“Emi Niyi; Rán Mi”
GẸGẸ BI WILFRED JOHN TI SỌ Ọ
Awọn adìhámọ́ra-ogun ará Burma gbejako wa lati iha mejeeji odò naa. Ọbẹ ìbọn wà lẹnu ìbọn wọ́n sì doju rìfọ́fà kọ wa,, wọn ń rìn ninu omi ti o mù wọn dé àyà ti wọn sì yí wa ká labẹ afara ọ̀nà márosẹ̀ naa.
Ẹ̀RÙ ba emi ati ẹnikeji mi. Ki ni gbogbo rẹ̀ dá lé lori? Bi o tilẹ jẹ pe a kò lóye èdè naa, a rí ihin-iṣẹ naa laipẹ—a wà labẹ ifaṣẹ-ọba muni. Pẹlu kìkì aṣọ ìnura ti a lọ́ mọ́dìí, wọn dà wá lọ si àgọ́ ọlọpaa ti ó wà nitosi ti oṣiṣẹ ti ń sọ èdè Gẹẹsi kan sì fi ọ̀rọ̀ wá wa lẹnuwo.
Ọdun 1941 ni, nigba ogun agbaye keji, wọn sì fura sí wa pe a jẹ́ agbẹ̀hìnbẹbọjẹ́. Lẹhin ti a ṣalaye iṣẹ iwaasu Kristian wa lọna ti o tẹ́ oṣiṣẹ naa lọ́rùn, ó sọ fun wa pe a ṣe kongẹ ire pe a moribọ kuro ninu ikoloju naa. Ó sọ pe, ọpọ awọn wọnni ti a fura si ni a taníbọn, laibi wọn ni ibeere kankan. A dupẹ lọwọ Jehofa a sì gba imọran oṣiṣẹ naa lati maṣe maa fẹsẹ palẹ kaakiri nibi awọn afara ni ọjọ-iwaju.
Bawo ni mo ṣe kó sinu iru ipo bẹẹ ni Burma (ti a ń pe ni Myanmar nisinsinyi)? Ẹ jẹ ki ń ṣalaye ki n sì pese alaye nipa ipò àtilẹ̀wá mi.
Yíyàn kan Ti Mo Ṣe Ni Kutukutu Igbesi-Aye
A bí mi ni Wales ni 1917 mo sì kó pẹlu awọn òbí mi ati aburo mi ọkunrin nigba ti mo wà ni ọmọ ọdun mẹfa lọ si New Zealand, nibi ti mo ti dagba ni oko ẹran-ọsin baba mi. Ni ọjọ kan ó gbé ìdì awọn iwe ogbologbo kan ti ó ti rà ni ile-itaja àlòkù kan wá sile. Eyi ni ninu idipọ meji Studies in the Scriptures, eyi ti a tẹjade lati ọwọ́ Watch Tower Bible and Tract Society. Iwọnyi wá di ohun-ìní ti mama mi kàsí iyebiye, ati gẹgẹ bi ìyá Timoteu, Eunike, ó fi ìfẹ́-ọkàn lati lo ìgbà èwe mi ninu ṣiṣiṣẹsin fun ire Ijọba Jehofa si mi lọkan.—2 Timoteu 1:5.
Ni 1937 yíyàn meji kò mi loju: lati gba iṣabojuto oko ẹran-ọsin baba mi tabi lati sọ fun Jehofa gẹgẹ bi Isaiah wolii Ọlọrun ti sọ pe, “Emi niyi; rán mi.” (Isaiah 6:8) Ọ̀dọ́, onilera, ti o wà lominira kuro ninu awọn ẹrù-iṣẹ́ miiran ni mi. Mo ti tọ́ igbesi-aye oko wò mo sì gbadun rẹ̀. Ni ọwọ miiran ẹwẹ, emi kò ni iriri kankan gẹgẹ bi ojiṣẹ alakooko kikun, tabi aṣaaju-ọna. Ki ni kí n ṣe—ṣiṣiṣẹ lóko tabi ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna kan?
