Singapore—Ọ̀ṣọ́ Iyebíye Ilẹ̀ Éṣíà Tí Wọ́n Bà Jẹ́
PẸ̀KẸ̀N! Ní títọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ ibi, ilẹ̀kùn onírin ńlá ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Àwọn Obìnrin Changi ní Singapore pa dé mọ́ opó kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún 71, tí ó jẹ́ Kristẹni kan. Ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ti gbìyànjú láti ṣàlàyé ipò ìdúró rẹ̀ fún adájọ́ tí ó wà lórí àléfà pé: “N kì í ṣe ewu sí ìjọba yìí.”
Pẹ̀kẹ̀n! Ìyá àgbà kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún 72 tẹ̀ lé e, Kristẹni míràn. Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? Ó ní àwọn ìtẹ̀jáde mẹ́rin, tí a gbé karí Bíbélì, tí Watch Tower Society ṣe lọ́wọ́, papọ̀ pẹ̀lú ẹ̀dà Bíbélì Mímọ́ tirẹ̀.
Lápapọ̀, àwọn 64 tí wọ́n jẹ́ ọmọ́ ilẹ̀ Singapore, láti ọmọ ọdún 16 sí ẹni ọdún 72, ni wọ́n fàṣẹ ọba mú, tí wọ́n sì dájọ́ pé wọ́n jẹ̀bi. Àwọn 47 kọ̀ jálẹ̀ láti san owó ìtánràn lórí ìpinnu ṣíṣe ohun tó tọ́, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n fún ìwọ̀n àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó wà láti orí ọ̀sẹ̀ kan sí ọ̀sẹ̀ mẹ́rin. Báwo ni èyí ṣe lè ṣẹlẹ̀ ní ìlú ńlá ilẹ̀ olómìnira tí a ṣàpèjúwe bí ọ̀kan lára àwọn ibi dídára jù lọ láti gbé ní gbogbo àgbáyé? Báwo ni èyí ṣe lè ṣẹlẹ̀ ní ìlú ńlá ilẹ̀ olómìnira kan tí ó lókìkí jákèjádò ayé nítorí ipò ọrọ̀ ajé rẹ̀ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀, ìtẹ̀síwájú jíjọnilójú, àti àwọn ilé ìgbàlódé àti ìfàyè-gba-ìsìn tí ó sọ pé òun ní?
Ìlú Ńlá Ilẹ̀ Olómìnira Ìgbàlódé
Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ gbọ́ ìtàn ráńpẹ́ nípa rẹ̀. Ìtàn òde òní nípa Singapore bẹ̀rẹ̀ ní 1819 nígbà tí Alàgbà Thomas Stamford Raffles láti Britain dé ibẹ̀. Raffles tí ó jẹ́ aṣojú Ilé Iṣẹ́ Ìlà Oòrùn Íńdíà, ń wá ìpìlẹ̀ ìgbéṣẹ́ṣe ní ìhà Ìlà Oòrùn ayé. Ó pinnu láti ronú nípa Singapore. Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ̀ òwò ṣíṣe tí ó ti ní ipa kan lórí ìdàgbàsókè Ìlà Oòrùn Éṣíà títí di oní olónìí yìí.
Ṣáájú kí Singapore tó gba òmìnira, a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ bí ìlú ńlá tí ó rí wúruwùru. Lónìí, kò sí ẹni tí yóò ṣàpèjúwe Singapore bí èyí tí ó rí wúruwùru. Òdì kejì rẹ̀ ni ó jẹ́. Láàárín 30 ọdún tó kọjá, wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣàtúnkọ́ ìlú ńlá náà tán, níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe, wọ́n fi àwọn ohun tí ó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀ yálà nípa fífi iwájú àwọn ògbólógbòó ilé sílẹ̀ tàbí títún odindi ìgbékalẹ̀ àwọn ilé ọlọ́rọ̀ ìtàn náà ṣe sí àwọn ilé ìgbàlódé. Singapore ti di oríta ètò ìrìnnà ọkọ̀ ní etíkun ìhà Ìlà Oòrùn, ó sábà máa ń ní tó 800 ọkọ̀ òkun ní èbúté nígbà kan. Àwọn ohun èlò ìṣiṣẹ́ ọlọ́gbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga ti ìgbàlódé ń jẹ́ kí a lè já ẹrù kúrò nínú ọkọ̀ òkun akẹ́rù kan kí a sì tún di ẹrù sí i láàárín wákàtí mélòó kan. Iye owó dúkìá ilé àti ilẹ̀ àgbègbè ètò ọrọ̀ ajé ìlú ńlá náà ga tó 60,000 dọ́là tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lórí mítà kan níbùú lóròó.
