Brunost—Wàràkàṣì Aládùn Láti Norway
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NORWAY
TẸ̀ LÉ mi ká lọ sí agbo ilé kékeré kan ní Norway. Bọ́tà, búrẹ́dì tí a fi ògidì ọkà ṣe, àti onírúurú àwọn ohun jíjẹ mìíràn wà lórí tábìlì fún oúnjẹ òwúrọ̀. Àmọ́, dúró ná! Ó ṣì ku ohun kan. Kò pẹ́ tí ẹnì kan béèrè pé: ‘Brunost dà?’
Lára gbogbo ohun tí a ń kó sínú búrẹ́dì ẹlẹ́ran, títí kan ọgọ́rọ̀ọ̀rún oríṣiríṣi wàràkàṣì tó wà, brunost, tàbí wàràkàṣì aláwọ̀ ilẹ̀, yàtọ̀ sí gbogbo wàràkàṣì yòó kù. A máa ń rí i ní agboolé tó pọ̀ jù lọ ní Norway, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìdá mẹ́rin gbogbo wàràkàṣì tí wọ́n ń jẹ ní orílẹ̀-èdè yí. Lọ́dọọdún, àwọn ará Norway ń jẹ 12,000 tọ́ọ̀nù brunost, tí ó túmọ̀ sí ìpíndọ́gba tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó kìlógíráàmù 3 fún ẹnì kọ̀ọ̀kan. Lákòókò kan náà, nǹkan bíi 450 tọ́ọ̀nù brunost ni a ń kó lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè bí Australia, Kánádà, Denmark, Sweden, àti United States.
Ní hòtẹ́ẹ̀lì kan ní Norway ni ọ̀pọ̀ àwọn àjèjì ti kọ́kọ́ tọ́ brunost wò. Yálà wàràkàṣì yí rí roboto tàbí ó jẹ́ onígun mẹ́rin, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máa ń wà lára oúnjẹ òwúrọ̀ nígbà gbogbo—tí ó sì máa ń ní ohun ìgéǹkan kékeré tí a ń pè ní ostehøvel. A máa ń fi gé awẹ́ pẹlẹbẹ lórí wàràkàṣì náà.
Ṣùgbọ́n kí ni brunost ní gidi? Láti mọ̀, a bẹ seter, tàbí oko pápá orí òkè ńlá kan nígbà ẹ̀ẹ̀rùn wò, níbi tí wọ́n ṣì ti ń ṣe brunost lọ́nà ti àtilẹ̀wá.
Ṣíṣe Brunost Lọ́nà Ti Àtilẹ̀wá
Nígbà tí a dé, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fún wàrà àwọn ewúrẹ́ náà ni. Wọ́n jẹ́ kí a bá obìnrin tí ń ṣe wàràkàṣì náà ṣiṣẹ́ bí ó ti ń sọ wàrà ewúrẹ́ náà di wàràkàṣì aládùn.
Wọ́n máa ń fún wàrà àwọn ewúrẹ́ náà lẹ́ẹ̀mejì lójúmọ́, wọ́n sì ń da wàrà náà sínú kẹ́tùrù ńlá kan. Wọn óò sè é gbóná dé ìwọ̀n 30 lórí òṣùwọ̀n Celsius, wọ́n óò sì da èròjà rennin, èròjà tí ń mú kí wàrà dì, sí i. Wàrà dídì funfun náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí í yà sọ́tọ̀ kúrò lára wàrà tó kù, tí a ń pè ní omi wàrà. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára omi wàrà náà ni wọ́n ṣiṣẹ́ takuntakun láti yọ́ kúrò lára wàràkàṣì náà, wọ́n sì ń kó wàràkàṣì funfun náà jọ sínú àwọn ọpọ́n onígi mìíràn láti di wàràkàṣì funfun ti ewúrẹ́ ilẹ̀ Norway. Níwọ̀n bí wàràkàṣì náà ti jẹ́ “kògbókògbó,” ó ní láti pọ́n fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta kí a tó lè lò ó.