Awọn olubanisọrọ lati ẹ̀ka ọfiisi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Australia jẹ́ orisun iṣiri. Wọn bẹ agbegbe wa ni New Zealand wò wọn sì rọ̀ mi lati lo ìgbà èwe mi ṣiṣeyebiye lati fi ṣiṣẹsin Ọlọrun. (Oniwasu 12:1) Mo jiroro ọ̀ràn naa pẹlu awọn òbí mi, wọn sì gbà pẹlu ọgbọn ti ń bẹ ninu fifi ifẹ-inu Ọlọrun si ipo iwaju julọ. Mo tun ronu jinlẹ lori awọn ọ̀rọ̀ Jesu Kristi ninu Iwaasu rẹ̀ lori Òkè pe: “Ẹ tete maa wá ijọba Ọlọrun ná, ati òdodo rẹ̀; gbogbo nǹkan wọnyi ni a o sì fi kun un fun yin.”—Matteu 6:33.
Mo ṣe yíyàn mi! Niwọn bi kò ti sí ẹ̀ka awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kankan ni New Zealand nigba naa, a késí mi lati ṣiṣẹsin ni ẹ̀ka Australia ni Sydney. Nipa bayii, ni 1937, mo wọ ọkọ̀ oju-omi kan lọ si Australia lati di ojiṣẹ alakooko kikun ti Jehofa Ọlọrun.
‘Iṣẹ-ayanfunni wo ni emi yoo gbà?’ ni mo ṣe kayeefi. Sibẹ, ki ni ohun ti o jámọ́ ná? Mo ti sọ, nitootọ, fun Jehofa pe, ‘Emi niyi. Lò mi nibikibi ti o bá fẹ́.’ Fun ọdun meji mo ṣeranlọwọ ni ṣiṣe awọn ẹ̀rọ rẹkọọdu tí awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lò ni awọn akoko wọnyẹn lati lu ohùn àwo asọye Bibeli ti a gbà silẹ fun awọn onile. Bi o ti wu ki o ri, lajori idanilẹkọọ mi ni ẹ̀ka naa jẹ́ fun iṣẹ ibi ikẹru-iwe si.
Lọ si Singapore
Ni 1939, mo gba iṣẹ-ayanfunni kan si Ila-oorun Jijinnarere—lati ṣiṣẹsin ni ibi ikẹrusi Society ni Singapore. Ibi ikẹrusi naa ṣiṣẹ gẹgẹ bi ikorijọ igbokegbodo fun gbigba ati kíkó awọn iwe lati Australia, Britain, ati United States lọ si ọpọ awọn orilẹ-ede ni Asia.
Singapore jẹ ilu-nla elédè pupọ nibi ti aṣa Gabasi ati ti Europe ti dapọ. Èdè Malay jẹ́ ọ̀nà ijumọsọrọpọ ti o wọpọ, ki a sì baa lè waasu lati ẹnu-ọna de ẹnu-ọna, awa ajeji nilati kọ́ ọ. Ni ọpọ èdè, a ní awọn ohun kan ti a ń pe ni kaadi ẹ̀rí. Iwọnyi ní igbejade ṣoki nipa ihin-iṣẹ Ijọba naa ti a tẹ̀ sori wọn.
Lakọọkọ na mo kọ́ kaadi ẹ̀rí lede Malay sori mo sì bẹrẹ sii mú akojọpọ-ọrọ mi pọ̀ sii ni kẹrẹkẹrẹ ni èdè yẹn. Ṣugbọn a tun maa ń kó awọn iwe-ikẹkọọ Bibeli ni ọpọlọpọ awọn èdè miiran lọwọ pẹlu. Fun awọn eniyan ara India, fun apẹẹrẹ, a ní awọn itẹjade ni èdè Bengali, Gujarati, Hindi, Malayalam, Tamil, ati Urdu. Lati lè bá awọn eniyan ti wọn jẹ́ ẹgbẹ́ awujọ èdè pupọ bẹẹ pade jẹ́ iriri titun kan fun mi.