Iye àwọn olùgbé ibẹ̀ tí a fojú díwọ̀n sí 3,400,000 ní onírúurú àwọn ará China, Malaysia, Íńdíà, Europe, àti àwọn mìíràn nínú. Lára àwọn èdè tí wọ́n ń sọ ni Mandarin, Malay, Tamil, àti Gẹ̀ẹ́sì.
Àwọn ọ̀nà orí ilẹ̀ yíyá kánkán àti ti abẹ́lẹ̀ oníkìlómítà 83 ń jẹ́ kí Singapore ní ìgbékalẹ̀ ètò ìrìnlọrìnbọ̀ tí ó gbéṣẹ́, tí ó sì jẹ́ ti ìgbàlódé jù lọ lágbàáyé. Àwọn ọgbà ìtura tí ó kún fún ohun ọ̀gbìn wà lọ́pọ̀ yanturu káàkiri ìlú ńlá náà, láàárín àwọn ilé ìgbàlódé gíga gogoro ibẹ̀. Ohun “jíjojúnígbèsè” kan fún arìnrìn-àjò afẹ́ tí kò tí ì dé ibẹ̀ rí ni Hòtẹ́ẹ̀lì Raffles tí a tún kọ́ lódindi, tí a tọ́ka sí ní pàtó bí ohun ìrántí orílẹ̀-èdè nítorí tí ó pilẹ̀ ṣẹ̀ ní 1889. Èkejì ni ibi àkójọ àwọn ewéko àti ti ohun ọ̀gbìn tí ó jẹ́ hẹ́kítà 52, tí hẹ́kítà 4 lára rẹ̀ jẹ́ igbó àìro, tí àwọn ẹkùn máa ń káàkiri inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí.
A Mú Ẹ̀rí Òmìnira Ìsìn Dáni Lójú
Gẹ́gẹ́ bí àṣekún sí ìtẹ̀síwájú ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ tí kò láfiwé, Singapore ṣèlérí òmìnira ìsìn fún gbogbo àwọn olùgbé ibẹ̀. Ó dunni pé Singapore kò tí ì mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ní pàtàkì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí i pé ìyẹn jẹ́ òtítọ́.
Àkọsílẹ̀ Òfin Orílẹ-Èdè Olómìnira Singapore pèsè ìpìlẹ̀ ìfọwọ́sọ̀yà fún òmìnira ìjọsìn ní Ẹ̀ka 15(1) pé: “Olúkúlùkù ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́wọ́ ìsìn rẹ̀, kí ó sì máa ṣe é, kí ó sì máa tàn án kálẹ̀.”
Ẹ̀ka 15(3) nínú Àkọsílẹ̀ Òfin náà sọ pé: “Gbogbo ẹgbẹ́ onísìn ní ẹ̀tọ́—
(a) láti bójú tó àwọn àlámọ̀rí ìsìn rẹ̀;
(b) láti fìdí àwọn ẹgbẹ́ múlẹ̀, kí ó sì bójú tó o fún àwọn ète ti ìsìn tàbí ọrẹ àánú; àti
(d) láti kó ohun ìní jọ, kí ó sì jẹ́ tirẹ̀, kí ó sì ní in, kí ó sì lò ó lọ́nà tí ó bófin mu.”
Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn, ní ọdún 1936, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára ẹgbẹ́ àwùjọ Singapore. Fún ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n fi ń bá ṣíṣe àwọn ìpàdé ìjọ lọ déédéé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tí ó wà ní Ojúlé 8, Òpópónà Exeter, ní ìdojúkọ ọjà kan tí wọ́n máa ń ná nígbà gbogbo. Ìjọ náà kún dáadáa, lákòókò kan náà, ó ń kó ipa aláìlẹ́gbẹ́ tirẹ̀ ní mímú kí ìgbésí ayé àwùjọ fẹsẹ̀ múlẹ̀.
