Ìtàn Ìgbésí Ayé
Mò Ń Gbádùn Inú Rere Onífẹ̀ẹ́ àti Àbójútó Jèhófà
GẸ́GẸ́ BÍ FAY KING ṢE SỌ Ọ́
Onínúure ni àwọn òbí mi, àmọ́ bíi ti àwọn èèyàn mìíràn, wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn rárá. Màmá mi máa ń sọ pé: “Ọlọ́run ní láti wà, bí ò bá sí, ta ló dá àwọn òdòdó, ta ló sì dá àwọn igi?” Àmọ́ ìgbàgbọ́ rẹ̀ ò jù bẹ́ẹ̀ lọ.
BÀBÁ mi kú ní ọdún 1939 nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá, mo sì ń gbé lọ́dọ̀ màmá mi ní Stockport, ní gúúsù Manchester, ní ilẹ̀ England. Ìgbà gbogbo ni mò ń fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá mi, mo sì ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Bíbélì bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀. Nítorí náà mo pinnu láti lọ sí Ìjọ Áńgílíkà láti wo ohun tí mo lè rí kọ́ níbẹ̀.
Ìsìn tí wọ́n ń ṣe ní Ṣọ́ọ̀ṣì náà kò fi bẹ́ẹ̀ nítumọ̀ sí mi, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ka àwọn Ìwé Ìhìn Rere, àwọn ọ̀rọ̀ Jésù máa ń mú un dá mi lójú lọ́nà kan ṣáá pé Bíbélì jóòótọ́. Bí mo bá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, ó máa ń yà mi lẹ́nu pé èmi fúnra mi ò ṣe ka Bíbélì lákòókò yẹn. Kódà lẹ́yìn-ọ̀-rẹ́yìn, nígbà tí obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ìdílé wa fún mi ní ìwé “Májẹ̀mú Tuntun” ní ìtumọ̀ ti òde òní, mi ò kà á.
Ogun Kòríà tó bẹ́ sílẹ̀ ní 1950 mú mi ronú gan-an. Ṣe ìjà náà máa kárí ayé bíi ti Ogun Àgbáyé Kejì ni? Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, báwo ni mo ṣe máa ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù tó sọ pé kí n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá mi? Àmọ́ ṣá o, ṣe màá káwọ́ lẹ́rán kí ń máa wòran káwọn èèyàn ya wọ orílẹ̀-èdè mi kí n má sì ṣe ohunkóhun láti dá wọn dúró ni? Bí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé mò ń sá fún ohun tó yẹ kí ń ṣe nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan yìí dà mí lọ́kàn rú, ó ṣì dá mi lójú hán-un pé ìdáhùn gbogbo ìbéèrè mi wà nínú Bíbélì, àmọ́ mi ò mọ apá ibi tí wọ́n wà àti bí mo ṣe lè rí wọ́n.
Mò Ń Wá Òtítọ́ Kiri Ní Ọsirélíà
Ní ọdún 1954 èmi àti màmá mi pinnu pé ká ṣí lọ sí Ọsirélíà níbi tí Jean, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ń gbé. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Jean sọ fún mi pé òun ti sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n máa wá sọ́dọ̀ mi nítorí òun mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì mò sì fẹ́ràn láti máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Ó fẹ́ mọ èrò mi nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó jẹ́wọ́ fún mi pé: “Èmi kò mọ̀ bóyá àlàyé wọn tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà, ṣùgbọ́n ohun tí mo mọ̀ ni pé àlàyé wọn pọ̀ ju ti àwọn ṣọ́ọ̀ṣì yòókù lọ.”
Tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Bill àti Linda Schneider, tó ń wá sọ́dọ̀ mi jẹ́ ènìyàn àtàtà. Wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni àádọ́rin ọdún, wọ́n sì ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún ọ̀pọ̀ ọdún. Wọ́n ti ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ rédíò táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò nílùú Adelaide lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Àkókò tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ni wọ́n forúkọ sílẹ̀ láti di ajíhìnrere alákòókò-kíkún. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bill àti Linda ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an, síbẹ̀ mo ṣì ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìsìn mìíràn.
Òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi kan mú mi lọ sí ìpàdé kan tí ajíhìnrere Billy Graham darí, lẹ́yìn náà àwa bíi mélòó kan lọ bá àlùfáà kan tó ní ká máa béèrè ìbéèrè. Mo béèrè ìbéèrè kan tó ti ń dààmú mi, mo ni: “Báwo ni Kristẹni ṣe lè sọ́ pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá òun kó sì tún lọ máa pa wọ́n lójú ogun?” Gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ pariwo gèè, láìsí àní-àní ìbéèrè yẹn ti ń dààmú àwọn náà pẹ̀lú! Àlùfáà náà wá dáhùn pé: “Mi ò mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Mo ṣì ǹ ronú nípa rẹ̀ ni.”
Láàárín àkókò yẹn, ẹ̀kọ́ Bíbélì tí Bill àti Linda ń kọ́ mi ń bá a nìṣó, nígbà tó sì di September 1958, mo ṣèrìbọmi. Mo pinnu pé ohun tí àwọn tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ ṣe ni èmi náà máa ṣe, nítorí náà ní oṣù August ọdún tó tẹ̀ lé e, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé, ìyẹn ajíhìnrere alákòókò-kíkún. Oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn náà ni wọ́n pè mi kí ń wá dara pọ̀ mọ́ ọ̀wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Inú mi mà dùn o nígbà tí mo gbọ́ pé Jean, ẹ̀gbọ́n mi, ti tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ó sì ti ṣèrìbọmi!
Ilẹ̀kùn Àǹfààní Ṣí Sílẹ̀
Mo ń sìn nínú ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó wà ní Sydney mo sì ń kọ́ àwọn èèyàn bíi mélòó kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé wọn. Lọ́jọ́ kan mo bá àlùfáà Ìjọ Áńgílíkà kan tó ti fẹ̀yìn tì pàdé, mo sì bi í pé kí ni ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ sọ nípa òpin ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lóun ti fi ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kọ́ àwọn èèyàn fún àádọ́ta ọdún, síbẹ̀ ìdáhùn rẹ̀ yà mi lẹ́nu, ó ní: “Mo ní láti fara balẹ̀ wádìí ìyẹn nítorí mi ò mọ Bíbélì bíi ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Kété lẹ́yìn náà la gbọ́ pé wọ́n ń wá àwọn tí yóò yọ̀ǹda ara wọn láti lọ sìn lórílẹ̀-èdè Pakistan. Mo fẹ́ lọ, àmọ́ mi ò mọ̀ pé wọ́n ò ní rán àwọn obìnrin tí kò tíì lọ́kọ lọ, àwọn àpọ́n tàbí àwọn lọ́kọláya ni wọ́n máa rán lọ. Àmọ́ ó dájú pé wọ́n fi ìwé tí mo fi béèrè fún iṣẹ́ náà ránṣẹ́ sí orílé-iṣẹ́ wa ní Brooklyn nítorí pé kó pẹ́ sí àkókò yẹn ni mo gba lẹ́tà kan tó sọ fún mi pé, tó bá wù mí láti lọ, àyè wà nílùú Bombay (tá a ń pè ní Mumbai nísinsìnyí), lórílẹ̀-èdè Íńdíà. Ọdún 1962 ni. Mo lọ, mo sì gbé ní ìlú Bombay fún ọdún kan àtààbọ̀ kí ń tó ṣí lọ sí ìlú Allahabad.
Kò pẹ́ rárá tí mo fi tẹra mọ́ kíkọ́ èdè Hindi. Èdè Íńdíà yìí kò nira láti kọ́, nítorí pé bí wọ́n tí ń kọ èdè náà sílẹ̀ bá bí wọ́n ṣe ń sọ ọ́ mu. Àmọ́ ìgbà gbogbo ni ọ̀ràn náà máa ń tojú sú mi nígbà tí àwọn tí mò ń wàásù fún bá sọ pé kí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì dípò tí mo fi ń fi agídí sọ èdè àwọn! Bó ti wù kó rí, orílẹ̀-èdè tuntun yìí mú kí ń ṣe àwọn ohun alárinrin tó gba aápọn, mo sì gbádùn bíbá àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ mi tó wá láti Ọsirélíà kẹ́gbẹ́.