Nígbà náà, wàràkàṣì aláwọ̀ ilẹ̀ tàbí brunost náà ńkọ́? Ní gidi, a óò wá da wàrà àti ọ̀rá wàrà mọ́ ògidì omi wàrà náà, a óò sì wá se àdàlú yìí. A gbọ́dọ̀ máa rò ó léraléra. Bí àdàlú náà ti ń hó, púpọ̀ lára ooru àdàlú náà yóò gbẹ, àwọ̀ omi wàrà náà yóò sì yí pa dà. Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta, yóò di wàrà aláwọ̀ ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, a óò kó o kúrò nínú kẹ́tùrù náà, a óò sì máa rò ó lọ nígbà tí wàrà náà bá ń tutù. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, tẹ̀ ẹ́ rubutu, lẹ́yìn náà, a óò wá ṣù ú. Láìdà bíi ti wàràkàṣì funfun, brunost kò ní láti pọ́n. Lọ́jọ́ kejì, gbàrà tí a bá ti kó wàràkàṣì aláwọ̀ ilẹ̀ náà kúrò nínú ìṣù tí ó wà, ó ti délẹ̀ láti tẹ́ gbogbo àwọn olólùfẹ́ wàràkàṣì aláwọ̀ ilẹ̀ ti ewúrẹ́ ilẹ̀ Norway lọ́rùn.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìlànà bí a ṣe ń ṣe é ṣì jẹ́ bákan náà, ọ̀nà tí a ń gbà ṣe wàràkàṣì látijọ́ yìí ni a ti fi ìmújáde aládàá-ńlá àfẹ̀rọṣe kan rọ́pò. Oko ìpèsè oúnjẹ tí ń ti ara ẹran jáde, tí ó wà lórí òkè náà, ni àwọn oko ìpèsè oúnjẹ tí ń ti ara ẹran jáde tí ń lo ohun èlò ìṣiṣẹ́ aláìṣísíta àti àwọn ìdáná tí ń lo ooru gbígbóná dípò àwọn kẹ́tùrù onírin ṣíṣísílẹ̀ tí a ń lò látijọ́ náà.
Ìhùmọ̀ Kan Láti Ọ̀wọ́ Àwọn Ará Norway
Báwo ni brunost ti pilẹ̀ ṣẹ̀? Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1863, obìnrin afúnwàrà náà, Anne Haav, tí ń gbé Àfonífojì Gudbrandsdalen, gbìyànjú àṣeyẹ̀wò kan tí ó di ìlọsíwájú ìmọ̀ ìṣe. Ó fi ògidì wàrà màlúù ṣe wàràkàṣì, ó sì ronú nípa dída ọ̀rá wàrà sí omi wàrà náà kí ó tó sè é. Ohun tí ó gbé jáde ni wàràkàṣì aláwọ̀ ilẹ̀, tí ó ládùn, tí ọ̀rá wà nínú rẹ̀ dáradára. Lẹ́yìn náà, àwọn ènìyàn tún bẹ̀rẹ̀ sí í lo wàrà ewúrẹ́ àti àdàlù wàrà ewúrẹ́ àti wàrà màlúù gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀ fún ìṣèmújáde rẹ̀. Ní 1933, nígbà tí Anne Haav ti darúgbó kùjẹ́kùjẹ́, wọ́n fi àkànṣe ẹ̀bùn ẹ̀yẹ ọba Norway dá a lọ́lá fún ìhùmọ̀ rẹ̀.
Lónìí, oríṣi àkànṣe brunost mẹ́rin ló wà: Ekte Geitost, wàràkàṣì gidi láti ara ewúrẹ́, tí a fi ògidì wàrà ewúrẹ́ ṣe. Gudbrandsdalsost, tí ó wọ́pọ̀ jù lọ, ni a sọ lórúkọ àfonífojì náà, ó sì ní wàrà ewúrẹ́ ní ìwọ̀n ìpín 10 sí 12 nínú ọgọ́rùn-ún tí ìyókù sì jẹ́ wàrà màlúù. Fløtemysost, wàràkàṣì ọlọ́ràá olómi wàrà, tí a fi ògidì wàrà màlúù ṣe. Prim, wàràkàṣì aláwọ̀ ilẹ̀ olómi wàrà, fúlọ́fúlọ́, tí a fi wàrà màlúù ṣe, àmọ́ a fi ṣúgà sí i. A kò sè é tó àwọn oríṣi yòó kù. Ọ̀rá inú rẹ̀, ìṣùpọ̀ rẹ̀, àti àwọ̀—bí wàràkàṣì náà yóò ṣe mọ́ láwọ̀ tó tàbí bí yóò ṣe dúdú láwọ̀ tó—sinmi lórí ìṣirò ìfiwéra omi wàrà, ọ̀rá wàrà, àti wàrà àti lórí àkókò tí a fi sè é. Ohun tó mú kí brunost náà ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ ní gidi ni pé, omi wàrà ni wọ́n fi ṣe é, kì í ṣe èròjà casein, ti wàrà. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ní ọ̀pọ̀ ṣúgà inú wàrà nínú, tí ń fún un ní ìtọ́wò dídùn, bíi ti midin-mín-ìndìn bàbádúdú.
Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará Norway, brunost kì í wulẹ̀ ṣe oúnjẹ aládùn kan ṣùgbọ́n apá kan oúnjẹ òòjọ́ wọn tí ó pọn dandan. Nísinsìnyí, o lè fẹ́ láti tọ́ àkànṣe ìmújáde ilẹ̀ Norway yí wò fúnra rẹ.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ṣíṣe Brunost Tìrẹ Fúnra Rẹ
Ṣíṣe brunost aládùn jẹ́ ọgbọ́n ọnà tí ó nílò ìrírí púpọ̀. Dájúdájú, àṣírí òwò ni àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó wà nínú ṣíṣe oríṣiríṣi brunost. Àmọ́, bóyá o fẹ́ ṣe àṣeyẹ̀wò kan, kí o sì ṣe brunost tìrẹ? Ìlànà yí, pẹ̀lú àròpọ̀ lítà wàrà méje àti ọ̀rá wàrà sì jẹ́ ìpìlẹ̀, yóò fúnni ní nǹkan bíi 700 gíráàmù brunost àti 500 gíráàmù wàràkàṣì funfun bí ìmújáde tí a kò rò tẹ́lẹ̀.
1. Se wàrà lítà márùn-ún dé ìwọ̀n ìgbóná 30 lórí òṣùwọ̀n Celsius, da èròjà rennin sí i, kí o sì dúró fún nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Lábẹ́ ipò yí, wàrà náà yóò bẹ̀rẹ̀ sí í dì.
2. Gé wàràkàṣì tí ó wà lọ́tọ̀ náà sí ìgọ̀n, sì máa fìṣọ́ra rò ó. Èyí jẹ́ láti yọ omi wàrà náà kúrò lára wàràkàṣì náà. Ó lè ṣàǹfààní láti tún gbé wàrà náà gbóná sí i.
3. Yọ wàràkàṣì náà kúrò nípa sísẹ́ omi wàrà náà. A lè lo wàràkàṣì náà bíi wàràkàṣì rírọ̀ tàbí kí a fún un, kí a sì ṣù ú fi ṣe wàràkàṣì funfun.
4. Àdàlù omi wàrà tí a sè náà sábà máa ń ní nǹkan bí ìdá méjì nínú mẹ́ta omi wàrà àti ìlàta wàrà àti ọ̀rá wàrà. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, o ní láti da nǹkan bíi lítà méjì ọ̀rá wàrà àti/tàbí wàrà sí i. Lo dẹ̀sílítà mẹ́rin sí márùn-ún ọ̀rá wàrà láti rí wàràkàṣì lásán tí ó ní ọ̀rá nínú dáradára yọ. Ìwọ̀n ọ̀rá wàrà tí ó kéré yóò yọ wàràkàṣì tí kò lọ́ràá tó bẹ́ẹ̀.
5. Jẹ́ kí àdàlù náà máa hó bí o ti ń rò ó. Ó ń gba wákàtí mélòó kan kí omi wàrà náà tó hó tó. Lẹ́yìn náà, yóò dì dáadáa. Ohun tí o fi lè mọ̀ èyí lè jẹ́ pé o lè rí ìsàlẹ̀ kẹ́tùrù náà nígbà tí o ń rò ó. Bí omi wàrà náà bá ṣe hó tó ni wàràkàṣì náà yóò dì tó, tí yóò sì dúdú tó.
6. Da wàrà aláwọ̀ ilẹ̀ náà kúrò nínú kẹ́tùrù, kí o sì rò ó dáradára bí ó ti ń tutù. Èyí ṣe pàtàkì, kí wàràkàṣì náà má baà ṣe ṣákaṣàka.
7. Tí ó bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tutù tán, wàrà náà yóò ti dì gan-an débi pé a lè lọ̀ ọ́, kí a sì ṣù ú. Jẹ́ kí ó wà nílẹ̀ mọ́jú.
Gẹ́gẹ́ bí àfikún oúnjẹ, brunost máa ń dùn jù lọ bí a bá gé e pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ, ó sì máa ń dára jù lórí búrẹ́dì gbígbóná tàbí kéèkì rírọ̀.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure TINE Norwegian Dairies