Wọ́n Fòfin De Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
Gbogbo èyí yí pa dà ní January 12, 1972. Wọ́n gbé àṣẹ kan jáde tí wọ́n fi lé àwọn ènìyàn kúrò nílùú lábẹ́ Òfin Ìjọba ti Ìlénìyànkúrò-láwùjọ, orí 109, tí ó pa á láṣẹ fún míṣọ́nnárì Kristẹni náà, Norman David Bellotti, àti aya rẹ̀, Gladys, tí wọ́n ti lo ọdún 23 ní Singapore, láti fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀. Kíá, òfin kan tí ó fagi lé ìforúkọsílẹ̀ Ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Singapore tẹ̀ lé èyí. Láàárín wákàtí mélòó kan, àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n já ilẹ̀kùn iwájú ti gba Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n gbé ìfòfindè lábẹ́ àṣẹ kan jáde lórí gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Watch Tower Society. Bí àkókò kíká Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ kò ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn.
Lẹ́yìn náà, ìjọba ta Gbọ̀ngàn Ìjọba náà bí ọ̀kan lára àwọn ìgbésẹ̀ àìdúrógbẹ́jọ́ wọn, wọ́n sì ṣe gbogbo èyí láìsí ìsọfúnni tẹ́lẹ̀—kò sí ìjẹ́jọ́, kò sí ìgbẹ́jọ́, kò sí àǹfààní láti fèsì.
Ìjọba Singapore ti tọ́ka léraléra sí àìkópa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú iṣẹ́ ológun gẹ́gẹ́ bí ìdí tí ó fi yẹ láti fòfin dè wọ́n pátápátá. Ní àkókò kan tí kò tí ì pẹ́, ní December 29, 1995, Ọ̀gbẹ́ni K. Kesavapany, aṣojú Singapore títí lọ ní Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní Geneva, sọ àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí nínú lẹ́tà kan tí ó kọ sí H. E. Ibrahim Fall, Igbákejì Akọ̀wé Àgbà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn, ní Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní Geneva, pé:
“Ohun tí ó fà á tí Ìjọba mi fi fòfin de ìgbòkègbodò ẹgbẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ nítorí ààbò orílẹ̀-èdè. Bí ẹgbẹ́ náà bá ń bá a lọ, yóò jẹ́ ìpalára fún ire àwọn ará ìlú àti ìwàlétòlétò nǹkan ní Singapore. Ohun kan tí ó dọ́gba lọ́nà pípọndandan pẹ̀lú ìfagilé ìforúkọsílẹ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé kí a ka gbogbo àwọn ìtẹ̀jáde wọn léèwọ̀ láti lè fún fífòfinde ẹgbẹ́ náà lókun àti láti ṣẹ́pá títan èrò ìgbàgbọ́ wọn kálẹ̀ àti sísọ ọ́ di púpọ̀.”
Lójú ìkìlọ̀ jíjẹ́ ewu fún ààbò orílẹ̀-èdè Singapore, ó yẹ kí a ṣàkíyèsí pé iye àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n kọ iṣẹ́ ológun jẹ́ nǹkan bí ẹni márùn-ún láàárín ọdún kan. Singapore ní àwọn ọmọ ogun tí iye wọ́n jẹ́ nǹkan bí 300,000. Ìjọba Singapore ti kọ̀ jálẹ̀ láti jíròrò iṣẹ́ tí kì í ṣe ti ológun ní orílẹ̀-èdè fún ìwọ̀nba àwọn ènìyàn tí ọ̀ràn náà kàn.