Mo ṣì lè ranti ikede adayafoni naa ni September 1939 daradara, ipolongo ogun ni Europe. A ṣe kayeefi, ‘Yoo ha ga sii ti yoo sì ni Ila-oorun Jijinnarere ninu bi?’ Ó dabi ibẹrẹ Armageddoni loju mi—mo ronu pe ó jẹ́ akoko yiyẹ kan! Mo nimọlara itẹlọrun pe mo ń lo ìgbà èwe mi daradara ati lọna ti o yẹ.
Papọ pẹlu iṣẹ mi ni ibi ikẹrusi, mo ni ipin kikun ninu awọn ipade ijọ ati iṣẹ-ojiṣẹ pápá. A ṣe awọn ikẹkọọ Bibeli, awọn eniyan kan sì dahunpada ti wọn sì yọnda araawọn fun iribọmi ninu omi. A kó wọn lọ si etikun kan ti o wà nitosi a sì rì wọn bọnu omi lílọ́wọ́ọ́wọ́ ni etikun Singapore. A tilẹ pinnu lati ṣe apejọ kan, a ń fi pẹlẹpẹlẹ pín awọn iwe ikesini laaarin awọn ẹni titun. Si ayọ wa, nǹkan bii awọn eniyan 25 wá si ohun ti a gbagbọ pe yoo jẹ́ apejọpọ wa ti o gbẹhin ṣaaju Armageddoni.
Ijumọsọrọpọ laaarin awọn ẹ̀ka Society ni a pààlà si lọna lilekoko nipasẹ ogun naa. Ile-ikẹrusi Singapore, fun apẹẹrẹ, gba akiyesi ṣoki kan pe awọn aṣaaju-ọna ara Germany mẹta ni akoko tó fun lati dé Singapore ni akoko kan ṣaa ninu ọkọ̀ oju-omi ti a kò darukọ rẹ̀ ni oju-ọna sibi iṣẹ-ayanfunni kan ti a kò darukọ. Ọsẹ melookan lẹhin naa wọn dé wọn sì lo wakati mẹwaa arunilọkansoke pẹlu wa. Bi o tilẹ jẹ pe èdè jẹ́ iṣoro kan, a lè lóye pe ibi ti a pínyàn fun wọn ni Shanghai.
Iṣẹ-Ayanfunni Mi ni Shanghai
Ni ọdun kan lẹhin naa emi pẹlu gba iṣẹ-ayanfunni kan lati ṣiṣẹsin ni Shanghai. A kò fun mi ni adirẹsi opopona kankan, kìkì nọmba adirẹsi ile-ifiweranṣẹ nikan ni a fun mi. Lẹhin ti wọn ti yẹ̀ mi wo finnifinni ni ile-ifiweranṣẹ naa, ó ṣeeṣe fun mi lati fidii idanimọ mi mulẹ ṣinṣin lati lè jẹ́ ẹni ti a fun ni adirẹsi ile Society. Bi o ti wu ki o ri, ara China ti ń gbe ninu ile naa fun mi ni isọfunni pe ẹ̀ka naa ti kó lọ, kò sì sí adirẹsi ifiweranṣẹ titun.
‘Ki ni ǹ bá ṣe nisinsinyi o?’ ni mo ṣe kayeefi. Mo gbadura jẹ́ẹ́jẹ́ fun itọsọna. Bi mo ti gboju soke, mo rí awọn ọkunrin mẹta, ti wọn ga ju gbogbo awọn eniyan yooku lọ diẹ ti wọn sì yatọ ni irisi lọna kan ṣáá. Dajudaju wọn dabi awọn ará Germany mẹta ti wọn duro ni Singapore fun iwọnba awọn wakati ti ń yara sare kọja wọnni. Lọgan, mo yara bọ́ siwaju wọn.
