ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwwd àpilẹ̀kọ 43
  • Wàrà Ọmú Ìyá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wàrà Ọmú Ìyá
  • Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • ‘Fífi Ọwọ́ Títọ̀nà Mú Ọ̀rọ̀ Òtítọ́’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Brunost—Wàràkàṣì Aládùn Láti Norway
    Jí!—1997
Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
ijwwd àpilẹ̀kọ 43
Ìyá kan gbé ọmọ ẹ̀ lọ́wọ́, ó ń wò ó bó ṣe ń sùn.

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Wàrà Ọmú Ìyá

Ìwé ìwádìí kan tí wọ́n ṣe fáwọn agbẹ̀bí sọ pé: “A ò lè fi wàrà màlúù tí wọ́n pò pọ̀ mọ́ àwọn èròjà aṣaralóore míì fáwọn ìkókó wé wàrà tó wà nínú ọmú ìyá láéláé.” Ohun kan tó mú kí wàrà ọmú ìyá ṣàrà ọ̀tọ̀ ni pé bí ìkókó náà ṣe ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni wàrà ọmú ìyá ẹ̀ á máa yí pa dà kó lè bá ohun tí ọmọ náà nílò mu.

Rò ó wò ná: Tí ọmọ kan bá ń mu ọmú ìyá ẹ̀, èròjà tó wà nínú wàrà náà nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í mu ún máa yàtọ̀ sí èyí tó máa wà níbẹ̀ nígbà tó fi máa mu ún tán. Bí àpẹẹrẹ, gbàrà tí ọmọ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í mu ọmú, wàrà náà máa ń ní ọ̀pọ̀ èròjà protein, mineral, vitamins àti omi. Àmọ́ bó ṣe ń mu ọmú náà lọ, àwọn èròjà tó wà nínú wàrà náà á yí pa dà ní ti pé ọ̀rá inú ẹ̀ máa pọ̀ sí i, ìyẹn sì máa jẹ́ kí ọmọ náà yó dáadáa. Kódà, ọjọ́ orí ọmọ kan àti bí ojú ọjọ́ ṣe rí máa ń mú kí wàrà ọmú ìyá yí pa dà.

Àwọn èròjà kan irú bíi melatonin tó máa ń jẹ́ kéèyàn sùn dáadáa máa ń pọ̀ nínú wàrà ọmú ìyá lálẹ́, àwọn èròjà míì sì máa ń pọ̀ lójúmọmọ. Bí àwọn èròjà yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ ló ń pinnu ìgbà tí ọmọ ìkókó kan máa sùn àtìgbà tó máa jí.

Tí obìnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, fún bí ọjọ́ mélòó kan, wàrà yẹ́lò tí wọ́n máa ń pè ní colostrum ló máa ń jáde nínú ọmú rẹ̀. Wàrà yìí máa ń tètè dà, ó sì ní ọ̀pọ̀ èròjà aṣaralóore. Torí náà, tó bá tiẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lọmọ náà mu, ó máa ṣe é láǹfààní gan-an. Wàrà yìí tún ní ọ̀pọ̀ èròjà tó ń gbógun ti àrùn, òun ló sì máa ń dáàbò bo ọmọ náà lọ́wọ́ àwọn kòkòrò àrùn tó lè ṣe é ní jàǹbá. Bákan náà, ó tún máa ń jẹ́ káwọn ọmọ lè yàgbẹ́ dáadáa, kí inú wọn lè mọ́.

Tí obìnrin kan bá tiẹ̀ bí ìbejì, kò sídìí láti ṣàníyàn pé bóyá wàrà náà ò ní tó fáwọn ọmọ náà torí pé iye wàrà táwọn ọmọ yẹn nílò ni ọmú obìnrin náà máa pèsè.

Kí lèrò ẹ? Ṣé àwọn èròjà tó wà nínú wàrà ọmú ìyá àtàwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́