Ìkálọ́wọ́kò Tí A Kò Fi Bò
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún lábẹ́ ìráragbaǹkan tí kò dájú, apá tuntun tí a kò fi bò nínú ìkálọ́wọ́kò ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ ní 1992 nígbà tí wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn ènìyàn bíi mélòó kan—tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a kà léèwọ̀ lábẹ́ Òfin Àwọn Ìtẹ̀jáde Tí A Kò Nífẹ̀ẹ́ Sí. Watch Tower Society rán W. Glen How, Agbẹjọ́rò Ayaba, amòfin kan tí ó jẹ́ ẹni ọdún 75, tí ó sì ti jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ìgbà tí ó ti dáyé, lọ sí Singapore ní 1994. Ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Agbẹjọ́rò Ayaba jẹ́ kí wọ́n yọ̀ǹda fún un láti fara hàn ní àwọn ilé ẹjọ́ Singapore. Lójú ẹ̀rí fífi ìsìn dáni lójú nínú Àkọsílẹ̀ Òfin, wọ́n kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Singapore, títí kan pípe ìlẹ́sẹ̀ńlẹ̀ ìfàṣẹmúni náà àti ìkàléèwọ̀ ti 1972 náà níjà lábẹ́ òfin. Ní August 8, 1994, Adájọ́ Àgbà Yong Pung How, ti Ilé Ẹjọ́ Gíga Singapore, fagi lé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn náà. Àwọn ìsapá síwájú sí i láti pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nípa ìpinnu náà kò kẹ́sẹ járí.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1995, ó jọ pé ìpẹ̀jọ́ tí a gbé karí Àkọsílẹ̀ Òfin Singapore ti tanná ran àwọn ìkálọ́wọ́kò púpọ̀ sí i pàápàá. Lábẹ́ ìwéwèé bíi ti ẹgbẹ́ ológun kan tí wọ́n pè ní Ìgbéṣẹ́ṣe Onírètí, àwọn òṣìṣẹ́ ọba tí wọ́n jẹ́ amí láti Ẹ̀ka Àwọn Ẹgbẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti inú Ẹ̀ka Ìṣèwádìí Ìwà Ọ̀daràn já wọ àwùjọ kéékèèké mélòó kan ti àwọn Kristẹni tí ń ṣèpàdé ní àwọn ilé àdáni. Ó kéré tán 70 ọlọ́pàá àti àwọn òṣìṣẹ́ aṣètìlẹ́yìn ni wọ́n wá fi ogun kó àwọn ènìyàn náà, tí ó yọrí sí fífàṣẹ ọba mú ènìyàn 69. Wọ́n kó gbogbo àwọn ènìyàn náà lọ sí àwọn ibùdó ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò, wọ́n béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn kan fún gbogbo òru náà, wọ́n sì fẹ̀sùn lílọ sí àwọn ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti níní àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì kan gbogbo wọn. Wọ́n fi àwọn kan sí àhámọ́ àdáwà fún ohun tí ó tó wákàtí 18, tí wọn kò tilẹ̀ lè tẹ àwọn ìdílé wọn láago.
Wọ́n jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn àjèjì. Ṣùgbọ́n wọ́n gbẹ́jọ́ àwọn 64 tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Singapore ní ilé ẹjọ́ ní apá ìparí 1995 àti ní ìbẹ̀rẹ̀ 1996. Wọ́n dá gbogbo àwọn 64 náà lẹ́bi. Àwọn 47 lára wọn, tí wọ́n wà láàárín ọdún 16 sí 72, kò san owó ìtánràn tí ó jẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n tí ó pẹ́ tó láti ọ̀sẹ̀ kan sí mẹ́rin.
Kí wọ́n tó kó wọn lọ sí túbú wọn, wọ́n bọ́ tọkùnrin tobìnrin wọn síhòòhò, wọ́n sì yẹ gbogbo ara wọn wò lójú àwọn ènìyàn bíi mélòó kan. Wọ́n ní kí àwọn obìnrin kan na apá wọn, kí wọ́n sì lóṣòó lẹ́ẹ̀marùn-ún, kí wọ́n ya ẹnu wọn, kí wọ́n sì gbé ahọ́n wọn sókè. Ó kéré tán, wọ́n ní kí obìnrin kan fi àwọn ìka rẹ̀ fẹ ihò ìdí rẹ̀. Nígbà tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, àwọn kan lára àwọn ọkùnrin náà ní láti mu omi láti inú agbada ibi ìyàgbẹ́. Wọ́n ṣe àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan bí ọ̀daràn paraku, wọ́n fi wọ́n sí àhámọ́ àdáwà fún gbogbo àkókò tí wọ́n fi há wọn mọ́, oúnjẹ tí wọ́n sì ń fún wọn jẹ́ ìdajì iye tó tọ́ sí wọn. Àwọn alábòójútó ẹlẹ́wọ̀n kan tilẹ̀ gba Bíbélì Àwọn Ẹlẹ́rìí kan.
Àmọ́, ẹ jẹ́ kí a wo díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ tí àwọn kan lára àwọn obìnrin tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n náà sọ. Ohun tí ìròyìn wọn ní tààràtà fi hàn yàtọ̀ pátápátá sí ìrísí nigínnigín tí ìlú ńlá ìgbàlódé yìí ní.
“Inú túbú náà dọ̀tí. Agbada ìfọǹkan àti ibi ìyàgbẹ́ ibẹ̀ wà ní ipò tí ń múni banú jẹ́. Wọ́n ń ríni lára, wọ́n sì dọ̀tí. Okùn aláǹtakùn àti ìdọ̀tí wà lábẹ́ àga tí mo fi jókòó.”