“Mo tọrọ gafara, ẹ jọwọ,” ni mo sọ pẹlu ìwàǹwára. Wọn duro wọn sì tẹju mọ́ mi pẹlu ibẹru ati ojú ti ń wadii ẹni wo. Mo beere pe, “Singapore. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ṣe ẹ ranti mi?”
Lẹhin ìgbà diẹ, wọn dahun pada pe “Ja! Ja! Ja!” Gbàgì ni a dì mọra, ti omije ayọ sì ń ṣàn jade ni oju mi. Ninu ọpọ araadọta-ọkẹ awọn eniyan, bawo ni ó ṣe ṣẹlẹ pe awọn ọkunrin mẹta wọnni nilati kọja ni ọgangan ibẹ yẹn ni akoko pato yẹn? Mo wulẹ sọ pe, “Jehofa, mo dupẹ lọwọ rẹ.” Awọn idile ará China mẹta, awọn ará Germany mẹta naa, ati emi ni kìkì awọn Ẹlẹ́rìí ti ń bẹ ni Shanghai nigba naa.
Hong Kong ati Burma Lẹhin Naa
Lẹhin ṣiṣiṣẹsin ni Shanghai fun oṣu bii melookan, a yàn mi si Hong Kong. Nigba ti aṣaaju-ọna alabaaṣiṣẹpọ mi ọjọ-iwaju lati Australia kọ̀ tí kò dé, mo wà ni emi nikan, Ẹlẹ́rìí kanṣoṣo ni ilu ti a tẹ̀dó naa. Lẹẹkan sii, mo nilati rán araami leti pe mo ti sọ fun Jehofa pe, “Emi niyi; rán mi.”
Igbokegbodo mi ni a dari rẹ̀ sí kìkì awọn ará China ti ń sọ èdè Gẹẹsi, sibẹ ó jẹ́ iṣoro fun mi lati kọja awọn ẹnu-ọna ile-gbigbe wọn, niwọn bi o ti jẹ pe awọn iranṣẹ ti a fi ṣọ́ ibẹ̀ ń sọ èdè China nikan. Nitori naa mo kọ́ èdè China diẹ ni èdè ibilẹ meji ti a ń lò julọ. Ó ṣiṣẹ! Emi yoo tọ awọn iranṣẹ ẹ̀ṣọ́ naa lọ, emi yoo fi kaadi iṣẹ mi hàn ti emi yoo sì sọ awọn ọ̀rọ̀ diẹ ti mo mọ̀ ni èdè China, lẹhin eyi ti wọn sábà maa ń késí mi wọle.
Lẹẹkan ri nigba ti mo ṣebẹwo si ile-ẹkọ kan, mo tẹle ọ̀nà igbaṣe nǹkan yii ninu isapa kan lati bá olukọ-agba ile-ẹkọ naa sọrọ. Olukọ onipo kekere kan bá mi ni ibi àbáwọlé gbọngan. Mo tẹle e wọnu awọn yàrá ikawe melookan, mo sọrọ itẹwọgba nipa ìwà ọ̀wọ̀ ti awọn ọmọde naa fihàn, mo sì murasilẹ lati di ẹni ti a mú mọ olukọ-agba. Olukọ naa kan ilẹkun, ó ṣí i, o tàdí mẹhin, ó sì wawọ́ si mi pe ki n bọ́ siwaju. Si iyalẹnu ti o bí mi ninu, ó ti fi ẹ̀sọ̀ mú mi lọ si ile-igbọnsẹ! Ó jọ bi ẹni pe èdè China mi ni a ti ṣì lóye ati pe, gẹgẹ bi olukọ àgbà naa ti sọ fun mi lẹhin naa, ó ti ṣì mí mú fun oluṣabẹwo ọ̀pá omi-ẹrọ ati ọ̀nà ti ẹ̀gbin omi-ìgbẹ́ ń gbà.
