Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
“Ní Ojoojúmọ́ ní Ibi Ọjà”
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù lo gbogbo àǹfààní láti tan ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kálẹ̀. Láti lè wá àwọn ẹni yíyẹ rí, ó fèrò-wérò “nínú sínágọ́gù pẹ̀lú àwọn Júù . . . àti ní ojoojúmọ́ ní ibi ọjà pẹ̀lú àwọn tí ó wà ní àrọ́wọ́tó.”—Ìṣe 17:17.
Irú ìtara bẹ́ẹ̀ ti jẹ́ àmì ìdánimọ̀ àwọn olùjọsìn tòótọ́ ti Jèhófà láti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. (Mátíù 28:19, 20) Lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bákan náà ń lo onírúurú ọ̀nà bí wọ́n ti ń fi ìtara ran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́ láti wá sínú ìmọ̀ pípéye ti òtítọ́. (1 Tímótì 2:3, 4) Ìrírí tí ó tẹ̀ lé e yìí láti Australia ṣàkàwé èyí.
Lọ́jọ́ márùn-ún nínú ọ̀sẹ̀, Sid àti Harold máa ń gba pípàtẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí ibùdókọ̀ ojú irin ní Sydney lọ́wọ́ ara wọn. Ó ti tó ọdún márùn-ún nísinsìnyí tí wọ́n ti ń ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà yìí. Sid, tí ó jẹ́ ẹni ọdún 95, ṣàlàyé pé: “Nígbà tí mo di ẹni ọdún 87, n kò lè wakọ̀ mọ́. Ìyẹn já mi kulẹ̀ nítorí pé mo máa ń gbádùn ìgbòkègbodò jíjẹ́rìí fún gbogbo ènìyàn. Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mo wà nítòsí ibi ìṣèbẹ̀wòsí gbígbajúmọ̀ tí a ń pè ní Echo Point ní Katoomba, mo rí ayàwòrán kan tí ń ta àwọn àwòrán ìrísí ojú ilẹ̀. Mo wo àwòrán náà fínnífínní, mo sì sọ fún ara mi pé, ‘Mo ní àwòrán tí ó dára ju èyí lọ nínú àpò ìjẹ́rìí mi—tí owó rẹ̀ kò sì tó nǹkan lẹ́gbẹ́ owó àwọn àwòrán náà!’ Nítorí náà, mo pinnu láti ṣe pẹpẹ ìpàtẹ ìwé kékeré kan, kí ó wà ní ibi tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sábà máa ń gbáríjọ sí, kí n sì máa fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì aláwọ̀ mèremère tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pín kiri lọ àwọn tí ó bá ń kọjá lọ.
“Ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, mo gbé pẹpẹ ìpàtẹ ìwé náà lọ sí Sydney, Harold sì dara pọ̀ mọ́ mi. A máa ń gba dídúró síbi pẹpẹ ìpàtẹ ìwé náà lọ́wọ́ ara wa, a sì ń bá ìjọ àdúgbò wa ṣiṣẹ́.” Harold, tí ó ti di ẹni ọdún 83 nísinsìnyí, sọ pé: “Ìwọ̀nba ènìyàn díẹ̀ ni ó máa ń wà nílé ní ọjọ́ Monday sí Friday. Nítorí náà, ṣíṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà lọ́nà yìí ń jẹ́ kí a wà níbi tí àwọn ènìyàn máa ń wà. Bí ó ṣe sábà máa ń rí, a rí ìyọrísí tí ó sàn jù. Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ń fi sóde tayọ lọ́lá gan-an ní orílẹ̀-èdè yìí.”
Sid wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti lo ibi mẹ́rin tàbí márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, kò pẹ́ púpọ̀ tí àwọn ènìyàn fi mọ̀ wá bí ẹní mowó. Àwọn kan tilẹ̀ máa ń tọ̀ wá wá fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Àwọn mìíràn máa ń mú ìbéèrè tí wọ́n ń fẹ́ ìdáhùn sí wá. Àwọn kan sì wulẹ̀ ń fẹ́ láti bá wa sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú díẹ̀. Àkókò yìí nìkan ni àwọn ìpadàbẹ̀wò mi máa ń fúnra wọn tọ̀ mí wá,” ó rẹ́rìn-ín músẹ́.
Harold fi kún un pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì ní tòótọ́. Láàárín oṣù kan, ẹni mẹ́rin bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n rí gbà láti ọwọ́ wa àti nítorí àwọn ìbéèrè tí ó ṣeé ṣe fún wa láti fi Bíbélì dáhùn. Irú àwọn ìrírí wọ̀nyí ń fún wa níṣìírí lọ́pọ̀lọpọ̀.”
Gẹ́gẹ́ bí Sid àti Harold—àti gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi gbogbo ń lo gbogbo àǹfààní láti tan ìhìn iṣẹ́ wọn tí ó ṣe pàtàkì kálẹ̀. Nípa báyìí, wíwàásù “ìhìn rere” náà ń bá a nìṣó “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”—Mátíù 24:14.