ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 4/1 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ O Rántí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Wàrà Ọmú Ìyá
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • “Òfin Jèhófà Pé”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Òfin Tí Ó Wà Ṣáájú Kristi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 4/1 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú àṣẹ tó wà nínú Ẹ́kísódù 23:19 tó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ se ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀”?

Àṣẹ tó wà nínú Òfin Mósè yìí, tó sì fara hàn nígbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì, lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ohun tó tọ́, ó tún jẹ́ ká mọ bó ṣe ní ìyọ́nú àti ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn tó. Ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìjọsìn èké gan-an.—Ẹ́kísódù 34:26; Diutarónómì 14:21.

Kéèyàn se ọmọ ewúrẹ́ tàbí ọmọ ẹran mìíràn nínú wàrà ìyá rẹ̀ yóò jẹ́ ohun tó lòdì sí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ṣètò àwọn nǹkan. Ìdí tí Ọlọ́run fi pèsè wàrà ìyá ni kí ọmọ lè mú un kó sì lè jẹ́ kí ọmọ náà dàgbà. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé, síse ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀ yóò jẹ́ “àìbọ̀wọ̀ fún àjọṣe tí Ọlọ́run fi sí àárín òbí àti ọmọ tó sì fẹ́ kó wà bẹ́ẹ̀.”

Láfikún sí i, àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí síse ọmọ ẹran nínú wàrà ìyá rẹ̀ jẹ́ ètùtù kan táwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣe kí òjò lè rọ̀. Tó bá jẹ́ pé ètùtù táwọn abọ̀rìṣà ń ṣe ni lóòótọ́, a jẹ́ pé òfin náà yọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú lílọ́wọ́ sí àwọn ìwà òpònú àti ìwà ìkà tó máa ń wáyé nínú ìjọsìn àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Òfin Mósè dìídì sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ rìn nínú ìlànà àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn.—Léfítíkù 20:23.

Ju gbogbo rẹ̀ lọ, òfin yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run oníyọ̀ọ́nú. Ní ti gidi, òfin náà tún láwọn àṣẹ mìíràn tó ka ìwà ìkà sáwọn ẹranko léèwọ̀. Èyí ò ní jẹ́ kéèyàn ṣe ohun tó lòdì sí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ṣètò àwọn nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, òfin náà ní àwọn àṣẹ tó sọ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ fi ẹran kan tí kò bá tíì lo ọjọ́ méje tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́dọ̀ ìyá rẹ̀ rúbọ. Ó tún sọ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ pa ẹran kan àti ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà, bẹ́ẹ̀ náà léèyàn ò gbọ́dọ̀ kó ìyá ẹyẹ kan pa pọ̀ mọ́ àwọn ẹyin tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ nínú ìtẹ́.—Léfítíkù 22:27, 28; Diutarónómì 22:6, 7.

Ó ṣe kedere pé Òfin Mósè kì í kàn án ṣe àkójọ àwọn àṣẹ àtàwọn ìkàléèwọ̀ rẹpẹtẹ kan lásán. Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní òfin náà ni pé, àwọn ìlànà rẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ ìwà tó bójú mu, ìyẹn sì fi àwọn ànímọ́ ṣíṣeyebíye tí Jèhófà ní hàn.—Sáàmù 19:7-11.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

© Timothy O’Keefe/Index Stock Imagery

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́