Lẹhin oṣu mẹrin ti o kun fun igbokegbodo, awọn ọlọpaa Hong Kong fi tó mi leti pe ìfòfindè kan ni a ti gbekari iṣẹ iwaasu wa ati pe emi yoo nilati dawọ wiwaasu duro tabi ki a lé mi kuro nílùú. Mo yan ìlélọ kuro nílùú niwọnbi anfaani iwaasu ti ń baa lọ lati ti ṣí silẹ sibẹ ni ibomiran. Nigba ti mo wà ni Hong Kong, mo ti fi iwe 462 sode mo sì ti ran awọn meji miiran lọwọ lati ṣajọpin ninu iṣẹ-ojiṣẹ naa.
Lati Hong Kong, a yàn mi si Burma. Nibẹ ni mo ti ṣe aṣaaju-ọna ti mo sì ṣetilẹhin ninu iṣẹ ibi ikẹrusi ni Rangoon (Yangon nisinsinyi). Ọ̀kan lara awọn iriri ti o larinrin julọ ni ti wiwaasu ninu awọn ilu ati abule ti ó rí gatagata lẹbẹẹba ọ̀nà ńlá ti o wá lati Rangoon lọ si Mandalay ati kọja lọ si ilu Lashio ti ń bẹ ni ibode awọn ará China. Emi ati ẹnikeji mi ti o jẹ́ aṣaaju-ọna kò afiyesi jọ sori awọn awujọ ti ń sọ èdè Gẹẹsi, ti a ń gba ọgọrun-un melookan awọn asansilẹ-owo fun iwe-irohin Consolation (ti o jẹ iwe-irohin Ji! nisinsinyi). Lọna ti o ṣe kòńgẹ́, oju-ọna ńlá yii lati Rangoon lọ si Mandalay ni yoo di eyi ti a wà mọ si Oju-ọna Burma, ọ̀nà ti a ń gbà fi awọn ipese ogun ti America ṣọwọ si China.
Ririn la aarin eruku ti ó muni dé kókósẹ̀ já sábà maa ń jẹ́ ki a nimọlara aini fun àwẹ̀dá ìwẹ̀. Eyi ni ó ṣamọna si iṣẹlẹ ti a rohin rẹ̀ ni ibẹrẹ, ti didi ẹni ti a faṣẹ-ọba mu nigba ti a ń wẹ̀ ninu odò labẹ afárá kan. Laipẹ lẹhin ìgbà naa awọn igbesẹ ologun ati ailera fipá mú wa pada si Rangoon. Ó ṣeeṣe fun mi lati duro ni Burma titi di 1943, nigba ti awọn igbesẹ ogun ti a mú ga sii naa fipá mú mi lati pada si Australia.
Pada si Australia
Laaarin akoko yii, igbokegbodo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ti fofinde ni Australia. Bi o ti wu ki o ri, ifofinde naa ni a mú kuro laipẹ, ati ni asẹhinwa-asẹhinbọ a késí mi lẹẹkan sii lati ṣiṣẹ ni ẹ̀ka ọfiisi. Lẹhin naa, ni 1947, mo gbé Betty Moss, ẹni ti o ti ń ṣiṣẹ ni ẹ̀ka Society ni Australia niyawo. Baba ati ìyá Betty jẹ́ aṣaaju-ọna, wọn sì fun oun ati arakunrin rẹ̀ Bill niṣiiri lati fi iṣẹ aṣaaju-ọna ṣe iṣẹ igbesi-aye wọn. Betty bẹrẹ iṣẹ aṣaaju-ọna ni ọjọ ti o pari ile-ẹkọ, nigba ti o pe ọmọ ọdun 14. Mo wo sàkun rẹ̀ pe a nilati jẹ́ gẹ́gẹ́-ko-gẹ́gẹ́, niwọn bi oun pẹlu, nitootọ, ti sọ fun Jehofa pe, “Emi niyi; rán mi.”