Nígbà tí mo ṣì kéré, mo máa n ronú nípa ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n nígbà tí mo ṣèrìbọmi tán, ọwọ́ mi di nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ju kí ń máa ronú nípa ìgbéyàwó lọ. Àmọ́ nígbà tó yá mó wá bẹ̀rẹ̀ sí i rí i pé ó yẹ́ kí ń ní alábàákẹ́gbẹ́ kan nínú ayé mi. Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, mi ò fẹ́ fi iṣẹ́ tá a yàn fún mi nílẹ̀ òkèèrè sílẹ̀ nítorí náà mo gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀ràn náà, mo sì mú un kúrò lọ́kàn mi.
Ìbùkún Kan Tí Ń Kò Retí
Edwin Skinner ló ń bójú tó iṣẹ́ ní ẹ̀ka tó wà lórílẹ̀-èdè Íńdíà ní àkókò yẹn. O ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹjọ ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní 1946 pẹ̀lú ọ̀pọ̀ arákùnrin olóòótọ́ mìíràn títí kan Harold King àti Stanley Jones, tí wọ́n yàn sí Ṣáínà.a Ní ọdún 1958, wọ́n fi Harold àti Stanley sínú àhámọ́ àdáwà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n nítorí iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe nílùú Shanghai. Nígbà tí wọ́n tú Harold sílẹ̀ ní ọdún 1963, Edwin kọ̀wé sí i. Harold dá èsì ìwé náà padà lẹ́yìn tó padà sí Hong Kong láti ìrìn àjò rẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó sì sọ pé òun fẹ́ ní ìyàwó. Ó sọ fún Edwin pé òun ti gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà nígbà tóun wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó sì ní kí Edwin bá òun wá Ẹlẹ́rìí kan ti yóò jẹ́ aya rere.
Ní orílẹ̀-èdè Íńdíà, ọ̀pọ̀ jù lọ ìgbéyàwó ni wọ́n máa ń báni ṣọ̀nà rẹ̀, wọ́n sì máa ń ní kí Edwin bá àwọn ṣe é, àmọ́ kò jẹ́ gbà rárá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà ó mú lẹ́tà Harold fún Ruth McKay, ẹni tí ọkọ rẹ̀, Homer, jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò. Nígbà tó yá, Ruth kọ̀wé sí mi pé míṣọ́nnárì kan tó ti wà nínú òtítọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún ń wá ìyàwó, Ruth sì béèrè lọ́wọ́ mi bóyá ó wù mí láti kọ̀wé sí i. Àmọ́ kò sọ fún mi nípa ẹni tí arákùnrin náà jẹ́, kò sì sọ nǹkan mìíràn nípa arákùnrin náà.
Kò sẹ́ni tó mọ ohunkóhun nípa àdúrà mi pé mò ń wá alábàákẹ́gbẹ́, àyàfi Jèhófà nìkan, nítorí náà ohun tó kọ́kọ́ wá sí mi lọ́kàn ni pé kí ń sọ pé mi ò ṣe. Síbẹ̀ náà, bí mo ṣe ń ronú nípa rẹ̀ tó ni mo ń rántí pé Jèhófà kì í sábà dáhùn àdúrà wa lọ́nà táwa rò pé ó máa gbà dáhùn rẹ̀. Nítorí náà mo kọ̀wé padà sí Ruth mo sì sọ fún un pé mi ò tíì sọ pé mo gbà o, àmọ́ kó sọ fún arákùnrin náà pé kí ó tún kọ̀wé. Èmi gan-an ni Harold King kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí ní tààràtà.
Àwọn fọ́tò Harold àti ìtàn ìgbésí-ayé rẹ̀ ti wà nínú onírúurú ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé àtìgbàdégbà tó jáde nígbà tí wọ́n dá a sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní Ṣáínà. Ní àkókò yìí, wọ́n ti mọ̀ ọ́n káàkiri ayé, ṣùgbọ́n iṣẹ́ ìsìn tó fi òótọ́ inú ṣe ló wú mi lórí púpọ̀. Nítorí náà a kọ̀wé síra fún oṣù márùn-ún, mo sì lọ sí Hong Kong lẹ́yìn náà. A ṣègbéyàwó ní October 5, 1965.