“Wọ́n ní kí n bọ́ra síhòòhò, wọ́n sì fún mi ní aṣọ ẹlẹ́wọ̀n, ike ìfọṣẹsí kan (tí kò lọ́ṣẹ nínú), àti búrọ́ọ̀ṣì ìfọyín. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n míràn nínú túbú tí mo wà sọ fún mi pé, àwọn tí wọ́n ń wá ṣẹ́wọ̀n fún ìgbà kúkúrú kì í gba ọṣẹ ìfọyín tàbí pépà ìnùdí.”
“Àwa tí a wà nínú túbú kan jẹ́ 20. Ibi ìyàgbẹ́ onílòóṣòó, tí ògiri rẹ̀ ga dé ìbàdí mi, ni a ní. Ibi ìwẹ̀ náà ní ohun ìwẹ̀ òyìnbó kan àti agbada ìfọǹkan kan tí ó ní ẹ̀rọ omi kan. A ní láti máa wẹ̀ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ẹlẹ́ni mẹ́fà-mẹ́fà—gbogbo àwa tí a wà nínú túbú ní láti wẹ̀ láàárín ọgbọ̀n ìṣẹ́jú láàárọ̀.”
Lójú hílàhílo tí ó wà nínú ìfinisẹ́wọ̀n náà, gbogbo wọn kà á sí àǹfààní láti sin Ọlọ́run—nígbàkígbà, níbikíbi, àti nínú ipòkípò tí ó lè jẹ́. Kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e yìí tí ọmọdébìnrin ọ̀dọ́langba kan sọ:
“Láti wákàtí tí mo ti wọ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n, mo sábà máa ń rán ara mi létí nípa ìdí tí mo fi wà níbẹ̀. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó tẹ́tí sí àdúrà mi, kí ó má sì ṣe pa mí tì. Mo nímọ̀lára pé ó dáhùn àdúrà mi nítorí pé ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ló ràn mí lọ́wọ́ láti forí tì í. Ìgbà náà ni mo wá tó mọ bí mo ṣe sún mọ́ ọn tó, ó sì ti fún mi lókun lọ́pọ̀lọpọ̀, ní mímọ̀ pé ó ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí wa. Mo nímọ̀lára pé mo láǹfààní láti lè la ìdánwò yí já nítorí orúkọ rẹ̀.”
Àwọn ìwé agbéròyìnjáde jákèjádò ayé yára gbé ìròyìn náà. Àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ní Australia, Kánádà, Europe, Hong Kong, Malaysia, United States, àti ní àwọn ibòmíràn sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n sì tún ṣàtúnsọ rẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star, ti Kánádà, fi àkọlé ìròyìn rẹ̀ náà, “Wọ́n Fi Ìyáàgbà Sẹ́wọ̀n Nítorí Níní Bíbélì,” ṣàkópọ̀ ìrujáde ìbínú tí ó ṣẹlẹ̀ lákòókò náà. Láìsí sísẹ́, ayé ní ìṣòro púpọ̀ tí ó kan àwọn ènìyàn púpọ̀ púpọ̀ sí i, àmọ́ nínú ọ̀ràn yí, ìbéèrè tí àwọn ẹni tí háà ṣe níbi gbogbo ń béèrè jẹ́ ọ̀kan náà. “Ní Singapore kẹ̀?”
Ó ṣòro láti lóye ìdí tí a fi ní láti sọ ìsìn kan tí gbogbo ìṣe rẹ̀ ṣí payá, tí ó ní ààbò òfin ní kíkún ní àwọn ilẹ̀ tí ó lé ní 200 káàkiri àgbáyé di ohun tí a ń ṣenúnibíni sí ní Singapore. Ó wá túbọ̀ ṣòro gan-an láti lóye rẹ̀ nígbà tí a bá ronú pé kò sí ìsìn míràn tí wọ́n tí ì bá lò lọ́nà oníwà àìbọ́gbọ́nmu àti àìdúrógbẹ́jọ́ bẹ́ẹ̀ ní Singapore.