Lẹhin ti a ti gbeyawo fun ọdun kan, a késí mi sinu iṣẹ ayika, mo sì ṣebẹwo si ijọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ṣiṣiṣẹ ni agbegbe Australia ti o jinna si ilu jẹ́ ipenija gidi. Awọn ikun-omi ayaluni lojiji maa ń gbé iṣoro irin-ajo kalẹ lemọlemọ, ni pataki lori oju-ọna alámọ̀ ti ń yọ̀. Ìwọ̀n ìgbóná-ìtutù ni ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn maa ń lọ soke de 110 lori ìwọ̀n Fahrenheit labẹ ìbòji. Bi a ti ń gbé ninu awọn àgọ́ onítapólì, a rí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn olóooru ti ń jónilára naa gẹgẹ bi eyi ti o fẹrẹẹ má ṣeefarada ti ìgbà òtútù sì maa ń tutù wọnu eegun.
Ayọ ni o jẹ lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alaboojuto agbegbe nigba ti o jẹ pe agbegbe meji pere ni o wà ni Australia. Donald MacLean ṣiṣẹsin agbegbe kan, emi sì ṣiṣẹsin ekeji. Lẹhin naa ni a o paarọ agbegbe. Ó jẹ́ ohun ti o dunmọni lati kà nipa awọn ijọ ti wọn wà nisinsinyi nibi ti a ti ṣiṣẹsin nigba kan ri. Irugbin otitọ Bibeli ti rú ó sì ti mesojade dajudaju!
Pada si Ibi ti Gbogbo Rẹ̀ ti Bẹrẹ
Ni 1961, mo ni anfaani lilọ si kilaasi akọkọ ti ile-ẹkọ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Gilead lẹhin ti a kó o lọ si Brooklyn, New York. Mo ti gba iwe ikesini ṣaaju si ile-ẹkọ naa ṣugbọn emi kò lè tẹwọgba a nitori ailera. Ni ipari idanilẹkọọ oloṣu mẹwaa naa, a késí mi lati tẹwọgba New Zealand gẹgẹ bi ibi ayanfunni mi.
Nitori naa lati January 1962, emi ati Betty ti wà nihin-in ni New Zealand, ọ̀kan lara awọn ilẹ Australia. A sábà maa ń tọka sii gẹgẹ bi ọ̀kan lara awọn erekuṣu ti o lẹwa julọ ni Pacific. Niti iṣakoso Ọlọrun, ó ti jẹ́ ohun ayọ lati ṣiṣẹsin ninu iṣẹ ayika ati ti agbegbe, Fun ohun ti o ju ọdun 14 ti o kọja lọ, lati April 1979, a ti ń ṣiṣẹ ni ẹ̀ka ọfiisi New Zealand.
Emi ati Betty ni a ti lé ni 70 ọdun bayii, awa mejeeji sì ni 116 ọdun iṣẹ-isin Ijọba alakooko kikun ti kò dawọ duro. Betty bẹrẹ iṣẹ aṣaaju-ọna ni January 1933, emi sì bẹrẹ ni April 1937. Ohun pupọ ni o ti jẹ́ ayọ wa bi a ti ń wo awọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ wa tẹmi ti wọn ń ṣe ohun ti a ṣe nigba ti a jẹ́ ọ̀dọ́, iyẹn ni pe, wọn kọbiara si imọran Oniwasu 12:1 pe: “Ranti Ẹlẹdaa rẹ nisinsinyi ni ọjọ èwe rẹ.”
Ohun ayọ wo ni ó ti jẹ́ lati lo eyi ti o fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo igbesi-aye wa ni wiwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun ati sisọni di ọmọ-ẹhin, gẹgẹ bi Oluwa wa Jesu Kristi ti pàṣẹ! (Matteu 24:14; 28:19, 20) Inu wa dun tobẹẹ debi pe a dahunpada si ikesini Ọlọrun gẹgẹ bi wolii Isaiah nigba pipẹ sẹhin ti ṣe pe, “Emi niyi; rán mi.”