìpín 3 péré nínú ọgọ́rùn-ún sì sọ pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún orílẹ̀-èdè náà. Ìwọ̀n kéréje àwọn ará Japan ló ṣàpèjúwe àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí aláápọn àti olóòótọ́ ọkàn. Ìwádìí náà wáyé ní oṣù December tó kọjá, tẹ̀ lé ọdún kan tí àṣírí àwọn ìwà ẹ̀gàn mélòó kan, tí àwọn lọ́gàálọ́gàá oníṣẹ́ ọba mélòó kan ní Japan hù, tú síta.