Ní gidi, igbákejì ọ̀gá ọlọ́pàá kan tí ó ṣáájú ẹgbẹ́ akóni kan tí ó lọ kó Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́wọ́ ní ilé ẹjọ́ pé, èyí ni ìgbà kan ṣoṣo tí wọ́n tí ì fún òun àti àwọn òṣìṣẹ́ òun láṣẹ láti da ìpàdé ìsìn kan rú. Àwọn àyọlò tí ó tẹ̀ lé e yìí wá láti inú ẹ̀dà àkọsílẹ̀ ẹ̀rí:
Ìbéèrè: (Sí ẹlẹ́rìí) Bí o bá mọ̀, ǹjẹ́ Ẹ̀ka Àwọn Ẹgbẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti ṣèwádìí, kí wọ́n sì pe àwùjọ onísìn kan tí a kò forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́jọ́ rí, yàtọ̀ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
Ìdáhùn: Kò sí èyí tí mo mọ̀.
Lẹ́yìn náà ìbéèrè ń bá a lọ.
Ìbéèrè: (Sí ẹlẹ́rìí) Ǹjẹ́ ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ti lọ kó àwùjọ àwọn onísìn kékeré kan, tí ń ṣèpàdé nínú ilé kan tí a kò forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ Òfin Àwọn Ẹgbẹ́, lọ́nà tí ó jọ èyí nígbà kankan rí bí?
Ìdáhùn: N kò tí ì ṣe bẹ́ẹ̀ rí.
Ìpè fún Gbígbégbèésẹ̀
Àjọ Adáríjini Lágbàáyé àti Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò Jákèjádò Ayé fi àkànṣe alákìíyèsí tiwọn pẹ̀lú ránṣẹ́ lọ́kọ̀ọ̀kan láti fojú sí bí ìgbẹ́jọ́ náà ti jẹ́ òtítọ́ tó. Alákìíyèsí ti Àjọ Adáríjini Lágbàáyé tí kò ṣègbè náà, Andrew Raffell, tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ agbẹjọ́rò láti Hong Kong, sọ ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí pé: “Mo kọ ọ́ sínú ìròyìn mi pé, ó fara hàn bí ìgbẹ́jọ́ ojúlarí.” Ó ṣàlàyé síwájú sí i pé, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí wọ́n pè bí ẹlẹ́rìí kò lè ṣàlàyé fún ilé ẹjọ́ ìdí tí a fi ka àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí èyí tí a kò fẹ́. Raffell ṣàkọsílẹ̀ díẹ̀ lára àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì tí wọ́n fòfin dè náà tí Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I àti Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Jùlọ wà lára wọn. Ó fi kún un pé, a kò lè kà wọ́n sí ẹni tí a kò fẹ́ ní gidi lọ́nàkọnà.
Alákìíyèsí tí ó wá láti Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò Jákèjádò Ayé, Cecil Rajendra, sọ ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí pé:
“Láti ilẹ̀ wá, ó hàn gbangba sí alákìíyèsí yìí pé gbogbo ìgbẹ́jọ́ náà kò fi ibì kan yàtọ̀ sí . . . àfihàn asán tí a gbé kalẹ̀ láti ṣojú ayé pé, a ṣì ń ṣe ìjọba tiwa-n-tiwa ní Singapore.
“Ìyọrísí rẹ̀ jẹ́ àbájáde tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí iyè méjì nígbà kankan ṣáájú, nígbà tí ìgbẹ́jọ́ náà ń lọ lọ́wọ́, tàbí nígbà tí ó parí pé, gbogbo àwọn tí a fẹ̀sùn kàn ni a óò dá lẹ́bi ẹ̀sùn tí a fi kàn wọ́n.
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbẹ́jọ́ náà ní ilé ẹjọ́ kékeré kan, tí àwọn ẹ̀sùn náà ní gidi sì jẹ́ àìpa Òfin Nípa Àwọn Ẹgbẹ́ mọ́ lọ́nà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, ipò àyíká ilé ẹjọ́ náà jẹ́ ti ẹ̀rù àti ìkójìnnìjìnnì-báni.
“Èyí jẹ́ ní pàtàkì nítorí pé àwọn ọlọ́pàá tí wọn kò dín ní 10, tí wọ́n wọṣọ iṣẹ́, ló wà níbẹ̀ (àwọn 6 wà nínú iyàrá ilé ẹjọ́ náà, àwọn 4 sì wà ní ìta) pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ Ẹ̀ka Àkànṣe mélòó kan tí wọn kò wọṣọ iṣẹ́, tí wọ́n jókòó sí òkè.”