Àwa méjèèjì fẹ́ ṣègbéyàwó ká sì máa bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún wa nìṣó, bí a sì ti ṣe ń dàgbà sí i la ń rí i pé a nílò alábàákẹ́gbẹ́ gan-an ni. Mo wa nífẹ̀ẹ́ Harold gan-an, nígbà tí mo rí inú rere àti ìgbatẹnirò tó ń fi hàn sí àwọn èèyàn àti bó ṣe máa ń yanjú àwọn ìṣòro tá a ní nínú iṣẹ́ ìsìn wa, ọ̀wọ̀ tí mo ní fun un jinlẹ̀ gidigidi. Ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbáko la fi gbádùn ìgbéyàwó wa tó kún fún ayọ̀, a sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà.
Àwọn ará Ṣáínà máa ń ṣiṣẹ́ gan-an, mo sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. Èdè tí wọ́n ń sọ ní Hong Kong ni èdè Cantonese, ìyẹn ẹ̀ya èdè Chinese kan tó ní ìró púpọ̀ nínú ju èdè Mandarin lọ, ó sì ṣòro láti kọ́. Èmi àti Harold bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì ṣe àwọn iṣẹ́ tá a yàn fún wa káàkiri ìpínlẹ̀ Hong Kong. Dájúdájú, a láyọ̀ gan-an, ṣùgbọ́n àìsàn kan tó le ṣe mí ní ọdún 1976.
Mò Ń Fara Da Àìsàn Tó Le
Mo ti ní àrùn àsun-ùndá ẹ̀jẹ̀ fún oṣù bíi mélòó kan, ìwọ̀n sẹ́ẹ̀lì inú ẹ̀jẹ̀ mi sì ti lọ́ sílẹ̀ gan-an. Iṣẹ́ abẹ́ ni yóò yanjú ọ̀ràn náà àmọ́ àwọn dókítà nílé ìwòsàn sọ fún mi pé àwọn ò lè ṣe iṣẹ́ abẹ náà láìlo ẹ̀jẹ̀ nítorí táwọn bá ṣe é láìlo ẹ̀jẹ̀, mo lè kú. Lọ́jọ́ kan tí àwọn dókítà ń sọ̀rọ̀ nípa mi, àwọn nọ́ọ̀sì fẹ́ yí mi lérò padà, wọ́n ní kò yẹ kí n kàn fi ẹ̀mí mi ṣòfò. Iṣẹ́ abẹ méjìlá ni wọ́n fẹ́ ṣe nílé ìwòsàn lọ́jọ́ yẹn, mẹ́wàá nínú wọn jẹ́ oyún ṣíṣẹ́, àmọ́ kò sẹ́ni tó kìlọ̀ fún àwọn obìnrin wọ̀nyẹn pé wọ́n fẹ́ fi ẹ̀mí àwọn ọmọ inú wọn ṣòfò.
Níkẹyìn, Harold kọ̀wé tó yọ ọ̀ràn kúrò lọ́rùn ilé ìwòsàn tó bá ṣẹlẹ̀ pé mo kú, àwọn dókítà náà sì gbà pé àwọn á ṣe iṣẹ́ abẹ náà. Wọ́n gbé mi lọ sí yàrá tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ abẹ, wọ́n sì ti múra láti fi oògùn pa ìmọ̀lára mi. Ẹni tó fẹ́ fún mi ni oògùn apàmọ̀lára náà kọ̀ láti fún mi, nítorí náà wọ́n ní kí ń máa lọ sílé.
Lẹ́yìn náà ni a lọ sọ́dọ̀ dókítà kan tó ní ilé ìwòsàn àdáni tó ti máa ń tọ́jú àwọn obìnrin. Nígbà tó mọ bí ipò mi ti le koko tó, ó gbà láti ṣe iṣẹ́ abẹ náà lówó pọ́ọ́kú, tí a ò bá sáà ti sọ iye tóun gbà lọ́wọ́ wa fún ẹnikẹ́ni. Ó ṣe iṣẹ́ abẹ náà láìlo ẹ̀jẹ̀ rárá, ó sì kẹ́sẹjárí. Inú rere onífẹ̀ẹ́ àti àbójútó Jèhófà sí èmi àti Harold lákòókò yẹn kò kéré rárá.
Ní 1992, àrùn kan tí kò gbóògùn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe Harold. A lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, wọ́n sì fìfẹ́ tọ́jú wa níbẹ̀. Ọkọ mi ọ̀wọ́n parí ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní 1993 ní ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin.
Mo Padà sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
Mo láyọ̀ láti jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Hong Kong, àmọ́ ó ṣòro fún mi láti máa fara gba ooru àti ọ̀rinrin. Lẹ́yìn náà ni lẹ́tà ìyanu kan dé láti orílé-iṣẹ́ wa ní Brooklyn, tí wọ́n fẹ́ fi mọ̀ bóyá nítorí àìlera mi, á wù mi láti lọ sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa tó ní ohun ìtọ́jú àìsàn ju ti ibi tí mo wà lọ. Nítorí náà, ní ọdún 2000, mo padà sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì mo sì dára pọ̀ mọ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì nílùú London. Ẹ wo bí ètò tí wọ́n ṣe fún mi yìí ti fìfẹ́ hàn tó! Wọ́n fi ọ̀yàyà tẹ́wọ́ gbà mí, mo sì gbádùn oríṣiríṣi iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi níbẹ̀, ọ̀kan lára rẹ̀ ni bíbójútó ilé ìkàwé tó wà fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì, ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ìdìpọ̀ ìwé ló sì wà níbẹ̀.
Mo tún dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí ń sọ èdè Chinese tí wọ́n ń ṣèpàdé nílùú London, síbẹ̀ àwọn nǹkan ti yí padà. Nísinsìnyí, àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń wá láti Hong Kong, àmọ́ ọ̀pọ̀ ló ń wá láti apá ibi tí kì í ṣe orí omi ní Ṣáínà. Wọ́n ń sọ èdè Mandarin, èyí sì mú kí iṣẹ́ ìwàásù gba ìsapá gan-an. A gbọ́ ìròyìn káàkiri orílẹ̀-èdè yìí pé àwọn ará ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n wá láti Ṣáínà tí wọ́n sì ti gboyè àkọ́kọ́ jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga ṣe ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì alárinrin. Wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ gan-an, wọ́n sì mọrírì òtítọ́ Bíbélì tí wọ́n ń kọ́. Nǹkan ayọ̀ ló jẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Nínú yàrá mi tuntun tó tòrò minimini, mo máa ń ronú nípa ìgbésí ayé aláyọ̀ ti mo ń gbé, inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà sì máa ń jọ mi lójú. Èyí máa ń fara hàn nínú gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìfẹ́ rẹ̀, bó sì ṣe ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nìkọ̀ọ̀kan kò fara sin rárá. Ọ̀nà ọpẹ́ mi pọ̀ nítorí pé ó fìfẹ́ bójú tó mi ní gbogbo ọ̀nà.—1 Pétérù 5: 6, 7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtàn ìgbésí ayé àwọn méjèèjì yìí wà nínú Ile-Iṣọ Na, July 15, 1963 ti èdè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ewé 437 sí 442, àti Ile-Iṣọ Na April 1, 1967, ojú ewé 118 sí 127.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìgbà tí mò ń sìn ní Íńdíà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Harold King rèé ní ọdún 1963 àti nígbà tó ń sìn ní Ṣáínà ní àwọn ọdún 1950
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọjọ́ ìgbéyàwó wa ní Hong Kong, October 5, 1965
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwa àti àwọn ará Bẹ́tẹ́lì ti Hong Kong, Arákùnrin àti Arábìnrin Liang ló wà láàárín, Arákùnrin àti Arábìnrin Gannaway ló wà lápá ọ̀tún