Ní sísọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe ìgbẹ́jọ́ náà fúnra rẹ̀, Rajendra ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé:
“Ìṣesí Adájọ́ tí a sọ náà lákòókò àkíyèsí ẹjọ́ náà (àti lákòókò ìgbẹ́jọ́ náà lódindi, bí àwọn àkọsílẹ̀ ẹ̀rí ti fi hàn) fẹ̀rí hàn pé ó kù díẹ̀ káàtó. . . . Ní ìyàtọ̀ sí gbogbo àfiṣàpẹẹrẹ ìgbẹ́jọ́ tí kì í ṣe ojúsàájú, léraléra ni Adájọ́ náà ń gbè sí ẹ̀yìn agbẹjọ́rò ìjọba, tí ó sì ń wẹ́ agbẹjọ́rò àwọn olùjẹ́jọ́ mọ́lẹ̀ láti máà béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ ẹlẹ́rìí agbẹjọ́rò ìjọba lórí ohun ẹ̀rí, fún àpẹẹrẹ, Bíbélì ẹ̀dà ìtumọ̀ ti King James, tí agbẹjọ́rò ìjọba gbé kalẹ̀ láti fi hàn pé àwọn tí a fẹ̀sùn kàn náà ní àwọn ìtẹ̀jáde tí a fòfin dè lọ́wọ́!”
Àníyàn jákèjádò ayé tí ó jẹ́ àbájáde kíká tí Singapore ká ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lọ́wọ́ kò pọ̀ gan-an débi pé ìwé ìròyìn kan tí wọ́n ń ṣe ní Belgium, tí ó ní àkọlé náà, Human Rights Without Frontiers, tẹ ìròyìn olójú ewé 18 kan, tí gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ dá lórí ogun tí ìjọba Singapore ń gbé dìde sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, jáde. Nígbà tí Willy Fautré, tí ó jẹ́ olóòtú àgbà fún ìwé ìròyìn yẹn, ń kọ ọ̀rọ̀ olóòtú, ó ṣàlàyé ìwọ̀n ojúlówó òmìnira ọmọnìyàn nínú ipò ìṣèlú èyíkéyìí lọ́nà àìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ jù lọ pé:
“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àǹfààní òmìnira ìsìn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àmì ipò gbogbogbòò ti òmìnira ọmọnìyàn ní àwùjọ èyíkéyìí, ìwọ̀nba àwọn ètò àjọ ẹlẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tí kì í ṣe ti ìsìn ni wọ́n ti lọ́wọ́ nínú yálà ìlànà mímú irú àwọn ìfìyàtọ̀sí àti àìráragbaǹkan tí a gbé karí ìsìn tàbí èrò ìgbàgbọ́ kúrò, tàbí nínú ìdàgbàsókè àwọn ìlànà ètò ìlú tí yóò dáàbò bo òmìnira ìsìn.”
Ìwé ìròyìn Human Rights Without Frontiers tẹ àkọsílẹ̀ àwọn ìdámọ̀ràn rẹ̀ jáde ní lẹ́tà gàdàgbàgàdàgbà ní ẹ̀yìn ìròyìn wọn.
Ìrànlọ́wọ́ ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ fún Singapore. Wọ́n bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àwọn aládùúgbò wọn, wọn kò sì ní hùwà ọ̀daràn kan lòdì sí wọn. Kò sí ará Singapore kan tí ó ní láti dààmú nípa pé ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò fọ́ ilé òun tàbí kọ lu òun láti ja òun lólè, láti na òun, tàbí láti fipá bá òun lò pọ̀.
Iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba àfínnúfíndọ̀ṣe wọn ń fún ìgbésí ayé ìdílé lókun, ó sì ń mú kí ó sunwọ̀n sí i, ó sì ń fún jíjẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè rere níṣìírí. Wọ́n ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti kọ́ àwọn ìlànà Bíbélì tí ń gbéni ró àti bí ó ṣe lè fi wọ́n sílò nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Àwọn ìpàdé wọn fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà jẹ́ apá kan ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Kristẹni wọn. Èyí ti mú kí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè rere.
Ó yẹ kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Singapore tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún orílẹ̀-èdè wọn, tí wọ́n sì fẹ́ ohun dídára jù lọ fún ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ rọ ìjọba láti fojú ọ̀tun wo ipò títọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà láwùjọ Singapore. Ó tó àkókò wàyí láti mú ìgbésẹ̀ ìgbóguntìwọ́n kúrò, kí a sì dá ohun tó tọ́ sí olúkúlùkù ọmọ orílẹ̀-èdè pa dà fún wọn—òmìnira ìjọsìn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 26]
Gbogbo Ayé Ń Wòye
1. “Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá Singapore fi ogun já wọ ilé márùn-ún lálẹ́ ọjọ́ kan ní February tó kọjá, wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọ̀dọ́langba tí iye wọ́n jẹ́ 69, wọ́n sì kó wọn lọ sí orílé-iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá. Bẹ́ẹ̀ kọ́ ló yẹ kí a parí àwọn ìpàdé tí a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”—The Ottawa Citizen, Kánádà, December 28, 1995, ojú ìwé A10.
2. “Yóò jẹ́ orísun ìtẹ́lọ́rùn gidi fún gbogbo àwọn tí àǹfààní òmìnira ìsìn àti ẹ̀tọ́ ẹ̀rí ọkàn ń jẹ lọ́kàn, ká ní Ìjọba Singapore fẹ́ láti ṣàtúnṣe ipò rẹ̀ nípa àwọn mẹ́ńbà àwọn ènìyàn aláìlẹ́ṣẹ̀-lọ́rùn, tí kò lè pani lára yìí, kí ó sì gbà wọ́n láyè láti ṣe ìsìn wọn, kí wọ́n sì máa tàn án kálẹ̀ láìsí ìbẹ̀rù tàbí ìdíwọ́.”—Ọ̀jọ̀gbọ́n Bryan R. Wilson, Yunifásítì Oxford, England.
3. “Nínú ọ̀wọ́ àwọn ìgbẹ́jọ́ kan tí ó fa kí àwọn ẹgbẹ́ àwọn ajàfómìnira aráàlú jákèjádò ayé yarí, àwọn ilé ẹjọ́ Singapore ti fi ẹni 63 lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n láti November tó kọjá.”—Asahi Evening News, Japan, January 19, 1996, ojú ìwé 3.
4. “Ó yẹ kí a jẹ́ kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa pàdé pọ̀, kí wọ́n sì máa ṣe ìsìn wọn lálàáfíà láìsí híhalẹ̀ ìfàṣẹmúni tàbí ìfinisẹ́wọ̀n mọ́ wọn. Òmìnira ìsìn jẹ́ ẹ̀tọ́ pàtàkì tí Àkọsílẹ̀ Òfin Singapore fi dáni lójú.”—Àjọ Adáríjini Lágbàáyé, November 22, 1995.
5. Chan Siu-ching, alága Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Ìdájọ́ Òdodo àti Àlàáfíà ti Àgbègbè Àbójútó Kátólíìkì ní Hong Kong, sọ nínú lẹ́tà kan tí ó kọ sí Lee Kuan Yew, Mínísítà Àgbà, ní Ọ́fíìsì Olórí Ìjọba, tí ó ní déètì June 1, 1995, nínú, pé: “Kókó pàtàkì inú ọ̀ràn náà ni pé, bí ìjọba Singapore bá tilẹ̀ ka àwọn tí wọ́n ń kọ iṣẹ́ ológun sí ẹni tí ń ṣẹ̀ sí òfin, tí a sì gbọ́dọ̀ fẹ̀sùn kàn, kò yẹ kí ó kan àwọn mẹ́ńbà wọn yòó kù tí wọ́n wulẹ̀ ń bá wọn pàdé pọ̀ fún ète jíjọ́sìn. . . .
“Nítorí náà, a ń kọ̀wé láti béèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lọ́wọ́ Ìjọba yín pé:
1. kí ó má ṣe fòfin de Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n lè gbádùn òmìnira ìjọsìn àti ẹ̀rí ọkàn;
2. kí ó jáwọ́ fífẹ̀sùnkan àwọn mẹ́ńbà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wulẹ̀ ń pé jọ pọ̀ fún ète ìsìn.
3. kí ó tú àwọn mẹ́ńbà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti fàṣẹ ọba mú láìpẹ́ yìí, nítorí pé wọ́n wulẹ̀ lọ fún ìgbòkègbodò ìsìn, sílẹ̀.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí a fẹ̀sùn kàn wọ́n
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ẹlẹ́rìí tí ó jẹ́ ẹni ọdún 71 yìí wí fún adájọ́ pé: “N kì í ṣe ewu sí ìjọba yìí.” Síbẹ̀, wọ́n fi í sẹ́wọ̀n